Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máàkù Ò Rẹ̀wẹ̀sì

Máàkù Ò Rẹ̀wẹ̀sì

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Máàkù Ò Rẹ̀wẹ̀sì

MÁÀKÙ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Bíbélì mẹ́rin tó sọ nípa ìtàn ìgbésí ayé Jésù. Ìwé Máàkù ló kúrú jù nínú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, òun ló sì rọrùn jù láti kà. Ta ni Máàkù? Ǹjẹ́ o rò pé Máàkù mọ Jésù?— a Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìṣòro tí Máàkù dojú kọ, ká sì wo ìdí tí ẹ̀sìn Kristẹni kò fi sú u.

Ẹ̀yìn ìgbà tí Hẹ́rọ́dù Àgírípà Ọba fi àpọ́sítélì Pétérù sẹ́wọ̀n ni Bíbélì kọ́kọ́ dárúkọ Máàkù. Ó ṣẹlẹ̀ pé lóru ọjọ́ kan, áńgẹ́lì kan dá Pétérù sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó lọ sílé Màríà ìyá Máàkù tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù. Nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn tí wọ́n pa Jésù nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni ni áńgẹ́lì yẹn dá Pétérù sílẹ̀.—Ìṣe 12:1-5, 11-17.

Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Pétérù fi lọ sílé Màríà?— Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nítorí ó mọ àwọn tó wà nínú ìdílé Màríà àti pé ó mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa ń ṣèpàdé nílé Màríà. Ó ti pẹ́ tí Bánábà mọ̀lẹ́bí Máàkù ti di ọmọ ẹ̀yìn, á fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ṣáájú ìgbà Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni tàbí nígbà yẹn gan-an. Bíbélì ròyìn ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí Bánábà fi hàn sáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn nígbà yẹn. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Jésù mọ Bánábà àti Màríà tó jẹ́ ìyá Máàkù àti Máàkù ọmọ rẹ̀.—Ìṣe 4:36, 37; Kólósè 4:10.

Nínú ìwé Ìhìn Rere tí Máàkù kọ, ó kọ̀wé pé lóru ọjọ́ tí wọ́n mú Jésù, ọ̀dọ́kùnrin kan wà níbẹ̀ tó wọ aṣọ láti “bo ìhòòhò ara rẹ̀.” Máàkù sọ pé nígbà tó di pé àwọn ọ̀tà tó mú Jésù fẹ́ mú ọ̀dọ́kùnrin náà, ọ̀dọ́kùnrin náà sá lọ. Ta lo rò pé ó ṣeé ṣe kí ọ̀dọ́kùnrin yẹn jẹ́?— Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Máàkù! Ó fi hàn pé nígbà tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi ibi tí wọ́n ti jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ lóru ọjọ́ yẹn, ó jọ pé Máàkù sáré wá ẹ̀wù kan wọ̀, ó sì tẹ̀ lé wọn.—Máàkù 14:51, 52.

Ká sòótọ́, Máàkù láǹfààní láti bá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run rìn. Ó ṣeé ṣe kó wà níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ dà sórí àwọn àpọ́sítélì nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ó sì tún bá àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, bíi Pétérù rìn. Ó tún tẹ̀ lé Bánábà mọ̀lẹ́bí rẹ̀ nígbà tó lọ mú Sọ́ọ̀lù mọ Pétérù ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí Jésù fara han Sọ́ọ̀lù nínú ìran. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Bánábà lọ sí Tásù láti lọ wá Pọ́ọ̀lù rí.—Ìṣe 9:1-15, 27; 11:22-26; 12:25; Gálátíà 1:18, 19.

Lọ́dún 47 Sànmánì Kristẹni, wọ́n yan Bánábà àti Sọ́ọ̀lù láti máa ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì, wọ́n sì mú Máàkù dání. Àmọ́ nítorí ìdí kan tá ò mọ̀ Máàkù fi wọ́n sílẹ̀ ó sì padà sí Jerúsálẹ́mù. Nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, inú bí Sọ́ọ̀lù, ẹni tí wọ́n wá forúkọ Róòmù rẹ̀ tó ń jẹ́ Pọ́ọ̀lù mọ̀, kò sì fojú kékeré wo ohun tí Máàkù tá a tún mọ̀ sí Jòhánù ṣe yìí.—Ìṣe 13:1-3, 9, 13.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà padà láti ìrìn àjò míṣọ́nnárì yìí, wọ́n ròyìn àṣeyọrí tó bùáyà tí wọ́n ṣe. (Ìṣe 14:24-28) Ní oṣù bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì ṣètò láti lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n wàásù fún tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn. Ó wu Bánábà pé kí wọ́n mú Máàkù dání, àmọ́ ǹjẹ́ o mọ ohun tí Pọ́ọ̀lù rò?— “Pọ́ọ̀lù kò ronú pé ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” nítorí pé Máàkù ti fi wọ́n sílẹ̀ tó sì padà lọ sílé nígbà kan rí. Ó dájú pé ohun tó wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà yóò ba Máàkù lọ́kàn jẹ́!

Bó ṣe di pé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà gbaná jẹ nìyẹn, lẹ́yìn “ìbújáde ìbínú mímúná,” wọ́n pínyà, kálukú sì bá tiẹ̀ lọ. Bánábà mú Máàkù dání, wọ́n lọ wàásù ní Kípírọ́sì, àmọ́ Pọ́ọ̀lù mú Sílà ní tiẹ̀, wọ́n sì lọ padà bẹ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn wò gẹ́gẹ́ bí ètò tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀. O ò rí i pé ọkàn Máàkù ti ní láti bà jẹ́ gidigidi nítorí ó dá ìjà sílẹ̀ láàárín Pọ́ọ̀lù àti Bánábà!—Ìṣe 15:36-41.

A ò mọ ìdí tí Máàkù fi padà sílé nígbà àkọ́kọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nítorí ìdí pàtàkì kan ni. Bó ti wù kó rí, ó hàn gbangba pé ó dá Bánábà lójú pé Máàkù kò tún ní padà mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì lọ̀rọ̀ rí lóòótọ́. Máàkù ò rẹ̀wẹ̀sì! Nítorí pé lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó bá Pétérù rìnrìn àjò míṣọ́nnárì lọ sí Bábílónì, ìlú tó jìnnà réré sí ilé rẹ̀. Láti ibẹ̀ ni Pétérù ti kọ lẹ́tà ránṣẹ́ láti fi kí àwọn ará, ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú lẹ́tà náà pé: “Máàkù ọmọkùnrin mi ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”—1 Pétérù. 5:13.

Wo bí Pétérù àti Máàkù ti sún mọ́ra wọn tó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run! Tá a bá ka ìwé Ìhìn Rere Máàkù a óò rí ẹ̀rí èyí. Àwọn nǹkan kan wà tí Máàkù sọ nínú ìwé náà tó jẹ́ pé Pétérù ló fojú ara rẹ̀ rí i nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun táwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa ìjì líle kan tó wáyé ní Òkun Gálílì. Máàkù sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ibi tí Jésù sùn sí nínú ọkọ̀ náà àti ohun tó sùn lé lórí. Ẹni tó bá jẹ́ apẹja bíi Pétérù nìkan ló lè kíyè sí èyí. Ká lè rí bọ́rọ̀ yìí ṣe jẹ́ gan-an, o ò ṣe jẹ́ ká kúkú jọ ka ìtàn yìí pa pọ̀ nínú Mátíù 8:24; Máàkù 4:37, 38; àti Lúùkù 8:23, ká sì fi àwọn ẹsẹ wọ̀nyí wéra wọn.

Nígbà tó yá tí wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù, ó gbóríyìn fún Máàkù fún bó ṣe dúró ti òun gbágbáágbá. (Kólósè 4:10, 11) Nígbà tí wọ́n tún fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n níbẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ó kọ̀wé sí Tímótì pé kó mú Máàkù wá. Ó ṣàlàyé pé: “Ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́.” (2 Tímótì 4:11) Ká sòótọ́, Máàkù láǹfààní láti sin Ọlọ́run lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an nítorí pé kò rẹ̀wẹ̀sì!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà tó o bá ń kàwé pẹ̀lú ọmọ rẹ, tó o bá rí àmì yìí (—), ohun tó ń sọ ni pé kó o dánú dúró díẹ̀, kó o jẹ́ kí ọmọ náà sọ èrò ọkàn rẹ̀.

Ìbéèrè:

Ibo ni Máàkù gbé, kí sì nìdí tó o fi lè sọ pé ó ṣeé ṣe kó mọ Jésù?

Ta lẹni tó ran Máàkù lọ́wọ́ tó sì dúró tì í?

Kí ni ì bá ti mú kí Máàkù rẹ̀wẹ̀sì?

Báwo la ṣe mọ̀ pé Máàkù wá dẹni tó rí ojú rere Pọ́ọ̀lù nígbà tó yá?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ta ló ṣeé ṣe kí ọ̀dọ́kùnrin yìí jẹ́? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí i, kí sì nìdí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn àǹfààní wo ni Máàkù ní nítorí pé kò rẹ̀wẹ̀sì?