Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun A Rí Là Ń Gbà Gbọ́

Ohun A Rí Là Ń Gbà Gbọ́

Ohun A Rí Là Ń Gbà Gbọ́

“Àwọn onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀ ni àwọn tó gbà pé èèyàn ò lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àti ìwàláàyè ọjọ́ iwájú, táwọn ẹlẹ́sìn Kristi àtàwọn ẹlẹ́sìn míì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Tàbí kẹ̀, téèyàn bá tiẹ̀ máa mọ̀ ọ́n, kì í ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.”—Ọ̀MỌ̀RÀN KAN TÓRÚKỌ RẸ̀ Ń JẸ́ BERTRAND RUSSELL. ỌDÚN 1953.

ỌKÙNRIN tó kọ́kọ́ gbé èrò pé “Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀” jáde jẹ́ onímọ̀ nípa ẹranko. Orúkọ rẹ̀ ni Thomas Huxley. Ọdún 1825 ni wọ́n bí i. Ó gbé ayé nígbà ayé ọ̀gbẹ́ni Charles Darwin, ó sì wà lára àwọn tó gbà pé èèyàn àti gbogbo àgbáyé ṣàdédé wà ni, pé kò sẹ́ni tó dá wọn. Lọ́dún 1863, Huxley kọ̀wé pé òun ò rí ẹ̀rí pé Ọlọ́run kan wà tó “nífẹ̀ẹ́ wa tó sì ń bójú tó wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe sọ.”

Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí fara mọ́ èrò àwọn olókìkí èèyàn yẹn, wọ́n ń sọ pé kìkì ohun táwọn bá rí làwọn máa gbà gbọ́. Wọ́n ní ìwà omùgọ̀ gbáà ló jẹ́ kéèyàn gba ẹnì kan gbọ́ tàbí gba ohun kan gbọ́ láìsí ẹ̀rí.

Ǹjẹ́ ohun tí Bíbélì sọ fún wa ni pé ká kàn gbà pé Ọlọ́run wà láìsí ẹ̀rí tó fi hàn bẹ́ẹ̀? Rárá o. Bíbélì sọ pé ìwà òmùgọ̀ gbáà ló jẹ́ téèyàn bá gba ohun kan gbọ́ láìsí ẹ̀rí. Ó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.

Ṣé Ọlọ́run wà lóòótọ́? Ǹjẹ́ ẹ̀rí èyíkéyìí wà tó fi hàn pé Ọlọ́run wà, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé bóyá ó nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì ń bójú tó wa?

Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run Fara Hàn

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ń bá àwọn ọ̀mọ̀wé ará Áténì sọ̀rọ̀, ó ní, Ọlọ́run “dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀.” Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn oníyèmejì tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí pé ọ̀rọ̀ àwa èèyàn jẹ Ọlọ́run lógún ní ti pé, “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:24-27.

Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi gbà dájú pé Ọlọ́run wà àti pé ọ̀rọ̀ àwa èèyàn jẹ ẹ́ lógún? Pọ́ọ̀lù sọ ìdí kan fún wa nínú ìwé tó kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù. Ó sọ nípa Ọlọ́run pé: “Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá.”—Róòmù 1:20.

Àwọn àpilẹ̀kọ mẹ́ta tó tẹ̀ lé èyí yóò sọ nípa mẹ́ta lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, èyí tó hàn kedere nínú àwọn ohun tó dá. Bó o ti ń gbé àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí yẹ̀ wò, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ẹ̀kọ́ wo ni mo lè rí kọ́ látinú mímọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run wọ̀nyí?’

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

Bíbélì kò sọ pé ká kàn gbà pé Ọlọ́run wà láìsí ẹ̀rí?