Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìràwọ̀ Ń Fi Agbára Ọlọ́run Hàn

Àwọn Ìràwọ̀ Ń Fi Agbára Ọlọ́run Hàn

Àwọn Ìràwọ̀ Ń Fi Agbára Ọlọ́run Hàn

“Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.”—AÍSÁYÀ 40:26.

OÒRÙN jẹ́ oríṣi ìràwọ̀ kan tó tóbi, àmọ́ àwọn ìràwọ̀ mìíràn wà tó tún tóbi ju oòrùn lọ. Síbẹ̀ náà, oòrùn tóbi ju ayé lọ ní ìlọ́po ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlógún àtààbọ̀ [330,000]. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìràwọ̀ tó sún mọ́ ayé ni kò tóbi tó oòrùn. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìràwọ̀ míì bíi èyí tí wọ́n ń pè ní V382 Cygni tóbi ju oòrùn lọ ní ìlọ́po mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.

Báwo ni agbára tó ń jáde láti ara oòrùn ṣe pọ̀ tó? Wo bí iná kan ti ní láti lágbára tó bó o bá fi kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún jìnnà sí i, àmọ́ tó ṣì ń rà ọ́ lára burúkú-burúkú. Nǹkan bí àádọ́jọ mílíọ̀nù [150,000,000] kìlómítà ni oòrùn fi jìnnà sí ayé. Síbẹ̀ lọ́jọ́ tí oòrùn bá mú dáadáa, ìwọ̀n bó ṣe gbóná tó lè ta èèyàn lára gan-an! Ṣíún báyìí lára agbára oòrùn ló ń dé sí ayé, síbẹ̀ ìwọ̀nba díẹ̀ yìí ti tó láti gbé ẹ̀mí àwọn ohun alààyè ró lórí ilẹ̀ ayé.

Kódà, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣírò rẹ̀ pé àpapọ̀ agbára tó ń jáde lára oòrùn nìkan ti tó láti gbé ẹ̀mí àwọn ohun alààyè ró nínú ọ̀kẹ́ àìmọye irú ayé wa yìí. Tún wo ọ̀nà míì tá a lè gbà mọ bí agbára oòrùn ṣe tó. Ilé iṣẹ́ tó ń sọ ìròyìn nípa ojú ọjọ́ nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé, tá a bá tọ́jú agbára tó ń jáde lára oòrùn pa mọ́ ní ìṣẹ́jú àáyá kan péré, “iye agbára yẹn á tó agbára iná mànàmáná” tí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà máa lò ní “mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ọdún.”

Ohun kan wà nínú oòrùn tó máa ń mú kí agbára tó kàmàmà jáde. Oòrùn tóbi gan-an ni, agbára tó sì ń ti inú rẹ̀ wá pọ̀ débi pé yóò gba àìmọye mílíọ̀nù ọdún kí agbára tó ń jáde bọ náà tó lè dé ìta. Ilé iṣẹ́ tó ń sọ ìròyìn nípa ojú ọjọ́ nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ nínú ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì wọn pé: “Bó bá ṣẹlẹ̀ pé oòrùn ṣíwọ́ agbára tó ń mú jáde lónìí yìí, yóò tó àádọ́ta mílíọ́nù ọdún ká tó lè mọ̀ lórí ilẹ̀ ayé pé oòrùn ti ṣíwọ́ iṣẹ́!”

Gbé kókó yìí yẹ̀ wò ná: Tó o bá gbójú wòkè lọ́wọ́ alẹ́ wàá rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìràwọ̀ lójú ọ̀run. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìràwọ̀ yìí ló ń mú agbára tó bùáyà jáde, bíi ti oòrùn. Ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe sì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀kẹ́ àìmọye ìràwọ̀ ló wà lójú ọ̀run!

Ibo làwọn ìràwọ̀ yìí ti wá? Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń ṣèwádìí gbà pé fún àwọn ìdí tí wọn kò tíì lóye síbẹ̀, ńṣe ni ayé àti ìsálú ọ̀run kan ṣàdédé wà, láti nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́rìnlá ọdún sẹ́yìn. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó yìí ṣe kedere, ó ní: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì. 1:1) Láìsí àní-àní, Ẹni tó dá àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n jẹ́ nǹkan àrágbáyamúyamù yìí, la lè sọ ní tòótọ́ pé ó jẹ́ alágbára tó gadabú.— Aísáyà 40:26.

Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Lo Agbára Rẹ̀

Jèhófà Ọlọ́run máa ń fi agbára rẹ̀ ran àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ takuntakun kó lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù kì í ṣe àkàndá èèyàn, èèyàn bíi tiwa náà ni, àmọ́ ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere láìka inúnibíni gbígbóná janjan tó dojú kọ sí. Báwo ló ṣe ṣe é? Ó sọ pé Ọlọ́run fún òun ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”—2 Kọ́ríńtì 4:7-9.

Jèhófà Ọlọ́run tún lo agbára rẹ̀ láti pa àwọn tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí àwọn ìlànà tó fi lélẹ̀ lórí ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù. Jésù Kristi mẹ́nu kan ìparun Sódómù àti Gòmórà láti fi ṣe ẹ̀rí pé àwọn èèyàn burúkú nìkan ni Jèhófà máa ń fi agbára rẹ̀ pa run. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé, láìpẹ́ Jèhófà tún máa lo agbára rẹ̀ láti pa àwọn tí wọ́n bá ń ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run run.—Mátíù 24:3, 37-39; Lúùkù 17:26-30.

Ẹ̀kọ́ Wo Lo Rí Kọ́?

Tó o bá ronú dáadáa lórí bí àwọn ìràwọ̀ ṣe ń fi agbára Ọlọ́run hàn, èyí lè mú kó o ní irú èrò tí Dáfídì Ọba ní, ó sọ pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn, àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?”—Sáàmù 8:3, 4.

Tá a bá ronú lórí bí ayé àti ìsálú ọ̀run yìí ṣe tóbi tó, a óò rí i pé àwa èèyàn kéré gan-an ni, èyí á sì jẹ́ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Síbẹ̀, èyí ò fi hàn pé àwa èèyàn ò já mọ́ nǹkan kan rárá o. Jèhófà mí sí wòlíì Aísáyà láti ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú yìí, ó ní: “[Ọlọ́run] ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga. Àárẹ̀ yóò mú àwọn ọmọdékùnrin, agara yóò sì dá wọn, àwọn ọ̀dọ́kùnrin pàápàá yóò sì kọsẹ̀ dájúdájú, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà. Wọn yóò fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì. Wọn yóò sáré, agara kì yóò sì dá wọn; wọn yóò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.”—Aísáyà 40:29-31.

Tó o bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ọlọ́run yóò fún ọ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó o lè máa bá a lọ láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, wàá ní láti béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni o. (Lúùkù 11:13) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, o lè fara da àdánwò èyíkéyìí, wàá sì ní okun tí wàá fi lè máa ṣe ohun tí ó tọ́.—Fílípì 4:13.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, o lè ní okun tí wàá fi lè máa ṣe ohun tí ó tọ́

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Whirlpool, ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Píleyádésì; ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Óríónì Nebula, ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Andromeda

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Oòrùn tóbi ju ayé lọ ní ìlọ́po ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlógún àtààbọ̀ [330,000]

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]

Píleyádésì: NASA, ESA àti AURA/Caltech; gbogbo àwọn tó kù lókè: National Optical Astronomy Observatories