Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nípa Ìjọba Ọlọ́run

Nípa Ìjọba Ọlọ́run

Ohun Tá a Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù

Nípa Ìjọba Ọlọ́run

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan tí yóò ṣàkóso lórí gbogbo ayé. Jésù sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: . . . ‘Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’”—Mátíù 6:9, 10; Dáníẹ́lì 2:44.

Àwọn wo ni yóò jẹ́ alákòóso Ìjọba Ọlọ́run?

Nítorí kí Jésù lè jẹ́ Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n ṣe bí i. Áńgẹ́lì kan sọ fún ìyá Jésù pé: “Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.” (Lúùkù 1:30-33) Jésù yan àwọn kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀. Ó sọ fáwọn àpọ́sítèlí rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan.” (Lúùkù 22:28, 29; Dáníẹ́lì 7:27) Iye àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000].—Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1.

Ibo ló máa jẹ́ ibùjókòó Ìjọba Ọlọ́run?

Ìjọba Ọlọ́run yóò máa ṣàkóso láti ọ̀run wá. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín [ní ọ̀run], èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀. . . . Mo ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba.”—Jòhánù 14:2, 3, 12; Dáníẹ́lì 7:13, 14.

Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe sí ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé?

Jésù máa palẹ̀ àwọn èèyàn búburú mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Jésù sọ pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn [Jésù] bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì . . . Àwọn wọ̀nyí yóò sì lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Mátíù 25:31-34, 46.

Àwọn wo ló máa wà lórí ilẹ̀ ayé tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣàkóso lé lórí?

Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5; Sáàmù 37:29; 72:8) Àwọn èèyàn tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti máa fìfẹ́ hàn sí ọmọnìkejì wọn ni yóò kún inú ayé. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:34, 35.

Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé?

Jésù yóò mú àìsàn kúrò láyé. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó bá ogunlọ́gọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀ “nípa ìjọba Ọlọ́run, ó sì mú àwọn tí wọ́n nílò ìwòsàn lára dá.” (Lúùkù 9:11) Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Jòhánù rí Jésù tí Ọlọ́run ti jíǹde nínú ìran, ó sọ pé: “Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan . . . mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́.’”—Ìṣípayá 21:1-4.

Ìjọba Ọlọ́run yóò sọ ayé di Párádísè. Ọ̀daràn kan tí wọ́n pa lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù sọ pé: “Jésù, rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Jésù sì wí fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:42, 43; Aísáyà 11:4-9.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo orí kẹjọ nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.