Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí A Ṣe Lè Tu Aláìsàn Tó Ń Retí Ikú Nínú

Bí A Ṣe Lè Tu Aláìsàn Tó Ń Retí Ikú Nínú

Bí A Ṣe Lè Tu Aláìsàn Tó Ń Retí Ikú Nínú

“Nígbà tí mo gbọ́ pé àìsàn ìyá mi máa gbẹ̀mí ẹ̀, ńṣe lọ̀rọ̀ náà kàn mí ku, tí ọkàn mí dà rú, tí mò ń rò ó pé, ‘Ìyá mi máa kú kẹ̀?’”—Grace, láti ilẹ̀ Kánádà.

TÍ DÓKÍTÀ bá sọ pé àìsàn èèyàn wa kan máa yọrí sí ikú, ńṣe lọkàn tẹbí tọ̀rẹ́ máa ń dà rú, wọ́n sì lè má mọ ohun tí wọ́n máa ṣe. Àwọn míì lè máa ṣiyèméjì ní ti bóyá kí wọ́n la ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀ fún aláìsàn náà àbí kí wọ́n rọra pẹ́ ẹ sọ. Ní tàwọn míì, wọ́n máa ń rò ó pé bóyá lara àwọn á lè gbà á kí wọ́n máa rí béèyàn wọn ṣe ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn títí táìsàn náà á fi sọ ọ́ dìdàkudà. Ọ̀pọ̀ sì máa ń dààmú lórí pé àwọn ò ní mọ ohun táwọn máa sọ nígbà tó bá kù díẹ̀ kónítọ̀hún kú.

Kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe tó o bá gba irú ìròyìn burúkú bẹ́ẹ̀? Báwo lo ṣe lè jẹ́ “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́,” tó máa pèsè ìtùnú, tó sì máa dúró ti aláìsàn náà nígbà wàhálà yẹn?—Òwe 17:17.

Ohun Tó Sábà Máa Ń Ṣẹlẹ̀

Ńṣe ni ìdààmú sábà máa ń báni téèyàn ẹni bá lùgbàdì àìsàn burúkú. Kódà, àwọn dókítà táwọn aláìsàn ti kú lójú wọn lọ́pọ̀ ìgbà tàbí tí wọ́n ti máa ń gba ẹni tó fẹ́ kú nímọ̀ràn pàápàá máa ń dààmú, tí wọn ò ní mọ ohun tí wọ́n tún lè ṣe, tó bá dọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe máa tọ́jú aláìsàn tó ń retí ikú àti bí wọ́n ṣe máa tù ú nínú.

Tó bá ṣẹlẹ̀ pé àìsàn ń han èèyàn rẹ kan léèmọ̀, ó ṣeé ṣe kó o má lè mú un mọ́ra. Ohun tí ìyá ààfin Hosa ní ilẹ̀ Brazil sọ nígbà tí àbúrò rẹ̀ obìnrin ṣàìsàn tó máa yọrí sí ikú, ni pé: “Ìbànújẹ́ ńlá ló máa ń jẹ́ láti máa rí ẹni tó o fẹ́ràn gan-an tó ń jẹ̀rora ṣáá.” Nígbà tí Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run rí i pé ẹ̀tẹ̀ kọ lu ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ńṣe ló kígbe pé: “Ọlọ́run, jọ̀wọ́! Mú un lára dá, jọ̀wọ́!”—Númérì 12:12, 13.

Ìdí tó fi máa ń dùn wá gan-an tá a bá rí i pé èèyàn wa kan ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn ni pé àwòrán Jèhófà, Ọlọ́run wa aláàánú ni a dá wa. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Aísáyà 63:9) Táwa èèyàn bá ń jìyà, báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà? Wo bó ṣe máa ń rí lára Jésù ná. Ó fìwà jọ Baba rẹ̀ pátápátá. (Jòhánù 14:9) Nígbà tí Jésù rí àwọn táìsàn ń ṣe, “àánú [wọn] ṣe é.” (Mátíù 20:29-34; Máàkù 1:40, 41) Gẹ́gẹ́ bí a sì ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn yìí, nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù kú, tí Jésù sì rí irú ìbànújẹ́ tí ikú máa ń dá sílẹ̀ láàárín ẹbí àti ojúlùmọ̀, ó dààmú gan-an, ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé” lójú. (Jòhánù 11:32-35) Àní ọ̀tá gbáà ni Bíbélì pe ikú, ó sì ṣèlérí pé àìsàn àti ikú yóò dópin.—1 Kọ́ríńtì 15:26; Ìṣípayá 21:3, 4.

Lóòótọ́, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ́bi fẹ́nì kan, yálà ìwọ fúnra rẹ tàbí ẹlòmíì, nígbà tó o gbọ́ ìròyìn burúkú náà pé ikú làìsàn èèyàn rẹ máa yọrí sí. Ṣùgbọ́n dókítà kan tó ń jẹ́ Marta Ortiz, gbà wá nímọ̀ràn kan nínú ìwé tó fi ṣàkójọ ìwádìí rẹ̀ nípa bá a ṣe ń bójú tó aláìsàn tó ń retí ikú, ó ní: “Má ṣe dẹ́bi fún ẹnikẹ́ni nípa ohun tó dé bá aláìsàn náà, yálà àwọn dókítà, àwọn nọ́ọ̀sì, tàbí ìwọ fúnra rẹ. Ńṣe nìyẹn kàn tún máa dá wàhálà míì sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn, tí kò ní jẹ́ kí wọ́n lè gbájú mọ́ ìtọ́jú aláìsàn tó ń retí ikú náà, bẹ́ẹ̀ ìyẹn ló sì ṣe pàtàkì jù.” Àwọn ohun tó ń ṣèrànwọ́ wo lo lè ṣe tónítọ̀hún á fi lè gba kámú lórí ọ̀rọ̀ àìsàn rẹ̀ tó máa yọrí sí ikú?

Máa Ronú Nípa Aláìsàn Náà, Má Ro Ti Àìsàn Rẹ̀

Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o máa wo ohun tó o lè ṣe fún aláìsàn náà dípò tí wàá fi jẹ́ kí ìrònú àkóbá tí àìsàn yẹn ti ṣe gbà ọ́ lọ́kàn. Báwo lo ṣe máa ṣe é? Nọ́ọ̀sì kan tó ń jẹ́ Sarah sọ pé: “Mo máa ń fara balẹ̀ wo àwọn fọ́tò táláìsàn náà yà nígbà tára rẹ̀ ṣì dá ṣáṣá. Màá tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa tó bá ń sọ ìtàn ara rẹ̀ fún mi. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n máa rántí irú ẹni tó jẹ́ àti ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ dípò kí n kàn máa wo ohun táìsàn ti sọ ọ́ dà báyìí.”

Ìyáàfin Anne-Catherine, tóun náà jẹ́ nọ́ọ̀sì, sọ bóun kì í ṣeé fọ̀rọ̀ mọ sórí ohun táìsàn náà ti sọ onítọ̀hún dà báyìí. Ó ní: “Ẹyinjú aláìsàn náà ni mo máa ń wò, màá sì pọkàn pọ̀ sórí ohun tí mo bá lè ṣe láti mú kí ara túbọ̀ tu aláìsàn náà.” Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè pèsè ìtùnú fún ẹni tí kò ní pẹ́ kú, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní The Needs of the Dying—A Guide for Bringing Hope, Comfort, and Love to Life’s Final Chapter, sọ pé: “Lóòótọ́, ara sábà máa ń ta wá tá a bá ń wo èèyàn wa táìsàn tàbí jàǹbá ti sọ dìdàkudà. Ohun tó ti dáa kéèyàn ṣe nírú àsìkò bẹ́ẹ̀ ni pé kéèyàn máa wo ẹyinjú onítọ̀hún, èyí tá jẹ́ kéèyàn lè máa fọkàn sí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an yàtọ̀ sí ohun táìsàn ti sọ wọ́n dà.”

Àmọ́ ká sòótọ́, ó gba ẹ̀mí ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìpinnu àtọkànwá kéèyàn tó lè ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ohun tí alàgbà ìjọ kan tó ń jẹ́ Georges, tó sábà máa ń lọ bẹ àwọn aláìsàn tó ń retí ikú wò, sọ ni pé: “Ìfẹ́ tá a ní fún arákùnrin tàbí arábìnrin wa yìí gbọ́dọ̀ lágbára ju àìsàn yẹn lọ lọ́kàn wa.” Tó o bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹni náà jẹ ọ́ lógún ju èrò rẹ nípa àìsàn rẹ̀, ìyẹn ló máa ṣe ìwọ àti aláìsàn yẹn láǹfààní jù. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Yvonne, tó ti tọ́jú àwọn ọmọdé tó lárùn jẹjẹrẹ sọ pé: “Tó o bá mọ̀ pé o ṣì lè ṣe nǹkan táláìsàn náà á fi lè máa wò ó pé òun ṣì jẹ́ ẹni iyì, wàá lè fọwọ́ tó yẹ mu ìnira táìsàn náà ń fà bá a.”

Máa Tẹ́tí Gbọ́ Wọn

Àwọn èèyàn lè máa lọ́ tìkọ̀ láti kàn sẹ́ni tí kò ní pẹ́ kú bo tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Kí nìdí? Wọ́n lè máa rò ó pé, ‘Kí làwọn máa wá sọ táwọn bá rí i?’ Àmọ́ ìyáàfin Anne-Catherine tí kò tíì pẹ́ tó ṣètọ́jú ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó jẹ́ aláìsàn tó ń retí ikú, fi hàn pé béèyàn ò bá tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nígbà tó débẹ̀, nǹkan gidi ló ti ṣe yẹn. Ó ní: “Ọ̀rọ̀ ẹnu wa nìkan kọ́ ló ń tuni nínú, ìṣarasíhùwà wa náà ń ṣe bẹbẹ. Kéèyàn jókòó sún mọ́ aláìsàn, kéèyàn mú ọwọ́ rẹ̀ dání, kéèyàn da omijé lójú nígbà tó ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, tó bá gbà bẹ́ẹ̀, gbogbo ìwọ̀nyẹn ló ń fi hàn pé à ń bá a dárò.”

Ó máa ń dáa kí ẹni tó ń ṣàìsàn sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, kó sọ èrò ọkàn rẹ̀ fàlàlà. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, aláìsàn yẹn máa ń róye pé ìṣòro òun ń kó ìdààmú bá àwọn èèyàn òun, kò wá ní fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn tó le jù. Àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ onítọ̀hún náà lè má fẹ́ máa jíròrò ọ̀rọ̀ míì tó kan onítọ̀hún lójú rẹ̀ mọ́, kódà wọ́n tún lè máa fi ọ̀rọ̀ míì nípa ìlera rẹ̀ pa mọ́ fún un. Kí ni gbogbo àpabò yẹn máa wá yọrí sí? Dókítà kan tó ń tọ́jú àwọn tí àìsàn wọn máa yọrí sí ikú ṣàlàyé pé àníyàn nípa pé kí ọ̀rọ̀ tí tọ̀tún tòsì ń bò má ṣáà lu “kì í jẹ́ kí wọ́n lè tètè gba kámú lórí bí ọ̀rọ̀ àìsàn náà ṣe jẹ́, kí wọ́n sì gbájú mọ́ àbójútó aláìsàn náà gan-an fúnra rẹ̀.” Nítorí náà bí aláìsàn náà bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ipò àìsàn rẹ̀ tàbí ti ikú rẹ̀, ẹ jẹ́ kó sọ ọ́ bó ṣe fẹ́.

Nígbà tí ọ̀rọ̀ ikú dé bá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́, wọn ò lọ́ tìkọ̀ láti sọ ìdààmú ọkàn wọn fún Jèhófà Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Hesekáyà Ọba, tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì, gbọ́ pé òun máa kú, ó sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀. (Aísáyà 38:9-12, 18-20) Bákan náà, a ní láti jẹ́ káwọn aláìsàn tó ń retí ikú fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn nípa bí ikú ṣe fẹ́ dá ẹ̀mí wọn légbodò. Bóyá ó ń dùn wọ́n pé ọwọ́ àwọn kò ní lè tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́, irú bíi rírin ìrìn àjò kan, níní ìdílé tiwọn, fífara ro ọmọ-ọmọ wọn, tàbí àìní lè sin Ọlọ́run dépò tí wọ́n ń fẹ́. Wọ́n tún lè máa bẹ̀rù pé àwọn ẹbí àti ojúlùmọ̀ àwọn tiẹ̀ lè sá fáwọn nítorí èrò pé wọn ò ní mọ ohun tí wọ́n máa sọ tí wọ́n bá wá. (Jóòbù 19:16-18) Ìbẹ̀rù pé ìyà máa jẹ àwọn, pé wọ́n á dẹni tí ẹ̀yà ara rẹ̀ kọṣẹ́, tàbí ìbẹ̀rù pé àwọn máa kú pàápàá sì tún lè gbà wọ́n lọ́kàn.

Nọ́ọ̀sì náà Anne-Catherine ní: “Ó ṣe pàtàkì pé kó o jẹ́ kí èèyàn rẹ yìí sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ láìjálu ọ̀rọ̀ rẹ̀ tàbí kó o máa dá a lẹ́bi tàbí kó o máa sọ fún un pé ọ̀rọ̀ náà kò le tó bẹ́ẹ̀. Ìyẹn gan-an lọ́nà tó o lè gbà mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, ohun tó ń fẹ́, ohun tó ń bà á lẹ́rù àtohun tó ń retí.”

Mọ Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù

Ìrònú nípa ìyà tó ń jẹ èèyàn rẹ tó ń ṣàìsàn náà, àti bí ìtọ́jú tó ń gbà ṣe lágbára tó àti bí ìyẹn ṣe ń dá kún ìnira rẹ̀ lè dà ọ́ lọ́kàn rú gan-an tí wàá fi gbàgbé ohun pàtàkì kan táláìsàn náà nílò. Ohun náà ni pé kó máa fúnra rẹ̀ yan ohun tó ń fẹ́.

Láàárín àwọn ẹ̀yà míì, ìdílé aláìsàn náà lè má sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nípa ipò àìsàn rẹ̀ fún un, wọ́n á láwọn ò fẹ́ yọ ọ́ lẹ́nu. Kódà wọ́n lè ṣe é débi pé wọ́n á máa ṣèpinnu nípa irú ìtọ́jú tó máa gbà láìfi lọ̀ ọ́ rárá. Ìṣòro tàwọn ẹ̀yà míì yàtọ̀ sí èyí. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin nọ́ọ̀sì kan tó ń jẹ́ Jerry sọ pé: “Nígbà míì, àwọn tó wá kí aláìsàn náà a máa dá jíròrò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì tó dùbúlẹ̀ sí bíi pé kò tiẹ̀ sí níbẹ̀.” Kò sí èyí tó buyì kún aláìsàn náà nínú ọ̀nà méjèèjì.

Ohun pàtàkì míì tí aláìsàn náà nílò ni ìrètí. Láwọn orílẹ̀-èdè téèyàn ti lè rí ìtọ́jú tó jíire gbà láwọn ilé ìwòsàn, ìrètí aláìsàn ni pé bó pẹ́ bó yá, lọ́nà kan ṣáá, òun á rí oògùn tó máa wo òun sàn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Michelle, tó tọ́jú ìyá rẹ̀ láàárín ìgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí àrùn jẹjẹrẹ tún padà yọjú lára rẹ̀, ṣàlàyé pé: “Tí Màmá bá tún fẹ́ gbìyànjú ìtọ́jú míì wò tàbí ó fẹ́ kàn sí oníṣègùn míì, n kì í jẹ́ kó sú mi, ńṣe la jọ máa ń ṣèwádìí nípa rẹ̀. Mo ti wá rí i pé á dáa kí n má tan ara mi jẹ pé ara Màmá á kàn dédé yá, àti pé kí n má sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa kò ìrẹ̀wẹ̀sì bá a.”

Tó bá wá di pé kò sí ẹ̀rí pé àìsàn yẹn máa sàn ńkọ́? Má gbàgbé pé ó yẹ kí aláìsàn náà lè sọ̀rọ̀ nípa ikú rẹ̀ bó ṣe fẹ́. Arákùnrin Georges, alàgbà ìjọ tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú, sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì pé ká má ṣe fi ọ̀rọ̀ pé àìsàn rẹ̀ máa yọrí sí ikú láìpẹ́ pa mọ́ fún un. Ìyẹn á jẹ́ kó lè ṣe gbogbo ètò tó bá fẹ́ ṣe, kó sì fọkàn sí ìgbà tó máa kú.” Irú ìṣètò bẹ́ẹ̀, lè jẹ́ kí ọkàn aláìsàn náà balẹ̀ pé òun ṣe ètò tó yẹ ní ṣíṣe kóun tó kú, àti pé òun ò tún ní dá kún ìṣòro àwọn èèyàn.

Àmọ́ ṣá o, irú nǹkan báwọ̀nyí kì í rọrùn láti sọ. Ṣùgbọ́n tẹ́ ẹ bá jọ sọ irú ògidì ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, ẹ ó lè fi bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn yín hàn fún ara yín. Ẹni tí kò ní pẹ́ kú náà lè fẹ́ yanjú èdèkòyédè tó bá wà nílẹ̀, kó sọ ohun tó dùn ún, kó sì tọrọ àforíjì bó ṣe yẹ. Irú ọ̀rọ̀ àjọsọ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí ọkàn ìwọ àtẹni tó fẹ́ kú náà túbọ̀ fà mọ́ra ju tàtẹ̀yìnwá lọ.

Bó O Ṣe Lè Tu Aláìsàn Tọ́jọ́ Ikú Rẹ̀ Sún Mọ́lé Nínú

Báwo lo ṣe lè tu ẹni tí kò ní pẹ́ kú nínú? Dókítà tó ń jẹ́ Ortiz, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú ní: “Jẹ́ kí aláìsàn náà sọ ohun ìkẹyìn tó ń fẹ́. Tẹ́tí sí i dáadáa. Gbìyànjú láti ṣe ohun tó ń fẹ́ fún un, tó bá ṣeé ṣe. Tí ohun tó ń fẹ́ yẹn kò bá ní ṣeé ṣe, sòótọ́ fún un.”

Ọkàn ẹni tí kò ní pẹ́ kú náà lè máa fà sáwọn kan tó wà ní góńgó ẹ̀mí ẹ̀ gan-an. Arákùnrin Georges ní: “Ńṣe ni kó o bá aláìsàn náà kàn sírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ráńpẹ́ ló kàn lè bá wọn sọ torí okun rẹ̀ tó ń tán lọ.” Kódà bó tiẹ̀ jẹ́ ẹ̀rọ tẹlífóònù ni wọ́n fi lè bára wọn sọ̀rọ̀, wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ ìṣírí fún ara wọn kí wọ́n sì jọ gbàdúrà pọ̀. Obìnrin ará ilẹ̀ Kánádà kan tó ń jẹ́ Christina, táwọn èèyàn rẹ̀ mẹ́ta kú tẹ̀ léra, sọ pé: “Bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ àkókò ikú wọn ni wọ́n máa ń nílò àdúrà àwọn Kristẹni bíi tiwọn sí i.”

Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa bẹ̀rù láti sunkún lójú èèyàn wa tó ń kú lọ? Rárá o. Tó o bá sunkún, ńṣe nìyẹn á jẹ́ kóun náà lè ráyè tú ẹ̀ nínú. Ìwé náà, The Needs of the Dying, sọ pé: “Ìrírí ńláǹlà ló máa ń jẹ́ pé kí ẹni tó ń kú lọ tuni nínú, ó sì tún lè ṣe ẹni tó fẹ́ kú náà láǹfààní gan-an.” Tí aláìsàn táwọn èèyàn ti ń tọ́jú lọ́tùn-ún lósì náà bá ń tu àwọn èèyàn nínú, ńṣe nìyẹn máa jẹ́ kó tún rántí pé ọ̀rẹ́, bàbá, tàbí ìyá tó láájò ẹni lòun jẹ́.

Lóòótọ́, ipò nǹkan lè má jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ láti wà lọ́dọ̀ èèyàn rẹ ní àkókò tó fẹ́ kú. Àmọ́ tó bá wá ṣeé ṣe fún ọ láti wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nílé ìwòsàn tàbí nílé lásìkò tó fẹ́ kú, gbìyànjú láti di ọwọ́ rẹ̀ mú títí tá a fi gbẹ́mìí mì. Ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà ìkẹyìn yẹn lè jẹ́ kó o láǹfààní láti sọ̀rọ̀ ìdárò tàbí kó o fi ìmọ̀lára tó ò tíì ráyè sọ jáde rí hàn. Kódà bí onítọ̀hún ò bá tiẹ̀ lè sọ̀rọ̀ tàbí mira mọ́, má ṣe jẹ́ kí ìyẹn dá ọ dúró láti kí i pé ó dìgbóṣe, pé ẹ ó tún ríra nígbà àjíǹde.—Jóòbù 14:14, 15; Ìṣe 24:15.

Tó o bá gbìyànjú láti ṣe àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe lásìkò ìkẹyìn yẹn, ìyẹn lè gbà ọ́ lọ́wọ́ kíkábàámọ́ tó bá yá. Ká sòótọ́, ìrántí ọ̀rọ̀ àti ẹ̀mí ìdárò rẹ àtàwọn nǹkan míì tó wáyé lásíkò tó kú náà lè wà lára ohun tí yóò máa tù ọ́ nínú títí lọ lẹ́yìn ikú rẹ̀. Wàá sì tún máa rántí pé o dúró tì í gẹ́gẹ́ bí alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ ní ‘ìgbà wàhálà.’—Òwe 17:17.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

Jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹni náà jẹ ọ́ lógún ju èrò rẹ nípa àìsàn rẹ̀ ló máa ṣe ìwọ àti aláìsàn yẹn láǹfààní jù

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ọ̀nà Táwọn Èèyàn Lè Gbà Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀tọ́ Aláìsàn

Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wọ́n máa ń gbìyànjú láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí aláìsàn tó ń retí ikú ní láti kú ikú rẹ̀ jẹ́jẹ́ àti lọ́nà iyì. Téèyàn bá ṣàkọsílẹ̀ ìtọ́ni nípa irú ìtọ́jú ìṣègùn tó ń fẹ́ ṣáájú, ìyẹn máa ń jẹ́ káwọn èèyàn lè túbọ̀ bọ̀wọ̀ fáwọn ẹ̀tọ́ yẹn, kí wọ́n sì jẹ́ kí aláìsàn náà kú sílé rẹ̀ tàbí sílé ìwòsàn.

Ohun tí ìtọ́ni nípa ìtọ́jú ìṣègùn yóò ṣe nìyí:

• Yóò jẹ́ kí àwọn dókítà, aláìsàn àtàwọn èèyàn rẹ̀ lè tètè gbọ́ ara wọn yé

• Á jẹ́ kí aláìsàn ti fúnra rẹ̀ ṣèpinnu irú ìtọ́jú tó ń fẹ́ ṣáájú, dípò táwọn èèyàn rẹ̀ á fi máa ṣe wàhálà nípa ìyẹn

• Kò ní jẹ́ káwọn èèyàn kàn fún aláìsàn ní ìtọ́jú tí kò fẹ́, tí kò wúlò, tó le koko, tó tún gbówó lórí.

Lára ìsọfúnni tó ní láti wà nínú ojúlówó ìtọ́ni nípa ìtọ́jú ìṣègùn ni:

• Orúkọ ẹni tó jẹ́ aṣojú rẹ nínú ọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn

• Irú ìtọ́jú ìṣègùn tí wàá fẹ́ láti gbà tàbí èyí tí o kò fẹ́ tó bá di pé àwọn oníṣègùn kò rọ́gbọ́n dá sí ọ̀rọ̀ ìtọ́jú rẹ

• Tó bá ṣeé ṣe, fi orúkọ dókítà tó mọ̀ nípa irú ìtọ́jú tó o sọ pé o fẹ́ sí i

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Máa ronú nípa irú ẹni tó jẹ́ àti ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ dípò kó o kàn máa wo ohun táìsàn ti sọ ọ́ dà báyìí