Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fa Àwọn Ìjábá Láti Máa Fi Jẹ Àwa Èèyàn Níyà?

Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fa Àwọn Ìjábá Láti Máa Fi Jẹ Àwa Èèyàn Níyà?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fa Àwọn Ìjábá Láti Máa Fi Jẹ Àwa Èèyàn Níyà?

Ọlọ́run kì í lo àwọn ìjábá láti fi jẹ gbogbo èèyàn níyà pa pọ̀, àtẹlẹ́ṣẹ̀ àtaláìṣẹ̀. Kò tíì ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí, kò sì ní ṣe é láéláé. Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì sọ nínú Jòhánù kìíní orí kẹrin ẹsẹ ìkẹjọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”

Ìfẹ́ ló ń darí ohun gbogbo tí Ọlọ́run ń ṣe. Ìfẹ́ kì í jẹ́ kéèyàn ṣe ohun tó bá lè pa aláìṣẹ̀ lára, nítorí Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ kì í ṣiṣẹ́ ibi sí aládùúgbò ẹni.” (Róòmù 13:10) Bákan náà, Jóòbù 34:12 sọ pé: “Ní tòótọ́, Ọlọ́run kì í ṣe burúkú.”

Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ìjábá, irú bíi “ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà” yóò máa wáyé ní àkókò wa yìí. (Lúùkù 21:11) Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí a ò ṣe lè sọ pé awojú-ọjọ́ tó wo bójú ọ̀run ṣe rí tó sì sọ pé òjò máa rọ̀ ló fa òjò, bẹ́ẹ̀ náà la ò ṣe lè sọ pé Jèhófà ló ń fa àwọn ìjábá tó ń wáyé tìtorí pé ó sọ tẹ́lẹ̀ pé nǹkan wọ̀nyẹn máa ṣẹlẹ̀. Tó bá wá jẹ́ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìpalára táwọn ìjábá ń ṣe, kí ló ń fà á?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù. (1 Jòhánù 5:19) Látìgbà tí Sátánì ti ṣọ̀tẹ̀ lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá èèyàn ló ti di apààyàn títí dòní olónìí. (Jòhánù 8:44) Pàǹtírí lásán tí kò níláárí ni Sátánì ka ẹ̀mí àwa èèyàn sí. Onímọtara-ẹni-nìkan ẹ̀dá ni. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ló kún inú ayé tí Sátánì Èṣù ń darí yìí. Lóde òní, aráyé fàyè gba ìrẹ́jẹ, wọ́n máa ń fọwọ́ ọlá gbá àwọn tí kò rí jájẹ lójú, wọ́n á wá mú kó di dandan fún wọn láti máa lọ gbé ní agbègbè tí ìjábá àbáláyé tàbí tí jàǹbá táwọn èèyàn fà ti lè ṣẹlẹ̀. (Éfésù 2:2; 1 Jòhánù 2:16) Torí náà, àwọn oníwọra èèyàn ló jẹ̀bi àwọn kan lára ìpalára tí ìjábá fà bá àwọn èèyàn. (Oníwàásù 8:9) Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

Àfọwọ́fà àwọn èèyàn pọ̀ lára ohun tó fa àwọn jàǹbá kan. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ìpalára tí àjálù ìjì líle àti omíyalé tó ṣẹlẹ̀ nílùú New Orleans lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà fà àti ti òkè kan tí òjò ńlá mú kó ya bo àwọn ilé kan mọ́lẹ̀ létíkun kan lórílẹ̀ èdè Fẹnẹsúélà. Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá a mẹ́nu kàn yìí àtàwọn míì, ohun tó jẹ́ kí ìjì tó jà àti òjò tó rọ̀ ṣèpalára púpọ̀ ni àìní ìmọ̀ tó pọ̀ tó nípa àyíká, kíkọ́lé àti ṣíṣe àwọn nǹkan lọ́nà àjàǹbàkù, àìsí ètò tó gún régé, ṣíṣàìgba ìkìlọ̀ àti àṣìṣe ti àwọn aláṣẹ.

Ẹ jẹ́ ká tún wo ìjábá tó wáyé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Nígbà tí Jésù wà láyé, wíwó tí ilé gogoro kan wó lójijì ló ṣekú pa èèyàn méjìdínlógún. (Lúùkù 13:4) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àṣìṣe àwọn èèyàn kan ló fa jàǹbá yìí, ó sì lè jẹ́ “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀,” tàbí kó jẹ́ méjèèjì. Àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn kì í ṣe ìdájọ́ Ọlọ́run.—Oníwàásù 9:11.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ ti mú ìjábá èyíkéyìí wá rí? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ ó yàtọ̀ sí ìjábá àbáláyé tàbí jàǹbá táwọn èèyàn fà, torí pé ó nídìí tí Jèhófà fi mú un wá àti pé ó lójú àwọn tó pa run, kì í sì í ṣe ohun tó ń wáyé ní gbogbo ìgbà. Àpẹẹrẹ méjì kan ni ti Ìkún-omi tó wáyé nígbà ayé Nóà àti ti ìparun Sódómù àti Gòmórà nígbà ayé Lọ́ọ̀tì. (Jẹ́nẹ́sísì 6:7-9, 13; 18:20-32; 19:24) Ńṣe ni Ọlọ́run fi ìjábá yìí dá àwọn ẹni ibi tí kò ronú pìwà dà lẹ́jọ́, àmọ́ ó pa àwọn tó jẹ́ olódodo mọ́ láàyè.

Ohun kan tó dájú ni pé, Jèhófà Ọlọ́run lágbára láti mú ìwà ibi kúrò, ohun tó sì máa ṣe nìyẹn. Bákan náà, ó lágbára láti fòpin sí ìyà, kó sì mú gbogbo ohun tí ìjábá ti fà kúrò. Ìwé Sáàmù 72:12 sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi Ọba tí Ọlọ́run ti yàn pé: “Yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́.”