Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Sáwọn Èèyàn?

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Sáwọn Èèyàn?

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Sáwọn Èèyàn?

“Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.”—LÚÙKÙ 6:31.

1, 2. (a) Kí ni Ìwàásù Lórí Òkè? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó máa tẹ̀ lé e?

 KÁ SÒÓTỌ́ Àgbà Olùkọ́ ni Jésù Kristi. Nígbà táwọn aṣáájú ìsìn tó jẹ́ ọ̀tá rẹ̀ ní káwọn ẹ̀ṣọ́ lọ mú un wá, ọwọ́ òfo làwọn ẹ̀ṣọ́ yẹn padà dé. Wọ́n sọ ohun tó fà á tí wọn ò fi mú Jésù bọ̀, wọ́n ní: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.” (Jòh. 7:32, 45, 46) Ìwàásù Lórí Òkè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwàásù Jésù tó rinlẹ̀. Ó wà ní orí karùn-ún sí ìkeje nínú Ìhìn Rere Mátíù, ohun tó jọ ọ́ sì wà nínú Lúùkù 6:20-49. a

2 Gbólóhùn pàtàkì kan wà nínú ìwàásù yẹn tó sọ bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn èèyàn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé òun ni ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ jù lọ nínú ìwàásù ọ̀hún. Bí Jésù ṣe sọ gbólóhùn ọ̀hún rèé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.” (Lúùkù 6:31) Jésù mà ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere fáwọn èèyàn o! Ó wo àwọn aláìsàn sàn, kódà ó jí òkú dìde. Àmọ́ ṣá, ìbùkún tó pọ̀ jù lọ táwọn èèyàn rí gbà ni ẹ̀kọ́ ìhìn rere tí Jésù kọ́ wọn. (Ka Lúùkù 7:20-22.) Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà máa ń dùn láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run bíi ti Jésù. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó máa tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àwọn ohun tí Jésù mẹ́nu bà nínú Ìwàásù Lórí Òkè nípa iṣẹ́ ìwàásù yìí àtàwọn kókó mìíràn nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn èèyàn.

Jẹ́ Onínú Tútù

3. Ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ onínú tútù.

3 Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mát. 5:5) Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe ṣàlàyé, jíjẹ́ onínú tútù kò sọ èèyàn di arindìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú tútù ló ń jẹ́ ká máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe láìjanpata. Irú ẹ̀mí yìí máa ń hàn nínú ìwà tá à ń hù sí ọmọnìkejì wa. Bí àpẹẹrẹ, a kì í “fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.”—Róòmù 12:17-19.

4. Kí nìdí táwọn onínú tútù fi jẹ́ aláyọ̀?

4 Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù nítorí pé wọn yóò “jogún ilẹ̀ ayé.” Jésù tó jẹ́ “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà” ni Ọlọ́run “yàn ṣe ajogún ohun gbogbo,” torí náà, òun ni olórí àwọn tó máa jogún ilẹ̀ ayé, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ló máa ṣàkóso rẹ̀. (Mát. 11:29; Héb. 1:2; Sm. 2:8) Ó sì ti wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà tó jẹ́ “ọmọ ènìyàn” máa ní àwọn tó máa bá a ṣàkóso nínú Ìjọba ọ̀run. (Dán. 7:13, 14, 21, 22, 27) Torí pé “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi” ni àwọn onínú tùtù èèyàn tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàájì wọ̀nyí, àwọn náa máa jogún ayé pẹ̀lú Jésù. (Róòmù 8:16, 17; Ìṣí. 14:1) Àwọn onínú tútù míì tún wà tí wọ́n máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba yẹn.—Sm. 37:11.

5. Tá a bá jẹ́ oníwà tútù bíi ti Kristi, kí ló máa ṣe fún wa?

5 Tá a bá jẹ́ ẹni líle, ó ṣeé ṣe kí ìwà wa máa tán àwọn èèyàn ní sùúrù, ìyẹn sì lè mú kí wọ́n máa yẹra fún wa. Àmọ́, tá a bá jẹ́ oníwà tútù bíi ti Kristi, èyí á mú kí ìwà wa máa tu àwọn ará ìjọ lára á sì lè mú ká máa gbé wọn ró. Ìwà tútù wà lára èso tí ẹ̀mí Ọlọ́run á mú ká ní tá a bá ‘jẹ́ ẹni tẹ̀mí tí ẹ̀mí sì ń darí wa.’ (Ka Gálátíà 5:22-25.) Ó dájú pé a fẹ́ wà lára àwọn onínú tútù tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà á máa darí!

Ayọ̀ Àwọn Aláàánú Mà Pọ̀ Jọjọ O!

6. Àwọn ànímọ́ pàtàkì wo la fi máa ń mọ àwọn “aláàánú”?

6 Jésù tún sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè pé: “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú, níwọ̀n bí a ó ti fi àánú hàn sí wọn.” (Mát. 5:7) Ẹni tó bá jẹ́ “aláàánú” máa ń ní ìyọ́nú fẹ́ni tó níṣòro, ó máa ń gba tirú ẹni bẹ́ẹ̀ rò, kódà ó máa ń ṣàánú fún un. Jésù ṣiṣẹ́ ìyanu láti yanjú ìṣòro àwọn tíyà ń jẹ torí pé “àánú wọn ṣe é.” (Mát. 14:14; 20:34) Nítorí náà, ojú àánú àti ìgbatẹnirò yẹ kó mú káwa náà jẹ́ aláàánú.—Ják. 2:13.

7. Nígbà tí àánú ṣe Jésù, kí ló ṣe?

7 Nígbà táwọn èrò pàdé Jésù lọ́nà bó ṣe fẹ́ lọ sinmi, “àánú wọ́n ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” Látàrí èyí, ó “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:34) Ẹ wo bí ayọ̀ wa ṣe pọ̀ tó bá a ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn tá a sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí àánú Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó!

8. Kí nìdí táwọn aláàánú fi jẹ́ aláyọ̀?

8 Ìdí tí àwọn aláàánú fi jẹ́ aláyọ̀ ni pé a ó “fi àánú hàn sí wọn.” Tá a bá ń fi àánú hàn sáwọn èèyàn, àwọn náà á máa fi àánú hàn sí wa. (Lúùkù 6:38) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yóò dárí jì yín pẹ̀lú.” (Mát. 6:14) Àwọn aláàánú nìkan ló máa rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbà, àwọn nìkan sì ni inú Ọlọ́run máa dùn sí, téyìí á sì jẹ́ kí wọ́n ní ayọ̀.

Ìdí Tí “Àwọn Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà” Fi Jẹ́ Aláyọ̀

9. Báwo la ó ṣe máa hùwà tá a bá jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà?

9 Jésù sọ ohun míì tó lè fún èèyàn láyọ̀ nígbà tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, níwọ̀n bí a ó ti pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run.’” (Mát. 5:9) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a pè ní “ẹlẹ́mìí àlàáfíà” níbí yìí túmọ̀ sí “ẹni tó ń wá àlàáfíà.” Tá a bá jẹ́ ẹni tó ń wá àlàáfíà, a ò ní máa fàyè gba ohunkóhun tó lè “ya àwọn tí ó mọ ara wọn dunjú nípa,” irú bí ìfọ̀rọ̀-èké banijẹ́, a kò sì ní máa lọ́wọ́ sírú nǹkan bẹ́ẹ̀. (Òwe 16:28) Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, a ó máa ṣàlékún àlàáfíà tó wà láàárín àwọn ará ìjọ àti àwọn tí kì í ṣe ará ìjọ. (Héb. 12:14) Pàápàá jù lọ, a ó máa rí i dájú pé àlàáfíà wà láàárín àwa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run.—Ka 1 Pétérù 3:10-12.

10. Kí nìdí tí “àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà” fi jẹ́ aláyọ̀?

10 Jésù sọ pé ìdí tí “àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà” fi jẹ́ aláyọ̀ ni pé a ó máa “pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run.’” Nítorí pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù pé òun ni Mèsáyà, wọ́n ti gba “ọlá àṣẹ láti di ọmọ Ọlọ́run.” (Jòh. 1:12; 1 Pét. 2:24) Àwọn “àgùntàn mìíràn” tí Jésù ní, táwọn náà jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà ńkọ́? Jésù á jẹ́ “Baba Ayérayé” fún wọn nígbà Ìjọba Ẹgbẹ̀rún Ọdún tí òun àtàwọn ajùmọ̀jogún rẹ̀ jọ máa ṣe lọ́run. (Jòh. 10:14, 16; Aísá. 9:6; Ìṣí. 20:6) Ìgbà tí Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún yẹn bá dópin la tó wá lè fi gbogbo ẹnu sọ pé àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà yẹn ti di ọmọ Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé.—1 Kọ́r. 15:27, 28.

11. Báwo la ó ṣe máa ṣe sáwọn èèyàn tá a bá jẹ́ kí “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” máa darí wa?

11 Ká tó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run àlàáfíà,” a gbọ́dọ̀ ní àwọn ànímọ́ rẹ̀. Lára rẹ̀ ni pé ká jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. (Fílí. 4:9) Tá a bá jẹ́ kí “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” máa darí wa, ohun tó máa mú àlàáfíà wá la ó máa ṣe sáwọn èèyàn. (Ják. 3:17) Ní tòótọ, a máa láyọ̀ tá a bá jẹ́ ẹni tó ń wá àlàáfíà.

“Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”

12. (a) Kí ni Jésù sọ nípa ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí? (b) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn?

12 Oore tó dára jù lọ tá a lè ṣe fáwọn èèyàn ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tó ń wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Sm. 43:3) Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé àwọn ni “ìmọ́lẹ̀ ayé” ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn káwọn èèyàn bàa lè rí “iṣẹ́ àtàtà,” ìyẹn iṣẹ́ rere tí wọ́n ń ṣe fáwọn èèyàn. Iṣẹ́ rere yẹn á máa tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí “níwájú àwọn ènìyàn,” tàbí lédè mìíràn, á máa ṣe gbogbo arayé láǹfààní. (Ka Mátíù 5:14-16.) Lónìí, à ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa tàn nípa ṣíṣe rere sáwọn aládùúgbò wa àti nípa wíwàásù ìhìn rere “ní gbogbo ayé,” ìyẹn “ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 26:13; Máàkù 13:10) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí!

13. Àwọn nǹkan wo làwọn èèyàn ń kíyè sí lára wa?

13 Jésù sọ pé: “Ìlú ńlá kan kò lè fara sin nígbà tí ó bá wà lórí òkè ńlá.” Tí wọ́n bá tẹ ìlú kan dó sórí òkè, kedere làwọn èèyàn á máa rí i. Bákan náà, àwọn èèyàn ń kíyè sí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe, wọ́n sì ń kíyè sí àwọn iṣẹ́ àtàtà wa àtàwọn ànímọ́ tá a ní, irú bí ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìwà mímọ́.—Títù 2:1-14.

14. (a) Báwo ni fìtílà ọ̀rúndún kìíní ṣe rí? (b) Kí ló túmọ̀ sí lati má ṣe fi ìmọ́lẹ̀ wa pamọ́ sábẹ́ “apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n”?

14 Jésù sọ pé táwọn èèyàn bá tan fìtílà, wọn kì í gbé e sábẹ́ apẹ̀rẹ̀, àmọ́ orí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n máa ń gbé e sí kó bàa lè tàn sára gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ilé. Irú fìtílà tí wọ́n sábàá máa ń lò ní ọ̀rúndún kìíní jẹ́ àtùpa alámọ̀ tí wọ́n fi òwú àtùpà sí, òwú yìí á máa fa epo (tó sábàá máa ń jẹ́ òróró olífì) èyí táá máa mú kí iná jò. Ó fẹ́ jọ àtùpa karosíìnì tí wọ́n ń fi agolo tàbí ìgò ṣe lóde òní. Orí ọ̀pá tí wọ́n fi irin tàbí igi ṣe ni wọ́n máa ń gbé e sí, èyí á sì wá jẹ́ kó lè máa “tàn sára gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ilé.” Àwọn èèyàn ò ní tan fìtílà yìí tán kí wọ́n wá gbé e sábẹ́ “apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n,” ìyẹn irú apẹ̀rẹ̀ ńlá kan tá a fi ń ra nǹkan lọ́jà. Jésù ò fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun fi ìmọ́lẹ̀ wọn pamọ́, bí ìgbà tí wọ́n tọ́jú rẹ̀ sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n. Torí náà, a ní láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn, ká má ṣe gbà kí àtakò tàbí inúnibíni pa wá lẹ́nu mọ́ débi tá a ó fi fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ pamọ́.

15. Kí ni “àwọn iṣẹ́ àtàtà” wa ń mú káwọn èèyàn kan ṣe?

15 Ẹ̀yìn tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa títan fìtílà tán ló wá sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” Nítorí “àwọn iṣẹ́ àtàtà” wa, àwọn kan ti dẹni tó ń “fi ògo fún” Ọlọ́run nípa dídi ìránṣẹ́ rẹ̀. Àbí ẹ ò rí i pé ìdí pàtàkì rèé tó fi yẹ ká máa “tàn bí atànmọ́lẹ̀ nínú ayé”!—Fílí. 2:15.

16. Kí ni jíjẹ́ tá a jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ayé” túmọ̀ sí?

16 Jíjẹ́ tá a jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ayé” túmọ̀ sí pé a ní láti máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni-dọmọ-ẹ̀yìn. Àmọ́, ó tún gba pé ká máa ṣe nǹkan míì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀, nítorí pé èso ìmọ́lẹ̀ ní gbogbo onírúurú ohun rere àti òdodo àti òtítọ́ nínú.” (Éfé. 5:8, 9) Ó yẹ ká máa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ìwà tó bá ìlànà Ọlọ́run mu. Àní ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pétérù yìí pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.” (1 Pét. 2:12) Àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe tó bá ṣẹlẹ̀ pé gbúngbùngbún wà láàárín àwa àtẹnì kan tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

“Wá Àlàáfíà, Ìwọ Pẹ̀lú Arákùnrin Rẹ”

17-19. (a) Kí ni “ẹ̀bùn” tí Jésù ń sọ nípa rẹ̀ nínú Mátíù 5:23, 24? (b) Báwo ni yíyanjú gbúngbùngbún tó bá wà láàárín àwa àti arákùnrin wa ti ṣe pàtàkì tó, báwo sì ni Jésù ṣe fi èyí hàn?

17 Nínú Ìwàásù Lórí Òke, Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ máa di àwọn arákùnrin wọn sínú tàbí kí wọ́n kórìíra wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ní kí wọ́n tètè wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin tí wọ́n bá ṣẹ̀. (Ka Mátíù 5:21-25.) Kíyè sí ìmọ̀ràn Jésù yẹn dáadáa. Ká sọ pé ẹnì kan mú ẹ̀bùn wá sórí pẹpẹ tó sì wá rántí níbẹ̀ pé arákùnrin òun ní ohun kan lọ́kàn lòdì sóun, kí ló yẹ kó ṣe? Ó ní láti fi ẹ̀bùn rẹ̀ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ, kó sì kọ́kọ́ lọ yanjú ọ̀ràn náà pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀. Lẹ́yìn tó bá ti ṣèyẹn tán, ó lè wá fi ẹ̀bùn rẹ̀ rúbọ.

18 “Ẹ̀bùn” tí ibí yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jẹ́ ọrẹ tí wọ́n fi ń rúbọ, èyí tẹ́nì kan lè mú lọ sí tẹ́ńpìlì Jèhófà. Lóòótọ́ fífi ẹran rúbọ ṣe pàtàkì gan-an fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyé ìgbà yẹn, torí pé ó wà lára ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún wọn nínú Òfin Mósè lórí ọ̀ràn ìjọsìn. Àmọ́ tẹ́nì kan bá rántí pé arákùnrin òun ní ohun kan lọ́kàn lòdì sóun, ohun tó ṣe pàtàkì jù lákòókò yẹn ni yíyanjú aáwọ̀ náà, kì í ṣe ẹbọ tó fẹ́ rú. Jésù sọ pé “fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” Onítọ̀hún ní láti kọ́kọ́ yanjú gbúngbùngbún tó wà láàárín òun àti arákùnrin rẹ̀ ná kó tó lè ṣe ohun tí Òfin ní kó ṣe.

19 Kì í ṣe irú ẹbọ kan pàtó tàbí irú ẹ̀ṣẹ̀ kan pàtó ni Jésù ń sọ níbí yìí o. Torí náà, tẹ́nì kan tó fẹ́ rú ẹbọ èyíkéyìí bá rántí pé arákùnrin òun ní nǹkan kan lọ́kàn lòdì sóun, kó kọ́kọ́ dá ẹbọ tó fẹ́ rú dúró ná. Tó bá jẹ́ ẹran ló fẹ́ fi rúbọ, ó ní láti fi ẹran yẹn sílẹ̀ láàyè “níwájú pẹpẹ” tí wọ́n ti ń rú ọrẹ ẹbọ sísun ní àgbàlá àwọn àlùfáà nínú tẹ́ńpìlì. Ó dìgbà tí ìṣòro náà bá yanjú tán kó tó lè padà lọ rú ẹbọ náà.

20. Kí nìdí tó fi yẹ ká tètè máa yanjú ọ̀ràn ní kíákíá tí arákùnrin kan bá ṣe nǹkan tó bí wa nínú?

20 Lójú Ọlọ́run, níní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ará wa jẹ́ apá pàtàkì ìjọsìn tòótọ́. Táwọn èèyàn bá ń fi ẹran rúbọ, àmọ́ tí wọn ò ṣe dáadáa sáwọn èèyàn bíi tiwọn, irú ẹbọ bẹ́ẹ̀ kò ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. (Míkà 6:6-8) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí yanjú àwọn ọ̀ràn ní kíákíá.” (Mát. 5:25) Pọ́ọ̀lù sọ ohun kan tó jọ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.” (Éfé. 4:26, 27) Tẹ́nì kan bá ṣe nǹkan kan fún wa tó yẹ ká torí ẹ̀ bínú, ó yẹ ká tètè yanjú ọ̀rọ̀ náà kíákíá kó má bàa di pé ìbínú yẹn pẹ́ nínú wa ká sì tipa bẹ́ẹ̀ gba Èṣù láyè.—Lúùkù 17:3, 4.

Máa Fọ̀wọ̀ Àwọn Èèyàn Wọ̀ Wọ́n

21, 22. (a) Báwo la ṣe lè lo àwọn ìmọ̀ràn Jésù tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò tán yìí? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

21 Àwọn gbólóhùn mélòó kan tá a ti jíròrò lára Ìwàásù Lórí Òkè tí Jésù ṣe yìí yẹ kó ràn wá lọ́wọ́ láti máa jẹ́ onínúure ká sì máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni gbogbo wa, síbẹ̀ a lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù yẹn torí pé kò retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ, Bàbá wa ọ̀run náà ó sì retí kọjá ohun tágbára wa ká. Tá a bá ń gbàdúrà, tá a sì ń sapá gidigidi, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́ onínú tútù, aláàánú àti ẹlẹ́mìí àlàáfíà, a ó sì lè máa tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí táá máa mú ògo bá Jèhófà. Láfikún sí i, a ó lè máa wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin wa tó bá di pé aáwọ̀ ṣẹlẹ̀.

22 Ara ohun tó máa mú kí ìjọsìn wa ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà ni pé ká máa ṣe dáadáa sáwọn aládùúgbò wa. (Máàkù 12:31) Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a máa jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ míì tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè, tó yẹ kó ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe rere sáwọn èèyàn. Lẹ́yìn tá a bá ti ṣàṣàrò lórí àwọn kókó tá a ti jíròrò látinú ìwàásù Jésù tó rinlẹ̀ yìí, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Báwo ni mo ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn?’

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ yìí, wàá rí i pé á ṣe ọ́ láǹfààní gan-an tó o bá kọ́kọ́ ka àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàgbéyẹ̀wò àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ onínú tútù?

• Kí nìdí tí “àwọn aláàánú” fi jẹ́ aláyọ̀?

• Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn?

• Kí nìdí tá a fi ní láti tètè ‘wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin wa’?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ìwà tó bá ìlànà Ọlọ́run mu

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Sa gbogbo ipá rẹ láti wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ