Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìkún-Omi Ìgbà Ayé Nóà—Òótọ́ Pọ́ńbélé Ni, Kì Í Ṣe Ìtàn Àròsọ

Ìkún-Omi Ìgbà Ayé Nóà—Òótọ́ Pọ́ńbélé Ni, Kì Í Ṣe Ìtàn Àròsọ

Ìkún-Omi Ìgbà Ayé Nóà—Òótọ́ Pọ́ńbélé Ni, Kì Í Ṣe Ìtàn Àròsọ

ǸJẸ́ ò ń retí àkókò kan tí ayé máa dára ju báyìí lọ, tí gbogbo èèyàn á máa gbé pọ̀ lálàáfíà, tí kò ní sí ogun, ìwà ọ̀daràn àti ìfojú-ẹni-gbolẹ̀ mọ́? Tó bá jẹ́ pé ohun tó ò ń fẹ́ nìyẹn, ìtàn kan tó ṣeé ṣe kó o mọ̀ dáadáa lè múnú ẹ dùn. Ìtàn yẹn ni ìtàn Nóà, ọkùnrin rere kan tó kan ọkọ̀ áàkì tó gba ẹ̀mí ẹ̀ àti tàwọn ará ilé rẹ̀ là nígbà tí Ìkún-omi tó kárí ayé pa àwọn èèyàn búburú run.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ìtàn táwọn èèyàn mọ̀ bí ìtàn yẹn. Ìtàn nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Nóà wà lákọọ́lẹ̀ ní orí kẹfà sí ìkẹsàn-án ìwé Jẹ́nẹ́sísì nínú Bíbélì, Kùránì sì tún ìtàn yìí sọ. Bákan náà ló tún wà nínú ìtàn àtẹnudẹ́nu àìmọye àwọn èèyàn kárí ayé, kódà ó wà nínú ìtàn àtẹnudẹ́nu ilẹ̀ Yorùbá. Ṣé lóòótọ́ ni Ìkún-omi náà ṣẹlẹ̀ àbí àlọ́ kan tí wọ́n kàn fi ń kọ́ àwọn èèyàn lọ́gbọ́n? Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ti kọjá táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń fa ọ̀rọ̀ yìí mọ́ra wọn lọ́wọ́. Síbẹ̀, Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàlàyé ìtàn yìí lọ́nà tó ṣe kedere, ó sì jẹ́ kó hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni, kì í ṣe ìtàn àròsọ. Ìwọ wo ohun tó sọ:

Ìtàn tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì nípa Ìkún-omi sọ ọdún, oṣù àti ọjọ́ tó bẹ̀rẹ̀, ó sì sọ ìgbà tí ọkọ̀ áàkì náà gúnlẹ̀ àti ibi tó gúnlẹ̀ sí, bákan náà ló sọ ìgbà tí Ìkún-omi náà gbẹ láyé. Ó tún sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí ọkọ̀ áàkì yẹn ṣe rí, ìyẹn gígùn rẹ̀, títóbi rẹ̀, gíga rẹ̀ àti fífẹ̀ rẹ̀ tó fi mọ́ àwọn ohun èlò tí wọ́n fi kàn án. Àlọ́ kì í sábàá sọ irú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ìyẹn ló mú kí ìtàn náà yàtọ̀ sí àlọ́.

Àwọn àkọsílẹ̀ méjì wà nínú Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ìdílé táwọn èèyàn ti ṣẹ̀ wá, àkọsílẹ̀ méjèèjì ló sì jẹ́rìí sí i pé èèyàn tó ti gbélé ayé rí ni Nóà. (1 Kíróníkà 1:4; Lúùkù 3:36) Ẹni tó ń ṣèwádìí jinlẹ̀ gan-an ni Ẹ́sírà àti Lúùkù tí wọ́n ṣèwádìí nípa ìtàn yẹn. Lúùkù ṣèwádìí ìtàn ìlà ìdílé Jésù, ó sì rí i pé inú ìran Nóà ló ti wá.

Aísáyà àti Ìsíkíẹ́lì tí wọ́n jẹ́ wòlíì tún mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ nípa Nóà àti Ìkún-omi, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àpọ́sítélì Pétérù náà sì mẹ́nu bà wọ́n.—Aísáyà 54:9; Ìsíkíẹ́lì 14:14, 20; Hébérù 11:7; 1 Pétérù 3:19, 20; 2 Pétérù 2:5.

Jésù Kristi náà sọ̀rọ̀ nípa Ìkún-omi nígbà tó sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò rí pẹ̀lú ní àwọn ọjọ́ Ọmọ ènìyàn: wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì, ìkún omi sì dé, ó sì pa gbogbo wọn run.” (Lúùkù 17:26, 27) Ká ní Ìkún-omi kankan ò wáyé ni, ohun tí Jésù sọ nípa “àwọn ọjọ́ Ọmọ ènìyàn” ì bá má ní ìtumọ̀ kankan.

Àpọ́sítélì Pétérù sàsọtẹ́lẹ̀ pé “àwọn olùyọṣùtì” tí wọ́n á máa pẹ̀gàn ohun tí Bíbélì sọ ń bọ̀. Ó sọ pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú ìdàníyàn wọn, òtítọ́ yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí wọn, pé . . . ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.” Ṣó yẹ kí “òtítọ́ yìí” bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí tiwa náà? Rárá o! Pétérù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 3:3-7.

Lẹ́ẹ̀kan sí i, Ọlọ́run tún máa pa àwọn ẹni ibi run, àwọn tó máa là á já yóò sì tún wà bíi tìgbà yẹn. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nóà, a lè wà lára àwọn olódodo tó máa rí ìgbàlà tí wọ́n á sì dénú ayé tó dára ju ayé tá à ń gbé yìí lọ.