Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọlọ́run Fi Àánú Hàn sí Mi

Ọlọ́run Fi Àánú Hàn sí Mi

Ọlọ́run Fi Àánú Hàn sí Mi

Gẹ́gẹ́ bí Bolfenk Moc̆nik ṣe sọ ọ́

“Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, ọmọ mi, mọ́kàn le.” Ìyá mi ló sọ ọ̀rọ̀ akin tó jẹ́ kánjúkánjú yìí, bó sì ṣe sọ ọ́ tán ló dì mọ́ mi. Lẹ́yìn náà, àwọn ológun mú mi lọ, ìgbẹ́jọ́ sì bẹ̀rẹ̀. Níkẹyìn, adájọ́ kéde pé kí n lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí bà nínú jẹ́ lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́, ká sòótọ́, ńṣe lọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́ gan-an.

ỌDÚN 1952 ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí wáyé lórílẹ̀ èdè Slovenia. a Àmọ́, ọdún 1930, ìyẹn ohun tó lé ní ogún ọdún ṣáájú àkókó tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ni ìtàn mi ti bẹ̀rẹ̀. Ìyẹn ni ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, (ìyẹn orúkọ tí wọn máa ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn) máa ṣe ìrìbọmi fún àwùjọ àwọn èèyàn kan lápapọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè mi. Àwọn òbí mi, Berta àti Franz Moc̆nik wà lára àwọn tó ṣèrìbọmi náà. Ọmọ ọdún mẹ́fà ni mí nígbà yẹn, àbúrò mi obìnrin tó ń jẹ́ Majda sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin. Ilé wa tó wà ní ìlú Maribor ni wọ́n máa ń lò fún gbogbo ìgbòkègbodò Kristẹni.

Nígbà tó di ọdún 1933, Adolf Hiltler gba ìjọba nílẹ̀ Jámánì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé ní Jámánì ló ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè Yugoslavia láti lọ máa wàásù ìhìn rere níbẹ̀. Inú àwọn òbí mi máa ń dùn láti gba àwọn adúróṣinṣin èèyàn bẹ́ẹ̀ lálejò. Ọ̀kan lára irú àwọn àlejò bẹ́ẹ̀ tí mo lè rántí dáadáa ni Arákùnrin Martin Poetzinger, ẹni tó lo ọdún mẹ́sàn-án ní àgọ́ tí ìjọba Násì ti ń fàwọn èèyàn ṣiṣẹ́ àṣekú. Nígbà tó yá, ó di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì sìn nínú ìgbìmọ̀ náà láti ọdún 1977 sí 1988.

Nígbà tí Arákùnrin Martin bá wá sọ́dọ̀ wa, orí bẹ́ẹ̀dì mi ló máa ń sùn sí, èmi àti àbúrò mi á sì lọ sùn sínú yàrá àwọn òbí wa. Arákùnrin Martin ní ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kékeré kan tó lẹ́wà gan-an, tó sì ṣeé tì bọ àpò. Ìwé yìí ló mú kí ń máa ronú nípa ọ̀pọ̀ nǹkan bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì kéré. Mo fẹ́ràn kí n máa ṣí ìwé yẹn wò.

Àkókò Ìdánwò Tó Le Kú

Ní ọdún 1936, nígbà tí agbára Hitler wá pọ̀ sí i, àwọn òbí mi lọ sí ìpàdé àgbáyé kan tó fa kíki, èyí tí wọ́n ṣe nílùú Lucerne, lórílẹ̀-èdè Switzerland. Ohùn bàbá mi dùn ó sì rinlẹ̀ dáadáa, èyí ló mú kí wọ́n yàn án pé kó wá ka àsọyé Bíbélì, wọ́n sì gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀ káwọn èèyàn lè máa gbọ́ àsọyé náà káàkiri ilẹ̀ Slovenia. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìpàdé àgbáyé tó fa kíki yẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni tó bùáyà sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Yúróòpù. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n fìyà jẹ tí wọ́n sì kú sínú àgọ́ tí ìjọba Násì ti ń fàwọn èèyàn ṣiṣẹ́ àṣekú.

Nígbà tó di oṣù September ọdún 1939, Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, nígbà tó fi máa di oṣù April ọdún 1941 ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jámánì ti gba àwọn apá ibì kan nílẹ̀ Yugoslavia. Wọ́n ti gbogbo ilé ìwé tó wà nílẹ̀ Slovenia pa. Wọ́n ní a ò gbọ́dọ̀ sọ èdè wa ní gbangba. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí rògbòdìyàn ìṣèlú, wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ogun. b Nítorí èyí, àwọn aláṣẹ mú ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì pa àwọn kan lára wọn. Ọ̀dọ́kùnrin kan tí mo mọ̀ dáadáa tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Franc Drozg wà lára àwọn tí wọ́n pa náà. Nǹkan bíi kìlómítà kan ààbọ̀ sí ilé wa ni ibi táwọn ọmọ ogun Násì ti ń pa àwọn èèyàn. Mo ṣì rántí bí màmá mi ṣe máa ń fi aṣọ dí etí nítorí ariwo ìbọn. Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí Franc sọ nínú lẹ́tà ìdágbére tó kọ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kan ni pé: “A ó pàdé nínú Ìjọba Ọlọ́run.”

Mo Ṣe Ohun Kan Tí Mo Kábàámọ̀ Rẹ̀ Gan-an

Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni mí nígbà yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí Franc ṣe dúró ṣinṣin yẹn wú mi lórí gan-an, àmọ́ ẹ̀rù bà mí. Ṣé bémi náà ṣe máa kú rèé? Ìgbàgbọ́ mi ò lágbára tó, mi ò sì ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Nígbà tó yá, wọ́n pè mí fún iṣẹ́ ológun. Ẹ̀rù tó ń bà mí ti bo ìgbàgbọ́ mi mọ́lẹ̀, bí mo ṣe di ọmọ ogun nìyẹn.

Ibi táwọn ọmọ ogun ti ń bá àwọn ará Rọ́ṣíà jà ni wọ́n rán mi lọ. Kò pẹ́ tí mo fi rí àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́gbẹ́ mi tí wọ́n ń kú lọ́tùn-ún-lósì. Ogun yẹn le kú. Ẹ̀rí ọkàn mi wá bẹ̀rẹ̀ sí í dà mí láàmù gan-an. Mo bẹ Jèhófà pé kó dárí jì mí, mo sì ní kó fún mi lókun tí màá fi máa rìn ní ọ̀nà títọ́. Nígbà táwọn ọmọ ogun kan wá gbéjà kò wá, ìdàrúdàpọ̀ ṣẹlẹ̀, bí mo ṣe ráyè sá lọ nìyẹn.

Mo mọ̀ pé tọ́wọ́ bá fi tẹ̀ mí pẹ́nrẹ́n, wọ́n máa pa mí dà nù ni. Fún oṣù méje lẹ́yìn náà, ńṣe ni mo ń fara pa mọ́ káàkiri. Mo tiẹ̀ dọ́gbọ́n fi káàdì pélébé kan ránṣẹ́ sí Majda, àbúrò mi. Ọ̀rọ̀ tí mo kọ sínú rẹ̀ rèé: “Mo ti kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi àkọ́kọ́, mo sì ti ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá mìíràn báyìí.” Ohun tí mo ní lọ́kàn ni pé Ọlọ́run ni mo fẹ́ máa ṣiṣẹ́ fún báyìí, àmọ́ ó tó ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn náà kí n tó wá ṣe bẹ́ẹ̀.

Ní oṣù August, ọdún 1945, ìyẹn oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Jámánì túúbá fún àwọn ọmọ ogun tó ń bá wọn jà, ó ṣeé ṣe fún mi láti padà sí ìlú Maribor. Ohun kan tó yà mí lẹ́nu ni pé, nínú ìdílé wa, kò sẹ́ni tó bógun tó le kú yẹn lọ! Èmi, bàbá mi, ìyá mi, àti àbúrò mi yè é. Àmọ́ ṣá o, nígbà yẹn, ìjọba Kọ́múníìsì, tó jẹ́ ìjọba bóofẹ́-bóokọ̀ ló ń ṣàkóso, wọ́n sì ń ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wọn àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ ní bòókẹ́lẹ́.

Ní oṣù February ọdún 1947, wọ́n dájọ́ ikú fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ta kan tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Orúkọ wọn ni: Rudolf Kalle, Dus̆an Mikić àti Edmund Stropnik. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n yí ìdájọ́ yẹn padà, wọ́n ní kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lọ ṣẹ̀wọ̀n ogún ọdún. Àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn gbé ìròyìn nípa gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jáde fáyé gbọ́, àwọn èèyàn sì wá rí ìwà àìdáa táwọn aláṣẹ hù sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí mo ka àwọn ìròyìn náà, ó dùn mí dọ́kàn. Ìgbà yẹn ni mo wá mọ ohun tó yẹ kí n ṣe.

Ìgbàgbọ́ Mi Sọjí Padà

Ojú mi rí màbo kí n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ pé mo ní láti fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nítorí náà, mo túbọ̀ fi kún ìsapá mi kémi náà lè máa wàásù ní bòókẹ́lẹ́. Nítorí pé mo tẹra mọ́ Bíbélì kíkà, ìgbàgbọ́ mi wá lágbára débi ti mo fi lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà àìmọ́, irú bí lílo tábà.

Lọ́dún 1951, mo ṣèrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé Kristẹni, èyí tí mo ti pa tì láti nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn. Níkẹyìn, Jèhófà wá di Bàbá mi tòótọ́. Mo wá rí i pé olóòótọ́ àti adúróṣinṣin ni, ìfẹ́ rẹ̀ kì í sì í kùnà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣe àwọn ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́, àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé, Ọlọ́run ń dárí jini fi mí lọ́kàn balẹ̀ gan-an. Bàbá onífẹ̀ẹ́ ni Ọlọ́run, ńṣe ló ń fi “àwọn okùn ìfẹ́” fà mí.—Hóséà 11:4.

Láwọn ìgbà tí nǹkan fi le koko yẹn, a máa ń ṣèpàdé ní bòókẹ́lẹ́ ní ilé àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì ń fi ọgbọ́n bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ. Kò tíì pé ọdún kan tí mo ṣèrìbọmi táwọn aláṣẹ fi mú mi. Màmá mi rí mi fúngbà díẹ̀ kí wọ́n tó gbẹ́jọ́ mi. Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ ìtàn yìí, màmá mi dì mọ́ mi, ó sì sọ pé: “Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, ọmọ mi, mọ́kàn le.” Nígbà tí adájọ́ sọ pé mo máa lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún, mi ò gbọ̀n jìnnìjìnnì, ńṣe lọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.

Inú yàrá ẹ̀wọ̀n kótópó kan báyìí ni wọ́n jù mí sí pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́ta mìíràn, mo sì lo àǹfààní yẹn láti wàásù fáwọn ẹlẹ́wọ̀n náà, àwọn tó jẹ́ pé kò sí bí wọ́n ì bá ṣe gbọ́ ìwàásù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ní Bíbélì tàbí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ó yà mí lẹ́nu gan-an pé mo lè rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tí mo sì lè ṣàlàyé wọn, ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé mo ti jèrè púpọ̀ látinú ìdákẹ́kọ̀ọ́ tí mo ti fi ọ̀pọ̀ àkókó ṣe ṣáájú ìgbà yẹn. Mo máa ń sọ fún àwọn tá a jọ ń ṣẹ̀wọ̀n pé tó bá jẹ́ pé ọdún márùn-ún ni máa fi wà lẹ́wọ̀n, Jèhófà á fún mi lókun láti fara dà á. Àmọ́, ó lè ṣí ọ̀nà àbáyọ sílẹ̀ fún mi kí ọdún márùn-ún tó pé. Mo sì mọ̀ pé tí Ọlọ́run bá ṣí ọ̀nà àbáyọ sílẹ̀ lóòótọ́, kò sẹ́ni tó tó bẹ́ẹ̀ láti tì í!

A Lómìnira Díẹ̀

Ní oṣù November ọdún 1953, ìjọba kéde pé àwọn dá gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lẹ́wọ̀n sílẹ̀. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni mo wá mọ̀ pé wọ́n ti mú òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ ìwàásù wa kúrò ní oṣù méjì ṣáájú kí wọ́n tó dá wa sílẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ la bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúntò ọ̀ràn nípa ìjọ àti ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù. A rí ibì kan tá a ti lè máa ṣèpàdé nísàlẹ̀ ilé kan ní àárín ìlú Maribor. A gbé àkọlé kan sára ògiri ilé náà tó kà pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ìjọ Maribor.” Ayọ̀ kúnnú wa gan-an pé à ń sin Jèhófà lómìnira, a sì mọyì rẹ̀ gan-an.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1961, mo di aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn àwọn tí wọ́n máa ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù. Ní nǹkan bí oṣú mẹ́fà lẹ́yìn náà, wọ́n pè mí kí n wá ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Yugoslavia. Ìlú Zagreb, nílẹ̀ Croatia ló wà nígbà yẹn. Yàrá kékeré kan ni wọ́n fi ṣé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nígbà yẹn, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ló sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Àwọn Kristẹni ará wa tí wọ́n ń gbé nítòsí máa ń wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lójoojúmọ́ láti wá ṣèrànwọ́ nínú títẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ní àwọn èdè ìbílẹ̀.

Àwọn arábìnrin tí wọ́n ń gbé nítòsí pẹ̀lú máa ń wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Lára iṣẹ́ tí wọ́n máa ń ṣe ni dídi àwọn ìwé ìròyìn pa pọ̀. Oríṣiríṣi iṣẹ́ ni mo máa ń ṣe nígbà yẹn, irú bíi kíkàwé láti ṣàtúnṣe àwọn àṣìṣe tó bá wà níbẹ̀, títúmọ̀ èdè, fífi lẹ́tà jíṣẹ́, mo sì máa ń ṣàkójọ àwọn àkọsílẹ̀ kan.

Iṣẹ́ Mi Yí Padà

Lọ́dún 1964, wọ́n yàn mí pé kí n máa ṣe iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, ìyẹn ṣíṣèbẹ̀wò déédéé sáwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè kan láti fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Mo mọyì iṣẹ́ yìí gan-an. Lọ́pọ̀ ìgbà, bọ́ọ̀sì tàbí ọkọ̀ ojú irin ni mo máa ń wọ̀ láti ìjọ kan sí òmíràn. Ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni mo máa ń gun kẹ̀kẹ́ tàbí kí n fẹsẹ̀ rìn kí n tó lè dé ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láwọn abúlé kéékèèké. Láwọn ìgbà míì, ńṣe ni ẹrọ̀fọ̀ máa ń mù mí dé ọrùn ẹsẹ̀.

Nínú ìgbésí ayé ọmọ ẹdá, àwọn ìgbà apanilẹ́rìn-ín kan máa ń wà. Lọ́jọ́ kan, arákùnrin kan fi kẹ̀kẹ́ kan tí ẹṣin ń fà gbé mi lọ sí ìjọ tó kàn tí mo fẹ́ bẹ̀ wò. Bá a ṣe ń lọ lójú ọ̀nà eléruku kan, ọ̀kan lára àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ yẹn yọ. Yakata làwa méjèèjì ṣubú sílẹ̀. Bá a ṣe jókòó sílẹ̀ẹ́lẹ̀ tá à ń wo ẹṣin yẹn, bẹ́ẹ̀ lòun náà dúró gan-n-boro, tó ń wò wá tìyanu-tìyanu. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, a ṣì máa ń rẹ́rìn-ín tá a bá rántí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Mi ò jẹ́ gbàgbé ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn táwọn ọ̀rẹ́ wa àtàtà tó wà láwọn àrọko yẹn fi hàn, ó sì máa ń múnú mi dùn nígbà gbogbo.

Ní ìlú kan tó ń jẹ́ Novi Sad, mo pàdé obìnrin kan tó ń jẹ́ Marika, aṣáájú-ọ̀nà ni. Ìfẹ́ tó ní sí ẹ̀kọ́ Bíbélì àti ìtara tó fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wú mi lórí gan-an débi pé ó wù mí láti fẹ́ ẹ. Lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, a bẹ̀rẹ̀ sí í rìnrìn-àjò láti lọ bẹ àwọn ìjọ wò.

Ìdílé mi fara da ipò lílekoko láwọn àkókò táwọn aláṣẹ fòfin de iṣẹ́ ìwàásù. Níbi tí bàbá mi ti ń ṣiṣẹ́, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀tá nígbà ogun, bí wọ́n ṣe dá a dúró ní ibiṣẹ́ náà nìyẹn. Ó jà fitafita pé kí wọ́n tiẹ̀ lè pè é padà, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ já sí, nítorí èyí ìrẹ̀wẹ̀sì bá a gidigidi. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ tutù fúngbà díẹ̀, àmọ́, ìgbàgbọ́ rẹ̀ tún sọjí padà kó tó dí pé ó kú. Ó jẹ́ onítara nínú ìjọ rẹ̀ títí tó fi kú lọ́dún 1984. Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni màmá mi, ó sì ṣe olóòótọ́ títí tó fi kú lọ́dún 1965. Majda, àbúrò mi obìnrin ṣì ń sìn ní ìjọ tó wà nílùú Maribor.

A Lọ Ṣiṣẹ́ Ìwàásù ní Orílẹ̀-Èdè Austria

Lọ́dún 1972, wọ́n ní kí èmi àti Marika, ìyàwó mi lọ sórílẹ̀-èdè Austria láti lọ wàásù fún ọ̀pọ̀ àwọn ará Yugoslavia tí wọ́n ń gbé Austria, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Nígbà tá a dé ìlú Vienna, tó jẹ́ olú ìlú Austria, a ò mọ̀ pé ibẹ̀ máa wá di ibi tá a ó ti máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa fún ìgbà pípẹ́. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a dá àwọn ìjọ tuntun àtàwọn àwùjọ tó ń sọ àwọn èdè tí wọ́n ń sọ ní Yugoslavia sílẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè Austria.

Láìpẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, mò ń bẹ àwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ tó ń pọ̀ sí i yìí wò káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Nígbà tó yá, wọ́n ní ká tún lọ ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Jámánì àti Switzerland, níbi tí wọ́n ti dá irú àwọn ìjọ yẹn sílẹ̀. Mo ṣèrànwọ́ láti ṣètò àwọn àpéjọ àti àpèjọ àgbègbè láwọn orílẹ̀-èdè yìí.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ara àwọn Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń ṣèbẹ̀wò sáwọn àpèjọ ńlá bẹ́ẹ̀, èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún mi láti tún pàdé Arákùnrin Martin Poetzinger tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ìtàn mi. A rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ láti nǹkan bí ogójì ọdún sẹ́yìn nígbà tá a fi máa ń gbà á lálejò nílé wa. Mo wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘Ṣé ó rántí bí mo ṣe fẹ́ràn láti máa ṣí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ rẹ̀ wò?’

Ó wá sọ pé: “Dúró ná.” Bó ṣe sọ bẹ́ẹ̀ tán ló jáde kúrò nínú yàrá. Nígbà tó padà dé, ó mú ìwé yẹn lé mi lọ́wọ́, ó sì sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi, mo fún ẹ ní ẹ̀bùn yìí.” Ìwé yẹn ṣì wà níbi ìkówèésí mi títí dòní, mo sì fẹ́ràn rẹ̀ gan-an.

Àìlera Kò Dí Mi Lọ́wọ́

Lọ́dún 1983, dókítà sọ pé mo ní àrùn jẹjẹrẹ, kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà náà tí wọ́n sọ fún mi pé ikú ni àìsàn yìí máa já sí. Nǹkan ò fararọ láwọn àkókò yìí rárá, pàápàá jù lọ fún Marika, ìyàwó mi. Àmọ́ nítorí pé ó ń tọ́jú mi tìfẹ́tìfẹ́, táwọn arákùnrin àti arábìnrin wa náà ò sì dá mi dá ìṣòro mi, mo ṣì ń gbádùn ìgbésí ayé alárinrin.

Èmi àti Marika ń bá iṣẹ́ alákòókò kíkún lọ nílùú Vienna. Lọ́pọ̀ ìgbà mo máa ń tilé lọ sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa láràárọ̀ láti lọ ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè, Marika á sì máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ láàárín ìlú ní tiẹ̀. Inú mi dùn gan-an bí mo ṣe ń rí àwùjọ kékeré ti àwọn ará Yugoslavia tí wọ́n ń gbé nílẹ̀ Austria bí wọ́n ṣe ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí iye wọn sì ti lé ní ẹ̀ẹ́dégbèje [1,300] báyìí. Èmi àti Marika ti láǹfààní láti ran ọ̀pọ̀ lára wọn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, mo láǹfààní láti kópa nínú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tuntun tá a kọ́ sí orílẹ̀-èdè tó para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí. A ṣe ọ̀kan ní Croatia lọ́dún 1999, a ṣe òmíràn ní Slovenia lọ́dún 2006. Mo wà lára àwọn tí wọ́n ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn, tí wọ́n ní kó wá sọ àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ ìwàásù láwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn ní nǹkan bí àádọ́rin ọdún sẹ́yìn.

Ká sòótọ́, Bàbá onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó sì ṣe tán láti dárí àwọn ìṣìnà àti àṣìṣe wa jì wá lọ́nà títóbi. Mo mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà kì í ṣọ́ àwọn àṣìṣe wa! (Sáàmù 130:3) Ní tòdodo, Ọlọrun ṣojú rere sí mi ó sì fàánú hàn sí mi. c

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orílẹ̀-èdè mẹ́fà, títí kan ilẹ̀ Slovenia ló para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè Yugoslavia nígbà kan rí.

b Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tó bá Bíbélì mu táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í lọ sójú ogun, wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé,” tó wà lójú ìwé 22 nínú ìwé ìròyìn yìí.

c Arákùnrin Bolfenk Moc̆nik kú ní ọjọ́ kọkànlá oṣù April, ọdún 2008, nígbà tá à ń ṣàkójọ àpilẹ̀kọ yìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwòrán láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún: Àwọn òbí mi, Berta àti Franz Moc̆nik, Majda àbúrò mi, àti èmi, ní ìlú Maribor lórílẹ̀-èdè Slovenia láwọn ọdún 1940

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àti Marika ìyàwó mi