Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwọ Kò Mọ Ibi Tí Yóò Ti Ṣàṣeyọrí!

Ìwọ Kò Mọ Ibi Tí Yóò Ti Ṣàṣeyọrí!

Ìwọ Kò Mọ Ibi Tí Yóò Ti Ṣàṣeyọrí!

“Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere.”—ONÍW. 11:6.

1. Kí nìdí tí ìdàgbàsókè irúgbìn fi jẹ́ ohun ìyanu àtohun tó lè jẹ́ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

 IṢẸ́ àgbẹ̀ gba sùúrù. (Ják. 5:7) Ìdí ni pé, lẹ́yìn tí àgbẹ̀ bá gbin irúgbìn kan, ó ní láti fara balẹ̀ dúró dìgbà tá bẹ̀rẹ̀ sí í hù. Tí nǹkan bá sì lọ bó ṣe yẹ, èèhù irúgbìn yìí á máa yọrí jáde bọ̀ látinú ilẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Irúgbìn náà á wá máa dàgbà títí yóò fi so èso. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ èso oko náà yóò gbó tó láti kórè. Ẹ ò rí i pé ohun ìyanu ló jẹ́ láti rí ọ̀nà àrà tí irúgbìn gbà ń dàgbà! Tá a bá sì ń rántí pé Ọlọ́run ló ń jẹ́ kó dàgbà, ìyẹn náà á tún jẹ́ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Òótọ́ ni pé a lè bójú tó irúgbìn náà, ká tiẹ̀ máa fúnra wa bomi rin ín tí òjò kò bá rọ̀. Àmọ́ Ọlọ́run nìkan ló lè mú kó dàgbà.—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 3:6.

2. Kí ni Jésù kọ́ni nípa bí ẹnì kan ṣe ń di ọmọlẹ́yìn nínú àwọn àpèjúwe tá a gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí?

2 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, Jésù fi iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run wé bí àgbẹ̀ ṣe ń fúnrúgbìn. Nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa àwọn ilẹ̀ tó yàtọ̀ síra, ó jẹ́ ká mọ̀ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé àgbẹ̀ náà, ìyẹn akéde Ìjọba Ọlọ́run, gbin irúgbìn tó dára, bí ọkàn ẹni tó wàásù fún ṣe rí ló máa pinnu bóyá irúgbìn náà yóò dàgbà tàbí kò ní dàgbà. (Máàkù 4:3-9) Nínú àpèjúwe afúnrúgbìn tó sùn, Jésù ṣàlàyé pé àgbẹ̀ náà kò mọ bí irúgbìn náà ṣe ń dàgbà, ìyẹn bí ẹnì kan ṣe ń di ọmọlẹ́yìn. Ìdí ni pé Ọlọ́run ló ń mú kí nǹkan dàgbà, kì í ṣe nípa ìsapá èèyàn. (Máàkù 4:26-29) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá gbé àpèjúwe mẹ́ta mìíràn tí Jésù ṣe yẹ̀ wò, ìyẹn àpèjúwe hóró músítádì, ti ìwúkàrà àti ti àwọ̀n ńlá. a

Àpèjúwe Hóró Músítádì

3, 4. Apá wo lára ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù fi wé hóró músítádì?

3 Ohun méjì ni àpèjúwe hóró músítádì, tóun náà wà nínú ìwé Máàkù orí kẹrin jẹ́ ká mọ̀. Àkọ́kọ́ ni báwọn èèyàn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń pọ̀ sí i lọ́nà tó bùáyà. Èkejì ni bí Ọlọ́run ṣe ń dáàbò bo àwọn tó ń tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ Ìjọba Rẹ̀. Jésù sọ pé: “Kí ni ohun tí a ó fi ìjọba Ọlọ́run wé, tàbí àpèjúwe wo ni a ó fi gbé e kalẹ̀? Bí hóró músítádì kan, tí ó jẹ́ pé ní àkókò tí a gbìn ín sínú ilẹ̀, ó jẹ́ tín-ń-tín jù lọ nínú gbogbo irúgbìn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé—ṣùgbọ́n nígbà tí a ti gbìn ín, ó yọ, ó sì tóbi ju gbogbo ọ̀gbìn oko yòókù, ó sì mú àwọn ẹ̀ka ńlá jáde, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lè rí ibùwọ̀ lábẹ́ òjìji rẹ̀.”—Máàkù 4:30-32.

4 Níhìn-ín, Jésù lo àpèjúwe tó jẹ́ ká rí bí “ìjọba Ọlọ́run” ṣe ń tẹ̀síwájú, èyí tó hàn kedere látinú bí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń tàn káàkiri àti bí ìjọ Kristẹni ṣe ń gbèrú láti ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni títí di àkókò yìí. Hóró músítádì jẹ́ èso tín-ń-tín kan, tá a lè fi ṣàkàwé ohun tó bá kéré gan-an. (Fi wé Lúùkù 17:6.) Àmọ́ tó bá yá, hóró músítádì tín-ń-tín yìí lè wá di irúgbìn tó ga tó èèyàn ní ìdúró, á sì tún láwọn ẹ̀ka tó nípọn díẹ̀, ìyẹn ni pé, ó lè di ohun tá a lè pè ní igi.—Mát. 13:31, 32.

5. Báwo ni ìjọ Kristẹni ṣe gbèrú ní ọ̀rúndún kìíní?

5 Látìgbà tí Ọlọ́run ti fẹ̀mí mímọ́ yan ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni ni ìjọ Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrú díẹ̀díẹ̀. Láàárín àkókò kúkúrú, ìjọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn kéréje yìí wá di èyí tó ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn onígbàgbọ́. (Ka Ìṣe 2:41; 4:4; 5:28; 6:7; 12:24; 19:20.) Nígbà tó fi máa tó ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ọmọlẹ́yìn tó ń ṣe iṣẹ́ ìkórè ti pọ̀ gan-an débi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ nínú ìwé tó kọ sáwọn ará ìjọ Kólósè pé a ti “wàásù [ìhìn rere] nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kól. 1:23) Ìbísí yìí mà pọ̀ o!

6, 7. (a) Báwo ni ìjọ Kristẹni ṣe ti gbèrú tó láti ọdún 1914? (b) Ìtẹ̀síwájú wo ló ṣì tún máa wáyé?

6 Àwọn ẹ̀ka “igi” músítádì, ìyẹn ìjọ Kristẹni, ti gbèrú ju báwọn èèyàn ṣe rò lọ látìgbà tí Ọlọ́run ti fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lọ́run lọ́dún 1914. Àwọn èèyàn Ọlọ́run ti fojú ara wọn rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Aísáyà sọ, pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè.” (Aísá. 60:22) Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, àwùjọ kékeré ti àwọn ẹni àmì òróró tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run kò lè mọ̀ rárá pé, tó bá fi máa di ọdún 2008, àwọn Ẹlẹ́rìí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méje ni yóò máa kópa nínú iṣẹ́ ìkórè náà ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n [230] lọ. Dájúdájú, ìtẹ̀síwájú yìí yani lẹ́nu gan-an ni, àfi bíi ti hóró músítádì inú àpèjúwe Jésù!

7 Ṣùgbọ́n ṣé ìtẹ̀síwájú yẹn ti wá parí síbẹ̀ ni? Rárá o. Tó bá yá, gbogbo èèyàn tó bá wà ní ayé ni yóò jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà yẹn, Ọlọ́run á ti pa gbogbo àwọn alátakò run. Kì í ṣe àwọn èèyàn ló máa ṣe é o, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fúnra rẹ̀ ló máa ṣe àyípadà yẹn. (Ka Dáníẹ́lì 2:34, 35.) Ìgbà yẹn la óò wá rí ìmúṣẹ ìkẹyìn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tí wòlíì Aísáyà sọ, pé: “Ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísá. 11:9.

8. (a) Àwọn wo ni àwọn ẹyẹ inú àpèjúwe Jésù ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí ni Ọlọ́run ń dáàbò bo wá lọ́wọ́ rẹ̀ nísinsìnyí?

8 Jésù sọ pé àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, tó jẹ́ ẹyẹ ìṣàpẹẹrẹ, rí ibùwọ̀ lábẹ́ òjìji Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn ẹyẹ yìí kò ṣàpẹẹrẹ àwọn ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run tó ń fẹ́ ṣa àwọn irúgbìn àtàtà jẹ o, bíi tàwọn ẹyẹ inú àpèjúwe ọkùnrin afúnrúgbìn èyí tó fúnrúgbìn sórí onírúurú ilẹ̀. (Máàkù 4:4) Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn olóòótọ́ ọkàn tó ń wá ààbò nínú ìjọ Kristẹni làwọn ẹyẹ inú àpèjúwe yìí dúró fún. Kódà, nísinsìnyí Ọlọ́run ń dáàbò bo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn àṣà ayé burúkú yìí, tó ń sọni di ẹlẹ́gbin lójú rẹ̀. (Fi wé Aísáyà 32:1, 2.) Bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe fi Ìjọba Mèsáyà wé igi, ó sì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Orí òkè ńlá ibi gíga Ísírẹ́lì ni èmi yóò gbé e lọ gbìn sí, ó dájú pé òun yóò sì yọ ẹ̀tun, yóò sì so èso, yóò sì di kédárì ọlọ́lá ọba. Abẹ́ rẹ̀ sì ni gbogbo ẹyẹ tí ó ní onírúurú ìyẹ́ apá yóò máa gbé ní ti tòótọ́; inú òjìji àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé ni wọn yóò máa gbé.”—Ìsík. 17:23.

Àpèjúwe Ìwúkàrà

9, 10. (a) Kí ni Jésù fi àpèjúwe ìwúkàrà ṣàlàyé? (b) Nínú Bíbélì, kí ni ìwúkàrà sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ, ìbéèrè wo la sì máa gbé yẹ̀ wò nípa àpèjúwe ìwúkàrà tí Jésù ṣe?

9 Kì í ṣe gbogbo ìgbà lèèyàn máa ń fojú rí ọ̀nà tí irúgbìn gbà ń dàgbà. Ohun tí Jésù ṣàlàyé nínú àpèjúwe tó sọ tẹ̀ lé e nìyẹn. Ó ní: “Ìjọba ọ̀run dà bí ìwúkàrà, èyí tí obìnrin kan mú, tí ó sì fi pa mọ́ sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ńlá mẹ́ta, títí gbogbo ìṣùpọ̀ náà fi di wíwú.” (Mát. 13:33) Kí ni ìwúkàrà yìí dúró fún, báwo ló sì ṣe kan ìtẹ̀síwájú Ìjọba Ọlọ́run?

10 Nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń fi ìwúkàrà ṣàpẹẹrẹ ẹ̀ṣẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ìwúkàrà lọ́nà yìí, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó wà nínú ìjọ Kọ́ríńtì ìgbàanì ṣe lè ní ipa búburú lórí àwọn ará. (1 Kọ́r. 5:6-8) Ṣé Jésù wá ń lo ìwúkàrà láti fi ṣàpẹẹrẹ ìbísí ohun tí kò dára ni?

11. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń lo ìwúkàrà láyé ọjọ́un?

11 Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ó yẹ ká gbé àwọn kókó mẹ́ta pàtàkì kan yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyè láti lo ìwúkàrà nígbà àjọyọ̀ Ìrékọjá, nígbà míì ó máa ń tẹ́wọ́ gba ẹbọ tó ní ìwúkàrà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń lo ìwúkàrà nígbà ẹbọ ìdàpọ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ìdúpẹ́, èyí tó jẹ́ ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe tí wọ́n fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ìbùkún rẹ̀. Àkókò oúnjẹ ayọ̀ lèyí sì máa ń jẹ́.—Léf. 7:11-15.

12. Kí la rí kọ́ látinú bí Bíbélì ṣe ń lo àfiwé?

12 Ìkejì, nínú Bíbélì wọ́n máa ń lo ohun kan láti fi ṣàkàwé nǹkan kan tí kò dára, nígbà míì wọ́n sì lè lo ohun kan náà láti ṣàkàwé ohun tó tọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ohun tó wà nínú 1 Pétérù 5:8 níbi tí wọ́n ti fi kìnnìún ṣàpẹẹrẹ bíi Sátánì ṣe jẹ́ ẹhànnà, àti eléwu ẹ̀dá. Àmọ́ Bíbélì tún fi Jésù wé kìnnìún nínú Ìṣípayá 5:5, ó pè é ní “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà.” Nínú ọ̀ràn ti Jésù, ńṣe ni Bíbélì fi kìnnìún ṣàpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo tí kì í bẹ̀rù ohunkóhun.

13. Kí ni àpèjúwe Jésù nípa ìwúkàrà jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tó ń mú kẹ́nì kan di ọmọlẹ́yìn Kristi?

13 Ìkẹta, nínú àpèjúwe ìwúkàrà yẹn, Jésù kò sọ pé ìwúkàrà náà sọ gbogbo ìyẹ̀fun di èyí tí kò wúlò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló kàn ń sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe búrẹ́dì. Ńṣe lobìnrin yẹn mọ̀ọ́mọ̀ fi ìwúkàrà sí ìyẹ̀fun náà, gbogbo ìyẹ̀fun náà sì wú bó ṣe ń fẹ́. Níwọ̀n bí obìnrin yìí ti fi ìwúkàrà náà pa mọ́ sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun náà, kò fojú rí bí ìyẹ̀fun náà ṣe ń wú. Èyí jẹ́ ká rántí àpèjúwe ọkùnrin tó fúnrúgbìn, tó sì lọ sùn lóru. Jésù sọ pé: “Irúgbìn náà sì rú jáde, ó sì dàgbà sókè, gan-an bí ó ṣe ṣẹlẹ̀, [ọkùnrin náà] kò mọ̀.” (Máàkù 4:27) Àpèjúwe yìí rọrùn gan-an láti fi ṣàlàyé bá ò ṣe lè mọ ohun tó ń mú kẹ́nì kan di ọmọlẹ́yìn Kristi. Ó ṣeé ṣe kí á má rí ìtẹ̀síwájú ẹni náà níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ ìtẹ̀síwájú yẹn máa ń hàn kedere nígbẹ̀yìn.

14. Apá wo nínú iṣẹ́ ìwàásù ni Jésù fi bí ìwúkàrà náà ṣe sọ gbogbo ìṣùpọ̀ di wíwú ṣàkàwé?

14 Kì í ṣe pé èèyàn ò fojú rí bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń tẹ̀ síwájú nìkan ni, ó tún ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Èyí ni ohun mìíràn tí Jésù fi àpèjúwe ìwúkàrà ṣàlàyé. Ńṣe ni ìwúkàrà yìí sọ gbogbo ìṣùpọ̀ náà di wíwú, ìyẹn “òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ńlá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.” (Lúùkù 13:21) Bíi ti ìwúkàrà yẹn, iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tó ń jẹ́ kí iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn máa pọ̀ sí i ti gbòòrò débi pé, a ti wàásù Ìjọba Ọlọ́run dé “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8; Mát. 24:14) Àǹfààní ńlá mà ló jẹ́ fún wa o, pé a wà lára àwọn tó ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò sí i lọ́nà tó pẹtẹrí bẹ́ẹ̀!

Àwọ̀n Ńlá

15, 16. (a) Sọ àpèjúwe àwọ̀n ńlá náà ní ṣókí. (b) Kí ni àwọ̀n ńlá náà ṣàpẹẹrẹ, apá wo lára ìtẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù sì fi tọ́ka sí?

15 Kì í ṣe bí àwọn tó pe ara wọn ní ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ṣe pọ̀ wọ̀ǹtì-wọnti tó ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe pé kí wọ́n jẹ́ ojúlówó ọmọlẹ́yìn. Kókó pàtàkì yìí ni Jésù fi àpèjúwe míì tó ṣe nípa ìtẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn àpèjúwe àwọ̀n ńlá, tọ́ka sí. Ó ní: “Ìjọba ọ̀run tún dà bí àwọ̀n ńlá kan, tí a jù sínú òkun, tí ó sì kó ẹja onírúurú jọ.”—Mát. 13:47.

16 Onírúurú ẹja ni àwọ̀n ńlá, tó ṣàpẹẹrẹ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run kó. Jésù wá sọ pé: “Nígbà tí [àwọ̀n náà] kún, wọ́n fà á gòkè sí etíkun àti pé, ní jíjókòó, wọ́n kó àwọn èyí àtàtà sínú àwọn ohun èlò, ṣùgbọ́n àwọn tí kò yẹ ni wọ́n dànù. Bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan: àwọn áńgẹ́lì yóò jáde lọ, wọn yóò sì ya àwọn ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn olódodo, wọn yóò sì jù wọ́n sínú ìléru oníná. Níbẹ̀ ni ẹkún wọn àti ìpayínkeke wọn yóò wà.”—Mát. 13:48-50.

17. Ìgbà wo ni iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ tí àpèjúwe àwọ̀n ńlá yẹn tọ́ka sí máa wáyé?

17 Ǹjẹ́ ìdájọ́ ìkẹyìn fáwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́, èyí tí Jésù sọ pé ó máa wáyé nígbà tí òun bá dé nínú ògo ńlá, ni ìyàsọ́tọ̀ inú àpèjúwe yìí ń tọ́ka sí? (Mát. 25:31-33) Rárá o. Ìgbà wíwàníhìn-ín Jésù lákòókò ìpọ́njú ńlá ni ìdájọ́ ìkẹyìn yẹn yóò wáyé. Àmọ́, bí àpèjúwe yẹn ṣe sọ, yíya àwọn ẹja àtàtà àti èyí tí kò yẹ sọ́tọ̀ wáyé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” b Àkókò tá a wà yìí gan-an sì ni, ìyẹn àkókò tó kángun sí ìpọ́njú ńlá náà. Báwo ni iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ yẹn ṣe ń wáyé lákòókò yìí?

18, 19. (a) Báwo la ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ náà lákòókò yìí? (b) Kí ló yẹ káwọn olóòótọ́ ọkàn ṣe? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé lójú ewé 21.)

18 Lákòókò wa yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn tí ẹja inú àpèjúwe yẹn dúró fún là ń pè jáde látinú òkun ọmọ aráyé tó lọ salalu, pé kí wọ́n wá sínú ìjọ Jèhófà. Àwọn kan máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi, àwọn míì máa ń wá sáwọn ìpàdé wa, àwọn míì sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ṣé gbogbo wọn ló máa ń di ojúlówó Kristẹni? Rárá o. Lóòótọ́, a lè ti ‘fà wọ́n gòkè sí etíkun,’ ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wa pé “èyí àtàtà” ni a kó sínú àwọn ohun èlò, èyí tó dúró fún ìjọ Kristẹni. Àwọn tí kò yẹ ni wọ́n kó dà nù, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ wọn yóò dà wọ́n sínú ìléru oníná, èyí tó ṣàpẹẹrẹ ìparun ọjọ́ iwájú.

19 Bí àwọn ẹja kan ṣe jẹ́ èyí tí kò yẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ti dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn dúró. Àwọn míì tí àwọn òbí wọn jẹ́ Kristẹni kò fẹ́ di ọmọlẹ́yìn tó ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù. Wọn ò ṣe tán láti di olùjọsìn Jèhófà, àwọn míì sì sin Jèhófà fúngbà díẹ̀ wọ́n jáwọ́. c (Ìsík. 33:32, 33) Ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn olóòótọ́ ọkàn jẹ́ kí Ọlọ́run kó wọn jọ sínú ìjọ rẹ̀ kó tó di ọjọ́ ìdájọ́ tó ń bọ̀, kí wọ́n má sì kúrò níbi ààbò náà.

20, 21. (a) Kí la rí kọ́ látinú àyẹ̀wò àwọn àpèjúwe Jésù nípa bí irúgbìn ṣe ń dàgbà? (b) Kí ni ìpinnu rẹ báyìí?

20 Kí la ti wá rí kọ́ látinú àyẹ̀wò ráńpẹ́ tá a ṣe nípa àwọn àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa bí irúgbìn ṣe ń dàgbà? Àkọ́kọ́, bí irúgbìn hóró músítádì tí Jésù sọ ṣe dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà làwọn tó ń kọbi ara sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé. Kò sóhun tó lè dá iṣẹ́ Jèhófà dúró kó má tàn kálẹ̀! (Aísá. 54:17) Láfikún sí i, Ọlọ́run tún ń dáàbò bo àwọn tó ń wá “ibùwọ̀ lábẹ́ òjìji [igi] náà” kúrò lọ́wọ́ Sátánì àti ayé burúkú rẹ̀. Ìkejì, Ọlọ́run ló ń mú kó dàgbà. Gẹ́lẹ́ bí ìwúkàrà tí obìnrin yẹn fi pa mọ́ sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ṣe sọ gbogbo rẹ̀ di wíwù láìjẹ́ pé obìnrin yẹn fojú rí i, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé, a kì í sábà fojú rí ìtẹ̀síwájú tó ń wáyé, àmọ́ ó ń ṣẹlẹ̀ dájúdájú! Ìkẹta, kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ìhìn rere ló ń di ọmọlẹ́yìn. Àwọn kan ti dà bí ẹja tí kò yẹ, tí Jésù sọ nínú àpèjúwe rẹ̀.

21 Ohun amóríyá ló mà jẹ́ o, láti rí bí Jèhófà ṣe ń fa ọ̀pọ̀ èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀! (Jòh. 6:44) Èyí sì ń jẹ́ ká máa pọ̀ sí i lọ́nà tó bùáyà káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè. Jèhófà Ọlọ́run lògo yẹ fún gbogbo ìtẹ̀síwájú yìí. Ó yẹ kí rírí tá à ń rí gbogbo ìtẹ̀síwájú yìí mú kí olúkúlùkù wa pinnu láti máa ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá nímọ̀ràn, pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ . . . , nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere, yálà níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, tàbí kẹ̀, bóyá àwọn méjèèjì ni yóò dára bákan náà.”—Oníw. 11:6.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àlàyé tá a fẹ́ ṣe yìí jẹ́ àtúnṣe sí èyí tá a ti ṣe sẹ́yìn nínú Ilé-Ìṣọ́nà June 15, 1992 ojú ìwé 17 sí 22, àti Ile-Iṣọ Na April 1, 1976, ojú ìwé 205 sí 209.

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé apá mìíràn lára iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ni Mátíù 13:39-43 ń tọ́ka sí, àkókò kan náà ló ní ìmúṣẹ pẹ̀lú àpèjúwe àwọ̀n ńlá, ìyẹn nígbà “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ ẹja ìṣàpẹẹrẹ náà kò dáwọ́ dúró, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ fífúnrúgbìn àti kíkórè kò ti dáwọ́ dúró ní gbogbo àkókò òpin yìí.—Ilé Ìṣọ́, October 15, 2000, ojú ìwé 25 àti 26; Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà, ojú ìwé 178 sí 181, ìpínrọ̀ 8 sí 11.

c Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ẹni tó bá ti dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ dúró tàbí tí kò wá sípàdé àwọn èèyàn Jèhófà mọ́ ti dẹni tí kò yẹ táwọn áńgẹ́lì máa ṣà dà nù nìyẹn? Rárá o! Tírú àwọn bẹ́ẹ̀ bá ṣe tán láti padà sọ́dọ̀ Jèhófà tọkàntọkàn, Jèhófà yóò gbà wọ́n padà.—Mál. 3:7.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni àpèjúwe Jésù nípa hóró músítádì kọ́ wa nípa bí iye àwọn tó ń dọmọ ẹ̀yìn ṣe ń pọ̀ sí i àti bí Ọlọ́run ṣe ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ Sátánì àti ayé burúkú rẹ̀?

• Kí ni ìwúkàrà inú àpèjúwe Jésù dúró fún, kí sì ni Jésù jẹ́ ká mọ̀ nípa bí ẹnì kan ṣe ń di ọmọlẹ́yìn?

• Apá wo lára ìtẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù tọ́ka sí nínú àpèjúwe àwọ̀n ńlá?

• Báwo la ṣe lè rí i dájú pé a ò kúrò láàárín àwọn tí Ọlọ́run ti kó sínú “àwọn ohun èlò”?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Kí ni àpèjúwe hóró músítádì kọ́ wa nípa ìtẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Kí la rí kọ́ látinú àpèjúwe ìwúkàrà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Kí ni yíya ẹja àtàtà kúrò nínú èyí tí kò yẹ ṣàpẹẹrẹ?