Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ò Ń Sọ “Èdè Mímọ́” Lọ́nà Tó Já Geere?

Ǹjẹ́ Ò Ń Sọ “Èdè Mímọ́” Lọ́nà Tó Já Geere?

Ǹjẹ́ Ò Ń Sọ “Èdè Mímọ́” Lọ́nà Tó Já Geere?

“Èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ . . . , kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà.”—SEF. 3:9.

1. Ẹ̀bùn àgbàyanu wo ni Jèhófà fún wa?

 ẸLẸ́DÀÁ wa, Jèhófà Ọlọ́run ló fún wa ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe èèyàn. (Ẹ́kís. 4:11, 12) Ó fún Ádámù, èèyàn àkọ́kọ́ ní agbára láti sọ̀rọ̀, ó sì tún fún un ní ọpọlọ láti ṣẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀ tuntun kó bàa lè mọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ sí i. (Jẹ́n. 2:19, 20, 23) Ẹ ò rí i pé ẹ̀bùn àgbàyanu nìyẹn jẹ́! Ó tiẹ̀ ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún aráyé láti bá Bàbá wọn ọ̀run sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì máa mú ìyìn bá orúkọ rẹ̀ ológo.

2. Kí nìdí táwọn èèyàn ò fi sọ èdè kan ṣoṣo mọ́?

2 Fún ẹgbẹ̀rún méjì ó dín ọ̀ọ́dúnrún [1,700] ọdún téèyàn kọ́kọ́ fi wà lórí ilẹ̀ láyé, èdè kan ṣoṣo ni gbogbo èèyàn ń sọ, “irú àwọn ọ̀rọ̀ kan” sì ni wọ́n ní. (Jẹ́n. 11:1) Nígbà tó di ọjọ́ Nímírọ́dù ni ọ̀tẹ̀ dé. Àwọn aláìgbọràn èèyàn wọ̀nyí ta ko ìtọ́ni Jèhófà, wọ́n kóra jọ síbi tá a wá mọ̀ sí Bábélì, wọ́n ní pé àwọn kò ní kúrò lójú kan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé gogoro kan tó kàmàmà, láti “ṣe orúkọ lílókìkí fún” ara wọn, kì í ṣe fún ògo Jèhófà. Nítorí náà, Jèhófà da èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn rú, ó sì mú kí wọ́n máa sọ oríṣiríṣi èdè. Báyìí ni wọ́n ṣe túká lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 11:4-8.

3. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà da èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀ rú ní Bábélì?

3 Lónìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èdè ló wà kárí ayé. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé ó ju ẹgbẹ̀rún méje ó dín igba [6,800] èdè lọ. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èdè wọ̀nyí ló ní ọ̀nà ìrònú tó yàtọ̀ síra. Ó jọ pé nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run da èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn rú, ó mú káwọn èèyàn yẹn gbàgbé èdè kan ṣoṣo tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ pátápátá. Kì í sì í ṣe pé ó fi àwọn ọ̀rọ̀ tuntun rọ́pò rẹ̀ nìkan ni, ó tún yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ronú padà tí wọ́n fi wá ní gírámà èdè tuntun. Abájọ tí orúkọ ibi tí ilé gogoro yẹn wà fi ń jẹ́ “Ìdàrúdàpọ̀” tàbí Bábélì! (Jẹ́n. 11:9) Ohun kan tó gbàfiyèsí ni pé Bíbélì nìkan ló ṣàlàyé tó tẹ́ni lọ́rùn nípa ìdí tí onírúurú èdè fi wà lónìí.

Èdè Tuntun Kan Tó Jẹ́ Èdè Mímọ́

4. Kí ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ wa?

4 Ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run mú kó ṣẹlẹ̀ ní Bábélì kàmàmà gan-an ni, àmọ́ ohun kan wà tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí tó kàmàmà ju bẹ́ẹ̀ lọ tó sì tún ṣe pàtàkì gan-an. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Sefanáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nígbà náà ni èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ . . . , kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sef. 3:9) Kí ni “èdè mímọ́” yẹn, báwo la sì ṣe lè máa sọ ọ́ lọ́nà tó já geere?

5. Kí ni ‘èdè mímọ́,’ kí ló sì máa jẹ́ àbájáde yíyí padà sí èdè náà?

5 Èdè mímọ́ náà jẹ́ òtítọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn ohun tó máa ṣe tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ohun tó jẹ́ ara “èdè” yẹn ni lílóye òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run dáadáa àti bí yóò ṣe sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, tí yóò sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jèhófà ní Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run, tí yóò sì mú ìbùkún ayérayé wá fáwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Kí ló máa jẹ́ àbájáde yíyí padà sí èdè mímọ́ yìí? Bíbélì sọ fún wa pé àwọn èèyàn yóò máa “pe orúkọ Jèhófà” wọ́n yóò sì máa “sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kò ní dà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Bábélì, kàkà bẹ́ẹ̀ yíyí padà sí èdè mímọ́ yìí yóò yọrí sí ìyìn orúkọ Jèhófà àti ìṣọ̀kan àwọn èèyàn rẹ̀.

Kíkọ́ Èdè Mímọ́

6, 7. (a) Kí lèèyàn máa ṣe tó bá fẹ́ kọ́ èdè tuntun, báwo nìyẹn sì ṣe wúlò nínú kíkọ́ èdè mímọ́? (b) Kí la óò gbé yẹ̀ wò báyìí?

6 Nígbà tẹ́nì kan bá fẹ́ kọ́ èdè tuntun, ohun tó máa ṣe yóò ju kó mọ àwọn ọ̀rọ̀ tuntun lọ. Kíkọ́ èdè tuntun gba pé kéèyàn kọ́ bí a ṣe ń ronú lọ́nà tuntun. Ohun tó bọ́gbọ́n mu àti ohun tó ń pani lẹ́rìn-ín ní èdè kan lè yàtọ̀ sí ti èdè mìíràn. Pípe ìró ọ̀rọ̀ tuntun ń mú kéèyàn lo ahọ́n ẹni lóríṣiríṣi ọ̀nà. Ohun kan náà ló máa ń ṣẹlẹ̀ téèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè mímọ́ tí í ṣe ẹ̀kọ́ òtítọ́. Ó máa gba ju pé kéèyàn kàn kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jẹ́ ìpìlẹ̀ lọ. Tá a bá fẹ́ mọ èdè tuntun yìí sọ dáadáa, ó gba pé ká tọ́ ìrònú wa sọ́nà ká sì sọ èrò inú wa di tuntun.—Ka Róòmù 12:2; Éfésù 4:23.

7 Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye èdè mímọ́ ká sì tún máa sọ ọ́ lọ́nà tó já geere? Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé èèyàn máa ń kọ́ àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ téèyàn bá ń kọ́ èdè kan, bẹ́ẹ̀ náà lèèyàn ṣe máa kọ́ àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó máa ranni lọ́wọ́ láti mọ èdè òtítọ́ sọ dáadáa. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun táwọn èèyàn máa ń lò láti fi kọ́ èdè tuntun, ká wá wo báwọn ohun náà ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ èdè tuntun tá a pè ní èdè mímọ́ yìí.

Bá A Ṣe Lè Máa Sọ Èdè Mímọ́ Lọ́nà Tó Já Geere

8, 9. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kọ́ èdè mímọ́, kí sì nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì gan-an?

8 Tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́. Èdè tuntun lè dà bí ohun tí kò lè yé èèyàn rárá nígbà téèyàn bá kọ́kọ́ gbọ́ tí wọ́n ń sọ ọ́. (Aísá. 33:19) Àmọ́ béèyàn bá ṣe túbọ̀ ń fetí sí ohun tó ń gbọ́ tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan táá sì máa mọ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sọ àwọn ọ̀rọ̀ náà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé, ó “pọndandan fún wa láti fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, kí a má bàa sú lọ láé.” (Héb. 2:1) Lemọ́lemọ́ ni Jésù gbà àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí fetí sílẹ̀.” (Mát. 11:15; 13:43; Máàkù 4:23; Lúùkù 14:35) Bẹ́ẹ̀ ni o, a ní láti ‘fetí sílẹ̀, kí òye ohun tá à ń gbọ́ sì yé wa’ ká lè máa tẹ̀síwájú nínú lílóye èdè mímọ́.—Mát. 15:10; Máàkù 7:14.

9 Fífetísílẹ̀ gba pé kéèyàn pọkàn pọ̀, àmọ́ èrè tó wà níbẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Lúùkù 8:18) Nígbà tá a bá wà nípàdé ìjọ, ṣé a máa ń pọkàn pọ̀ sórí ohun tá à ń gbọ́, àbí ń ṣe lọkàn wa máa ń pínyà? Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká sapá gidigidi láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tá à ń gbọ́. Bá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lọkàn wa máa yigbì.—Héb. 5:11

10, 11. (a) Yàtọ̀ sí títẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? (b) Kí ni sísọ èdè mímọ́ tún jẹ mọ́?

10 Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó mọ èdè náà sọ dáadáa. Wọ́n ti dámọ̀ràn fáwọn tó ń kọ́ èdè tuntun pé kí wọ́n máa fetí sílẹ̀ dáadáa kí wọ́n sì tún máa pe àwọn ọ̀rọ̀ bí àwọn tó mọ èdè yẹn sọ dáadáa ṣe ń pè é, àti pé kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tí wọ́n gbà ń sọ ọ́. Èyí á jẹ́ kí èdè náà yọ̀ mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu dáadáa táá sì jẹ́ káwọn èèyàn lóye ọ̀rọ̀ wọn dáadáa. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ káwa náà kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó mọ bí wọ́n ṣe ń lo “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” dáadáa láti kọ́ àwọn èèyàn ní èdè tuntun náà. (2 Tím. 4:2) Gba ìrànwọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó mọ̀ ọ́n sọ. Múra tán láti gba ìtọ́sọ́nà nígbà tó o bá ṣàṣìṣe.—Ka Hébérù 12:5, 6, 11.

11 Kì í ṣe gbígba òtítọ́ gbọ́ àti fífi kọ́ni nìkan ni sísọ èdè mímọ́ jẹ mọ́, ó tún kan mímú kí ìwà ẹni bá àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run mu. Títẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn tó ní ìwà rere lè ràn wá lọ́wọ́. Èyí kan títẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìtara wọn. Ó tún kan títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù látòkèdélẹ̀. (1 Kọ́r. 11:1; Héb. 12:2; 13:7) Tá a bá tẹra mọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀, yóò yọrí sí ìṣọ̀kan láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run, yóò sì mú kí wọ́n máa sọ èdè mímọ́ lọ́nà kan náà.—1 Kọ́r. 4:16, 17.

12. Báwo ni kíkọ́ nǹkan sórí ṣe lè ṣàǹfààní béèyàn bá ń kọ́ èdè tuntun?

12 Kọ́ ọ sórí. Àwọn tó ń kọ́ èdè ní láti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan tuntun sórí. Èyí kan kíkọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tuntun àti àkànlò èdè sórí. Fún àwa Kristẹni, kíkọ́ nǹkan ní àkọ́sórí lè ṣàǹfààní gan-an bá a bá fẹ́ mọ èdè mímọ́ sọ dáadáa. Ó dára ká mọ orúkọ àwọn ìwé Bíbélì sórí bí wọ́n ṣe tò tẹ̀ léra wọn. Àwọn kan pinnu pé àwọn fẹ́ kọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tó ń sọ nípa àwọn kókó pàtàkì sórí. Àwọn mìíràn rí i pé ó ṣàǹfààní láti kọ́ orin Ìjọba Ọlọ́run sórí, kí wọ́n kọ́ orúkọ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá sórí, àtàwọn orúkọ àwọn àpọ́sítélì méjìlá, àtàwọn ànímọ́ tó para pọ̀ jẹ́ èso ẹ̀mí. Láyé àtijọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ àwọn sáàmù sórí. Lóde òní, ọmọdékùnrin kan há ẹsẹ Bíbélì tó ju ọgọ́rin lọ sórí nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́fà péré! Ǹjẹ́ àwa náà lè lo ẹ̀bùn iyebíye tá a ní yìí lọ́nà tó dára gan-an?

13. Kí nìdí tí àsọtúnsọ fi ṣe pàtàkì gan-an?

13 Àsọtúnsọ máa ń ranni lọ́wọ́ láti máa rántí nǹkan, ìránnilétí sì jẹ́ apá pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ àwa Kristẹni. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Èmi yóò múra tán nígbà gbogbo láti rán yín létí nǹkan wọ̀nyí, bí ẹ tilẹ̀ mọ̀ wọ́n, tí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú òtítọ́ tí ó wà nínú yín.” (2 Pét. 1: 12) Kí nìdí tá a fi nílò ìránnilétí? Ìdí ni pé ó máa ń mú kí òye wa jinlẹ̀ sí i, ó ń jẹ́ kí ojú tá a fi ń wo ọ̀ràn túbọ̀ gbòòrò sí i, ó sì ń jẹ́ ká pinnu láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà nìṣó. (Sm. 119:129) Tá a bá ń gbé àwọn ìlànà Ọlọ́run yẹ̀ wò nígbà gbogbo, á jẹ́ ká máa yẹ ara wa wò, kò sì ní jẹ́ ká di “olùgbọ́ tí ń gbàgbé.” (Ják. 1:22-25) Bá ò bá máa rán ara wa létí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a ti kọ́, àwọn ohun mìíràn á máa darí ọkàn wa, ìyẹn sì lè mú ká má sọ èdè mímọ́ lọ́nà tó já geere mọ́.

14. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń kọ́ èdè mímọ́?

14 Kà á sókè. (Ìṣí. 1:3) Àwọn kan tó ń kọ́ èdè tuntun kì í fẹ́ sọ ọ́. Èyí ò ní jẹ́ kí wọ́n fi bẹ́ẹ̀ ní ìtẹ̀síwájú. Nígbà tá a bá ń kọ́ èdè mímọ́, a ní láti máa fi “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” kà á nígbà mìíràn ká bàa lè pọkàn pọ̀. (Ka Sáàmù 1:1, 2.) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tá à ń kà máa ríbi dúró sí lọ́kàn wa, a kò sì ní gbàgbé. Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ náà “fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà” jẹ mọ́ ṣíṣe àṣàrò. Bó ti ṣe pàtàkì pé kí oúnjẹ dà nínú wa lẹ́yìn tá a bá jẹun tán kó lè ṣe ara wa lóore, bákan náà ló ṣe ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò ká bàa lè lóye ohun tá à ń kà. Ǹjẹ́ a máa ń wá àkókò tó pọ̀ tó láti ṣàṣàrò lórí ohun tá a kọ́? Lẹ́yìn tá a bá ti ka Bíbélì a gbọ́dọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà.

15. Báwo la ṣe lè kọ́ “gírámà” èdè mímọ́?

15 Mọ gírámà èdè náà dáadáa. Téèyàn bá kọ́ èdè kan débì kan, ó ṣàǹfààní láti kọ́ gírámà èdè náà, ìyẹn bá a ṣe ń to àwọn ọ̀rọ̀ pọ̀ di gbólóhùn, ó sì tún yẹ kéèyàn kọ́ ìlànà èdè tuntun náà. Èyí á jẹ́ kéèyàn lóye bí wọ́n ṣe gbé èdè náà kalẹ̀, á sì jẹ́ ká lè máa sọ ọ́ bó ṣe yẹ. Bí èdè kan ṣe ní irú ọ̀rọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni èdè mímọ́ tí í ṣe ẹ̀kọ́ òtítọ́ ní “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera.” (2 Tím. 1:13) A ní láti máa tẹ̀ lé “àpẹẹrẹ” yẹn.

16. Ìṣòro wo la ní láti borí, báwo la sì ṣe lè ṣe é?

16 Máa tẹ̀ síwájú nínú sísọ ọ́. Ẹnì kan lè kọ́ èdè kan kó sì gbọ́ ọ débi tó lè máa fi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ àmọ́ kó má tẹ̀ síwájú nínú sísọ èdè náà dáadáa. Irú ìṣòro kan náà lè bá àwọn tó ń sọ èdè mímọ́. (Ka Hébérù 5:11-14.) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yìí? Múra tán láti máa kọ́ èdè náà lọ́nà tó gbòòrò sí i. Tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Nísinsìnyí tí a ti fi àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa Kristi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú, kí a má tún máa fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ mọ́, èyíinì ni, ìrònúpìwàdà kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́, àti ìgbàgbọ́ sípa Ọlọ́run, ẹ̀kọ́ lórí àwọn ìbatisí àti gbígbé ọwọ́ léni, àjíǹde àwọn òkú àti ìdájọ́ àìnípẹ̀kun.”—Héb. 6: 1, 2.

17. Kí nìdí tí kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé fi ṣe pàtàkì? Ṣàpèjúwe rẹ̀.

17 Ya àkókò kan pàtó sọ́tọ̀ tí wàá máa fi kẹ́kọ̀ọ́. Kéèyàn máa lo àkókò díẹ̀ láti máa fi kẹ́kọ̀ọ́ déédéé dára ju kéèyàn máa lo ọ̀pọ̀ àkókò ní ìdákúrekú lọ. Máa kẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí ọpọlọ rẹ ṣì jí pépé, tí o kò ní ní ìpínyà ọkàn. Kíkọ́ èdè tuntun dà bí ìgbà téèyàn ń gba ipa ọ̀nà kan kọjá nínú igbó. Béèyàn bá ṣe ń gba ibẹ̀ kọjá nígbà gbogbo tó, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà náà á ṣe rọrùn láti gbà tó. Téèyàn ò bá gba ojú ọ̀nà kan kọjá fún ìgbà pípẹ́, ojú ọ̀nà náà yóò dí. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká tẹra mọ́ sísọ èdè mímọ́ ká sì máa sọ ọ́ déédéé! (Dán. 6:16, 20) Ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà ká sì “wà lójúfò pẹ̀lú gbogbo àìyẹsẹ̀” bá a ti ń sọ èdè mímọ́ ti ẹ̀kọ́ òtítọ́.—Éfé. 6:18.

18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa sọ èdè mímọ́ nígbà gbogbo?

18 Tẹra mọ́ sísọ ọ́! Àwọn kan tí wọ́n ń kọ́ èdè tuntun lè lọ́ tìkọ̀ láti máa sọ ọ́ nítorí pé ojú ń tì wọ́n, tàbí nítorí pé ẹ̀rú ń bà wọ́n kí wọ́n má bàa ṣàṣìṣe. Ìyẹn kì í sì í jẹ́ kí wọ́n ní ìtẹ̀síwájú. Àwọn Yorùbá máa ń sọ pé, “kíkọ́ ni mímọ̀.” Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí tó bá di pé kéèyàn kọ́ èdè tuntun. Bí ẹni tó ń kọ́ èdè kan bá ṣe ń sọ èdè náà tó bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe máa yọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu tó. Bákan náà, àwa náà ní láti máa sọ èdè mímọ́ náà nígbà gbogbo. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ni a fi ń lo ìgbàgbọ́ fún òdodo, ṣùgbọ́n ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.” (Róòmù 10:10) Yàtọ̀ sí bá a ṣe máa “ń ṣe ìpolongo ní gbangba” nígbà tá a fẹ́ ṣèrìbọmi, a tún máa ń ṣe é ní gbogbo ìgbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, títí kan ìgbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí. (Mát. 28:19, 20; Héb. 13:15) Àwọn ìpàdé wa ń fún wa láǹfààní láti máa sọ èdè mímọ́ lọ́nà tó ṣe ṣàkó tó sì ṣe kedere.—Ka Hébérù 10:23-25.

Wọ́n Ń Fi Èdè Mímọ́ Yin Jèhófà Níṣọ̀kan

19, 20. (a) Kí ni ohun àgbàyanu táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé ṣe lọ́jọ́ wa yìí? (b) Kí lo pinnu láti máa ṣe?

19 Wo bí orí rẹ ṣe máa yá gágá tó ká sọ pé o wà ní Jerúsálẹ́mù láàárọ̀ ọjọ́ Sunday, ọjọ́ kẹfà oṣù Sífánì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni! Ní òwúrọ̀ ọjọ́ yẹn, ní nǹkan bí aago mẹ́sàn-án, àwọn tó kóra jọ sí yàrá òkè “bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀” lọ́nà iṣẹ́ ìyanu. (Ìṣe 2:4) Lóde òní, ẹ̀bùn fífi oríṣiríṣi èdè sọ̀rọ̀ kò sí fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mọ́. (1 Kọ́r. 13:8) Síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní èdè tó ju ọgbọ̀n-lé-nírínwó [430] lọ.

20 Ẹ wo bá a ti kún fún ìmoore tó pé èdè yòówù ká máa sọ, sísọ èdè mímọ́ ti ẹ̀kọ́ òtítọ́ ti so gbogbo wa pọ̀! Òdìkejì ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Bábélì sì ni èyí. Bí ẹní fi èdè kan ṣoṣo sọ̀rọ̀ làwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń mú ìyìn bá orúkọ rẹ̀. (1 Kọ́r. 1:10) Ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa sin Jèhófà ní “ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa kárí ayé bá a ṣe ń kọ́ láti máa sọ èdè mímọ́ náà lọ́nà tó já geere títí lọ, fún ìyìn Bàbá wa ọ̀run Jèhófà.—Ka Sáàmù 150:1-6.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni èdè mímọ́?

• Kí ni sísọ tá à ń sọ èdè mímọ́ jẹ mọ́?

• Kí ni yóò jẹ́ ká lè máa sọ èdè mímọ́ lọ́nà tó já geere?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

Máa sọ Èdè Mímọ́ Lọ́nà Tó Túbọ̀ Já Geere Nípa

◆ títẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́.

Lúùkù 8:18; Héb. 2:1

◆ títẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn tó mọ èdè náà sọ dáadáa.

1 Kọ́r. 11:1; Héb. 13:7

◆ kíkọ́ èdè náà sórí àti sísọ ọ́ ní àsọtúnsọ.

Ják. 1:22-25; 2 Pét. 1:12

◆ kíkà á sókè.

Sm. 1:1, 2; Ìṣí. 1:3

◆ mímọ “gírámà” èdè náà dáadáa.

2 Tím. 1:13

◆ títẹ̀ síwájú nínú sísọ ọ́.

Héb. 5:11-14; 6:1, 2

◆ yíyan àkókò pàtó tí wàá fi máa kẹ́kọ̀ọ́.

Dán. 6:16, 20; Éfé. 6:18

◆ títẹramọ́ sísọ ọ́.

Róòmù 10:10; Héb. 10:23-25

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Àwọn èèyàn Jèhófà ń fi ìṣọ̀kan sọ èdè mímọ́