Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Jẹ́ “Olùpèsè Àsálà” fún Wa

Jèhófà Jẹ́ “Olùpèsè Àsálà” fún Wa

Jèhófà Jẹ́ “Olùpèsè Àsálà” fún Wa

“Jèhófà yóò sì ràn wọ́n lọ́wọ́, yóò sì pèsè àsálà fún wọn.”—SM. 37:40.

1, 2. Òótọ́ pọ́ńbélé wo tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà ló ń tù wá nínú tó sì ń fún wa lókun?

 ÒJÌJI tí oòrùn máa ń gbé yọ kì í dúró sójú kan. Báyé ṣe ń yí, bẹ́ẹ̀ ni òjìji máa ń yí padà. Àmọ́ ṣá o, Ẹni tó dá ayé àti oòrùn, kì í yí padà. (Mál. 3:6) Bíbélì sọ pé: “Kò sì sí àyídà ìyípo òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Ják. 1:17) Òótọ́ pọ́ńbélé tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà yìí máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń fún wa lókun, àgàgà tá a bá dojú kọ àwọn àdánwò àti ìṣòro tó le gan-an? Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

2 Gẹ́gẹ́ bá a ti rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jèhófà jẹ́ “Olùpèsè àsálà” láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. (Sm. 70:5) Jèhófà kì í yí padà, ó sì máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nítorí náà, àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ lóde òní gbẹ́kẹ̀ lé e pé ‘yóò ran àwọn lọ́wọ́, yóò sì pèsè àsálà fún wọn.’ (Sm. 37:40) Báwo ni Jèhófà ti ṣe pèsè àsálà fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní? Báwo ló ṣe ń pèsè ọ̀nà àsálà fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

Jèhófà Ń Gbà Wá Lọ́wọ́ Àwọn Alátakò

3. Kí ló mú kó dá wa lójú pé àwọn alátakò kò lè dá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere táwọn èèyàn Jèhófà ń ṣe dúró?

3 Kò sí bí àtakò látọ̀dọ̀ Sátánì ṣe lè pọ̀ tó, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò fi ṣíwọ́ sísin Jèhófà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi.” (Aísá. 54:17) Àwọn alátakò ti gbìyànjú o, àmọ́ wọn ò lè dá iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run gbé fáwọn èèyàn rẹ̀ dúró. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì yẹ̀ wò.

4, 5. Àtakò wo làwọn èèyàn Jèhófà dojú kọ lọ́dún 1918, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?

4 Lọ́dún 1918, àwọn àlùfáà sún àwọn èèyàn ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kí wọ́n lè dá iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe dúró. Ní May 7, ọdún 1918, ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi òfin mú Arákùnrin J. F. Rutherford, tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù wa kárí ayé nígbà yẹn, wọ́n sì tún mú àwọn mìíràn tó wà ní orílé-iṣẹ́ wa. Kí oṣù méjì tó pé, wọ́n ti ṣèdájọ́ Arákùnrin Rutherford àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ pé wọ́n jẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì wá sọ wọ́n sẹ́wọ̀n alákòókò gígùn. Ṣé àwọn alátakò ti ṣàṣeyọrí nínú lílo ilé ẹjọ́ láti dá iṣẹ́ ìwàásù dúró nìyẹn? Rárá o!

5 Rántí pé Jèhófà ṣèlérí pé: “Ohun ìjà . . . tí a bá ṣe sí [wa] kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.” Nǹkan ṣàdédé yí padà ní March 26, ọdún 1919. Wọ́n dá Arákùnrin Rutherford àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tó wà lẹ́wọ̀n sílẹ̀ lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn-án pé kí wọ́n lọ sílé kí wọ́n sì padà wá sílé ẹjọ́ nígbà tó bá yá. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ìyẹn ní May 5, ọdún 1920, wọ́n tú ẹjọ́ náà ká, gbogbo ọ̀rọ̀ náà sì parí. Àwọn arákùnrin náà lo òmìnira tí wọ́n gbà yìí láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run nìṣó. Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Áà, ìtẹ̀síwájú ńláǹlà ti wà látìgbà náà wá! “Olùpèsè àsálà” ni ìyìn yẹ fún gbogbo ìtẹ̀síwájú yìí.—1 Kọ́r. 3:7.

6, 7. (a) Ìsapá wo ni wọ́n ṣe láti pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà run nígbà ìjọba Násì nílẹ̀ Jámánì, kí ló sì yọrí sí? (b) Ẹ̀rí wo ni ìtàn àwa èèyàn Jèhófà lóde òní fi hàn?

6 Wàyí o, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kejì yẹ̀ wò. Lọ́dún 1934, Hitler ṣèlérí pé òun máa pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Jámánì run. Kò fi ọ̀rọ̀ náà ṣeré o. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì ń sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Wọ́n hùwà ìkà sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì pa ọgọ́rọ̀ọ̀rún wọn nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ǹjẹ́ Hitler ṣàṣeyọrí nínú ìsapá rẹ̀ láti pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà run? Ǹjẹ́ ó dá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere dúró nílẹ̀ Jámánì? Rárá o! Lákòókò inúnibíni yẹn, àwọn ará wa ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ lábẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn tí ìjọba Násì pa rẹ́, àwọn ará wa lo òmìnira wọn láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó. Ní báyìí, ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́jọ àti ẹgbẹ̀rún márùn-ún [165,000] akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà nílẹ̀ Jámánì. Lẹ́ẹ̀kan sí i, “Olùpèsè àsálà” ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.”

7 Ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ti fi hàn pé Jèhófà kì yóò gba àwọn èèyàn láyè láti pa gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ run lódindi. (Sm. 116:15) Àmọ́, ǹjẹ́ Jèhófà ń dáàbò bò wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? Báwo ni Jèhófà ṣe ń pèsè àsálà fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

Ǹjẹ́ Jèhófà Máa Ń Dáàbò Bò Wá Lọ́wọ́ Ewu Nípa Ti Ara?

8, 9. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé a ò lè máa fìgbà gbogbo retí pé kí Jèhófà dáàbò bò wá lọ́wọ́ ewu ti ara? (b) Òótọ́ pọ́ńbélé wo ni kò yẹ ká gbàgbé?

8 A mọ̀ pé Jèhófà kò ṣèlérí pé òun á máa fìgbà gbogbo dáàbò bò wá lọ́wọ́ ewu ti ara lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Èrò wa nípa ọ̀rọ̀ yìí dà bíi tàwọn Hébérù olóòótọ́ mẹ́ta yẹn tí wọ́n kọ̀ láti forí balẹ̀ fún ère wúrà tí Nebukadinésárì Ọba ṣe. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run yìí kò fọkàn sí pé Jèhófà yóò ṣiṣẹ́ ìyanu láti dáàbò bo àwọn lọ́wọ́ ìpalára lọ́nà ìyanu. (Ka Dáníẹ́lì 3:17, 18.) Síbẹ̀, Jèhófà gbà wọ́n lọ́wọ́ iná ìléru náà. (Dán. 3:21-27) Àmọ́ ṣá o, láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì pàápàá, Jèhófà kì í fìgbà gbogbo dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà ìyanu. Àwọn alátakò pa ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà.—Héb. 11:35-37.

9 Àwa lóde òní ńkọ́? Ó dájú pé Jèhófà lè yọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nínú ewu ti ara nítorí òun ni “Olùpèsè àsálà.” Ǹjẹ́ a lè sọ ní pàtó pé Jèhófà ló yọ ẹnì kan nínú ewu ti ara tàbí òun kọ́? Rárá o. Àmọ́, ẹnì kan tó bọ́ lọ́wọ́ ewu lè sọ pé Jèhófà kó òun yọ. Ìkọjá àyè gbáà ló jẹ́ táwọn ẹlòmíràn bá sọ pé Jèhófà kọ́ ló kó onítọ̀hún yọ. Àmọ́ ṣá o, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé inúnibíni ti pa ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tòótọ́, gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Násì. Àwọn kan sì ti kú sínú jàǹbá. (Oníw. 9:11) A wá lè béèrè pé, ‘Ṣó wá túmọ̀ sí pé Jèhófà kì í ṣe “Olùpèsè àsálà” fáwọn olóòótọ́ tí ikú dá ẹ̀mí wọn légbodò ni?’ Rárá o.

10, 11. Kí nìdí téèyàn ò fi lágbára lórí ikú, àmọ́ kí ni Jèhófà máa ṣe nípa èyí?

10 Rò ó wò ná: Èèyàn ò lágbára lórí ikú, nítorí kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè “pèsè àsálà fún ọkàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ Ṣìọ́ọ̀lù,” tàbí Hédíìsì tí í ṣe ipò òkú. (Sm. 89:48) Àmọ́, ǹjẹ́ Jèhófà lágbára lórí ikú? Arábìnrin kan tó yè bọ́ nígbà ìjọba Násì òǹrorò rántí ọ̀rọ̀ ìtùnú tí ìyá rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún un nípa àwọn ará wa tó kú sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ó ní: “Tó bá jẹ́ pé títí ayé ni ikú máa gbé àwọn èèyàn dè, á jẹ́ pé ikú lágbára ju Ọlọ́run lọ nìyẹn, àbí?” Rárá o, ó dájú pé ikú kò lágbára tó Ọlọ́run Olódùmarè, ẹni tí í ṣe Orísun ìyè! (Sm. 36:9) Gbogbo àwọn tó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù, tàbí Hédíìsì, ìyẹn ipò òkú, ni Jèhófà ń rántí, yóò sì pèsè ọ̀nà àsálà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.—Lúùkù 20:37, 38; Ìṣí. 20:11-14.

11 Ní báyìí ná, Jèhófà ń dá sí ọ̀rọ̀ àwọn olóòótọ́ tó ń sìn ín lóde òní. Wàyí o, ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tó gbà jẹ́ “Olùpèsè àsálà” fún wa.

Jèhófà Ń Dáàbò Bò Wá Nípa Tẹ̀mí

12, 13. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ààbò nípa tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù, báwo sì ni Jèhófà ṣe ń pèsè irú ààbò bẹ́ẹ̀ fún wa?

12 Jèhófà ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí, ìyẹn sì ni ààbò tó ṣe pàtàkì jù. Jíjẹ́ tá a jẹ́ Kristẹni tòótọ́ mú ká mọ̀ pé ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju ìwàláàyè wa ti ìsinsìnyí lọ. Àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ni ohun ìní wa tó ṣe pàtàkì jù lọ. (Sm. 25:14; 63:3) Láìsí àjọṣe yẹn, ìwàláàyè wa ti ìsinsìnyí kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan, kò sì ní sí ìrètí fún wa láti wà láàyè lọ́jọ́ iwájú.

13 A dúpẹ́ pé Jèhófà ti fún gbogbo wa ní ohun tá a nílò tí kò ní jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ yingin. Àwọn ohun tó ń ràn wá lọ́wọ́ ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ tó wà kárí ayé. Ọ̀nà tó dára jù wo la lè gbà lo àwọn nǹkan wọ̀nyí? Tá a bá ń fi taratara kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ìgbàgbọ́ wa yóò máa lágbára sí i, ìrètí wa yóò sì túbọ̀ dájú. (Róòmù 15:4) Tá a bá ń fòótọ́ ọkàn gbàdúrà pé kó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dènà ìdẹwò, a ò sì ní ṣe ohun tó máa ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. (Lúùkù 11:13) Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí ẹgbẹ́ ẹrú náà ń fún wa nípasẹ̀ àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìpàdé, àpéjọ àyíká, àkànṣe àti àgbègbè, a óò máa jẹ “oúnjẹ” tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” á sì máa gbé wa ró. (Mát. 24:45) Irú àwọn ìpèsè bẹ́ẹ̀ máa ń mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, ó sì máa ń jẹ́ ká sún mọ́ Ọlọ́run dáadáa.—Ják. 4:8.

14. Sọ ìrírí kan tó fi hàn bí Jèhófà ṣe máa ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí.

14 Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀kan lára àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe máa ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí. Ṣẹ́ ẹ rántí àwọn òbí tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí? Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan tí wọ́n ti ń wá ọmọbìnrin wọn tó ń jẹ́ Theresa, wọ́n gbọ́ ìròyìn burúkú kan pé, wọ́n ti pa ọmọ náà. a Bàbá rẹ̀ sọ pé: ‘Mo gbàdúrà pé kí Jèhófà dáàbò bò ó. Àmọ́, nígbà tó wá jẹ́ pé òkú ẹ̀ la rí, mo gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé ẹnu kọ́kọ́ yà mí nípa ìdí tí Ọlọ́run kò fi dáhùn àdúrà mi. Lóòótọ́ mo mọ̀ dájú pé Jèhófà kò ṣèlérí pé òun á máa dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lọ́nà ìyanu nígbà gbogbo. Mo ṣáà ń bá a lọ ní gbígbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún mi lóye. Mímọ̀ pé Jèhófà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nípa tẹ̀mí ti tù mí nínú, ìyẹn ni pé ó ń pèsè ohun tá a nílò láti lè pa àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ mọ́. Irú ààbò yẹn ló sì ṣe pàtàkì jù lọ, nítorí pé ó lè mú ká ní ìyè ayérayé lọ́jọ́ iwájú. Lọ́nà yẹn, Jèhófà dáàbò bo Theresa, nítorí pé ó fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà títí tó fi kú. Mímọ̀ pé ìwàláàyè rẹ̀ ọjọ́ iwájú wà lọ́wọ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ fi mí lọ́kàn balẹ̀.’

Jèhófà Ń Gbé Wa Ró Tá A Bá Dùbúlẹ̀ Àìsàn

15. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń ṣàìsàn?

15 Jèhófà lè gbé wa ró “lórí àga ìnàyìn ti àmódi” gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ṣe sọ. (Sm. 41:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kì í pèsè àsálà nípa wíwoni sàn lọ́nà ìyanu lóde òní, ó máa ń ràn wá lọ́wọ́. Lọ́nà wo? Àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nípa ìwòsàn ara wa àtàwọn ọ̀ràn míì. (Òwe 2:6) A lè rí àwọn ìsọfúnni tó lè ràn wá lọ́wọ́ àtàwọn àbá tó gbéṣẹ́ nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó sọ̀rọ̀ nípa àìlera wa. Nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, Jèhófà lè fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” láti lè kojú ìṣòro wa, ká sì dúró ṣinṣin, láìka ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ sí. (2 Kọ́r. 4:7) Nípasẹ̀ irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, a ò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àìsàn wa gbà wá lọ́kàn tá ò fi ní fiyè sí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà.

16. Kí ló ran arákùnrin kan lọ́wọ́ láti fara da àìsàn rẹ̀?

16 Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin tá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí. Lọ́dún 1998, àyẹ̀wò fi hàn pé arákùnrin náà ní àìsàn tí wọ́n ń pè ní ALS. Àìsàn náà wá mú kó yarọ látòkè délẹ̀ nígbà tó yá. b Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti fara da àìsàn yìí? Ó ṣàlàyé pé: “Mo máa ń ní ìrora àti ìjákulẹ̀ nígbà tí mo bá rò ó pé ikú nìkan ló lè yọ mí nínú ìyà yìí. Nígbàkigbà tí ìbànújẹ́ bá dorí mi kodò, mo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà fún mi ní ohun mẹ́ta yìí: ọkàn tó pa rọ́rọ́, sùúrù àti ìfaradà. Mo mọ̀ pé Jèhófà ti dáhùn àwọn àdúrà yẹn. Ọkàn tó pa rọ́rọ́ máa ń jẹ́ kí n máa ronú lórí àwọn ohun tó ń mú ìtùnú wá fún mi, irú bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun tí mo bá dẹni tó ń fẹsẹ̀ rìn padà, tí mo bá lè jẹ́ oúnjẹ aládùn, tí mo sì lè bá ìdílé mi sọ̀rọ̀ padà. Sùúrù ń ràn mí lọ́wọ́ láti lè kójú àìfararọ àti ìṣòro tí àìsàn ara mi ń fà. Ìfaradà mú kí n máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó, tí mi ò sì jẹ́ kí àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run bà jẹ́. Èmi náà le sọ bí Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù ti sọ pé, Jèhófà ti gbé mi ró lórí ibùsùn àìsàn mi.”—Aísá. 35:5, 6.

Jèhófà Ń Pèsè Jíjẹ àti Mímu fún Wa

17. Kí ni Jèhófà ṣèlérí fún wa, kí ni ìlérí yìí sì túmọ̀ sí?

17 Jèhófà ṣèlérí pé òun á bójú tó wa nípa tara. (Ka Mátíù 6:33, 34 àti Hébérù 13:5, 6.) Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ńṣe la máa wá káwọ́ gbera, ká máa retí pé kí oúnjẹ dé lọ́nà ìyanu, tàbí ká kọ̀ ká má ṣiṣẹ́ kankan. (2 Tẹs. 3:10) Ohun tí ìlérí yẹn túmọ̀ sí ni pé: Tá a bá kọ́kọ́ wá Ìjọba Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé wa, tá a sì múra tán láti ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, a nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn ohun kòṣeémánìí. (1 Tẹs. 4:11, 12; 1 Tím. 5:8) Ó lè pèsè àwọn ohun tá à ń fẹ́ lọ́nà tá ò retí, bóyá ẹni tá a jọ ń sin Jèhófà ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ní ohun tara tá a nílò tàbí kó bá wa wá iṣẹ́.

18. Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé Ọlọ́run lè pèsè fún wa lákòókò tá a nílò nǹkan kan lójú méjèèjì.

18 Ṣẹ́ ẹ rántí obìnrin tó ń dá tọ́mọ tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí? Nígbà tóun àti ọmọbìnrin rẹ̀ kó lọ sí àgbègbè tuntun kan, ó ṣòro fún un gan-an láti ríṣẹ́. Ó ṣàlàyé pé: “Mo máa ń lọ sí òde ẹ̀rí ní òwúrọ̀, màá sì máa wá iṣẹ́ lọ́sàn-án. Mo rántí ọjọ́ kan tí mo lọ sílé ìtajà kan láti ra mílíìkì. Mo dúró mo sì ń wo àwọn ewébẹ̀ tó wà níbẹ̀, àmọ́ mi ò lówó láti fi ra èyíkéyìí lára wọn. Inú mi bà jẹ́ gan-an. Lọ́jọ́ yẹn, nígbà tí mo padà délé láti ilé ìtajà yẹn, mo bá àwọn àpò níbi àbáwọlé ẹ̀yìnkùlé mi, àwọn àpò náà sì kún fún oríṣiríṣi ewébẹ̀. Oúnjẹ wá pọ̀ rẹpẹtẹ tá a lè jẹ fún ọ̀pọ̀ oṣù. Mo sunkún, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.” Láìpẹ́ arábìnrin yìí wá mọ̀ pé arákùnrin tó wà nínú ìjọ òun tó ní ọgbà ewébẹ̀ ló gbé àwọn ewébẹ̀ náà wá. Arábìnrin náà kọ̀wé ìdúpẹ́ sí arákùnrin náà pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ gan-an lọ́jọ́ yẹn, mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó lò ọ́ láti fi inú rere hàn sí mi, èyí sì mú kí n rántí ìfẹ́ rẹ̀.”—Òwe 19:17.

19. Nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá dé, kí ló dá àwọn èèyàn Jèhófà lójú, kí ló sì yẹ ká pinnu láti ṣe ní báyìí?

19 Ó ṣe kedere pé ohun tí Jèhófà ṣe láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì àti lóde òní ti mú ká gbẹ́kẹ̀ lé e pé òun ni Olùrànlọ́wọ́ wa. Láìpẹ́, nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá dé bá ayé Sátánì yìí, a máa nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Àmọ́, ó dá àwọn èèyàn Jèhófà lójú pé yóò ràn àwọn lọ́wọ́. Wọn yóò gbé orí wọn sókè, wọn yóò sì máa yọ̀ nítorí wọ́n mọ̀ pé ìdáǹdè wọn ti sún mọ́lé. (Lúùkù 21:28) Ní báyìí ná, àdánwò yòówù kó dé bá wa, ẹ jẹ́ ká pinnu pé Jèhófà la máa gbẹ́kẹ̀ lé, ká sì mọ̀ dájú pé Ọlọ́run wa tí kì í yí padà jẹ́ “Olùpèsè àsálà” fún wa.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Wo àpilẹ̀kọ tó sọ nípa arákùnrin kan tó ní àìsàn tí wọ́n ń pè ní àrùn ALS, tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! ti oṣù January 2006, ojú ìwé 25 sí 29, lédè Gẹ̀ẹ́sì.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo ni Jèhófà ṣe ń pèsè àsálà fún àwọn tí ikú dá ẹ̀mí wọn légbodò?

• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ààbò nípa tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù?

• Kí ni ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun á bójú tó wa nípa tara túmọ̀ sí?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Wọ́n fòfin mú Arákùnrin Rutherford àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lọ́dún 1918, wọ́n dá wọn sílẹ̀ nígbà tó yá, wọ́n sì tú ẹjọ́ náà ká

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Jèhófà lè gbé wa ró lórí “àga ìnàyìn ti àmódi”