Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù—Sin Ọlọ́run bí Ọlọ́run Ṣe Fẹ́

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù—Sin Ọlọ́run bí Ọlọ́run Ṣe Fẹ́

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù—Sin Ọlọ́run bí Ọlọ́run Ṣe Fẹ́

Tìfẹ́tìfẹ́ ni Ọlọ́run ń pe àwọn èèyàn “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” kí wọ́n wá sin òun. (Ìṣí. 7:9, 10; 15:3, 4) Àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìkésíni yìí máa ń “rí adùn Jèhófà.” (Sm. 27:4; 90:17) Wọ́n sì ń yin Ọlọ́run bíi ti onísáàmù kan tó sọ pé: “Ẹ wọlé wá, ẹ jẹ́ kí a jọ́sìn, kí a sì tẹrí ba; ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú Jèhófà Olùṣẹ̀dá wa.”—Sm. 95:6.

Irú Ìjọsìn Tí Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ sí Gan-an

Jésù tó jẹ́ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa nípa bí Baba rẹ̀ ṣe ń ronú, nípa àwọn ìlànà rẹ̀ àtàwọn òfin rẹ̀. Nítorí náà, Jésù lè fi ìdánilójú sọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbà sin Jèhófà. Ó ní: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.”—Jòh. 1:14; 14:6.

Bí Jésù ṣe tẹrí ba fún Baba rẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára jù lọ fún wa láti tẹ̀ lé. Ó sọ pé: “Èmi kò ṣe nǹkan kan ní àdáṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.” Ó tún wá fi kún un pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” (Jòh. 8:28, 29) Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà ṣe ohun tó wu Baba rẹ̀?

Tọkàntọkàn ni Jésù fi ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀, ohun tí jíjọ́sìn Ọlọ́run sì túmọ̀ sí nìyẹn. Jésù fi hàn pé òun fẹ́ràn Baba òun nípa bó ṣe jẹ́ onígbọràn sí i, tó sì ń ṣe ohun tó fẹ́, kódà nígbà tó máa ná an ní ìwàláàyè rẹ̀ pàápàá. (Fílí. 2:7, 8) Apá kan pàtàkì nínú ọ̀nà tí Jésù gbà jọ́sìn Ọlọ́run ni bó ṣe ń sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn lójú méjèèjì, débi táwọn tó gbà á gbọ́ àtàwọn tí kò gbà á gbọ́ fi ń pè é ní Olùkọ́. (Mát. 22:23, 24; Jòh. 3:2) Láfikún sí i, Jésù fi ara rẹ̀ fún ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn èèyàn. Ó fi ara rẹ̀ jin iṣẹ́ náà débi pé kò fi bẹ́ẹ̀ ráyè sinmi, síbẹ̀ iṣẹ́ yẹn ń múnú rẹ̀ dùn gan-an. (Mát. 14:13, 14; 20:28) Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo bí ọwọ́ rẹ̀ ṣe dí tó yìí, ó máa ń wá àyè láti bá Baba rẹ̀ ọ̀run sọ̀rọ̀. (Lúùkù 6:12) Ọlọ́run sì fojú pàtàkì wo ọ̀nà tí Jésù gbà jọ́sìn òun yìí gan-an ni!

Jésù Sapá Láti Wu Ọlọ́run Dáadáa

Gbogbo ohun tí Jésù ṣe yìí ni Jèhófà ń rí, ó sì sọ pé òun tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 17:5) Àmọ́ Sátánì Èṣù náà ń wo bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́. Bó ṣe dójú sọ Jésù nìyẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé títí dìgbà yẹn kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó tíì sin Ọlọ́run bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ gan-an, ìyẹn ni pé kó ṣègbọràn sí i láìkù síbì kan. Èṣù sì fẹ́ rí i pé òun kò jẹ́ kí Jésù sin Jèhófà lọ́nà tó tọ́.—Ìṣí. 4:11.

Sátánì fi àwọn ohun tó lè dán ìdúróṣinṣin Jésù wò lọ̀ ọ́ kó lè ba ìṣòtítọ́ rẹ̀ jẹ́. Ó gbé Jésù lọ sórí “òkè ńlá kan tí ó ga lọ́nà kíkàmàmà, ó sì fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án.” Ó wá sọ pé: “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú bí ìwọ bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” Kí ni Jésù wá ṣe? Ó ní: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’” (Mát. 4:8-10) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù mọ̀ pé títẹríba fún Sátánì jẹ́ ìbọ̀rìṣà láìka èrè tó lè tibẹ̀ yọ sí. Jésù kò fẹ́ jọ́sìn ẹnikẹ́ni lọ́nàkọnà yàtọ̀ sí Jèhófà nìkan.

Ní tiwa, Sátánì lè má fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn lọ̀ wá ní pàṣípààrọ̀ fún ìjọsìn Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ó ṣì ń fẹ́ láti ṣèdíwọ́ fún ìjọsìn Ọlọ́run táwa Kristẹni olóòótọ́ ń ṣe. Ó ń fẹ́ ká jọ́sìn àwọn èèyàn tàbí ohunkóhun mìíràn.—2 Kọ́r. 4:4.

Kristi Jésù ní tiẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ àní títí dójú ikú. Bí Jésù kò ṣe jẹ́ kí ohunkóhun ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́, ńṣe ló gbé Jèhófà ga lọ́nà tí ẹ̀dá èèyàn kankan kò tíì ṣe rí. Àwa Kristẹni tòótọ́ lóde òní ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ Jésù nípa gbígbé ìjọsìn Ẹlẹ́dàá wa lékè ohunkóhun mìíràn. Ká sòótọ́, àjọṣe dáadáa tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run lohun ìní wa tó ṣeyebíye jù lọ.

Àwọn Ìbùkún Tó Wà Nínú Sísin Ọlọ́run Bó Ṣe Fẹ́

Ìbùkún rẹpẹtẹ ló wà nínú gbígbé “ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin” lójú Ọlọ́run lárugẹ. (Ják. 1:27) Bí àpẹẹrẹ, lóde òní, ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń di “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú” àti “aláìní ìfẹ́ ohun rere.” (2 Tím. 3:1-5) Àmọ́ téèyàn bá wà nínú ètò Ọlọ́run, àwọn tí yóò máa bá kẹ́gbẹ́ ni àwọn oníwà mímọ́ tó ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé ìlànà òdodo tí Ọlọ́run fi lélẹ̀. Ǹjẹ́ ìyẹn kì í tù wá lára?

Tá ò bá jẹ́ kí ayé yìí sọ wá dìdàkudà, a óò ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ìbùkún nìyẹn náà sì tún jẹ́ fún wa. Ẹ̀rí ọkàn wa á mọ́ tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà òdodo Ọlọ́run, tá a sì ń pa àwọn òfin Késárì tí kò ta ko òfin Ọlọ́run mọ́.—Máàkù 12:17; Ìṣe 5:27-29.

Fífi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run tún máa jẹ́ ká ní oríṣi ìbùkún míì. Tá a bá pọkàn pọ̀ sórí ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, tá ò máa ṣèfẹ́ inú ara wa, ìgbésí ayé wa á nítumọ̀, á sì tẹ́ wa lọ́rùn. Dípò tá a ó fi sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú,” ńṣe la máa fọkàn sí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, èyí tó jẹ́ ìrètí tó dájú.—1 Kọ́r. 15:32.

Ìwé Ìṣípayá tọ́ka sí àkókò kan tí gbogbo àwọn tó wà nípò mímọ́ lójú Jèhófà yóò “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà.” Àkọsílẹ̀ náà tún sọ pé: “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ yóò sì na àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n.” (Ìṣí. 7:13-15) Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó tóbi jù láyé àtọ̀run lẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ náà. Wo bí ayọ̀ rẹ ti máa pọ̀ tó nígbà tí Ọlọ́run bá gbà ọ́ sínú àgọ́ rẹ̀, tó sì ń fi ààbò rẹ̀ bò ọ́ kí ibi kankan má bàa bá ọ! Nísinsìnyí pàápàá, dé ìwọ̀n àyè kan, Ọlọ́run ń fi ààbò rẹ̀ bò wá, ó sì ń bójú tó wa.

Síwájú sí i, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ń ṣamọ̀nà gbogbo àwọn tó ń sìn ín bó ṣe fẹ́ lọ sí “àwọn ìsun omi ìyè.” Ìsun omi tó ń tuni lára yìí ṣàpẹẹrẹ gbogbo ètò tí Jèhófà ti ṣe kó lè ṣeé ṣe fún wa láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Dájúdájú, “Ọlọ́run yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn” nípasẹ̀ ìràpadà tí Kristi ṣe. (Ìṣí. 7:17) Yóò sọ ìran èèyàn di pípé, èyí tí yóò mú káwọn tó nírètí àtiwàláàyè títí láé ní ayọ̀ tó kọjá àfẹnusọ. Nísinsìnyí pàápàá, inú àwọn èèyàn aláyọ̀ tó ń sin Ọlọ́run ń dùn, wọ́n sì ń fi hàn látọkànwá pé àwọn mọrírì ohun tí Jèhófà ti ṣe fáwọn. Wọ́n ń sìn ín pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá tó wà lọ́run tó ń kọrin pé: “Títóbi àti àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè. Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé. Ta ni kì yóò bẹ̀rù rẹ ní ti gidi, Jèhófà, tí kì yóò sì yin orúkọ rẹ lógo, nítorí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin? Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì jọ́sìn níwájú rẹ, nítorí a ti fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ rẹ tí ó jẹ́ òdodo hàn kedere.”—Ìṣí. 15:3, 4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Kí ni Sátánì fi ń lọ̀ wá ní pàṣípààrọ̀ fún ìjọsìn Ọlọ́run?