Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “gbígbé ọwọ́ léni” nínú ìwé tó kọ sáwọn ará Hébérù. Ṣé ọ̀rọ̀ yíyan àwọn alàgbà sípò ló ń sọ ni àbí ọ̀rọ̀ nǹkan míì?—Héb. 6:2.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè fòté lé ohun tó ń sọ ní pàtó, ó jọ pé ọ̀rọ̀ gbígbé ọwọ́ léni láti fúnni lẹ́bùn ẹ̀mí mímọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ.

Bíbélì máa ń mẹ́nu kan gbígbé ọwọ́ léni nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa yíyannisípò iṣẹ́ ìsìn. Bí àpẹẹrẹ, Mósè “gbé ọwọ́ lé [Jóṣúà] lórí” nígbà tó fẹ́ yàn án ṣe arọ́pò rẹ̀. (Diu. 34:9) Nínú ìjọ Kristẹni náà, wọ́n máa ń gbé ọwọ́ lé àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n tí wọ́n bá fẹ́ yàn wọ́n sídìí iṣẹ́ pàtàkì. (Ìṣe 6:6; 1 Tím. 4:14) Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ sọ pé ká má ṣe fi ìkánjú gbé ọwọ́ lé ọkùnrin èyíkéyìí.—1 Tím. 5:22.

Àmọ́ nínú Hébérù orí kẹfà yìí, Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù níyànjú pé kí wọ́n “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú” nísinsìnyí tí wọ́n ti fi “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́” sílẹ̀. Ó wá mẹ́nu kan “ìrònúpìwàdà kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́, àti ìgbàgbọ́ sípa Ọlọ́run, ẹ̀kọ́ lórí àwọn ìbatisí àti gbígbé ọwọ́ léni.” (Héb. 6:1, 2) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé yíyannisípò alàgbà wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ohun àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tí Kristẹni máa ṣe kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa tẹ̀ síwájú ni? Rárá o. Àwọn ọkùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ló máa ń sapá láti di alàgbà, tí wọ́n á sì túbọ̀ máa wúlò sí i nínú ìjọ.—1 Tím. 3:1.

Ṣùgbọ́n wọ́n tún máa ń gbé ọwọ́ léni fún ìdí míì. Ní ọ̀rúndún kìíní, Jèhófà kọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lápapọ̀ sílẹ̀, ó wá tẹ́wọ́ gba ìjọ Kristẹni ẹni àmì òróró dípò wọn. (Mát. 21:43; Ìṣe 15:14; Gál. 6:16) Ọlọ́run wá fún àwọn Kristẹni yìí ní onírúurú ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́, irú bí ìfèdèfọ̀, láti fi hàn pé àwọn lòun tẹ́wọ́ gbà. (1 Kọ́r. 12:4-11) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí Kọ̀nílíù àti agboolé rẹ̀ di onígbàgbọ́, ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn, ẹ̀rí èyí sì hàn nípa bí “wọ́n [ṣe] ń fi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀.”—Ìṣe 10:44-46.

Nígbà míì, wọ́n máa ń fún àwọn èèyàn lẹ́bùn ẹ̀mí mímọ́ yìí nípa gbígbé ọwọ́ lé wọn. Nígbà tí Fílípì wàásù ìhìn rere nílùú Samáríà, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣèrìbọmi. Ìgbìmọ̀ olùdarí wá rán àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù lọ síbẹ̀. Láti ṣe kí ni? Bíbélì sọ pé: “[Àwọn méjèèjì] wá ń gbé ọwọ́ lé [àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi náà], wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.” Èyí sì ní láti jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n gba ẹ̀bùn ẹ̀mí, ìyẹn agbára láti ṣe àwọn ohun ìyanu táwọn èèyàn lè fojú rí. A mọ̀ bẹ́ẹ̀ torí pé nígbà tí Símónì tó ti ń fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀, rí ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ gbà ń ṣiṣẹ́ yìí, ó fi ìwọra gbìyànjú láti fowó ra irú agbára gbígbé ọwọ́ léni yẹn, kóun náà lè máa fún àwọn èèyàn ní ẹ̀mí mímọ́ tí wọ́n á fi máa ṣe iṣẹ́ ìyanu. (Ìṣe 8:5-20) Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn méjìlá ṣèrìbọmi ní ìlú Éfésù. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì gbé ọwọ́ lé wọn, ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, wọ́n sì ń sọ tẹ́lẹ̀.”—Ìṣe 19:1-7; fi wé 2 Tímótì 1:6.

Nítorí náà, ẹ̀rí fi hàn pé ọ̀rọ̀ gbígbé ọwọ́ lé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ láti lè fún wọn ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ ní Hébérù 6:2.