Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Ṣáko Lọ Kí Wọ́n Lè Pa Dà Sínú Agbo

Ẹ Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Ṣáko Lọ Kí Wọ́n Lè Pa Dà Sínú Agbo

Ẹ Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Ṣáko Lọ Kí Wọ́n Lè Pa Dà Sínú Agbo

“Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí àgùntàn mi tí ó sọnù.”—LÚÙKÙ 15:6.

1. Kí ló fi hàn pé Jésù jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́?

 BÍBÉLÌ pe Jésù Kristi, ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà, ní “olùṣọ́ àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn.” (Héb. 13:20) Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò wá sáyé ó sì fi hàn pé òun ni Olùṣọ́ Àgùntàn àrà ọ̀tọ̀ tó máa wá “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù” kàn. (Mát. 2:1-6; 15:24) Yàtọ̀ síyẹn, bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa forí lakú láti lè dáàbò bo àgùntàn rẹ̀, náà ni Jésù ṣe kú láti fi ara rẹ̀ ṣe ẹbọ ìràpadà fáwọn ẹni bí àgùntàn tó bá fẹ́ jàǹfààní ẹbọ náà.—Jòh. 10:11, 15; 1 Jòh. 2:1, 2.

2. Kí ló lè fà á táwọn Kristẹni kan fi di aláìṣiṣẹ́mọ́?

2 Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan tí wọ́n sọ pé àwọn mọrírì ẹbọ ìràpadà Jésù, tí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ti kúrò nínú ètò Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìrẹ̀wẹ̀sì, àìlera tàbí àwọn nǹkan míì ló bomi paná ìtara wọn tí wọ́n fi di aláìṣiṣẹ́mọ́. Ṣùgbọ́n, ìgbà tí wọ́n bá wà nínú agbo Ọlọ́run nìkan ni wọ́n lè ní irú ìbàlẹ̀ ọkàn àti ayọ̀ tí Dáfídì sọ nípa rẹ̀ nínú Sáàmù kẹtàlélógún. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.” (Sm. 23:1) Kò sóhun tó ń mú kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run tí àwọn èèyàn tó wà nínú agbo Ọlọ́run kò ní. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá fáwọn àgùntàn tó ti ṣáko lọ. Ta ló lè ran irú àwọn àgùntàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́? Ọ̀nà wo la lè gbà ṣèrànwọ́ fún wọn? Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tí wọ́n á fi ṣẹ́rí pa dà sínú agbo?

Ta Ló Lè Ràn Wọ́n Lọ́wọ́?

3. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe láti lè rí àgùntàn inú agbo Ọlọ́run tó sọ nù mú pa dà?

3 Ó gba ìsapá gan-an láti lè rí àgùntàn inú agbo Ọlọ́run tó sọ nù mú pa dà. (Sm. 100:3) Bí Jésù ṣe ṣàkàwé ọ̀rọ̀ náà nìyí: “Bí ọkùnrin kan bá wá ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ọ̀kan nínú wọn sì ṣáko lọ, kì yóò ha fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún náà sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, kí ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n láti wá ọ̀kan tí ó ṣáko lọ? Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ó rí i, mo sọ fún yín dájúdájú, yóò yọ̀ púpọ̀ lórí rẹ̀ ju lórí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún tí kò tíì ṣáko lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kì í ṣe ohun tí Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ní ìfẹ́-ọkàn sí, pé kí ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ṣègbé.” (Mát. 18:12-14) Ta ló wá lè ṣèrànwọ́ fáwọn ẹni bí àgùntàn tó ti ṣáko lọ kúrò nínú agbo Ọlọ́run?

4, 5. Ọwọ́ wo ló yẹ kí àwọn alàgbà máa fi mú agbo Ọlọ́run?

4 Táwọn alàgbà bá máa ṣèrànwọ́ fáwọn tó ti ṣáko lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ máa rántí pé àwọn ẹni tó ti yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ló wà nínú agbo Ọlọ́run, ìyẹn “agbo ẹran pápá ìjẹko” tó ṣeyebíye lójú Jèhófà. (Sm. 79:13) Ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ló yẹ káwọn olùṣọ́ àgùntàn fi mú irú àwọn àgùntàn àtàtà bẹ́ẹ̀, èyí sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn gbọ́dọ̀ jẹ àwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ yìí lógún gan-an. Ohun kan tó lè ṣèrànwọ́ púpọ̀ fún wọn ni pé káwọn alàgbà máa ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ wọn láti fà wọ́n mọ́ra. Ìṣírí tí olùṣọ́ àgùntàn kan bá fún wọn lè gbé wọn ró nípa tẹ̀mí kó sì mú kó túbọ̀ máa wù wọ́n láti pa dà sínú ètò Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 8:1.

5 Ojúṣe àwọn olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run ni láti wá àwọn àgùntàn tó ṣáko lọ kàn, kí wọ́n sì gbìyànjú láti mú wọn pa dà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn alàgbà ìjọ ìlú Éfésù létí pé, ojúṣe wọn ni pé kí wọ́n máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo. Ó ní: “Ẹ kíyè sí ara yín àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Bákan náà, Pétérù gba àwọn àgbà ọkùnrin lára àwọn ẹni àmì òróró níyànjú pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.”—1 Pét. 5:1-3.

6. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé òde òní làwọn àgùntàn inú agbo Ọlọ́run nílò àbójútó jù?

6 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Kristẹni ní láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà.” (Jòh. 10:11) Ọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn inú agbo Ọlọ́run jẹ ẹ́ lógún gidigidi, ó sì tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa bójú tó wọn nígbà tó sọ fún Símónì Pétérù pé kó ‘máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn àgùntàn òun kéékèèké.’ (Ka Jòhánù 21:15-17.) Òde òní làwọn àgùntàn inú agbo Ọlọ́run nílò irú àbójútó bẹ́ẹ̀ jù, nítorí pé Èṣù túbọ̀ ń gbógun lójú méjèèjì láti mú káwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run ṣe ohun tó lè ba ìgbàgbọ́ wọn jẹ́. Ó máa ń fẹ́ lo àìpé ẹ̀dá àtàwọn nǹkan ayé yìí láti fi tan àwọn àgùntàn inú agbo Jèhófà sínú ẹ̀ṣẹ̀. (1 Jòh. 2:15-17; 5:19) Àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ ni Sátánì sì máa ń tètè rí mú. Nítorí náà, wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ gan-an kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ká “máa rìn nípa ẹ̀mí.” (Gál. 5:16-21, 25) Láti lè ran irú àwọn àgùntàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ká sì mọ bá a ṣe lè lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó múná dóko.—Òwe 3:5, 6; Lúùkù 11:13; Héb. 4:12.

7. Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn alàgbà máa bójú tó àwọn ẹni bí àgùntàn tó wà níkàáwọ́ wọn?

7 Ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì, ọ̀pá gígùn, tó tẹ̀ kọdọrọ lórí, ni olùṣọ́ àgùntàn sábà máa ń fi da agbo ẹran rẹ̀. Abẹ́ ọ̀pá yìí làwọn àgùntàn máa ń gbà nígbà tí wọ́n bá fẹ́ wọlé tàbí tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú ọgbà ẹran, kí olùṣọ́ àgùntàn lè kà wọ́n. (Léf. 27:32; Míkà 2:12; 7:14) Bó ṣe yẹ kí olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ Kristẹni mọ gbogbo àgùntàn Ọlọ́run tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ náà nìyẹn, kó sì máa kíyè sí bí olúkúlùkù wọn ṣe ń ṣe. (Fi wé Òwe 27:23.) Ìdí nìyẹn tí ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn fi jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa ń jíròrò. Wọ́n máa ń jíròrò bí wọ́n ṣe máa ṣèrànwọ́ fáwọn àgùntàn tó ṣáko lọ kí wọ́n lè pa dà sínú agbo. Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ pé òun máa wá àwọn àgùntàn òun, pé òun á sì bójú tó wọn bó ṣe yẹ. (Ìsík. 34:11) Nítorí náà, inú Ọlọ́run máa ń dùn nígbà táwọn alàgbà náà bá sapá láti wá àwọn àgùntàn tó ṣáko lọ kàn láti mú wọn pa dà sínú agbo.

8. Àwọn ọ̀nà wo làwọn alàgbà lè gbà ṣèrànwọ́ fáwọn àgùntàn ìjọ?

8 Tí ẹnì kan nínú ìjọ bá ń ṣàìsàn tí olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run kan sì lọ kí i, ìyẹn máa fún un níṣìírí, á sì tún fún un láyọ̀. Bó ṣe máa ń rí náà nìyẹn tá a bá wá àgùntàn tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí lọ. Lára ohun táwọn alàgbà lè ṣe fónítọ̀hún ni pé wọ́n lè ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún un, wọ́n lè jọ gbé àpilẹ̀kọ kan yẹ̀ wò, wọ́n lè mẹ́nu kan kókó tí wọ́n gbádùn nípàdé, wọ́n sì lè gbàdúrà fún un. Wọ́n tún lè jẹ́ kó mọ̀ pé inú àwọn ará ìjọ yóò dùn tí wọ́n bá tún pa dà ń rí i nípàdé. (2 Kọ́r. 1:3-7; Ják. 5:13-15) Ìrànlọ́wọ́ ńlá ni wíwá wọn lọ, pípè wọ́n lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù tàbí kíkọ lẹ́tà sí wọn lè ṣe fún wọn! Tí alàgbà kan bá ń ṣèrànwọ́ fún àgùntàn tó ti sú lọ kúrò nínú agbo, ìyẹn lè fi kún ayọ̀ alàgbà náà fúnra rẹ̀.

Iṣẹ́ Gbogbo Wa Ni

9, 10. Kí nìdí tó o fi lè sọ pé àwọn alàgbà nìkan kọ́ ló yẹ kí ọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn tó ṣáko lọ jẹ lógún?

9 Àsìkò lílekoko tọ́wọ́ gbogbo èèyàn dí gan-an la wà yìí, nítorí náà a lè má tètè mọ̀ tí ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni bá ń sú lọ kúrò nínú ìjọ. (Héb. 2:1) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, gbogbo àgùntàn Jèhófà ló ṣeyebíye lójú rẹ̀. Bí ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ti ṣe pàtàkì nínú ara èèyàn ni olúkúlùkù wọn ṣe ṣe pàtàkì gan-an. Nítorí náà, ó yẹ kí gbogbo wa máa ṣàníyàn nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, ká sì máa ṣaájò ara wa. (1 Kọ́r. 12:25) Ṣé irú ẹ̀mí tó o ní nìyẹn?

10 Lóòótọ́ àwọn alàgbà ló yẹ kó múpò iwájú nínú wíwá àwọn àgùntàn tó ti ṣáko lọ kàn láti lè mú wọn pa dà sínú agbo, síbẹ̀ àwọn alábòójútó nìkan kọ́ ló yẹ kí ọ̀rọ̀ àwọn ará wa tó sú lọ jẹ lógún. Ó yẹ káwọn ará ìjọ náà bá àwọn alàgbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ yẹn. Gbogbo wa la lè sọ̀rọ̀ ìṣírí àti ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró fáwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin tó nílò ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sínú agbo Ọlọ́run, ó sì yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà wo la lè gbà ṣèrànwọ́ yìí?

11, 12. Báwo lo ṣe lè wà lára àwọn tó máa ṣèrànwọ́ fẹ́ni tó nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí?

11 Nígbà míì, àwọn alàgbà lè ṣètò pé kí àwọn akéde tó ti nírìírí máa bá àwọn akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ tí wọ́n fi hàn pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́ ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Ohun tírú ètò bẹ́ẹ̀ wà fún ni láti mú kí ‘ìfẹ́ tí wọ́n ní ní àkọ́kọ́’ sọ jí. (Ìṣí. 2:1, 4) Ọ̀nà kan tá a lè gbà gbé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ró, ká sì fún ìgbàgbọ́ wọn lókun ni pé ká bá wọn jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ àti ìsọfúnni tí wọ́n pàdánù ní gbogbo àkókò tí wọn ò fi wá sípàdé.

12 Táwọn alàgbà bá ní kó o bá akéde kan tó nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí ṣèkẹ́kọ̀ọ́, gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ ọ sọ́nà kó sì bù kún ìsapá rẹ. Bíbélì sọ pé, “yí àwọn iṣẹ́ rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà tìkára rẹ̀, a ó sì fìdí àwọn ìwéwèé rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (Òwe 16:3) Ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì àti ọ̀rọ̀ tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró tó o lè bá àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ láti pa dà sínú ètò jíròrò. Ronú nípa àpẹẹrẹ àtàtà ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. (Ka Róòmù 1:11, 12.) Ó ń wu Pọ́ọ̀lù gan-an láti rí àwọn Kristẹni nílùú Róòmù kó bàa lè fún wọn ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, kí ìgbàgbọ́ wọn lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in. Ó sì ń wọ̀nà fún pàṣípààrọ̀ ìṣírí tí wọ́n máa jọ fún ara wọn. Ǹjẹ́ kì í ṣe irú ẹ̀mí yẹn ló yẹ ká ní nígbà tá a bá fẹ́ ṣèrànwọ́ fáwọn àgùntàn tó ti ṣáko lọ kúrò nínú agbo Ọlọ́run?

13. Kí lo lè bá aláìṣiṣẹ́mọ́ kan jíròrò?

13 Nígbà tó o bá ń bá aláìṣiṣẹ́mọ́ náà jíròrò, o lè bi í pé, “Báwo lẹ ṣe rí òtítọ́?” O tún lè sọ ohun tó máa jẹ́ kó rántí ayọ̀ tó máa ń ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tẹ́lẹ̀ rí, bíi pé kó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìrírí alárinrin tó ti ní rí láwọn ìpàdé, lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti láwọn àpéjọ wa. Sọ̀rọ̀ nípa àwọn àkókò alárinrin tó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ ti jọ lò pa pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Mẹ́nu kan ayọ̀ tí sísún mọ́ Jèhófà ti jẹ́ kí ìwọ náà ní. (Ják. 4:8) Sọ bó o ṣe mọrírì ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń pèsè àwọn ohun táwa èèyàn rẹ̀ nílò, pàápàá bó ṣe ń tù wá nínú tó sì ń fún wa nírètí lákòókò ìpọ́njú wa.—Róòmù 15:4; 2 Kọ́r. 1:3, 4.

14, 15. Àwọn àǹfààní wo làwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ ti ní rí, èyí tá a lè mú kí wọ́n rántí?

14 Ó lè dáa láti rán aláìṣiṣẹ́mọ́ náà létí àwọn àǹfààní tó ti jẹ sẹ́yìn nítorí pé ó ń ṣe déédéé nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, ìmọ̀ rẹ̀ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ láti ṣe ń jinlẹ̀ sí i. (Òwe 4:18) Ó dájú pé, ìgbà tó ṣì ‘ń rìn nípa ẹ̀mí’ ló ṣeé ṣe fún un láti máa tètè yàgò fún ìdẹwò. (Gál. 5:22-26) Ìyẹn sì jẹ́ kó lè ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́ tó ń jẹ́ kó lè gbàdúrà sí Jèhófà fàlàlà, tó sì wá ní ‘àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ, èyí tó ń ṣọ́ ọkàn-àyà wa àti agbára èrò orí wa.’ (Fílí. 4:6, 7) Fi irú àwọn kókó wọ̀nyí sọ́kàn, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ onítọ̀hún jẹ ọ́ lógún lóòótọ́, kó o sì sa gbogbo ipá rẹ tìfẹ́tìfẹ́ láti fún arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ yìí níṣìírí láti pa dà sínú ètò Ọlọ́run.—Ka Fílípì 2:4.

15 Tó o bá jẹ́ alàgbà, kí lo lè ṣe tó o bá ń ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́? Tí wọ́n bá jẹ́ tọkọtaya, o lè sọ ohun tó máa mú kí wọ́n ronú nípa ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Sọ ohun tó máa mú wọn rántí bí òtítọ́ ṣe wú wọn lórí, bó ṣe bọ́gbọ́n mu, bó ṣe tẹ́ wọn lọ́rùn, àti bó ṣe sọ wọ́n dòmìnira! (Jòh. 8:32) Kí wọ́n sì tún rántí bí wọ́n ṣe kún fún ọpẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ń kọ́ nípa Jèhófà, ìfẹ́ rẹ̀ àtàwọn ohun àgbàyanu tó fẹ́ ṣe. (Fi wé Lúùkù 24:32.) Rán wọn létí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín Jèhófà àtàwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ àti àǹfààní ńláǹlà tí wọ́n ní láti máa gbàdúrà sí i fàlàlà. Rọ àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ náà dáadáa pé kí wọ́n tún fọwọ́ pàtàkì mú “ìhìnrere ológo ti [Jèhófà] Ọlọ́run aláyọ̀.”—1 Tím. 1:11.

Máa Fìfẹ́ Hàn sí Wọn

16. Sọ àpẹẹrẹ kan tó o mọ̀, èyí tó fi hàn pé ìrànlọ́wọ́ tá a bá ṣe fáwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ máa ń láṣeyọrí.

16 Ǹjẹ́ àwọn nǹkan tá a gbà yín nímọ̀ràn pé kẹ́ ẹ ṣe yìí tiẹ̀ lè ṣiṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni o. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún méjìlá ni ọmọkùnrin kan nígbà tó di akéde, ó sì di aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Àmọ́ nígbà tó yá, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe déédéé débi pé ó ti lé lọ́gbọ̀n ọdún báyìí tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún. Ìrànlọ́wọ́ tí alàgbà kan ṣe fún un jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tó mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe déédéé nínú ìjọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí alàgbà yẹn ṣe fún un gan-an ni!

17, 18. Àwọn ànímọ́ wo lo máa nílò tó o bá fẹ́ ṣèrànwọ́ fẹ́nì kan tó ṣáko lọ kúrò nínú agbo Ọlọ́run?

17 Ìfẹ́ ló ń mú káwa Kristẹni fẹ́ láti ṣèrànwọ́ fáwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ kí wọ́n lè dẹni tó tún ń ṣe déédéé lẹ́ẹ̀kan sí i. Ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:34, 35) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìfẹ́ ló ń fi àwọn Kristẹni tòótọ́ hàn yàtọ̀. Ǹjẹ́ kò sì yẹ ká nawọ́ irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ sí àwọn Kristẹni tó ti ṣèrìbọmi tó wá di aláìṣiṣẹ́mọ́? Ó yẹ bẹ́ẹ̀ o! Ṣùgbọ́n a ní láti lo onírúurú ànímọ́ Kristẹni nígbà tá a bá ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

18 Àwọn ànímọ́ wo lo máa nílò tó o bá fẹ́ ṣèrànwọ́ fẹ́ni tó ṣáko lọ kúrò nínú agbo Ọlọ́run? Yàtọ̀ sí ìfẹ́, wàá ní láti ní ìyọ́nú, inú rere, ìwà tútù àti ìpamọ́ra. Ipò míì lè gba pé kó o ní ẹ̀mí ìdáríjì. Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ ni pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kól. 3:12-14.

19. Kí nìdí tí gbogbo ìsapá wa láti rí i pé àwọn ẹni bí àgùntàn pa dà sínú agbo Kristẹni fi tó bẹ́ẹ̀ tó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ?

19 Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tó tẹ̀ lé èyí yóò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìdí táwọn kan fi ń ṣáko lọ kúrò nínú agbo Ọlọ́run. Yóò tún jẹ́ káwọn tó bá pa dà sínú ètò Ọlọ́run rí báwọn ará ìjọ ṣe máa tẹ́wọ́ gba àwọn. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ yẹn, tó o sì ń ṣàṣàrò lórí èyí tó ò ń kà lọ́wọ́ yìí, mọ̀ dájú pé gbogbo ìsapá rẹ láti rí i pé àwọn ẹni bí àgùntàn wọ̀nyí pa dà sínú agbo Kristẹni tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn ṣiṣẹ́ torí kí wọ́n ṣáà lè kó ọrọ̀ jọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ẹ̀mí ẹnì kan ṣoṣo téèyàn bá ràn lọ́wọ́ tó sì pa dà sínú agbo Ọlọ́run ju gbogbo owó ayé yìí lọ. Jésù gbé kókó yìí yọ nínú àkàwé rẹ̀ nípa àgùntàn tó sọ nù. (Mát. 18:12-14) Jọ̀wọ́ fi kókó yìí sọ́kàn bó o ṣe ń sapá lójú méjèèjì láti ṣèrànwọ́ fáwọn àgùntàn tó ṣeyebíye lójú Jèhófà, tó ti ṣáko lọ, kí wọ́n lè pa dà sínú agbo Ọlọ́run.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni ojúṣe àwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ nínú ọ̀rọ̀ àwọn ẹni bí àgùntàn tó ṣáko lọ kúrò nínú agbo?

• Ọ̀nà wo lo lè gbà ran àwọn tó ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀ lọ́wọ́?

• Àwọn ànímọ́ wo lo máa nílò láti lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ṣáko lọ kúrò nínú agbo Ọlọ́run?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ máa ń fi tìfẹ́tìfẹ́ sapá láti rí i pé àwọn tó ṣáko lọ pa dà sínú agbo Ọlọ́run