Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jákọ́bù, Ìwé Pétérù Kìíní àti Pétérù Kejì

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jákọ́bù, Ìwé Pétérù Kìíní àti Pétérù Kejì

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jákọ́bù, Ìwé Pétérù Kìíní àti Pétérù Kejì

NÍ NǸKAN bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jákọ́bù ọmọlẹ́yìn Jésù tó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀ kọ lẹ́tà kan sí “ẹ̀yà méjìlá tí ó tú ká káàkiri.” (Ják. 1:1) Ó kọ lẹ́tà yẹn láti rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára kí wọ́n sì lo ìfaradà nígbà àdánwò. Ó tún fún wọn ní ìmọ̀ràn lórí bí wọ́n ṣe máa ṣàtúnṣe sí àwọn nǹkan tí kò lọ déédéé nínú àwọn ìjọ.

Ṣáájú kí Nérò Olú Ọba ilẹ̀ Róòmù tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni lọ́dún 64 Sànmánì Kristẹni ni àpọ́sítélì Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ kìíní sáwọn Kristẹni. Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ wọn. Kò pẹ́ sígbà yẹn ló kọ lẹ́tà kejì nínú èyí tó ti rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n máa fiyè sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bákan náà ló tún rán wọn létí ọjọ́ Jèhófà tó ń bọ̀. Ó dájú pé a máa jàǹfààní tá a bá ń fiyè sí ohun tó wà nínú ìwé Jákọ́bù, ìwé Pétérù kìíní àti Pétérù kejì.—Héb. 4:12.

ỌLỌ́RUN Ń FI ỌGBỌ́N FÁWỌN TÓ BÁ Ń BÉÈRÈ “NÍNÚ ÌGBÀGBỌ́”

(Ják. 1:1–5:20)

Jákọ́bù sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífarada àdánwò, nítorí nígbà tí ó bá di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, yóò gba adé ìyè.” Jèhófà máa ń fi ọgbọ́n jíǹkí àwọn tó bá ń bá a nìṣó ní “bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́” kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe máa fara da àdánwò.—Ják. 1:5-8, 12.

Àwọn tó “di olùkọ́” nínú ìjọ pẹ̀lú nílò ìgbàgbọ́ àti ọgbọ́n. Jákọ́bù sọ pé ahọ́n jẹ́ “ẹ̀yà ara kékeré,” síbẹ̀ ó lè “fi èérí yí gbogbo ara,” ó wá kìlọ̀ nípa àwọn ìwà tó ń fi hàn pé èèyàn ní ẹ̀mí ayé, èyí tó lè ba àjọṣe èèyàn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Ó tún ṣàlàyé àwọn ìgbésẹ̀ tẹ́ni tó bá ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí lè gbé táá fi pa dà bọ̀ sípò.—Ják. 3:1, 5, 6; 5:14, 15.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

2:13—Ọ̀nà wo ni ‘àánú máa ń gbà yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìdájọ́’? Nígbà tá a bá ń jíhìn iṣẹ́ ọwọ́ wa fún Ọlọ́run, ó máa wo ti àánú tá a ṣe fáwọn ẹlòmíì mọ́ wa lára, ó sì máa dárí jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀. (Róòmù 14:12) Ṣé ẹ wá rí i báyìí pé ó yẹ kí àánú jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ànímọ́ tó máa hàn gbangba nínú ìgbésí ayé wa?

4:5—Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni Jákọ́bù fà yọ níbí yìí? Kì í ṣe pé Jákọ́bù fa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan yọ ní pàtó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn tí Ọlọ́run mí sí tó sọ yẹn jẹ́ kókó inú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Jẹ́nẹ́sísì 6:5; 8:21; Òwe 21:10 àti Gálátíà 5:17.

5:20—Ọkàn ta ni “ẹni tí ó yí ẹlẹ́ṣẹ̀ padà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀” yóò gbà là lọ́wọ́ ikú? Tí Kristẹni kan bá yí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó ń dá, níwọ̀n bí ẹni yẹn ti ronú pìwà dà, ẹni tó yí i lọ́kàn pa dà yẹn ti gba ọkàn rẹ̀ là kúrò lọ́wọ́ ikú tẹ̀mí, ìyẹn ipò àìní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run, àti ìparun ayérayé tó ṣeé ṣe kó dé bá a. Lọ́nà yìí, ẹni tó ran ẹlẹ́ṣẹ̀ yẹn lọ́wọ́ á tún máa tipa bẹ́ẹ̀ “bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ [onítọ̀hún] mọ́lẹ̀.”

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:

1:14, 15. Ibi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn ni ẹ̀ṣẹ̀ ti máa ń bẹ̀rẹ̀. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ gbà kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ráyè ta gbòǹgbò lọ́kàn wa nípa ríronú lórí àwọn nǹkan tí kò tọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tó ń gbéni ró ló yẹ ká ‘máa ronú lé lórí,’ àwọn ló sì yẹ ká máa fàyè gbà nínú ọkàn wa.—Fílí. 4:8.

2:8, 9. ‘Ṣíṣègbè’ tàbí ojúsàájú lòdì sí ìlànà ìfẹ́ tí í ṣe “ọba òfin.” Torí náà, àwa Kristẹni tòótọ́ ò gbọ́dọ̀ máa ṣojúsàájú.

2:14-26. “Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́” la ń gbà wá là, “kì í ṣe ní tìtorí àwọn iṣẹ́” tí Òfin Mósè là kalẹ̀ tàbí nípasẹ̀ iṣẹ́ tàwa Kristẹni. Ìgbàgbọ́ wa ò gbọ́dọ̀ mọ sórí ká kàn sọ pé a gba Ọlọ́run gbọ́. (Éfé. 2:8, 9; Jòh. 3:16) Ó gbọ́dọ̀ sún wa láti ṣe ohun tínú Ọlọ́run dùn sí.

3:13-17. Ó dájú pé “ọgbọ́n tí ó sọ̀ kalẹ̀ wá láti òkè” ló dára, ọgbọ́n “ti ilẹ̀ ayé, ti ẹranko, ti ẹ̀mí èṣù” kò dára. Ṣe ló yẹ ká máa ‘wá ọgbọ́n Ọlọ́run kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin.’—Òwe 2:1-5.

3:18. “Lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà” ni kí “àwọn tí ń wá àlàáfíà” máa fúnrúgbìn èso ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ ẹni tó ń wá àlàáfíà dípò ká jẹ́ agbéraga, aríjàgbá tàbí oníjàgídíjàgan.

‘Ẹ DÚRÓ GBỌN-IN NÍNÚ ÌGBÀGBỌ́’

(1 Pét. 1:1–5:14)

Pétérù rán àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni létí “ìrètí tí ó wà láàyè” tí wọ́n ní, ìyẹn ogún ti ọ̀run. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́.’” Lẹ́yìn tó ti fún wọn nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìtẹríba, ó rọ gbogbo wọn pé: “Ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú.”—1 Pét. 1:3, 4; 2:9; 3:8.

Níwọ̀n bí “òpin [ètò àwọn nǹkan Júù] ti sún mọ́lé,” Pétérù gba àwọn ará nímọ̀ràn pé kí wọ́n ‘yè kooro ní èrò inú, kí wọ́n wà lójúfò, kí wọ́n sì jẹ́ kí àdúrà jẹ wọ́n lọ́kàn.’ Ó wá fi kún un pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. . . . Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Sátánì], ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.”—1 Pét. 4:7; 5:8, 9.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

3:20-22—Báwo ni ìbatisí ṣe ń gbà wá là? Ó pọn dandan kẹ́ni tó bá fẹ́ rí ìgbàlà ṣe ìbatisí. Àmọ́, ìrìbọmi gan-an kọ́ ló máa gbà wá là. “Nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi” la lè rí ìgbàlà. Àwọn tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ pé ohun tó máa jẹ́ ká lè rí ìgbàlà ni kíkú tí Jésù kú láti fi ara rẹ̀ rúbọ, tí Ọlọ́run sì jí i dìde, àti pé ní báyìí “ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,” ó sì ní agbára lórí àwọn òkú àti alààyè. Ìrìbọmi téèyàn ṣe lẹ́yìn tó ti ní irú ìgbàgbọ́ yẹn ló dà bí ìgbà tí ‘ọkọ̀ áàkì gbé ènìyàn mẹ́jọ la omi já láìséwu.’

4:6—Àwọn wo ni “òkú” tí a “polongo ìhìn rere fún”? Àwọn wọ̀nyí làwọn tó ti “kú nínú àwọn àṣemáṣe àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀” wọn, ìyẹn ni pé wọ́n kú nípa tẹ̀mí, kí wọ́n tó gbọ́ ìhìn rere. (Éfé. 2:1) Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere, wọ́n dẹni tó “wà láàyè” nípa tẹ̀mí.

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:

1:7. Ká tó lè sọ pé ojúlówó ni ìgbàgbọ́ wa, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tá a ti dán wò tó sì ti yege. Irú ìgbàgbọ́ tó lágbára bẹ́ẹ̀ ló ‘ń pa ọkàn mọ́ láàyè.’ (Héb. 10:39) A ò gbọ́dọ̀ fà sẹ́yìn nígbà tí àdánwò ìgbàgbọ́ wa bá dé.

1:10-12. Àwọn áńgẹ́lì ń fẹ́ láti wo àwòfín àwọn ohun ìjìnlẹ̀ táwọn wòlíì Ọlọ́run ti kọ nígbà àtijọ́ nípa ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kí wọ́n lè lóye rẹ̀. Àmọ́, ìgbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìjọ Kristẹni làwọn òtítọ́ wọ̀nyí wá ṣe kedere. (Éfé. 3:10) Ṣé kò yẹ káwa náà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn áńgẹ́lì, ká máa sapá láti wádìí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”?—1 Kọ́r. 2:10.

2:21. Ńṣe ni ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa, ká má ṣe sá fún ìjìyà, tó bá jẹ́ pé ohun tó gbà nìyẹn ká lè fi hàn pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run, kódà tí ìjìyà náà bá tiẹ̀ la ikú lọ.

5:6, 7. Tá a bá kó gbogbo àníyàn wa lé Jèhófà lọ́wọ́, yóò ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fi ìjọsìn tòótọ́ sí ipò tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa, ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká máa ṣàníyàn tí kò yẹ nípa ohun tí ọjọ́ ọ̀la lè bí.—Mát. 6:33, 34.

“ỌJỌ́ JÈHÓFÀ YÓÒ DÉ”

(2 Pét. 1:1–3:18)

Pétérù sọ pé: “A kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” Tá a bá ń fiyè sí àsọtẹ́lẹ̀ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ “àwọn olùkọ́ èké” àtàwọn míì tó lè kọ́ wa ní ìwàkiwà.—2 Pét. 1:21; 2:1-3.

Pétérù ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn.” Ṣùgbọ́n “ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè.” Ohun tí Pétérù fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ìmọ̀ràn tó yè kooro tó fún àwọn ‘tó ń dúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ yẹn tí wọ́n sì ń fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’—2 Pét. 3:3, 10-12.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

1:19—Ta ni “ìràwọ̀ ojúmọ́,” ìgbà wo ló yọ, báwo la sì ṣe mọ̀ pé ìràwọ̀ ojúmọ́ ti yọ? Jésù Kristi ni “ìràwọ̀ ojúmọ́” náà, ìyẹn lẹ́yìn tó ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣí. 22:16) Lọ́dún 1914, Jésù Kristi di Mèsáyà Ọba, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ yọ bí ìràwọ̀ níwájú gbogbo ìṣẹ̀dá, èyí tó fi hàn pé ojúmọ́ ọjọ́ tuntun ti mọ́. Ìyípadà ológo tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù nígbà tó wà láyé jẹ́ àpẹẹrẹ ògo àti agbára tí Jésù máa ní nígbà tó bá di ọba Ìjọba Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ ká rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní láti ṣẹ dandan. Bá a ṣe ń fiyè sí ọ̀rọ̀ yìí, ó ń tànmọ́lẹ̀ sínú ọkàn wa, èyí sì jẹ́ ká mọ̀ pé Ìràwọ̀ Ojúmọ́ ti yọ.

2:4—Kí ni “Tátárọ́sì,” ìgbà wo sì ni Ọlọ́run ju àwọn áńgẹ́lì tó ṣọ̀tẹ̀ síbẹ̀? Ipò kan tó dà bí inú ẹ̀wọ̀n ni Tátárọ́sì, àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ áńgẹ́lì ló wà fún kò wà fáwọn ọmọ èèyàn. Òye àwọn ohun tó hàn kedere pé Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe ṣókùnkùn pátápátá sáwọn tó wà nínú ipò yẹn. Kò sí ìrètí kankan fáwọn tó wà ní Tátárọ́sì, ìparun ló ń dúró dè wọ́n. Ìgbà ayé Nóà ni Ọlọ́run ju àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn sínú Tátárọ́sì, inú ipò ẹ̀tẹ́ yẹn ni wọ́n sì máa wà títí tí ìparun wọn á fi dé.

3:17—Kí ni Pétérù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé àwọn Kristẹni yẹn “ti ní ìmọ̀ èyí tẹ́lẹ̀”? Ohun tí Pétérù sọ pé àwọn Kristẹni yẹn ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú tí Ọlọ́run ti fẹ̀mí rẹ̀ sọ fún òun àtàwọn míì tí wọ́n kọ Bíbélì. Níwọ̀n bí ìmọ̀ tó ń sọ yìí kì í ti í ṣe èyí tí kò lópin, àwọn Kristẹni ìgbà yẹn kò mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú. Fìrífìrí ohun tó ń bọ̀ lọ́nà ni wọ́n kàn rí.

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:

1:2, 5-7. Tá a bá sakun láti ní àwọn ànímọ́ bí ìgbàgbọ́, ìfaradà àti ìfọkànsin Ọlọ́run, yóò jẹ́ ká túbọ̀ máa ní “ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti nípa Jésù.” Ìyẹn nìkan kọ́, àwọn ànímọ́ yẹn ò ní jẹ́ ká “di aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso ní ti ìmọ̀ pípéye.”—2 Pét. 1:8.

1:12-15. Láti lè “fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú òtítọ́,” a nílò ìránnilétí lemọ́lemọ́, irú èyí tá a máa ń rí gbà láwọn ìpàdé ìjọ, látinú ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti látinú kíka Bíbélì.

2:2. Ó yẹ ká ṣọ́ra kí ìwà wa má bàa kó ẹ̀gàn bá Jèhófà àti ètò rẹ̀.—Róòmù 2:24.

2:4-9. Látinú ohun tí Jèhófà ti ṣe sẹ́yìn, ó dá wa lójú pé ó “mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò.”

2:10-13. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “àwọn ẹni ògo,” ìyẹn àwọn alàgbà ìjọ, ní kùdìẹ̀-kudiẹ tiwọn, tí wọ́n sì lè ṣàṣìṣe nígbà míì, a ò gbọ́dọ̀ máa sọ̀rọ̀ wọn tèébútèébú.—Héb. 13:7, 17.

3:2-4, 12. Tá a bá ń fiyè sí “àwọn àsọjáde tí àwọn wòlíì mímọ́ ti sọ ní ìṣáájú àti àṣẹ Olúwa àti Olùgbàlà,” yóò jẹ́ ká lè máa fi sọ́kàn ní gbogbo ìgbà pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé.

3:11-14. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń dúró de “ọjọ́ Jèhófà” tó sì ń fi í “sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí,” (1) a gbọ́dọ̀ ‘jẹ́ mímọ́ nínú ìwà,’ ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ mọ́ nípa tara, nípa tẹ̀mí, nípa ìwà híhù, ká sì jẹ́ kí èrò ọkàn wa wà ní mímọ́; (2) a gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kọ́wọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ tó ń fi “ìfọkànsin Ọlọ́run” hàn, irú bí iṣẹ́ tó jẹ mọ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yin; (3) a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwà wa àti ìṣe wa wà “ní àìléèérí,” ìyẹn ni pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ayé yìí kó èèràn ràn wá; (4) a gbọ́dọ̀ wà “ní àìlábààwọ́n,” ìyẹn ni pé ká máa ní èrò rere lọ́kàn nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe; (5) a sì gbọ́dọ̀ wà “ní àlàáfíà” pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, títí kan àwọn tí kì í ṣe Kristẹni.