Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Màríà

Àwọn Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Màríà

Àwọn Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Màríà

Ṣé ìṣòro kan tàbí ojúṣe kan tó o rò pó ju agbára ẹ lọ ti mu ẹ́ lómi rí? Àbí wàhálà tó wà nínú bíbójú tó ọ̀ràn àtijẹ àtimu ti jẹ́ kí nǹkan tojú sú ẹ? Bóyá o tiẹ̀ wà lára ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí nǹkan ti tojú sú tí ọkàn wọn ò sì balẹ̀ torí pé ipò nǹkan ti mú kí wọ́n sá gba orílẹ̀-èdè míì lọ. Pabanbarì ẹ̀ ni pé kò sẹ́ni tó máa sọ pé òun ò mọ bó ṣe máa ń ṣèèyàn nígbà téèyàn ẹni bá kú.

ṢÓ O mọ̀ pé gbogbo ìṣòro tá a kà sílẹ̀ yìí ni Màríà ìyá Jésù ti dojú kọ rí? Ohun tó wúni lórí jù lọ ni pé ó borí àwọn ìṣòro wọ̀nyẹn! Kí la wá lè rí kọ́ lára Màríà?

Kò síbi tí wọn ò ti mọ̀ nípa Màríà lágbàáyé. Kò sì yẹ kíyẹn yà wá lẹ́nu, torí pé ipa tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ló kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń bọ̀wọ̀ fún Màríà láwọn ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ọ̀wọ̀ tó yẹ Ìyá ọ̀wọ́n ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì máa ń fún Màríà, wọ́n sì máa fi ń ṣàpẹẹrẹ ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìwà ọ̀làwọ́. Àwọn olórí ìsìn ti kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn pé Màríà ni alágbàwí èèyàn lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Irú èèyàn wo lo rò pé ìyá Jésù jẹ́? Pàtàkì ibẹ̀ sì ni pé, irú èèyàn wo ló jẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run?

Ojúṣe Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀

Ọmọ ẹ̀yà Júdà ti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni Màríà, ọmọbìnrin Hélì. Ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n dárúkọ ẹ̀ nínú Bíbélì jẹ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ju agbára ẹ̀dá èèyàn lọ. Áńgẹ́lì kan ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Kú déédéé ìwòyí o, ẹni tí a ṣe ojú rere sí lọ́nà gíga, Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.” Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ò kọ́kọ́ yé Màríà, “ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí irú ìkíni tí èyí lè jẹ́.” Ìgbà yẹn ni áńgẹ́lì náà wá sọ fún un pé Jèhófà ti yàn án fún iṣẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó sì ṣe pàtàkì kan, ìyẹn ti dídi ìyá fún Ọmọ Ọlọ́run.—Lúùkù 1:26-33.

Ẹ ò rí i pé ojúṣe tóbìnrin tí ò tíì lọ́kọ yìí máa bójú tó ṣe pàtàkì gan-an! Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀? Màríà lè ti máa ronú pé ta ló máa gba òun gbọ́. Ṣé oyún yìí ò ní jẹ́ kí Jósẹ́fù, àfẹ́sọ́nà ẹ̀ já a sílẹ̀ báyìí? Ṣé oyún ẹ̀sín kọ́ ló fẹ́ ní yìí? (Diutarónómì 22:20-24) Àmọ́, kò kọ̀ láti gba ojúṣe pàtàkì náà.

Ìgbàgbọ́ tó lágbára tí Màríà ní ló jẹ́ kó gbà láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run tó ń jọ́sìn. Ó dá a lójú pé Jèhófà ò ní fi òun sílẹ̀. Ìdánilójú tó ní yìí ló jẹ́ kó lè sọ pé: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà! Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ.” Torí pé Màríà fọwọ́ pàtàkì mú àǹfààní tẹ̀mí tí Jèhófà fún un yìí, ó ṣe tán láti fara da àwọn ipò lílekoko tó ń bọ̀ wá dojú kọ.—Lúùkù 1:38.

Nígbà tí Màríà sọ fún Jósẹ́fù pé òun ti lóyún, ńṣe ni Jósẹ́fù fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àkókò ìbànújẹ́ lèyí máa jẹ́ fáwọn méjèèjì. Bíbélì ò sọ bí àkókò tí wọ́n fi ń fa ọ̀rọ̀ yìí ṣe gùn tó. Àmọ́, ó dájú pé ọkàn Màríà àti Jósẹ́fù ti máa balẹ̀ gan-an nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà fara han Jósẹ́fù. Áńgẹ́lì náà ṣàlàyé fún Jósẹ́fù pé oyún tí Màríà ní kọjá òye ẹ̀dá, ó sì sọ fún un pé kó mú ìyàwó ẹ̀ lọ sílé.—Mátíù 1:19-24.

Àkókò Lílekoko

Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn aláboyún ló máa ń múra sílẹ̀ de ọmọ tuntun jòjòló tí wọ́n ń retí, ohun tó sì ṣeé ṣe kí Màríà náà ti ṣe nìyẹn. Oyún àkọ́bí ló wà nínú ẹ̀ yìí. Síbẹ̀, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọn ò retí da gbogbo ètò tó ti ṣe sílẹ̀ rú. Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pàṣẹ pé kí gbogbo èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀ ní ìlú ìbílẹ̀ wọn. Torí náà Jósẹ́fù àti Màríà ìyàwó ẹ̀ tó lóyún oṣù mẹ́sàn-án sínú ní láti rírìn àjò tó tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kan àti àádọ́ta [150] kìlómítà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni wọ́n gùn lọ! Èrò ti pọ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ibì kan tó dákẹ́ rọ́rọ́ ló sì yẹ kí Màríà bímọ sí, àmọ́ ilé ẹran nìkan làyè wà. Kò lè rọrùn fún Màríà láti bímọ sílé ẹran. Ẹ̀rù lè máa bà á, kójú sì máa tì í.

Lákòókò tó le koko nígbèésí ayé Màríà yìí, ó dájú pé ó ti ní láti sọ ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ fún Jèhófà, kó sì nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa bójú tó òun àti ọmọ òun. Nígbà tó yá, àwọn olùṣọ́ àgùntàn kan wá kí i, wọ́n sì ń hára gàgà láti rí ọmọ jòjòló náà. Wọ́n sọ pé àwọn gbọ́ táwọn áńgẹ́lì pe ọmọ náà ní “Olùgbàlà kan . . . , ẹni tí í ṣe Kristi Olúwa.” Ìwé Mímọ́ sì sọ pé: “Màríà bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àsọjáde wọ̀nyí mọ́, ní dídé ìparí èrò nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” Ó ronú lórí ọ̀rọ̀ táwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyẹn sọ, ìyẹn sì fún un lókun.— Lúùkù 2:11, 16-19.

Àwa ńkọ́? Àwa náà lè jìyà láyé tá a wà yìí. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” lè dé bá ẹnikẹ́ni nínú wa, ìyẹn sì lè jẹ́ ká dojú kọ onírúurú ìṣòro àti ìpọ́njú. (Oníwàásù 9:11) Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa, ṣé a ò ní bínú ká sì máa wá sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run? Ẹ ò rí i pé ó máa dáa ká fara wé Màríà, ká sún mọ́ Ọlọ́run nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa ronú lórí àwọn nǹkan tá à ń kọ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé kò ní ṣòro fún wa láti fara da àdánwò.

Akúṣẹ̀ẹ́ àti Àtìpó Ni

Màríà tún dojú kọ àwọn ipò lílekoko míì, irú bí àìlówó lọ́wọ́ àti sísá kúrò nílùú tó ń gbé láìrò tẹ́lẹ̀. Ṣó o ti dojú kọ irú ìṣòro yìí rí? Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan ṣe sọ, “ìdajì àwọn tó wà láyé, ìyẹn nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn, ló jẹ́ pé owó tí wọ́n ń rí ná lójúmọ́ ò tó dọ́là méjì,” ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ̀rọ̀ àtijẹ àtimu ò sì rọrùn fún bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tó jọ pé nǹkan ṣẹnuure fún ni wọ́n ń gbé. Ìwọ ńkọ́? Ṣé wàhálà tó wà nídìí pípèsè oúnjẹ, aṣọ, àti ilé fún ìdílé ẹ kì í jẹ́ kó rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu tàbí kó tiẹ̀ mú kí nǹkan tojú sú ẹ nígbà míì?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ ni Jósẹ́fù àti Màríà. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Lára àwọn ẹ̀rí díẹ̀ tá a rí nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù jẹ́ ká mọ̀ pé ogójì ọjọ́ lẹ́yìn tí Màríà bímọ, òun àti Jósẹ́fù lọ sí tẹ́ńpìlì láti lọ rúbọ bí òfin ṣe sọ, “oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì” ni wọ́n sì mú dání. a (Lúùkù 2:22-24) Àwọn tó bá kúṣẹ̀ẹ́ débi pé wọn ò lè rówó ra ọmọ àgùntàn nìkan ni wọ́n máa ń gbà láyè láti firú nǹkan tí wọ́n mú wá yìí rúbọ. Torí náà, ọ̀ràn àtijẹ àtimu ò rọrùn fún Jósẹ́fù àti Màríà. Síbẹ̀, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí ìfẹ́ gbilẹ̀ nínú ìdílé wọn. Kò sì sí àníàní pé ọ̀rọ̀ nípa ìjọsìn Ọlọ́run ló jẹ wọ́n lógún jù lọ.—Diutarónómì 6:6, 7.

Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Màríà bí Jésù tán ní nǹkan tún yí pa dà bírí. Áńgẹ́lì kan sọ fún Jósẹ́fù pé kí òun àti ìdílé ẹ̀ sá lọ sí Íjíbítì. (Mátíù 2:13-15) Ẹ̀ẹ̀kejì rèé tí Màríà máa fi àdúgbò tó ti mọ̀ dáadáa sílẹ̀, àmọ́ ní báyìí orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀ pátápátá ló ń lọ. Àwọn Júù pọ̀ gan-an ní Íjíbítì, torí náà ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àárín wọn ni Màríà àti Jósẹ́fù máa gbé. Síbẹ̀ náà, kì í rọrùn láti gbé lórílẹ̀-èdè àjèjì, ó sì lè mú kí nǹkan tojú súùyàn. Ṣé ìwọ àti ìdílé ẹ wà lára ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ti fi orílẹ̀-èdè wọn sílẹ̀, bóyá nítorí pé wọn ń wá ibi tó máa ṣàwọn ọmọ wọn láǹfààní tàbí tí wọ́n sá nítorí ẹ̀mí wọn? Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá mọ díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kí Màríà dojú kọ ní Íjíbítì.

Ìyàwó àti Ìyá Tó Mọṣẹ́ Ẹ̀ Níṣẹ́

Yàtọ̀ sí ìtàn nípa bí Màríà ṣe bí Jésù àti bó ṣe tọ́ ọ dàgbà nígbà tó wà ní ìkókó, àwọn ìwé Ìhìn Rere ò tún fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Màríà. Síbẹ̀, a mọ̀ pé Màríà àti Jósẹ́fù bí àwọn ọmọ mẹ́fà yàtọ̀ sí Jésù. Èyí lè yà ẹ́ lẹ́nu. Àmọ́, gbọ́ ohun táwọn ìwé Ìhìn Rere sọ.

Jósẹ́fù máa ń fọ̀wọ̀ wọ Màríà nítorí àǹfààní tó ní láti bí Ọmọ Ọlọ́run. Ìyẹn ni ò jẹ́ kó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ títí tó fi bí Jésù. Ìwé Mátíù 1:25 sọ pé Jósẹ́fù “kò bá [Màríà] dàpọ̀ títí ó fi bí ọmọkùnrin kan.” Ọ̀rọ̀ náà “títí” tó wà nínú ẹsẹ yìí jẹ́ kó yé wa pé lẹ́yìn tí Màríà ti bí Jésù tán, Jósẹ́fù àti Màríà ní ìbálòpọ̀ bó ṣe máa ń wà láàárín àwọn lọ́kọláya. Ìwé Ìhìn Rere náà sọ pé lẹ́yìn-ò-rẹyìn Màríà bímọ fún Jósẹ́fù, ó bí ọkùnrin ó sì bí obìnrin. Ìdí nìyẹn tí Jákọ́bù, Jósẹ́fù, Símónì àti Júdásì fi jẹ́ iyèkan Jésù. Ó kéré tán Màríà tún bí ọmọbìnrin méjì. (Mátíù 13:55, 56) Àmọ́, bí gbogbo obìnrin ṣe ń lóyún ló ṣe lóyún àwọn ọmọ wọ̀nyí. b

Màríà nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin ò sọ pé káwọn obìnrin máa lọ síbi àjọyọ̀ Ìrékọjá, ó ti mọ́ Màríà lára láti máa bá Jósẹ́fù rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù fún àjọyọ̀ náà lọ́dọọdún. (Lúùkù 2:41) Ní tàlọ tàbọ̀, wọ́n á ní láti rin nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] kìlómítà, pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn! Àmọ́, ó dájú pé tẹ̀rín tọ̀yàyà ni wọ́n á fi máa rìn lọ síbi àjọyọ̀ yìí.

Ọ̀pọ̀ obìnrin ló ń fara wé àpẹẹrẹ rere Màríà lónìí. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára, wọ́n sì fi àwọn nǹkan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí du ara wọn kí wọ́n lè bójú tó àwọn ojúṣe tí Ìwé Mímọ́ gbé lé wọn lọ́wọ́. Àìmọye ìgbà làwọn obìnrin lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ wọ̀nyí máa ń fi hàn pé onísùúrù èèyàn àti onírẹ̀lẹ̀ làwọn, tí wọ́n sì máa ń fara da ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan! Bí wọ́n ṣe ń ronú lórí àpẹẹrẹ Màríà ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa fàwọn nǹkan tó bá jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú ìgbádùn tara wọn. Bíi ti Màríà, wọ́n mọ̀ pé jíjọ́sìn Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ọkọ àtàwọn ọmọ àwọn máa jẹ́ kí ìdílé àwọn wà níṣọ̀kan, kí ìfẹ́ sì jọba láàárín àwọn.

Lọ́jọ́ kan, nígbà tí Màríà àti Jósẹ́fù ń pa dà lọ sílé láti ibi tí wọ́n ti lọ ṣàjọyọ̀ ní Jerúsálẹ́mù, bóyá pẹ̀lú àwọn àbúrò Jésù, wọ́n rí i pé Jésù ò sí láàárín àwọn. Ṣó o mọ bára Màríà á ṣe máa gbóná tó fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta tó fi ń wá ọmọ ẹ̀? Nígbà tóun àti Jósẹ́fù jàjà rí Jésù nínú tẹ́ńpìlì, Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?” Ìwé Mímọ́ sọ pé bíi tàtẹ̀yìnwá, ńṣe ni Màríà “rọra pa gbogbo àsọjáde wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” Ẹ̀rí míì tún nìyẹn pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan ló jẹ Màríà lógún jù lọ. Ó máa ń fara balẹ̀ láti ronú lórí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí Jésù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí àtàwọn nǹkan míì fáwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹlẹ̀.—Lúùkù 2:41-52.

Ó Fara Da Ìjìyà àti Ikú Olólùfẹ́

Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù, alágbàtọ́ Jésù? Ibi tí Jósẹ́fù àti Màríà ti ń wá Jésù nígbà tí wọ́n lọ síbi àjọyọ̀ Ìrékọjá làwọn ìwé Ìhìn Rere ti dárúkọ Jósẹ́fù gbẹ̀yìn. Àwọn kan gbà pé torí pé Jósẹ́fù ti kú kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni Ìwé Mímọ́ ò ṣe dárúkọ ẹ̀ mọ́. c Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ó dà bíi pé opó ni Màríà nígbà tí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé. Nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù kú, ó fa ìyá rẹ̀ lé àpọ́sítélì Jòhánù lọ́wọ́. (Jòhánù 19:26, 27) Ó ṣeé ṣe kí Jésù má ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé Jósẹ́fù ṣì wà láàyè.

Ojú Jósẹ́fù àti Màríà rí nǹkan lákòókò tí wọ́n fi wà pa pọ̀! Àwọn áńgẹ́lì bẹ̀ wọ́n wò, wọ́n sá fún oníjàgídíjàgan èèyàn kan, wọ́n fìlú sílẹ̀ láìmọye ìgbà, wọ́n sì gbọ́ bùkátà ìdílé eléèyàn púpọ̀. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni wọ́n á ti fi sọ̀rọ̀ nípa Jésù lẹ́yìn tí wọ́n bá dé láti ibi iṣẹ́ nírọ̀lẹ́, tí wọ́n á máa ronú lórí àwọn nǹkan tó máa dojú kọ lọ́jọ́ iwájú, tí wọ́n á sì máa rò ó bóyá àwọn ń tọ́ ọ sọ́nà tó tọ́ táwọn sì ń múra rẹ̀ sílẹ̀ fóhun tó yẹ. Àmọ́ kí Màríà tó ṣẹ́jú pẹ́, Jósẹ́fù kú, ó sì dá a dá gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí.

Ṣé ọkọ tàbí ìyàwó tìẹ náà ti kú? Ṣé ẹ̀dùn ọkàn yẹn ṣì ń dà ẹ́ láàmú tí àárò rẹ̀ sì máa ń sọ ẹ́, kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún? Kò sí àní-àní pé ìgbàgbọ́ Màríà tù ú nínú, ìmọ̀ tó sì ní pé Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde jẹ́ kó nírètí tó dájú. d (Jòhánù 5:28, 29) Síbẹ̀, gbogbo àwọn èrò tó ń tuni nínú wọ̀nyẹn ò tán àwọn ìṣòro Màríà. Bíi tàwọn ìyá tó ń dá tọ́mọ lónìí, Màríà náà níṣòro títọ́ àwọn ọmọ láìsí ìrànlọ́wọ́ ọkọ.

Ó bọ́gbọ́n mu láti ronú pé lẹ́yìn tí Jósẹ́fù kú Jésù ló gbaṣẹ́ gbígbọ́ bùkátà ìdílé. Àmọ́, báwọn àbúrò Jésù ṣe ń dàgbà, àwọn náà dẹni tó tójú bọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ipa tiwọn láti bójú tó ìdílé. Nígbà tí Jésù tó “nǹkan bí [ọmọ] ọgbọ̀n ọdún,” ó filé sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní pẹrẹu. (Lúùkù 3:23) Ọ̀pọ̀ òbí ni kì í lè ṣàlàyé bó ṣe máa ń rí lára wọn nígbà tọ́mọ wọn ọkùnrin tàbí obìnrin tó ti tójú bọ́ bá filé sílẹ̀. Àkókò, ìsapá àti ìfẹ́ òbí sọ́mọ táwọn òbí fi tọ́ àwọn ọmọ dàgbà máa ń pọ̀ débi pé àárò àwọn ọmọ wọn máa ń sọ wọ́n gan-an lẹ́yìn táwọn ọmọ wọ̀nyẹn bá filé sílẹ̀. Ṣé ọmọ ẹ ọkùnrin tàbí obìnrin ti filé sílẹ̀ kọ́wọ́ rẹ̀ lè tẹ àwọn àfojúsùn rẹ̀? Ṣó o máa ń fi wọ́n yangàn lẹ́sẹ̀ kan náà kó o sì tún máa ronú pé kò yẹ kí wọ́n jìnnà sí ẹ? Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o lè mọ bó ṣe rí lára Màríà nígbà tí Jésù filé sílẹ̀.

Àwọn Ìṣòro Tí Kò Ronú Kàn

Ìṣòro míì tí Màríà dojú kọ yà á lẹ́nu gan-an torí kò ronú pé ó lè ṣẹlẹ̀. Bí Jésù ṣe ń wàásù tọ́pọ̀ èèyàn sì ń tẹ̀ lé e, àwọn àbúrò ẹ̀ ò fara mọ́ ohun tó ń wàásù. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ní ti tòótọ́, àwọn arákùnrin rẹ̀ kì í lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.” (Jòhánù 7:5) Kò sí àníàní pé Màríà ti máa ṣàlàyé ohun tí áńgẹ́lì yẹn sọ fún wọn, pé “Ọmọ Ọlọ́run” ni Jésù. (Lúùkù 1:35) Síbẹ̀, ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin lásán ni Jákọ́bù, Jósẹ́fù, Símónì àti Júdásì ka Jésù sí. Bí Màríà ṣe bára ẹ̀ nínú ìdílé tí ò ṣọ̀kan lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn nìyẹn.

Ṣé Màríà jẹ́ kọ́rọ̀ náà tojú sú òun, kó sì wá jáwọ́ lọ́rọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀? Rárá, kò ṣe bẹ́ẹ̀! Nígbà tí Jésù ń wàásù ní Gálílì lọ́jọ́ kan, ó lọ jẹun nínú ilé kan, ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn sì pé jọ láti fetí sọ́rọ̀ ẹ̀. Àwọn kan wà níta tí wọ́n ń wá Jésù. Àwọn wo lo rò pé wọ́n máa jẹ́? Màríà àtàwọn àbúrò Jésù ni. Èyí fi hàn pé nígbà tí Jésù ti sún mọ́ ìtòsí ilé, Màríà wá Jésù lọ, ẹ̀rí sì fi hàn pé ó mú àwọn àbúrò Jésù dání, bóyá wọ́n á yí èrò wọn pa dà tí wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.—Mátíù 12:46, 47.

Ìwọ náà lè ti máa gbìyànjú láti tẹ̀ lé Jésù àmọ́ káwọn mọ̀lẹ́bí ẹ máà fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Má ṣe jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ, má sì jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú ẹ! Bíi ti Màríà, ọ̀pọ̀ ló ti ní sùúrù fún ọ̀pọ̀ ọdún bí wọ́n ti ń gbìyànjú láti yí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn lérò pa dà kí wọ́n tó wá rí ìyípadà tó lápẹẹrẹ nígbèésí ayé àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Yálà wọ́n yí pa dà tàbí wọn ò yí pa dà, irú sùúrù bẹ́ẹ̀ ṣeyebíye lójú Ọlọ́run.—1 Pétérù 3:1, 2.

Ìṣòro Tó Le Jù

Kò sí àní-àní pé ìṣòro tó kẹ́yìn tí Ìwé Mímọ́ sọ pé Màríà ní ló bà á lọ́kàn jẹ́ jù. Ojú ara ẹ̀ ló fi ń wo ọmọ ẹ̀ tó kú ikú oró lẹ́yìn táwọn èèyàn ẹ̀ kọ̀ ọ́. Àwọn èèyàn ti ṣàpèjúwe ikú ọmọ bí “àdánù ńlá” tàbí “ikú tó ń dáni lóró jù lọ,” ọmọ náà ì báà kéré lọ́jọ́ orí tàbí kó ti dàgbà. Asọtẹ́lẹ̀ Síméónì arúgbó tí wọ́n pàdé ní tẹ́ńpìlì lọ́pọ̀ ẹ̀wádún sẹ́yìn ṣẹ sí Màríà lára, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n fi idà gún un lọ́kàn!—Lúùkù 2:34, 35.

Ṣé Màríà jẹ́ kí ìṣòro tó kẹ́yìn yìí ba òun lọ́kàn jẹ́ ju bó ti yẹ lọ tàbí kó sọ ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà di akúrẹtẹ̀? Rárá o. Ìgbà tí Bíbélì tún máa dárúkọ Màríà, àárín àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ló wà, tí gbogbo wọn jùmọ̀ ń “tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà.” Kò sì dá wà, torí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, tó ti wá bẹ̀rẹ̀ sí í nígbàgbọ́ nínú ẹ̀gbọ́n wọn báyìí, wà pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ ò rí bíyẹn ṣe máa tu Màríà nínú tó! eÌṣe 1:14.

Màríà gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ tó sì tẹ́ni lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí obìnrin tó fi tọkàntara sin Ọlọ́run, ìyàwó tó bọ̀wọ̀ fọ́kọ àti ìyá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀. Ó láwọn ìrírí tó ṣe é láǹfààní nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run. Ó borí ọ̀pọ̀ àdánwò àtàwọn ìṣòro. Nígbà tá a bá ń dojú kọ àwọn ìṣòro kan tá ò ronú kàn tàbí táwọn ìṣòro ìdílé ò fi wá lọ́kàn balẹ̀, ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ látara Màríà tó fòótọ́ inú fara da àwọn nǹkan wọ̀nyí.—Hébérù 10:36.

Kí la wá lè sọ nípa yíyá àwòrán Màríà láti máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀? Ṣáwọn ẹsẹ Bíbélì tó jẹ́ ká mọ ipa tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Màríà kó tó ìdí fún wa láti máa jọ́sìn rẹ̀?

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wọ́n fi ọ̀kan lára àwọn ẹyẹ wọ̀nyẹn ṣe ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. (Léfítíkù 12:6, 8) Bí Màríà sì ṣe rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé, ó gbà pé bíi ti gbogbo èèyàn aláìpé tó kù, òun náà ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àtàwọn nǹkan tí ẹ̀ṣẹ̀ ń fà látọ̀dọ̀ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́.— Róòmù 5:12.

b Wo àpótí tá a pe àkọlé ẹ̀ ní  “Ṣé Jésù Láwọn Àbúrò?”

c Àwọn èèyàn ti kíyè sí pé ó nídìí táwọn ìwé Ìhìn Rere ò fi dárúkọ Jósẹ́fù rárá nínú àkọsílẹ̀ tí wọ́n ṣe nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, torí pé wọ́n dárúkọ ìyá ẹ̀, wọ́n dárúkọ àwọn àbúrò ẹ̀ lọ́kùnrin, wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn àbúrò ẹ̀ obìnrin. Bí àpẹẹrẹ, níbi ìgbéyàwó tó wáyé ní Kánà, ẹ̀rí wà pé ńṣe ni Màríà ń forí ṣe fọrùn ṣe níbi ìnáwó náà, àmọ́ àkọsílẹ̀ náà ò sọ̀rọ̀ nípa Jósẹ́fù rárá. (Jòhánù 2:1-11) Lásìkò tó yàtọ̀ séyìí, a kà pé “ọmọkùnrin Màríà” làwọn aráàlú Jésù ń pè é, wọn ò pè é ní ọmọkùnrin Jósẹ́fù.—Máàkù 6:3.

d Fún àlàyé síwájú sí i nípa ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa àjíǹde, wo orí 7 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

e Wo àpótí tá a pe àkọlé ẹ̀ ní  “Kò Bẹ̀rù Láti Yí Pa Dà,” lójú ìwé 7.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

 Ṣé Jésù Láwọn Àbúrò?

Bẹ́ẹ̀ ni, ó ní. Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan ti sọ pé àwọn ò gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn Ìwé Ìhìn Rere mẹ́nu kan òótọ́ tí ò ṣeé já ní koro náà. (Mátíù 12:46, 47; 13:54-56; Máàkù 6:3) Àmọ́, àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ti sọ nǹkan méjì tó gbàfiyèsí nípa ohun táwọn kan ń sọ, pé Màríà ò bímọ lé Jésù. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé wọn fẹ́ káwọn èèyàn nígbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ ìsìn tí ṣọ́ọ̀ṣì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé lárugẹ nígbà tó yá, ìyẹn ni pé Màríà ò mọ ọkùnrin títí tó fi kú. Ìdí kejì sì ni pé èrò yẹn ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, torí kò sí ẹ̀rí tí wọ́n lè fi tì í lẹ́yìn.

Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn ohun tí wọ́n sọ jẹ́ kó dà bíi pé àwọn ọmọkùnrin tí obìnrin míì ti bí fún Jósẹ́fù kó tó fẹ́ Màríà ni Bíbélì pè ní “àwọn arákùnrin [Jésù].” Ohun tí wọ́n sọ yìí ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, torí ńṣe ló máa fi hàn pé lábẹ́ òfin, Jésù ò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ àkọ́bí tó ní ọlá àṣẹ láti jọba ní ìlà ìdílé Dáfídì.—2 Sámúẹ́lì 7:12, 13.

Àwọn kan tún sọ pé ìbátan làwọn ọkùnrin wọ̀nyí jẹ́ sí Jésù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ń kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “arákùnrin,” “ìbátan” àti “mọ̀lẹ́bí” ò dọ́gba. Èyí ló wá jẹ́ kí ọ̀mọ̀wé Frank E. Gaebelein parí èrò sí pé ọ̀rọ̀ òfìfo lásán lohun táwọn onísìn wọ̀nyẹn sọ. Ó ní: “Ọ̀nà tó nítumọ̀ jù lọ téèyàn lè gbà lóye ọ̀rọ̀ náà ‘àwọn arákùnrin’ ni pé àwọn ọmọkùnrin tí Màríà bí fún Jósẹ́fù ni wọ́n pè bẹ́ẹ̀, tọ́ràn bá sì rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àwọn àbúrò Jésù tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ ìyá kan náà là ń sọ̀rọ̀ nípa wọn.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

 Kò Bẹ̀rù Láti Yí Ẹ̀sìn Rẹ̀ Pa Dà

Júù làwọn òbí Màríà, ìsìn àwọn Júù ló sì ń ṣe. Ó máa ń lọ sí sínágọ́gù tó wà ládùúgbò ẹ̀, ìyẹn ibi táwọn Júù ti máa ń jọ́sìn Ọlọ́run, ó sì máa ń lọ sí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, bí ìmọ̀ tí Màríà ní nípa ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń pọ̀ sí i, ó wá rí i pé Ọlọ́run ò tẹ́wọ́ gba àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba ńlá òun mọ́. Àwọn olórí nínú ìsìn àwọn Júù ló pa ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ Mèsáyà. Kíyẹn tó ṣẹlẹ̀, Jésù ti sọ fún wọn pé: “Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Mátíù 23:38) Ọlọ́run fawọ́ ìbùkún ẹ̀ kúrò nínú ìjọsìn tí wọ́n ti tọ́ Màríà dàgbà.—Gálátíà 2:15, 16.

Ó ṣeé ṣe kí Màríà ti tó ọmọ àádọ́ta [50] ọdún nígbà tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Kí ló máa ṣe báyìí? Ṣó ronú pé inú ìsìn àwọn Júù ni wọ́n bí òun sí, torí náà ó yẹ kóun jólóòótọ́ sí àṣà àwọn baba ńlá òun? Àbí ńṣe ló sọ pé òun ti dàgbà jù láti yí ẹ̀sìn òun pa dà? Kò ṣe bẹ́ẹ̀ rárá! Màríà mọ̀ pé orí ìjọ Kristẹni ni ìbùkún Ọlọ́run wà báyìí, torí náà ó nígbàgbọ́ tó lágbára, kò sì bẹ̀rù láti yí ẹ̀sìn rẹ̀ pa dà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Wọ́n sá lọ sí Íjíbítì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àdánù tó ga jù lọ tó lè bá ìyá kan rèé