Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó O Máa Ń Bẹ̀rù Àwọn Òkú?

Ṣó O Máa Ń Bẹ̀rù Àwọn Òkú?

Ṣó O Máa Ń Bẹ̀rù Àwọn Òkú?

TỌ́PỌ̀ èèyàn bá máa dáhùn ìbéèrè yìí, ohun tí wọ́n máa sọ ni pé, “Rárá o. Kí ni mo fẹ́ máa bẹ̀rù òkú fún?” Wọ́n gbà pé ẹni tó bá ti kú ti kú nìyẹn. Àmọ́, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló gbà pé ẹ̀mí àwọn òkú ṣì ń gbé níbì kan.

Lórílẹ̀-èdè Benin, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ọ̀pọ̀ ló gbà gbọ́ pé àwọn òkú lè pa dà wá láti pa àwọn mọ̀lẹ́bí tó kù. Àwọn èèyàn máa ń ta àwọn nǹkan ìní wọn tàbí kí wọ́n jẹ gbèsè kí wọ́n lè rówó ra ẹran tí wọ́n máa fi ṣètùtù, kí wọ́n sì lè ṣayẹyẹ láti tu mọ̀lẹ́bí wọn tó ti kú lójú. Àwọn kan máa ń bá ẹ̀mí lò, èyí sì kan èrò náà pé ẹ̀mí kan wà nínú èèyàn tó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn téèyàn bá ti kú tá á sì máa báwọn alààyè sọ̀rọ̀. Àwọn nǹkan tó ń dẹ́rù bani ti ṣẹlẹ̀ sáwọn míì, tí wọ́n sì gbà pé ẹ̀mí àwọn òkú ló ń jẹ àwọn níyà.

Ọ̀kan lára àwọn tírú nǹkan tá à ń sọ yìí ti ṣẹlẹ̀ sí ni ọkùnrin kan tó ń gbé nítòsí ẹnubodè tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Benin, Agboọlá lorúkọ ẹ̀. Ó sọ pé: “Ńṣe là ń fi ìbẹ́mìílò ṣomi mu lágbègbè wa. Àṣà ilẹ̀ wa ni láti máa wẹ̀ fáwọn òkú lọ́nà àṣeyẹ ká lè múra wọn sílẹ̀ láti lọ sí ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí. Mo sábà máa ń ṣa àwọn èyí tó bá ṣẹ́ kù nínú àwọn ọṣẹ táwọn èèyàn bá fi wẹ òkú, màá sì wá gún un mọ́ àwọn ewé kan. Bí mo bá ṣe ń fi àdàpọ̀ ọṣẹ àtàwọn ewé yìí pa ìbọn ṣakabùlà tí mo máa ń gbé lọ sóko ọdẹ ni mo máa ń pe àyájọ́ tí mo sì máa dárúkọ irú ẹran tí mo bá fẹ́ pa lóko ọdẹ tí mò ń lọ. Irú àṣà yìí wọ́pọ̀ lágbègbè wa, ó sì máa ń dà bíi pé ó ń jẹ́ wa lọ́wọ́. Àmọ́, àwọn oríṣi ìbẹ́mìílò kan wà tó ń dẹ́rù bani.

“Nígbà táwọn ọmọkùnrin mi méjì fò ṣánlẹ̀ tí wọ́n sì kú lọ́sàn kan òru kan, mo fura pé ẹnì kan ló ń sà sí mi. Kí n lè mọ ẹni tó ń ṣe mí, mo lọ bá bàbá kan tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ pó gbówọ́ nínú iṣẹ́ babaláwo, òun ló sì wá sọ ibi tíná ti ń jó mi lábẹ́ aṣọ. Ohun tó wá burú jù ńbẹ̀ ni pé, bàbá yìí ṣàlàyé fún mi pé àwọn ọmọ mi méjèèjì wà ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí báyìí, tí wọ́n ń dúró de ìgbà tẹ́ni tó pa wọ́n máa kú kí wọ́n lè máa ṣẹrú fún un. Bàbá yẹn tún sọ pé ohun tó máa pàpà ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin mi kẹta náà nìyẹn. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà ni ọmọkùnrin mi kẹta fò ṣánlẹ̀ tóun náà sì kú.”

Ìgbà tó yá, Agboọlá pàdé John, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Inú Bíbélì ni John ti mú gbogbo àlàyé tó ṣe nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. Àlàyé yẹn ló yí ìgbésí ayé Agboọlá pa dà. Ó lè yí ìgbésí ayé tìẹ náà pa dà.

Ṣáwọn Òkú Wà Láàyè?

Ta ló lè dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó dáa jù lọ? Kò séèyàn tó lè dáhùn rẹ̀ bó ti wù kónítọ̀hún gbówọ́ tó nínú iṣẹ́ ìbẹ́mìílò. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà, Ẹlẹ́dàá gbogbo ohun abẹ̀mí tó wà “ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí,” ló lè dáhùn ẹ̀. (Kólósè 1:16) Ó dá àwọn áńgẹ́lì láti máa gbé ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí, ó sì dá àwa èèyàn àtàwọn ẹranko láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 104:4, 23, 24) Ọwọ́ rẹ̀ ni ìwàláàyè níbi gbogbo wà. (Ìṣípayá 4:11) Ní báyìí, gbé ohun tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa àwọn òkú yẹ̀ wò.

Jèhófà ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ikú. Ó kìlọ̀ fún Ádámù àti Éfà pé wọ́n máa kú tí wọ́n bá ṣàìgbọràn sóun. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Jèhófà ṣàlàyé pé: “Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru [tàbí iyẹ̀pẹ̀].” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Nígbà téèyàn bá kú, ara ẹ̀ máa jẹrà, ó sì máa pa dà di iyẹ̀pẹ̀. Ìgbésí ayé onítọ̀hún pin nìyẹn.

Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn, Ọlọ́run sì dájọ́ ikú fún wọn. Àmọ́, àwọn kọ́ ló kọ́kọ́ kú. Ébẹ́lì, ọmọkùnrin wọn ti kú ṣáájú wọn. Kéènì, ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ọkùnrin ló pa á. (Jẹ́nẹ́sísì 4:8) Kéènì ò bẹ̀rù pé àbúrò òun tó ti kú lè fẹ́ gbẹ̀san lára òun. Àmọ́, ẹ̀rù àwọn tó ṣì wà láàyè ló ń ba Kéènì, torí kò mọ ohun tí wọ́n lè ṣe fóun.—Jẹ́nẹ́sísì 4:10-16.

Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, inú bí Hẹ́rọ́dù Ọba gan-an nígbà táwọn awòràwọ̀ sọ fún un pé wọ́n ti bí “ọba àwọn Júù” lágbègbè tó ń ṣàkóso. Hẹ́rọ́dù pinnu láti ṣe gbogbo nǹkan tó bá gbà kó lè rẹ́yìn ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ bá a dupò, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin láti ọmọ ọdún méjì sísàlẹ̀. Àmọ́, áńgẹ́lì kan kìlọ̀ fún Jósẹ́fù pé kó mú Jésù àti Màríà, kí wọ́n sì “sá lọ sí Íjíbítì.”—Mátíù 2:1-16.

Nígbà tí Hẹ́rọ́dù kú, áńgẹ́lì náà sọ fún Jósẹ́fù pé kí wọ́n pa dà sí Ísírẹ́lì, “nítorí àwọn tí wọ́n ń wá ọkàn ọmọ kékeré náà ti kú.” (Mátíù 2:19, 20) Áńgẹ́lì náà, tó jẹ́ ẹni ẹ̀mí, mọ̀ pé Hẹ́rọ́dù ò lè ṣe Jésù ní nǹkan kan mọ́. Jósẹ́fù ò bẹ̀rù Hẹ́rọ́dù Ọba mọ́ torí ó ti kú. Àmọ́, Jósẹ́fù ń bẹ̀rù ohun tí Ákíláọ́sì, ọmọ ẹhànnà tí Hẹ́rọ́dù bí, lè ṣe. Ìdí nìyẹn tí Jósẹ́fù àti ìdílé ẹ̀ ṣe fara ṣoko sí Gálílì, torí ìjọba Ákíláọ́sì ò débẹ̀.—Mátíù 2:22.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ ká rí i pé àwọn òkú ò lágbára kankan. Kí la wá lè sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Agboọlá àtàwọn míì?

“Àwọn Ẹ̀mí Èṣù” Tàbí Àwọn Ẹ̀mí Àìmọ́

Nígbà tí Jésù dàgbà, ó báwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú pàdé. Wọ́n dá Jésù mọ̀, wọ́n sì pè é ní “Ọmọ Ọlọ́run.” Jésù náà sì mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́. Wọn kì í ṣe ẹ̀mí àwọn èèyàn tó ti kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù mọ̀ pé “ẹ̀mí èṣù” tàbí ẹ̀mí àìmọ́ ni wọ́n.—Mátíù 8:29-31; 10:8; Máàkù 5:8.

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jólóòótọ́ sí Ọlọ́run, ó sì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó ṣọ̀tẹ̀ sí i. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé nígbà tí Jèhófà lé Ádámù àti Éfà kúrò lọ́gbà Édẹ́nì, ó fàwọn kérúbù, tàbí àwọn áńgẹ́lì sí ìlà oòrùn ọgbà náà kẹ́nikẹ́ni má bàa wọbẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:24) Ó ṣe kedere pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn táwọn èèyàn máa ráwọn ẹ̀dá ẹ̀mí.

Kò pẹ́ sákòókò yẹn làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí kan wá sórílẹ̀ ayé tí wọ́n sì gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀. Jèhófà kọ́ ló rán wọn lóhun tí wọ́n wá ṣe láyé lásìkò yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n “ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” ní ibùgbé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, sílẹ̀. (Júúdà 6) Ìmọtara-ẹni-nìkan ló gbé wọn wá sáyé. Wọ́n gbé àwọn obìnrin níyàwó, wọ́n sì bí àwọn ọmọ abàmì táwọn èèyàn ń pè ní Néfílímù. Àwọn Néfílímù àtàwọn bàbá wọn tó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run fi ìwà ipá kún ilẹ̀ ayé wọ́n sì hu àwọn ìwà ibi míì lọ́nà tó bùáyà. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-5) Jèhófà yanjú ìṣòro yẹn nípa mímú kí òjò kan tó fa Àkúnya Omi rọ̀ kárí ayé nígbà ayé Nóà. Àkúnya omi yẹn ló pa àwọn aṣebi wọ̀nyẹn run lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó sì gbá àwọn Néfílímù wọ̀nyẹn lọ pẹ̀lú wọn. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn áńgẹ́lì wọ̀nyẹn?

Nígbà tí Àkúnya Omi yẹn bo ayé, wọ́n gbéra láti pa dà sí ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí lọ́run. Àmọ́, Jèhófà ò gbà wọ́n láyè láti pa dà sí “ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀.” (Júúdà 6) Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kò . . . fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ àwọn áńgẹ́lì tí ó ṣẹ̀, ṣùgbọ́n, nípa sísọ wọ́n sínú Tátárọ́sì, ó jù wọ́n sínú àwọn kòtò òkùnkùn biribiri láti fi wọ́n pa mọ́ de ìdájọ́.”—2 Pétérù 2:4.

Tátárọ́sì kì í ṣe ibi pàtó kan àmọ́ ipò kan tó dà bí ìgbà téèyàn wà lẹ́wọ̀n ni, ibi tí wọn ò ti ní lómìnira láti ṣohun tó bá wù wọ́n. Àwọn ẹ̀mí èṣù wọ̀nyẹn ò lè gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ mọ́, àmọ́ wọ́n ṣì lágbára láti darí ọkàn àwọn èèyàn kí wọ́n sì nípa lórí ìgbésí ayé wọn. Kódà, wọ́n lágbára lórí èèyàn àti ẹranko. (Mátíù 12:43-45; Lúùkù 8:27-33) Wọ́n tún máa ń tan àwọn èèyàn nípa ṣíṣe bí ẹni tó ti kú. Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́, wọn ò sì fẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú.

Bá A Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù

Agboọlá rí i pé àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa àwọn ẹni ẹ̀mí àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn òkú bọ́gbọ́n mu. Ó wá rí i pé òun ní láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, John sì ń fàwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Agboọlá ti wá mọ̀ pé inú sàréè làwọn ọmọ òun wà, ó sì ti mọ̀ pé kò sóhun tó jọ pé wọ́n ń dúró dìgbà tẹ́ni tó pa wọ́n bá kú kí wọ́n lè máa ṣẹrú rẹ̀. Ohun tó mọ̀ yìí ti tù ú nínú gan-an.—Jòhánù 11:11-13.

Agboọlá tún wá mọ̀ pé òun ní láti jáwọ́ pátápátá nínú ìbẹ́mìílò. Ó sun gbogbo nǹkan ìní ẹ̀ tó ní ín ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò. (Ìṣe 19:19) Àwọn kan ládùúgbò ẹ̀ kìlọ̀ fún un pé àwọn ẹ̀mí èṣù yẹn máa dà á láàmú. Àmọ́, Agboọlá ò bẹ̀rù. Ohun tó wà nínú ìwé Éfésù 6:11, 12 ló ṣe. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀. . . nítorí àwa ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú.” Lára àwọn ohun tó para pọ̀ di ìhámọ́ra tẹ̀mí yìí ni òtítọ́, ìgbàgbọ́, òdodo, ìhìn rere àlàáfíà àti idà ẹ̀mí, ìyẹn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìhámọ́ra yìí ti wá, ó sì lágbára gan-an!

Àwọn kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ Agboọlá pa á tì nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn àṣà àdúgbò tó ní ín ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò sílẹ̀. Àmọ́, ó láwọn ọ̀rẹ́ tuntun nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò náà, àwọn ọ̀rẹ́ tó ní báyìí sì gba ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gbọ́.

Agboọlá ti wá mọ̀ báyìí pé, láìpẹ́ Jèhófà máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò láyé, ó sì máa gba agbára lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Nígbà tó bá sì yá, Ó máa pa wọ́n run. (Ìṣípayá 20:1, 2, 10) Ọlọ́run máa jí “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí” dìde sórí ilẹ̀ ayé níbí. (Jòhánù 5:28, 29) Ébẹ́lì àtàwọn ọmọ tí ò mọwọ́ mẹsẹ̀ tí Hẹ́rọ́dù Ọba pa, tó fi mọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye míì, máa wà lára àwọn tí Jèhófà máa jí dìde. Agboọlá sì gbà gbọ́ dájú pé àwọn ọmọkùnrin òun náà máa wà lára wọn. Ó sì ṣeé ṣe káwọn èèyàn ẹ tó ti kú wà lára wọn. Gbogbo àwọn tó máa jíǹde nígbà náà ló máa jẹ́rìí sí i pé àwọn ò mọ nǹkan kan látìgbà táwọn ti kú títí dìgbà tí Ọlọ́run jí àwọn dìde, kódà wọ́n á jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ò tiẹ̀ mọ̀ bóyá wọ́n ṣe àṣeyẹ kankan fáwọn.

Kò sídìí kankan tí wàá fi máa bẹ̀rù àwọn òkú. Kàkà bẹ́ẹ̀, o lè máa wọ̀nà fún ìgbà tí wàá pa dà wà pẹ̀lú àwọn èèyàn ẹ tó ti kú. Ní báyìí ná, o ò ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ìgbàgbọ́ ẹ lè túbọ̀ máa lágbára sí i? Àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni kó o sì yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Tó o bá ti ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò lọ́nàkọnà, jáwọ́ ńbẹ̀ kíá. Dáàbò bo ara ẹ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù nípa gbígbé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.” (Éfésù 6:11) Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wọ́n máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a ni wọ́n sì máa ń lò.

Agboọlá ò bẹ̀rù òkú mọ́, ó sì ti kọ́ bó ṣe lè dáàbò bo ara ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Ó ní: “Mi ò mọ ẹni tó pa àwọn ọmọkùnrin mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Àmọ́, lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà, mo ti bí ọmọ méje míì. Kò sì sẹ́nì kankan láti ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí tó tíì ṣe wọ́n ní jàǹbá.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Agboọlá ò bẹ̀rù òkú mọ́, ó sì ti kọ́ bó ṣe lè dáàbò bo ara ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Kéènì ò bẹ̀rù pé àbúrò òun tó ti kú lè wá gbẹ̀san lára òun