Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Onídàájọ́ Tó Máa Ń Ṣohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

Onídàájọ́ Tó Máa Ń Ṣohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Onídàájọ́ Tó Máa Ń Ṣohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

Jẹ́nẹ́sísì 18:22-32

ÌDÁJỌ́ ÒDODO. Àìfigbá-kan-bọ̀kan nínú. Àìṣègbè. Ṣáwọn ànímọ́ rere yìí wù ẹ́? Ó máa ń wu àwa èèyàn pé káwọn ẹlòmíì má figbá kan bọ̀kan nínú fún wa. Ó ṣeni láàánú pé ìdájọ́ òdodo ti ròkun ìgbàgbé láyé òde òní. Àmọ́, Adájọ́ kan wà tó tó gbẹ́kẹ̀ lé, Jèhófà Ọlọ́run sì ni adájọ́ ọ̀hún. Ìgbà gbogbo ló máa ń ṣohun tó tọ́. Èyí ṣe kedere nínú ìjíròrò tó wáyé láàárín Jèhófà àti Ábúráhámù, bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì 18:22-32. a

Nígbà tí Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé òun fẹ́ lọ ṣàyẹ̀wò bí nǹkan ṣe ń lọ sí nílùú Sódómù àti Gòmórà, Ábúráhámù ro tàwọn olóòótọ́ tó ń gbé láwọn ìlú náà títí kan Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ábúráhámù bẹ Jèhófà, ó ní: “Ìwọ, ní ti tòótọ́, yóò ha gbá olódodo lọ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú bí? Ká sọ pé àádọ́ta olódodo wà ní àárín ìlú ńlá náà. Nígbà náà, ìwọ yóò ha . . . dárí ji ibẹ̀ ní tìtorí àádọ́ta olódodo tí wọ́n wà nínú rẹ̀ bí?” (Ẹsẹ 23, 24) Ọlọ́run wá sọ pé òun ò ní pa àwọn ìlú náà run tí òun bá lè rí àádọ́ta [50] èèyàn péré tí wọ́n jẹ́ olódodo nínú ìlú náà. Ábúráhámù tún bẹ Jèhófà lẹ́ẹ̀marùn-ún sí i pé kó jọ̀ọ́ kó dín iye yẹn kù, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó dórí olódodo mẹ́wàá. Ọlọ́run sì ń sọ fún Ábúráhámù ní gbogbo ìgbà tó fi ń dín iye yẹn kù pé òun ò ní pa àwọn ìlú yẹn run tí iye olódodo tí Ábúráhámù ń bẹ̀bẹ̀ fún bá wà níbẹ̀.

Ṣé Ábúráhámù ń bá Ọlọ́run jiyàn ni? Rárá o! Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ìwà àrífín gbáà nìyẹn. Àmọ́, bí Ábúráhámù ṣe sọ̀rọ̀ fi hàn pé tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ló fi ń bẹ Ọlọ́run. Kódà, ó pe ara rẹ̀ ní “ekuru àti eérú” lásánlàsàn. Ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ pé “jọ̀wọ́.” (Ẹsẹ 27, 30-32) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ fi hàn pé ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé Jèhófà ò ní figbá kan bọ̀kan nínú. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ábúráhámù sọ pé “kò ṣeé ronú kàn” pé kí Ọlọ́run pa olódodo pọ̀ pẹ̀lú ẹni búburú. Bàbá ńlá olóòótọ́ náà fi ìdánilójú sọ pé “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé” máa “ṣe ohun tí ó tọ́.”—Ẹsẹ 25.

Ṣóòótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tí Ábúráhámù sọ yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, bẹ́ẹ̀ sì tún kọ́. Ohun tó ní lọ́kàn ò tọ̀nà bó ṣe rò pé, ó kéré tán, olódodo èèyàn mẹ́wàá máa wà ní Sódómù àti Gòmórà. Àmọ́, òótọ́ pọ́ńbélé lohun tó sọ pé láé Ọlọ́run kò ní “gbá olódodo lọ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú.” Nígbà tí Ọlọ́run sì pa àwọn ìlú burúkú yẹn run, Ọlọ́run lo áńgẹ́lì rẹ̀ láti gba Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì là, torí pé wọ́n jẹ́ olódodo.—2 Pétérù 2:7-9.

Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa Jèhófà? Bí Jèhófà ṣe sọ fún Ábúráhámù pé òun fẹ́ lọ ṣàyẹ̀wò àwọn ìlú yẹn, ńṣe ni Jèhófà fẹ́ kí Ábúráhámù sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ jáde. Jèhófà wá fara balẹ̀ gbọ́ Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ̀ bó ṣe ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde. (Aísáyà 41:8) Ẹ ò rí ẹ̀kọ́ pàtàkì tí èyí kọ́ wa, pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó nírẹ̀lẹ̀, tó sì máa ń buyì àti ọlá fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé! Ó ṣe kedere nígbà náà pé a nídìí tó pọ̀ láti fọkàn tán Jèhófà, Onídàájọ́ tó máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà ìjíròrò yìí, áńgẹ́lì kan ló ṣojú fún Jèhófà láti bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀. Àpẹẹrẹ ibòmíì tí áńgẹ́lì ti ṣojú fún Jèhófà wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 16:7-11, 13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ábúráhámù bẹ Jèhófà torí ìlú Sódómù àti Gòmórà