Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀

Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn

Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀

Ó ṢE Jónà bíi pé kó lágbára láti dá ariwo tó ń dẹ́rù bani yẹn dúró. Ariwo tí Jónà ń gbọ́ ju ariwo ìgbì òkun tó ń bì, tó sì wá ń jẹ́ kí àwọn ìgbòkun ọkọ̀ òkun náà máa pariwo kíkankíkan lọ, kódà ariwo yẹn lágbára ju ìjì tó ń kọlu ọkọ̀ òkun náà látorí òkè lọ, tó sì ń jẹ́ kí ọkọ̀ náà máa rọ́ kẹ́kẹ́ bíi pé ó máa fọ́. Ariwo tó ni Jónà lára jù lọ ni ariwo àwọn atukọ̀, ìyẹn ọ̀gákọ̀ àtàwọn ọmọ iṣẹ́ ẹ̀, bí wọ́n ṣe ń sa gbogbo ipá wọn láti rí i pé ọkọ̀ òkun náà ò rì. Jónà mọ̀ pé àwọn èèyàn yìí ò ní pẹ́ bómi lọ torí òun.

Kí ló sún Jónà dénú ìṣòro tó kó sí yìí? Ó ti ṣàṣìṣe kan tó lágbára gan-an, ìyẹn sì ti múnú bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. Kí ló ṣe? Ṣé àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe ni? Ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí máa kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ìtàn Jónà jẹ́ ká rí i pé kódà àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn fẹsẹ̀ múlẹ̀ pàápàá lè ṣàṣìṣe, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n lè ṣàtúnṣe.

Wòlíì Kan Láti Gálílì

Táwọn èèyàn bá rántí Jónà, àwọn àṣìṣe tó ṣe ló sábà máa ń wá sọ́kàn wọn, irú bó ṣe ṣàìgbọràn àti bó ṣe ya olóríkunkun. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan míì wà tó yẹ ká mọ̀ nípa ọkùnrin yẹn. Má gbàgbé pé Jèhófà Ọlọ́run fúnra ẹ̀ ló yan Jónà gẹ́gẹ́ bíi wòlíì rẹ̀. Jèhófà ò ní yàn án fún ojúṣe tó tóyẹn ká sọ pé kì í ṣe olóòótọ́ tàbí olódodo.

Ìwé 2 Àwọn Ọba 14:25 sọ díẹ̀ fún wa nípa orírun Jónà. Ọmọ ìlú Gati-héférì ni, ìlú yẹn wà ní kìlómítà mẹ́rin péré sí ìlú Násárétì tí wọ́n ti máa tọ́ Jésù dàgbà ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn. a Ìgbà tí Jèróbóámù Ọba Kejì ń ṣàkóso lórí ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì ni Jónà ń sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. Ìgbà ayé Èlíjà ti kọjá lọ tipẹ́tipẹ́, Èlíṣà tó sì gbapò rẹ̀ ti kú nígbà tí bàbá Jèróbóámù ń ṣàkóso. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti lo Èlíjà àti Èlíṣà láti fòpin sí ìjọsìn Báálì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti tún ń mọ̀ọ́mọ̀ wọgbó lọ báyìí. Agbára sì ti wà lọ́wọ́ ọba kan tó ń “ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.” (2 Àwọn Ọba 14:24) Nítorí náà, iṣẹ́ Jónà ò rọrùn rárá. Síbẹ̀, tọkàntọkàn ló fi ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ.

Lọ́jọ́ kan, Jónà ṣèpinnu kan tó lágbára. Jèhófà gbé iṣẹ́ kan fún Jónà, Jónà sì rò pé iṣẹ́ náà nira gan-an. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà gbé fún un?

“Dìde, Lọ sí Nínéfè”

Jèhófà sọ fún Jónà pé: “Dìde, lọ sí Nínéfè ìlú ńlá títóbi náà, kí o sì pòkìkí lòdì sí i pé ìwà búburú wọn ti gòkè wá síwájú mi.” (Jónà 1:2) Kò nira láti mọ ìdí tí iṣẹ́ tí Jónà gbà yìí fi bà á lẹ́rù. Ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] kìlómítà nìlú Nínéfè wà lápá ìlà oòrùn ìlú Gati-héférì, téèyàn bá sì máa fẹsẹ̀ rìn ín, ó ṣeé ṣe kó gba onítọ̀hún lóṣù kan gbáko. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wàhálà láti fẹsẹ̀ rìnrìn àjò yẹn gan-an ló rọrùn jù nínu iṣẹ́ yẹn. Nílùú Nínéfè lọ́hùn-ún, Jónà máa jíṣẹ́ ìdájọ́ Jèhófà fáwọn aráàlú Ásíríà tí wọ́n rorò tí wọ́n sì jẹ́ òṣónú ẹ̀dá. Nígbà táwọn èèyàn Ọlọ́run ò fi gbogbo ara gbọ́rọ̀ Jónà, kí làwọn Kèfèrí wá máa ṣe? Ọgbọ́n wo ni ìránṣẹ́ Jèhófà kan ṣoṣo yìí máa dá sí i tá á fi kẹ́sẹ járí nílùú ńlá Nínéfè, ìlú tí Ọlọ́run wá pè ní “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀” nígbà tó yá?—Náhúmù 3:1, 7.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn nǹkan tí Jónà ń rò nìyí. Ohun tá a mọ̀ ni pé ó sá gbabòmíì lọ. Nígbà tí Jèhófà sọ pé kí Jónà lọ sápá ìlà oòrùn, ìwọ̀ oòrùn ló forí lé. Ó lọ sí etíkun ìlú Jópà níbi tó ti rí ọkọ̀ òkun kan tó ń lọ sí ìlú Táṣíṣì. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé orílẹ̀-èdè Sípéènì nìlú Táṣíṣì wà. Tó bá jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Sípéènì ni ìlú Táṣíṣì wà lóòótọ́, a jẹ́ pé ibi tí Jónà forí lé fi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún [3,500] kìlómítà jìnnà sí ìlú Nínéfè. Ó ṣeé ṣe kírú ìrìn àjò orí omi tó máa gbéèyàn lọ sí ìpẹ̀kun Òkun Mẹditaréníà, tí wọ́n ń pè ní Òkun Ńlá nígbà yẹn, gbà tó ìrìn àjò ọdún kan gbáko! Jónà pinnu pé àfi kóun sá fún iṣẹ́ tí Jèhófà rán òun.

Ṣéyìí wá fi hàn pé ojo ni Jónà? Ẹ máà jẹ́ ká yára dá a lẹ́jọ́. Bá a ṣe máa rí i, ó ṣàwọn ohun tó fi hàn pé onígboyà èèyàn ni. Bíi gbogbo wa, aláìpé èèyàn tó ń kojú àìmọye àṣìṣe náà ni Jónà. (Sáàmù 51:5) Ta ló lè fọwọ́ sọ̀yà nínú wa pé ẹ̀rù ò ba òun rí?

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè máa ṣe wá bíi pé ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe le jù fún wa tàbí pé a ò lè ṣe é pàápàá. Kódà, iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run retí pé kí gbogbo Kristẹni ṣe lè sú wa. (Mátíù 24:14) Ó rọrùn láti gbàgbé òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Máàkù 10:27) Bá a bá ti gbàgbé òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí rí, ó ṣeé ṣe ká lóye ohun tí Jónà dojú kọ. Àmọ́, kí ni àbájáde sísá tí Jónà ń sá lọ?

Jèhófà Bá Wòlíì Tó Ń Ṣe Tinú Ara Ẹ̀ Wí

Ẹ jẹ́ ká fojúunú wo Jónà bó ṣe ń fara balẹ̀ jókòó sínú ọkọ̀ òkun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ tàwọn ará Fòníṣíà. Jónà ń wo bí ọ̀gákọ̀ àtàwọn ọmọọṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń ti ọkọ̀ òkun wọn sórí omi, kí wọ́n lè kúrò ní etíkun. Bí ọkọ̀ náà ṣe ń lọ tí wọ́n sì ń jìnnà sí etíkun díẹ̀díẹ̀, Jónà á ti máa wò ó pé òun ti bọ́ lọ́wọ́ ewu iṣẹ́ ńlá tó ń ba òun lẹ́rù. Àmọ́ lójijì, ojú ọjọ́ yí pa dà.

Ìjì alágbára kan bẹ̀rẹ̀ sí í ru òkun gùdù, ìgbì òkun náà sì lágbára débi pé ó lè sọ àwọn ọkọ̀ òkun ìgbàlódé pàápàá di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Wákàtí mélòó ló gbà kí ìgbì òkun yẹn tó lágbára ju ọkọ̀ òkun onípákó yẹn lọ? Ṣé Jónà gan-an tiẹ̀ mọ ìgbà tóhun tó kọ pé, “Jèhófà fúnra rẹ̀ sì rán ẹ̀fúùfù ńláǹlà jáde sí òkun,” ṣẹlẹ̀? Kò dájú. Àmọ́, ó ṣáà mọ̀ pé àwọn atukọ̀ òkun náà bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pe oríṣiríṣi ọlọ́run wọn, ó sì mọ̀ pé àwọn ọlọ́run èké wọ̀nyẹn ò lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Àti ní ti ọkọ̀ òkun náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ fọ́.” (Jónà 1:4; Léfítíkù 19:4) Báwo ni Jónà á ṣe wá lanu láti gbàdúrà sí Ọlọ́run tó ń sá fún?

Bó ṣe rí i pé kò sóun tóun lè ṣe sí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀, ó lọ wábì kan sùn sí nínú ọkọ̀ náà. Ó sì sùn lọ fọnfọn. b Ọ̀gákọ̀ náà rí i níbi tó sùn sí, ló bá jí i pé kóun náà gbàdúrà sí ọlọ́run tiẹ̀ náà. Àwọn atukọ̀ òkun náà ti wá rí i pé ìjì tó ń jà náà kì í ṣe ojú lásán, wọ́n bá ṣẹ́ kèké kí wọ́n lè mọ ẹni tó fa ìṣòro náà. Ó dájú pé ọkàn Jónà á ti máa lù kìkì bí wọ́n ṣe ń dárúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kàn tó wà nínú ọkọ̀ náà. Nígbà tó yá, àṣírí tú. Torí Jónà ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí ìjì náà jà, òun náà sì ni kèké mú!—Jónà 1:5-7.

Jónà ṣàlàyé bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ fáwọn atukọ̀ náà. Ìránṣẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè ni. Ọlọ́run tó ń bínú sí i yìí ló ń sá fún, tó sì wá tìtorí ẹ̀ kó gbogbo wọn sí wàhálà. Ìdí àwọn ọkùnrin náà ti domi, Jónà sì rí i lójú wọn. Wọ́n wá bi í pé kí ni káwọn ṣe kí ọkọ̀ òkun àwọn má bàa dà nù, káwọn sì bómi lọ. Kí ló sọ? Ó ṣeé ṣe kí jìnnìjìnnì ti bo Jónà bó ṣe ń ronú nípa bóun á ṣe máa pòfóló nígbà tóun bá ń kú lọ nínú agbami okun tó tutù nini yẹn. Àmọ́, báwo ló ṣe máa jẹ́ káwọn ọkùnrin yìí kú báyẹn nígbà tó mọ̀ pé òun lè gbà wọ́n là? Torí náà, o sọ pé: “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì jù mí sínú òkun, òkun yóò sì pa rọ́rọ́ fún yín; nítorí mo mọ̀ pé èmi ni ó fà á tí ìjì líle ńláǹlà yìí fi dé bá yín.”—Jónà 1:12.

Ó dájú pé ojo èèyàn ò lè sọ̀rọ̀ báyìí. Kò sì sí àníàní pé inú Jèhófà máa dùn láti rí ìwà akọni tí Jónà hù, ní ti bó ṣe gbà láti fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu nítorí àwọn ẹlòmíì nírú àkókò tó nira yìí. Èyí fi hàn pé ìgbàgbọ́ Jónà lágbára gan-an ni. A lè fara wé e lónìí táwa náà bá ń yááfì àwọn nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí nítorí àwọn ẹlòmíì. (Jòhánù 13:34, 35) Tá a bá mọ ẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tara, tí ìbànújẹ́ ti sorí ẹ̀ kodò, tàbí tó nílò ìrànlọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìjọsìn, ṣé a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ran onítọ̀hún lọ́wọ́? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń múnú Jèhófà dùn.

Ó ṣeé ṣe kóhun tí Jónà fẹ́ ṣe wú àwọn atukọ̀ náà lórí gan-an, torí wọn ò kọ́kọ́ gbà láti jù ú sómi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti máa tukọ̀ náà nìṣó bóyá wọ́n á débùúté, àmọ́ pàbó ni gbogbo ẹ̀ já sí. Kàkà kéwé àgbọn ìjì náà dẹ̀, ńṣe ló túbọ̀ ń le koko sí i. Níkẹyìn, wọ́n rí i pé àwọn ò rọ́gbọ́n ẹ̀ dá. Wọ́n bá ké pe Jèhófà, Ọlọ́run Jónà pé kó ṣàánú àwọn, wọ́n gbé ọkùnrin náà, wọ́n sì jù ú sínú òkun.—Jónà 1:13-15.

Ọlọ́run Ṣàánú Jónà Ó sì Gbà Á Là

Jónà bára ẹ̀ láàárín agbami òkun tó ń ru gùdù yẹn. Ó ṣeé ṣe kóun náà dura díẹ̀, kó lè léfòó lórí omi, kó sì máa wo ọkọ̀ òkun yẹn bó ṣe ń sáré lọ lọ́ọ̀ọ́kán. Àmọ́, ìjì kan tó lágbára gbá a lọ sábẹ́ omi. Bó ṣe ń rì lọ sábẹ́ omi lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún, ó lè ti máa ronú pé ó ti parí fóun nìyẹn.

Jónà ṣàpèjúwe bọ́rọ̀ yẹn ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tó yá. Oríṣiríṣi èrò ló gba ọkàn rẹ̀. Ọkàn ẹ̀ bàjẹ́ bó ṣe ń ronú pé òun ò tún ní rí tẹ́ńpìlì ẹlẹ́wà Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù mọ́. Ó ń ronú bóun á ṣe rì lọ sábẹ́ omi lọ́hùn-ún, nísàlẹ̀ àwọn òkè tó wà lábẹ́ omi, táwọn koríko inú òkun sì máa lọ́ mọ́ òun lára. Ó ṣeé ṣe kó ti gbà pé sàréè òun nìyẹn.—Jónà 2:2-6.

Àmọ́, dúró ná o! Nǹkan kan ń da omi rú, nǹkan ọ̀hún tóbi ó sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ Jónà, ó dúdú, nǹkan abẹ̀mí sì ni. Nǹkan ọ̀hún yọ sí i lójijì, ó sì pa kuuru mọ́ ọn. Ó lanu, ó sì gbé e mì.

Bóyá ni Jónà ò ní parí ìgbésí ayé ẹ̀ síbí. Síbẹ̀, Jónà kíyè sí i pé ohun àrà kan ń ṣẹlẹ̀. Ó ṣì ń mí! Ẹja yẹn ò pa á lára, kò jẹ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ooru inú ẹja náà ò ṣeé ní nǹkan kan. Èèmọ̀ rèé o! Jónà ṣì wà láàyè, bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ibi tá a lè pè ní sàréè ló wà. Ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ba Jónà. Kò sí àníàní pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ló “ṣètò ẹja ńlá kan láti gbé Jónà mì.” cJónà 1:17.

Bí ìṣẹ́jú ti ń gorí ìṣẹ́jú, bẹ́ẹ̀ náà ni wákàtí ń gorí wákàtí. Nígbà tí Jónà wà níbi tó ṣókùnkùn jù lọ tó tíì rí rí yìí, ó ráyè ronú dáadáa, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run. Àdúrà tó gbà yẹn, tó wà ní orí kejì ìwé Jónà, sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa. Àdúrà yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Jónà mọ Ìwé Mímọ́ gan-an, torí pé léraléra ló ń tọ́ka sáwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Sáàmù. Àdúrà yẹn tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jónà ní ànímọ́ kan tó máa ń múnú ẹni dùn, ìyẹn ẹ̀mí ìmoore. Nígbà tí Jónà máa parí àdúrà rẹ̀, ó sọ pé: “Ní tèmi, èmi yóò fi ohùn ìdúpẹ́ rúbọ sí ọ. Èmi yóò san ohun ti mo jẹ́jẹ̀ẹ́. Ti Jèhófà ni ìgbàlà.”—Jónà 2:9.

Jónà wá kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà lè gba ẹnikẹ́ni là níbikíbi àti nígbàkigbà. Kódà ní “ìhà inú ẹja,” Jèhófà rí ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà nínú ìṣòro, ó sì gbà á là. (Jónà 1:17) Jèhófà nìkan ló lè pa ẹnì kan mọ́ láàyè láìséwu nínú ẹja ńlá kan fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta. Ó yẹ ká rántí lóde òní pé Jèhófà ni “Ọlọ́run, ẹni tí èémí [wa] wà lọ́wọ́ rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 5:23) Òun ló fun wa ní èémí tá à ń mí sínú, ìyẹn ìwàláàyè wa. Ṣá a moore Ọlọ́run? Ṣé kò wá yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn àṣẹ Jèhófà?

Jónà ńkọ́, ṣóhun náà fi hàn pé òun moore nípa ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni. Lẹ́yìn ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, ẹja náà gbé Jónà wá sí etíkun, ó sì “pọ Jónà sórí ilẹ̀ gbígbẹ.” (Jónà 2:10) Àbẹ́ ò rí nǹkan, kò sí pé Jónà ń lúwẹ̀ẹ́ dé etíkun! Àmọ́, fúnra ẹ̀ ló máa wá bó ṣe máa kúrò ní etíkun yẹn. Kò pẹ́ kò jìnnà, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ẹ̀mí ìmoore tí Jónà ní wá látọkàn ẹ̀. Ìwé Jónà 3:1, 2 sọ pé: “Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jónà wá nígbà kejì, pé: ‘Dìde, lọ sí Nínéfè ìlú ńlá títóbi náà, kí o sì pòkìkí fún un nípa ìpòkìkí tí èmi yóò sọ fún ọ.’” Kí ni Jónà máa ṣe?

Jónà ò jáfara. A kà pé: “Látàrí ìyẹn, Jónà dìde, ó sì lọ sí Nínéfè ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jèhófà.” (Jónà 3:3) Ohun tí Jónà ṣe nìyẹn, ó ṣègbọràn. Ó ṣe kedere pé ó kọ́gbọ́n látinú àṣìṣe ẹ̀. Ó yẹ ká nígbàgbọ́ bíi ti Jónà lórí kókó yìí pẹ̀lú. Kò sẹ́ni tí kì í dẹ́ṣẹ̀, a sì máa ń ṣàṣìṣe. (Róòmù 3:23) Àmọ́, ṣé a máa ń jọ̀gọ nù àbí ńṣe la máa ń kọ́gbọ́n látinú àwọn àṣìṣe wa, ká lè máa bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run?

Ṣé Jèhófà san Jónà lẹ́san ìgbọràn tó ṣe? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ ni. Ìdí kan ni pé, ó ṣeé ṣe kí Jónà mọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé àwọn atukọ̀ tó wà nínú ọkọ̀ tó wọ̀ náà yè bọ́. Gbàrà tí Jónà fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu nítorí àwọn tó wà nínú ọkọ̀ yẹn ni ìjì náà dáwọ́ dúró, àwọn atukọ̀ yẹn sì “bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù Jèhófà gidigidi,” wọ́n sì rúbọ sí Jèhófà dípò àwọn ọlọ́run wọn.—Jónà 1:15, 16.

Jèhófà tiẹ̀ tún wá san án lẹ́san tó jùyẹn lọ nígbà tó yá. Jésù lo àkókò tí Jónà lò nínú ẹja ńlá láti fi sàsọtẹ́lẹ̀ àkókò tóun náà máa lò nínú sàréè tàbí Ṣìọ́ọ̀lù. (Mátíù 12:38-40) Ẹ wo bínú Jónà ṣe máa dùn tó láti gbọ́ nípa ìbùkún yẹn nígbà tó bá jíǹde! (Jòhánù 5:28, 29) Jèhófà fẹ́ bù kún ìwọ náà. Bíi ti Jónà, ṣé ìwọ náà máa kọ́gbọ́n látinú àṣìṣe ara ẹ, ṣé wàá jẹ́ onígbọràn, ṣé wàá sì ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan tó o nífẹ̀ẹ́ sí nítorí àwọn ẹlòmíì?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìlú Gálílì, níbi tí Jónà ti wá, gbàfiyèsí torí àwọn Farisí fìgbéraga sọ fún Jésù pé: “Ṣe ìwádìí káàkiri, kí o sì rí i pé kò sí wòlíì kankan tí a óò gbé dìde láti Gálílì.” (Jòhánù 7:52) Ọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè àtàwọn tó ń ṣèwádìí ròyìn pé ohun táwọn Farisí wọ̀nyẹn ní lọ́kàn ni pé kò sẹ́nì kankan tó lè sọ pé wòlíì lòun lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Gálílì. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, a jẹ́ pé àwọn èèyàn yẹn ò ka ohun tó wà nínú ìtàn àti àsọtẹ́lẹ̀ sí.—Aísáyà 9:1, 2.

b Bíbélì Septuagint sọ pé Jónà hanrun, ìyẹn sì jẹ́ ká mọ bó ṣe sùn wọra tó. Àmọ́, kò ní dáa tá a bá rò pé torí kí Jónà má bàa dá sí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ló ṣe lọ wábi sùn sí, a lè rántí pé nígbà míì oorun máa ń kun àwọn tó bá rẹ̀wẹ̀sì. Nígbà tí Jésù wà lọ́gbà Gẹtisémánì lákòókò tí nǹkan ò rọrùn fún un, ńṣe ni Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù “ń tòògbé nítorí ẹ̀dùn-ọkàn.”—Lúùkù 22:45.

c Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ táwọn Hébérù máa ń pe ẹja túmọ̀ sí “ẹran abàmì inú òkun” tàbí “ẹja tó tóbi fàkìà-fakia.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí bá a ṣe lè mọ irú ẹ̀dá inú omi tó jẹ́ gan-an, ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ẹja àbùùbùtán tó wà nínu Òkun Mẹditaréníà tóbi débi pé wọ́n lè gbé odindi èèyàn mì. Àwọn ẹja àbùùbùtán tó tóbi jùyẹn lọ fíìfíì sì tún wà láwọn ibòmíì, bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹja àbùùbùtán kan wà tó gùn tó ọkọ̀ bọ́ọ̀sì mẹ́ta, ó sì ṣeé ṣe káwọn míì gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àwọn Tó Ń Ṣe Lámèyítọ́ Ta Ko Ìwé Jónà

▪ Ṣé ìtàn tó wà nínú ìwé Jónà ṣẹlẹ̀ lóòótọ́? Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń ṣe lámèyítọ́ ìwé Jónà. Láyé táwọn èèyàn sì ti wá ń ṣe lámèyítọ́ ìtàn àti ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ báyìí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń ka ìwé Jónà sí ìtàn àtẹnudẹ́nu tàbí ìtàn àròsọ lásánlàsàn. Òǹkọ̀wé kan ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ròyìn bí àlùfáà kan ṣe ṣàlàyé pé ìtándòwe lásán ni ìtàn Jónà àti ẹja ńlá tó gbé e mì, àlùfáà náà sọ pé, Jónà dé sí òtẹ́ẹ̀lì kan tí wọ́n ń pè ní Ẹja Àbùùbùtán nílùú Jópà. Ìgbà tí kò rówó san mọ́ lẹni tó ni òtẹ́ẹ̀lì náà lé e jáde. Ó ní bọ́rọ̀ ẹja àbùùbùtán tó gbé Jónà “mì” tó sì “pọ̀ ọ́” jáde nígbà tó yá ṣe rí nìyẹn! Ká sòótọ́, àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ Bíbélì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti mú ìtàn Jónà nírọ́, kódà tiwọn fẹ́ẹ̀ ju ti ẹja ńlá tó gbé Jónà mì lọ!

Kí nìdí tọ́pọ̀ èèyàn fi rò pé ìtàn àròsọ lásán ló wà nínú ìwé Bíbélì yìí? Ìdí ni pé ìyanu ni ìtàn tó wà níbẹ̀. Ó dà bíi pé tọ́pọ̀ àwọn tó máa ń ṣe lámèyítọ́ bá gbọ́ nípa iṣẹ́ ìyanu, ibi tí wọ́n sábà máa ń parí èrò sí ni pé: Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ láéláé. Àmọ́, ṣé irú èrò bẹ́ẹ̀ bọ́gbọ́n mu lóòótọ́? Bi ara ẹ pé, ‘Ṣé mo gba gbólóhùn àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì gbọ́?’ Gbólóhùn náà ni pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Kárí ayé, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó lọ́pọlọ gbà pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yẹn. Bó ti wù kó rí, nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu tó wà nínú Bíbélì, kò séyìí tó lágbára tó èyí tí gbólóhùn yẹn ṣàpèjúwe ẹ̀.

Rò ó wò ná: Kí ló wà nínú ìwé Jónà tí ò ní ṣeé ṣe fún Ẹni tó dá ọ̀run tó lọ salalu àti oríṣiríṣi àgbàyanu ìṣẹ̀dá tó wà lórí ilẹ̀ ayé? Ṣé ìjì ni kò lè mú kó jà ni, àbí ṣíṣètò ẹja ńlá láti gbé èèyàn mì ló máa ṣòroó ṣe fún un? Àbí ti ẹja tó lọ pọ ẹni tó gbé e mì la máa ní kò lágbára láti ṣe? Àwọn nǹkan wọ̀nyí ò le ṣòroó ṣe fún Ẹni tí agbára rẹ̀ ò láàlà.—Aísáyà 40:26.

Kódà, àwọn nǹkan àgbàyanu máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míì láìjẹ́ pé Ọlọ́run lọ́wọ́ sí i. Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́ pé lọ́dún 1758, atukọ̀ kan ré bọ́ sínú Òkun Mẹditaréníà látinú ọkọ̀ òkun rẹ̀, ẹja àbùùbùtán kan sì gbé e mì. Àmọ́, nígbà tí wọ́n yìnbọn lu ẹja náà, ó pọ atukọ̀ náà, wọ́n gbé e jáde kúrò nínú omi láàyè, ó sì fẹ́ẹ̀ máà sí nǹkan kan tó ṣe é. Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, a lè gbà pé nǹkan bàbàrà ni , kódà nǹkan àgbàyanu ni, àmọ́ kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu. Ṣé Ọlọ́run ò wá lè lo agbára rẹ̀ láti fi ṣe ohun tó jùyẹn lọ?

Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ tún sọ pé kò sẹ́ni tó lè wà nínú ẹja fún ọjọ́ mẹ́ta tí ooru ò ní mú pa. Àmọ́, má gbàgbé pé àwọn èèyàn ti gbọ́n débi pé wọ́n lè tọ́jú atẹ́gùn tó pọ̀ gan-an pa mọ́ sínú àgbá kékeré kan kí wọ́n lè lò ó láti fi máa mí lábẹ́ omi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. Ṣé Ọlọ́run ò wá ní lè lo agbára ńlá rẹ̀ tí ò láàlà àti ọgbọ́n rẹ̀ láti pa Jónà mọ́ láàyè kó sì máa mí fún ọjọ́ mẹ́ta? Bí áńgẹ́lì Jèhófà ṣe sọ fún Màríà, ìyá Jésù nígbà kan lọ̀rọ̀ rí, ó sọ pé: “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.”—Lúùkù 1:37.

Kí ló tún fi hàn pé òótọ́ ni ìtàn tó wà nínú ìwé Jónà? Bí Jónà ṣe ṣàpèjúwe ọkọ̀ òkun yẹn àtàwọn òṣìṣẹ́ tó wà nínú ẹ̀ kún rẹ́rẹ́, ó sì jóòótọ́. Ìwé Jónà 1:5 sọ pé àwọn atukọ̀ yẹn ju àwọn ẹrù tó wà nínú ọkọ̀ náà sínú òkun kí ọkọ̀ náà lè fúyẹ́. Àwọn òpìtàn ayé ìgbàanì àti òfin àwọn rábì pàápàá fi hàn pé ohun táwọn atukọ̀ ojú omi sábà máa ń ṣe nìyẹn tí ìjì bá ń jà lórí òkun. Bí Jónà sì ṣe wá ṣàpèjúwe Nínéfè nígbà tó yá bá àwọn ẹ̀rí tó wà nínú ìtàn àtàwọn èyí táwọn awalẹ̀pìtàn rí mu. Ẹ̀rí tó tún wá lágbára jù lọ ni bí Jésù Kristi ṣe fi bí Jónà ṣe wà nínú ẹja ńlá fún ọjọ́ mẹ́ta sàsọtẹ́lẹ̀ iye ọjọ́ tóun náà máa fi wà nínú sàréè. (Mátíù 12:38-40) Bí Jésù ṣe sọ̀rọ̀ nípa Jónà tún jẹ́rìí sí i pé òótọ́ ni ìtàn Jónà.

“Lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.”—LÚÙKÙ 1:37

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn atukọ̀ náà gbà láti ju Jónà sínú òkun