Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kì í Fi í Dáhùn Àwọn Àdúrà Kan?

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kì í Fi í Dáhùn Àwọn Àdúrà Kan?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kì í Fi í Dáhùn Àwọn Àdúrà Kan?

Bàbá tó ṣeé sún mọ́ ni Ọlọ́run. Bí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan ṣe máa ń fẹ́ káwọn ọmọ òun máa bá òun sọ̀rọ̀ fàlàlà, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe fẹ́ káwa náà máa gbàdúrà sóun. Lẹ́sẹ̀ kan náà, bó ṣe jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun táwọn ọmọ bá béèrè ni bàbá tó gbọ́n máa fún wọn, àwọn ìdí pàtàkì kan wà tí Ọlọ́run kì í fi í dáhùn àwọn àdúrà kan. Ṣé kò wá sí béèyàn ṣe lè mọ ìdí tí Ọlọ́run kì í fi í dáhùn àwọn àdúrà kan ni, àbí àwọn àpẹẹrẹ kan wà nínú Bíbélì tó lè jẹ́ ká mọ ìdí tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?

Àpọ́sítélì Jòhánù ṣàlàyé ìlànà kan tó ṣe pàtàkì téèyàn bá ń gbàdúrà, ó ní: “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:14) Àwọn ohun tá à ń gbàdúrà fún gbọ́dọ̀ bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Àwọn kan máa ń gbàdúrà fáwọn nǹkan tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Bí àpẹẹrẹ, àwọn míì máa ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ káwọn jẹ tẹ́tẹ́ tàbí kó jẹ́ káwọn borí nínú iyàn táwọn kọ́. Ìdí táwọn míì sì fi ń gbàdúrà ò tọ̀nà. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù kìlọ̀ pé kò dáa kéèyàn máa gbàdúrà lọ́nà yìí, ó ní: “Ẹ ń béèrè, síbẹ̀ ẹ kò rí gbà, nítorí tí ẹ ń béèrè fún ète tí kò tọ́, kí ẹ lè lò ó lórí àwọn ìfàsí-ọkàn yín fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara.”—Jákọ́bù 4:3.

Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹgbẹ́ méjì tó ń gbá bọ́ọ̀lù gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ káwọn borí. Àwa náà mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu ká retí pé kí Ọlọ́run dáhùn irú àwọn àdúrà tó ta kora bẹ́ẹ̀. Bákan náà ló ṣe rí táwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun méjì tí wọ́n fẹ́ bára wọn jà bá ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ káwọn ṣẹ́gun.

Àwọn tó kọ̀ láti pa òfin Ọlọ́run mọ́ kàn ń gbàdúrà lásán ni, Ọlọ́run ò ní dáhùn àdúrà wọn. Nígbà kan, Jèhófà rí i pé ó yẹ kóun sọ bó ṣe rí lára òun fáwọn tó ń fẹnu lásán jọ́sìn òun, ó sọ pé: “Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀; àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.” (Aísáyà 1:15) Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń yí etí rẹ̀ kúrò nínú gbígbọ́ òfin—àdúrà rẹ̀ pàápàá jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.”—Òwe 28:9.

Àmọ́, Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà àtọkànwá àwọn tó ń sa gbogbo ipá wọn láti máa sìn ín lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Ṣéyìí wá túmọ̀ sí pé gbogbo ohun tí wọ́n bá ti béèrè ni Jèhófà máa fún wọn. Rárá o. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́.

Mósè sún mọ́ Ọlọ́run gan-an, síbẹ̀ òun náà ní láti béèrè nǹkan “ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ [Ọlọ́run].” Mósè bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kóun wọ ilẹ̀ Kénáánì, ìyẹn ò sì bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, Mósè bẹ̀bẹ̀ pé: “Jẹ́ kí ń ré kọjá, jọ̀wọ́, kí n sì rí ilẹ̀ dáradára tí ó wà ní òdì-kejì Jọ́dánì.” Àmọ́ Ọlọ́run ti sọ fún Mósè tẹ́lẹ̀ pé kò ní dé ilẹ̀ náà torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. Nítorí náà, dípò tí Jèhófà fi máa dáhùn àdúrà Mósè, ó sọ fún un pé: “Ó tó ọ gẹ́ẹ́! Má ṣe tún bá mi sọ̀rọ̀ síwájú sí i mọ́ lórí ọ̀ràn yìí.”—Diutarónómì 3:25, 26; 32:51.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbàdúrà pé kí Ọlọ́run gba òun lọ́wọ́ ohun tó pè ní ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara.’ (2 Kọ́ríńtì 12:7) Ó ṣeé ṣe kí “ẹ̀gún” yìí jẹ́ ojú rẹ̀ tí kò ríran dáadáa tàbí àwọn alátakò àti “àwọn èké arákùnrin” tí wọ́n máa ń yọ ọ́ lẹ́nu lọ́pọ̀ ìgbà. (2 Kọ́ríńtì 11:26; Gálátíà 4:14, 15) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìgbà mẹ́ta ni mo pàrọwà sí Olúwa pé kí ó lè kúrò lára mi.” Àmọ́, Ọlọ́run mọ̀ pé tí Pọ́ọ̀lù bá ń bá a nìṣó láti máa wàásù láìka ìṣòro tó dà bí “ẹ̀gún nínú ẹran ara” ẹ̀ sí, ìyẹn máa fi agbára Òun hàn kedere, ó sì máa fi hàn pé tọkàntọkàn ni Pọ́ọ̀lù fi gbẹ́kẹ̀ lé Òun. Nítorí náà, dípò tí Ọlọ́run fi máa dáhùn àdúrà Pọ́ọ̀lù, ńṣe ló sọ fún un pé: “Agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.”—2 Kọ́ríńtì 12:8, 9.

Ó dájú pé Ọlọ́run mọ̀ jù wá lọ, ó mọ èyí tó lè ṣe wá láǹfààní nínú àwọn ohun tá à ń gbàdúrà fún. Jèhófà máa ń ṣe ohun tó máa ṣe wá láǹfààní tó sì bá ohun tí Bíbélì sọ pé ó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ mu.