Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé àrùn tí Bíbélì pè ní ẹ̀tẹ̀ náà làrùn tá a mọ̀ sí ẹ̀tẹ̀ lónìí?

Táwọn dókítà bá sọ pé ẹnì kan lárùn ẹ̀tẹ̀ lónìí, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé kòkòrò àrùn kan tó máa ń ranni ti ń ba onítọ̀hún lára jẹ́. Dókítà G.A. Hansen ló kọ́kọ́ rí kòkòrò àrùn yìí lọ́dún 1873. Àwọn tó ń ṣèwádìí ti wá mọ̀ pé kòkòrò àrùn yìí lè wà nínú ikunmú tàbí kẹ̀lẹ̀bẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́sàn-án kó tó kú. Wọ́n tún ti rí i pé ẹ̀tẹ̀ lè ran àwọn tó bá wà nítòsí ẹni tó lárùn ẹ̀tẹ̀, àtàwọn tó bá wọ aṣọ tónítọ̀hún ti wọ̀. Àjọ World Health Organization sọ pé àwọn tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ lọ́dún 2007 ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà okòólérúgba [220,000] lọ.

Kò sí àní-àní pé lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ńṣe ni wọ́n máa ń ya àwọn adẹ́tẹ̀ sọ́tọ̀ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, ohun tí Òfin Mósè sì pa láṣẹ náà nìyẹn. (Léfítíkù 13:4, 5) Àmọ́, ọ̀ràn nípa àìsàn nìkan kọ́ ni wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “ẹ̀tẹ̀,” ìyẹn tsa·raʹʽath, fún. Tsa·raʹʽath tún máa ń ran ilé àti aṣọ. Irú ẹ̀tẹ̀ yìí lè yọ lára òwú tàbí aṣọ ọ̀gbọ̀, ó sì lè yọ lára ohunkóhun tí wọ́n bá fi awọ ṣe. Nígbà míì, wọ́n lè fọ̀ ọ́ kúrò, àmọ́ tí àwọ̀ “ewéko àdàpọ̀-mọ́-yẹ́lò tàbí aláwọ̀ pupa rúsúrúsú” bá ṣì wà lára aṣọ tàbí awọ náà, wọ́n gbọ́dọ̀ sun aṣọ tàbí awọ náà. (Léfítíkù 13:47-52) Tí àrùn yìí bá bo ògiri ilé, àwọ̀ “ewéko àdàpọ̀-mọ́-yẹ́lò tàbí aláwọ̀ pupa rúsúrúsú” ló máa ń ní. Gbogbo òkúta tàbí amọ̀ tí àrùn náà bá wà lára ẹ̀ ni wọ́n gbọ́dọ̀ kó kúrò níbi táwọn èèyàn ń gbé. Tí ẹ̀tẹ̀ náà bá sì pa dà sára ilé náà, ńṣe ni wọ́n máa wó o, tí wọ́n á sì kó àwọn òkúta àtàwọn nǹkan tí wọ́n fi kọ́lé náà dà nù. (Léfítíkù 14:33-45) Àwọn kan sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé olú tó máa ń sú yọ sára ògiri balùwẹ̀ tàbí sára àwọn nǹkan tómi bá wà ni Bíbélì pè ní ẹ̀tẹ̀ tó máa ń wà lára aṣọ tàbí ilé. Àmọ́, a ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé bọ́ràn ṣe rí nìyẹn.

Kí nìdí táwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà fi gbaná jẹ́ nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wàásù nílùú Éfésù?

Nǹkan ń ṣẹnuure fáwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà ìlú Éfésù torí pé wọ́n ń ṣe “àwọn ojúbọ fàdákà Átẹ́mísì.” Átẹ́mísì yìí làwọn ará Éfésù gbà pé ó ń dáàbò bo àwọn, òun ni abo òrìṣà tó ń jẹ́ káwọn ọdẹ rí ẹran pa lóko ọdẹ, òun ló ń sọ àgàn dọlọ́mọ, tó sì ń jẹ́ kí wọ́n bí wẹ́rẹ́. (Ìṣe 19:24) Àwọn tó ń bọ òrìṣà Átẹ́mísì sọ pé ńṣe ló “jábọ́ láti ọ̀run,” àwọ́n sì wá kọ́ tẹ́ńpìlì kan fún un nílùú Éfésù. (Ìṣe 19:35) Àwọn èèyàn ka tẹ́ńpìlì yìí sí ọ̀kan lara àwọn ohun àràmàǹdà méje tó wà láyé ọjọ́un. Ẹgbàágbèje àwọn tó máa ń rìnrìn àjò lọ sílẹ̀ mímọ́ ló máa ń ya wọ ìlú Éfésù lóṣù March àti April lọ́dọọdún láti wá ṣayẹyẹ àjọ̀dún fún Átẹ́mísì. Báwọn àlejò ṣe máa ń ya bo ojúbọ náà jẹ́ káwọn ará Éfésù ronú pé ó yẹ káwọn máa ṣàwọn nǹkan táwọn tó ń bọ òrìṣà Átẹ́mísì á máa lò, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàwọn nǹkan táwọn àlejò á máa rà lọ sílé, àwọn nǹkan tí wọ́n lè wọ̀ sára láti fi dáàbò bo ara wọn tàbí èyí tí wọ́n á máa fi rúbọ sí òrìṣà Átẹ́mísì nígbà tí wọ́n bá délé. Àwọn ọ̀rọ̀ táwọn tó ń ṣèwádìí rí lára àwọn ògiri tó wà nílùú Éfésù jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn aráàlú Éfésù máa ń fi wúrà àti fàdákà ṣe ère Átẹ́mísì, wọ́n sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà tó wà níbẹ̀ lẹ́gbẹ́ tiwọn.

Pọ́ọ̀lù kọ́ wọn pé àwọn ère “tí a fi ọwọ́ ṣe kì í ṣe ọlọ́run.” (Ìṣe 19:26) Nítorí náà, àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà wò ó pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ gbàjẹ lẹ́nu àwọn, ni wọ́n bá dá rògbòdìyàn sílẹ̀ láti fi pa Pọ́ọ̀lù lẹ́nu mọ́. Ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà náà tó ń jẹ́ Dímẹ́tíríù sọ nǹkan tó ń bà wọ́n lẹ́rù, ó sọ pé: “Ewu ń bẹ, kì í ṣe kìkì pé iṣẹ́ àjókòótì tiwa yìí yóò wá di aláìníyì nìkan ni, ṣùgbọ́n pé tẹ́ńpìlì ńlá ti abo ọlọ́run Átẹ́mísì pẹ̀lú ni a ó kà sí asán àti pé ọlá ńlá rẹ̀ pàápàá, èyí tí gbogbo àgbègbè Éṣíà àti ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ń jọ́sìn ni a máa tó sọ di asán.”—Ìṣe 19:27.