Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ọjọ́ Ikú Mi Ò Tíì Pé”

“Ọjọ́ Ikú Mi Ò Tíì Pé”

“Ọjọ́ Ikú Mi Ò Tíì Pé”

Ọkọ̀ kan tí wọ́n fi ń kó pàǹtí yawọ́ mọ́ dírẹ́bà lọ́wọ́. Ló bá yà bàrà lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó ń rìn lọ jẹ́jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì. Ó sì kọ lu tọkọtìyàwó kan àtọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23]. Ìwé ìròyìn kan tí wọ́n ń tẹ̀ jáde nílùú New York sọ pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni tọkọtìyàwó yẹn gbẹ́mìí mì tí ọmọkùnrin yẹn sì dá kú lọ gbári. Nígbà tọ́mọkùnrin yẹn máa ta jí tó sì wá mohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Àbí mò ń lálàá ni kẹ̀, Ọlọ́run jọ̀ọ́ wá gbà mí o! Ọjọ́ ikú mi ò tíì pé.”

Ó ṢEÉ ṢE kó o ti gbọ́ irú ìtàn yìí rí. Tó bá jẹ́ pé díẹ̀ ló kù kẹ́nì kan bá jàǹbá kan lọ, àwọn èèyàn á ní, ‘ọjọ́ ikú ẹ̀ ni ò tíì pé,’ àmọ́ téèyàn kan bá kú ikú òjijì nínú jàǹbá kan tọ́pọ̀ èèyàn ò rò tẹ́lẹ̀, wọ́n á ní, ‘Àsìkò ẹ̀ ló tó’ tàbí kí wọ́n sọ pé ‘Àmúwá Ọlọ́run ni.’ Yálà wọ́n sọ pé kádàrá tẹ́ni yẹn fọwọ́ ara ẹ̀ yàn látọ̀run wá ni àbí wọ́n pè é ní àmúwá Ọlọ́run, nǹkan kan náà ló túmọ̀ sí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé kò sí nǹkan kan táwọn lè ṣe sáwọn nǹkan tó bá ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé àwọn torí pé àyànmọ́ ò gbóògùn. Kì í wulẹ̀ ṣe ìgbà táwọn èèyàn bá kú tàbí tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ nìkan làwọn èèyàn sábà máa ń rò bẹ́ẹ̀, ọjọ́ sì ti pẹ́ táwọn èèyàn ti nírú ìgbàgbọ́ yìí.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará Bábílónì láyé ọjọ́un gbà gbọ́ pé báwọn ìràwọ̀ ṣe ń gbéra láti ibì kan lọ síbòmíì máa ń nípa lórí ìgbésí ayé àwa èèyàn. Torí náà, wọ́n sábà máa ń wojú ọ̀run kí wọ́n lè ráwọn àmì tó máa jẹ́ kí wọ́n mohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Àwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù máa ń jọ́sìn abo ọlọ́run kádàrá, wọ́n sì gbà gbọ́ pé ó lágbára láti yan ọjọ́ ọ̀la rere tàbí búburú fáwọn, àwọn ìgbà míì sì wà tóhun tó bá yàn fún wọn máa ń ta ko ohun tí Súúsì àti Júpítà, tó jẹ́ àwọn olórí òrìṣà àkúnlẹ̀bọ wọn fẹ́ kí wọ́n ṣe.

Lápá Ìlà Oòrùn Ayé, àwọn onísìn Híńdù àti Búdà gbà gbọ́ pé àwọn nǹkan tẹ́nì kan bá ti ṣe nígbà tó kọ́kọ́ wá sáyé ló máa pinnu bí ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe máa rí báyìí, bí ẹnì kan bá sì ṣe lo ìgbésí ayé ẹ̀ báyìí ló máa pinnu bí nǹkan ṣe máa rí fún un nígbà tó bá pa dà wá sáyé. Ọ̀pọ̀ ìsìn, títí kan àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ló sì gbà gbọ́ pé bọ́ràn ṣe rí gan-an nìyẹn, tórí wọ́n gbà pé kálukú ló ti yan kádàrá tiẹ̀ látọ̀run.

Kò yà wá lẹ́nu nígbà náà pé títí dòní olónìí, nínú ayé ọ̀làjú tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì gbà pé kádàrá ló ń darí ìgbésí ayé àwọn látòkèdélẹ̀, àyànmọ́ àwọn sì ni gbogbo nǹkan tó bá ń ṣẹlẹ̀ sáwọn lójoojúmọ́ àti pé ìwọ̀nba lohun táwọn lè ṣe sí i. Ṣóhun tíwọ náà rò nìyẹn? Ṣé gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sẹ́dàá láyé, bẹ̀rẹ̀ látorí bí wọ́n ṣe bí wa, àwọn àṣeyọrí tá a máa ṣe, ìjákulẹ̀ tá a máa ní àtàwọn jàǹbá tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa láyé títí dórí ọjọ́ ikú wa, ló ti wà lákọọ́lẹ̀? Ṣé kádàrá ló ń darí ìgbésí ayé ẹ? Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Látọwọ́ Ken Murray/New York Daily News