Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Gbogbo Làkókò Wà Fún

Ohun Gbogbo Làkókò Wà Fún

Ohun Gbogbo Làkókò Wà Fún

Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, àní ìgbà fún gbogbo àlámọ̀rí lábẹ́ ọ̀run.” Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba ìgbàanì tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀ tún sọ pé, ìgbà tá à ń bímọ wà àti ìgbà téèyàn máa ń kú, ìgbà tá à ń kọ́lé àti ìgbà tá à ń wó o lulẹ̀, ìgbà tá à ń nífẹ̀ẹ́ àti ìgbà tá à ń kórìíra. Nígbà tó máa parí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Kí ni àǹfààní tí ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ní nínú ohun tí ó ń ṣiṣẹ́ kárakára nídìí rẹ̀?”—Oníwàásù 3:1-9.

NÍGBÀ táwọn kan bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ yìí, wọ́n á ní ohun tí Bíbélì sọ ni pé gbogbo nǹkan tẹ́dà ń ṣe láyé ló ti wà lákọọ́lẹ̀, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ pé Bíbélì ti ẹ̀kọ́ nípa kádàrá ẹ̀dá lẹ́yìn. Ṣóòótọ́ ni? Ṣé Bíbélì kọ́ni pé kádàrá ló ń darí ìgbésí ayé ẹ̀dá? Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ò lè ta kora, ohun tá a bá kà nínú ẹsẹ Bíbélì kan gbọ́dọ̀ bá àwọn ẹsẹ míì mu torí pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì yòókù nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ lórí kókó ọ̀rọ̀ yìí.—2 Tímótì 3:16.

Ìgbà àti Ìṣẹ̀lẹ̀ Tá Ò Mọ̀ Tẹ́lẹ̀

Sólómọ́nì tún sọ nínú ìwé Oníwàásù pé: “Mo padà láti rí i lábẹ́ oòrùn pé eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára, bẹ́ẹ̀ ni ìjà ogun kì í ṣe ti àwọn alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kì í ṣe ti àwọn ọlọ́gbọ́n pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ọrọ̀ kì í ṣe ti àwọn olóye pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti àwọn tí ó ní ìmọ̀ pàápàá.” Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Sólómọ́nì ṣàlàyé pé: “Nítorí pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”—Oníwàásù 9:11.

Sólómọ́nì ò sọ pé gbogbo nǹkan táwa èèyàn ń ṣe láyé ni Ọlọ́run ti kádàrá mọ́ wa, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé àwọn èèyàn ò lè mohun tó máa jẹ́ àbájáde àwọn ìdáwọ́lé wọn látòkèdélẹ̀ torí pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ séèyàn torí pé ẹni yẹn wà níbi tó yẹ lákòókò tó yẹ kó wà níbẹ̀, tàbí kẹ̀, nǹkan búburú lè ṣẹlẹ̀ sẹ́nikẹ́ni nígbàkigbà torí pé ó ṣe kòńgẹ́ rẹ̀.

Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò gbólóhùn náà: “Eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára.” O lè ti kà tàbí kó o ti gbọ́ nípa eré ìje kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ àmọ́ tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó, ìyẹn eré ìje ẹlẹ́gbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] mítà táwọn obìnrin sá nígbà ìdíje Òlíńpíìkì tó wáyé nílùú Los Angeles, ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1984. Àwọn méjì lára àwọn obìnrin tó ń sáré yẹn, ìyẹn obìnrin tó ń ṣojú fún ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àtèyí tó ń ṣojú fún orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ń retí pé àwọn làwọ́n máa gbégbá orókè nínú ìdíje yẹn. Nígbà tí wọ́n dáàárín ọ̀nà, àwọn méjèèjì ṣèèṣì kọ lura wọn. Bí ọ̀kan nínú wọn ṣe fìdí rẹmi nìyẹn, ìkejì ẹ̀ bá sọ̀rètí nù débi pé ipò keje ló gbé nínú ìdíje yẹn.

Ṣé kádàrá wọn ló jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn obìnrin méjèèjì yìí rí bó ṣe rí yìí? Àwọn kan lè sọ pé bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́, ó ṣe kedere pé torí pé wọ́n kọ lura wọn ni ò jẹ́ káwọn méjèèjì gbégbá orókè, kò sì sẹ́ni tó lè mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹn lè ṣèèṣì wáyé. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti kádàrá ẹ̀ pé àwọn méjèèjì máa kọ lura wọn ni? Ohun táwọn kan máa sọ gan-an nìyẹn. Àmọ́, àwọn tó sọ̀rọ̀ nípa bí ìdíje yẹn ṣe lọ sọ pé báwọn eléré ìje méjèèjì, tí ò ṣeé fọwọ́ rọ́ tì sẹ́yìn wọ̀nyí ṣe sáré kíkankíkan pẹ̀lú agbára wọn tó fẹ́ẹ̀ dọ́gba, torí kí wọ́n lè borí ara wọn ló fà á tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn fi ṣèèṣì wáyé. Bí Bíbélì ṣe sọ gan-an lọ̀rọ̀ rí, “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” Kò sí bá a ṣe lè múra sílẹ̀ fáwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe sí, àwọn nǹkan kan wà téèyàn lè má ronú kàn tẹ́lẹ̀ tó ṣeé ṣe kó nípa lórí àbájáde àwọn ìdáwọ́lé wa, ìyẹn ò sì ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú kádàrá.

Kí wá nìtúmọ̀ gbólóhùn tí Bíbélì sọ yẹn pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún”? Ṣáwọn nǹkan kan wà tá a lè ṣe tó máa pinnu bí ìgbésí ayé wa ṣe máa rí?

Ìgbà Tó Yẹ Kéèyàn Ṣe Nǹkan

Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì ò sọ̀rọ̀ nípa kádàrá àwa èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni ò sọ̀rọ̀ nípa àyànmọ́ ìgbésí ayé àwa ẹ̀dá, kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe àti bó ṣe máa nípa lórí àwa èèyàn. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé ẹsẹ Bíbélì yẹn ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tí “ìgbà tí a yàn kalẹ̀” ti wà fún, ó kọ̀wé pé: “Mo ti rí iṣẹ́ àjókòótì tí Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ aráyé láti jókòó tì. Ohun gbogbo ni ó ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀.”—Oníwàásù 3:10, 11.

Sólómọ́nì mẹ́nu kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tí Ọlọ́run ti fún àwa èèyàn láǹfààní láti ṣe. Ọlọ́run tún ti fún wa lómìnira láti máa yan ohun tó bá wù wá láti ṣe. Àmọ́ ṣá ó, gbogbo nǹkan ló ti ní àkókò tàbí ìgbà tó yẹ ká ṣe é, tá a bá fẹ́ kó yọrí síbi tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí Sólómọ́nì sọ nínú ìwé Oníwàásù 3:2 nípa “ìgbà gbígbìn àti ìgbà fífa ohun tí a gbìn tu.” Àwọn àgbẹ̀ mọ̀ pé ohun ọ̀gbìn kọ̀ọ̀kan ló ti ní àkókó tó yẹn káwọn gbìn ín. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí àgbẹ̀ kan bá kọ̀ láti gbin irè oko kan nígbà tó yẹ, tó wá lọ gbìn ín nígbà tí kò yẹ? Bó bá tiẹ̀ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí irè oko yẹn lè so dáadáa, àmọ́ tí kò rí èso mú níbẹ̀, ṣé kádàrá ẹ̀ náà ló fà á? Rárá o! Òun ló kọ̀ láti gbin irè oko yẹn lákòókò tó yẹ. Bí àgbẹ̀ yẹn bá fara balẹ̀ tẹ̀ lé ètò tí Ẹlẹ́dàá ti ṣe nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí, kò ní kìka àbámọ̀ bẹnu.

Torí náà, Ọlọ́run ò yan ohunkóhun mọ́ ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kò kádàrá ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí, àmọ́ ó ti ṣètò àwọn ìlànà kan tó ń nípa lórí àwọn nǹkan táwa èèyàn bá ṣe níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. Táwa èèyàn bá fẹ́ ṣàṣeyọrí nínú àwọn nǹkan tá à ń dáwọ́ lé nígbèésí ayé wa, a gbọ́dọ̀ mohun tí Ọlọ́run fẹ́, ká sì ṣe é lákòókò tó yẹ. Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run bá ti pinnu láti ṣe nìkan làwa èèyàn ò lè yí pa dà, Ọlọ́rún ò kádàrá nǹkan kan mọ́ wa o. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:11.

“Ọ̀rọ̀” wo wá ni Ọlọ́run ti sọ, tó bá ìfẹ́ rẹ̀ nípa ayé àti ọjọ́ ọ̀la àwa èèyàn mu, tó sì máa “ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú”?

Bó O Ṣe Lè Mọ Àsìkò Ọlọ́run

Sólómọ́nì sọ nǹkan kan tó máa jẹ́ kọ́rọ̀ yìí tètè yé wa dáadáa. Lẹ́yìn tó sọ pé: “Ohun gbogbo ni [Ọlọ́run] ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀,” ó wá fi kún ọ̀rọ̀ ẹ̀ pé: “Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn, kí aráyé má bàa rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.” Bí Bibeli Yoruba Atọ́ka ṣe tú ẹsẹ Bíbélì yẹn rèé, ó ní: ‘Pẹ̀lúpẹ̀lù ó fi ayérayé sí wọn ní àyà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò lè rídìí iṣẹ́ náà tí Ọlọ́run ń ṣe láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ títí dé òpin.’—Oníwàásù 3:11.

Onírúurú ọ̀rọ̀ làwọn èèyàn ti kọ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. Àmọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé, nínú ọkàn wa lọ́hùn-ún, ó fẹ́ẹ̀ máà sí ẹnì kan nínú wa tí kò tí ì ronú rí nípa ìdí tá a fi wà láyé àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa. Látìgbà táláyé ti dáyé ni inú àwa èèyàn kì í ti í dùn sí bó ṣe jẹ́ pé lẹ́yìn gbogbo kòókòó jàn-ánjàn-án tá a bá fayé wa ṣe ikú ló pàpà máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀. Nínú gbogbo àwọn nǹkan alààyè yòókù, àwa èèyàn dá yàtọ̀ torí pé a kì í ronú nípa bá a ṣe fẹ́ gbé láyé nísinsìnyí nìkan, àmọ́ a tún ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la wa àtàwọn nǹkan tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la. Kò tiẹ̀ sẹ́ni tó fẹ́ kú nínú wa pàápàá. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, Ọlọ́run ti ‘fi ayérayé sí wa ní àyà.’

Torí pé kò sẹ́ni tó fẹ́ kú làwọn kan ṣe máa ń ronú pé èèyàn ṣì máa ń wà láàyè nìṣó níbì kan lẹ́yìn tó bá kú. Àwọn kan sọ pé ohun kan wà nínú àwa èèyàn tó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn tá a bá kú. Àwọn kan nígbàgbọ́ nínú àtúnwáyé, nígbà táwọn míì sì gbà gbọ́ pé kádàrá ló ń darí ìgbésí ayé àwa ẹ̀dá tàbí pé a ti yan àyànmọ́ wa látọ̀run, àti pé àyànmọ́ ò gbóògùn. Ó ṣeni láàánú pé, kò séyìí tó tẹ́ àwọn èèyàn lọ́rùn látòkèdélẹ̀ nínú gbogbo àwọn àlàyé wọ̀nyí. Ìdí ni pé, bí Bíbélì ṣe sọ, àwọn èèyàn ò lè tipasẹ̀ agbára wọn “rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.”

Látìgbà táláyé ti dáyé làwọn ọ̀mọ̀ràn àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ti ń sapá láti mọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó jẹ́ àwámárìídìí, àmọ́ ibi pẹlẹbẹ náà lọ̀bẹ wọn ń fi lélẹ̀. Àmọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló fi ayérayé sí wa ní àyà tíyẹn sì ń jẹ́ kó máa wù wá láti fẹ́ máa wà láàyè, ṣé kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ ẹ̀, kọ́wọ́ wa lè tẹ ohun tó wù wá yẹn? Ó ṣe tán, Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sáàmù 145:16) Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a máa ráwọn àlàyé tó máa tẹ́ wa lọ́rùn nípa ìgbésí ayé àti ikú títí kan àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fáwa èèyàn àti ilẹ̀ ayé wa lọ́jọ́ iwájú.—Éfésù 3:11.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

“Eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára.”—Oníwàásù 9:11

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Bí àgbẹ̀ kan bá kọ̀ láti gbin irè oko nígbà tó yẹ kó gbìn ín, tí kò wá méso jáde bó ṣe yẹ, ṣé kádàrá ló fà á?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

Torí pé Ọlọ́run ti ‘fi ayérayé sí wa ní àyà’ la ò ṣe fẹ́ kú