Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣénú Ọlọ́run dùn sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ awòràwọ̀?

Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé, wíwo ìràwọ̀ túmọ̀ sí “kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa bí oòrùn, òṣùpá, ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì yòókù ṣe ń yí àti bí yíyí tí wọ́n ń yí ṣe kan ìgbésí ayé àwa èèyàn.” Bí ayé ṣe ń yí oòrùn po lọ́dọọdún, ọ̀ọ́kán ibi tí àgbájọ àwọn ìràwọ̀ wà ń yí pa dà tá a bá wò ó látorí ilẹ̀ ayé. Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń kíyè sí bí ọ̀ọ́kán ibi táwọn ìràwọ̀ wọ̀nyí wà ṣe máa ń yí pa dà, tí wọ́n sì máa ń sọ pé àwọn ìyípadà wọ̀nyẹn láwọn ìtumọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ará Bábílónì àtijọ́ ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wòràwọ̀, àwọn ni wọ́n sọ àwọn ìràwọ̀ kan àtàwọn àgbájọ ìràwọ̀ di òòṣà àkúnlẹ̀bọ. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà bẹ̀rẹ̀ sí í wòràwọ̀ nígbà tí wọ́n pa ìjọsìn tòótọ́ tì. Nígbà tó sì fi máa dìgbà tí Jòsáyà jọba ní Jùdíà wíwòràwọ̀ ti wá gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé òun ò fọwọ́ sírú ìjọsìn bẹ́ẹ̀. Òfin Mósè, tó ti wà lákọọ́lẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ti sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá lọ jọ́sìn ìràwọ̀ èyíkéyìí ni wọ́n gbọ́dọ̀ sọ lókùúta pa.—Diutarónómì 17:2-5.

Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí Jòsáyà Ọba ṣe káwọn ará Jùdíà lè máa ṣèjọsìn tòótọ́ ni àṣẹ tó pa pé, ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ rúbọ “sí oòrùn àti sí òṣùpá àti sí àwọn àgbájọ ìràwọ̀ sódíákì àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run.” Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ ìdí tí Jòsáyà Ọba fi pàṣẹ yìí, ó ní torí pé ó fẹ́ máa “tọ Jèhófà lẹ́yìn,” ó sì fẹ́ máa “pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (2 Àwọn Ọba 23:3-5) Àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn jẹ́ fáwọn tó ṣe tán láti sin Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” lóde òní pẹ̀lú.—Jòhánù 4:24.

Àwọn wo ni “Àwọn Ọmọ Súúsì” tí ìwé Ìṣe 28:11 sọ̀rọ̀ nípa wọn?

Ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì sọ pé ère “Àwọn Ọmọ Súúsì” wà lára ọkọ̀ òkun kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wọ̀ láti Málítà lọ sí Pútéólì. (Ìṣe 28:11) Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn atukọ̀ òkun láyé ìgbà yẹn ló máa ń gbé ère yìí síwájú ọkọ̀ òkun wọn, àwọn arìnrìn àjò náà sì nífẹ̀ẹ́ sí wọn.

Nínú ìtàn àròsọ kan táwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù máa ń sọ, wọ́n ní Súúsì (tí wọ́n tún ń pè ní Júpítà) àti Lídà bí ìbejì, orúkọ àwọn ọmọkùnrin méjèèjì sì ni Kásítọ̀ àti Pólúsì. Wọ́n ní ògbóǹtarìgì atukọ̀ òkun tó lágbára lórí ẹ̀fúùfù àti ìgbì òkun ni “Àwọn Ọmọ Súúsì” méjèèjì yìí. Bí wọ́n ṣe sọ àwọn méjèèjì dòòṣà àkúnlẹ̀bọ táwọn atukọ̀ òkun ń júbà fún nìyẹn. Àwọn tó máa ń rìnrìn àjò lórí omi sábà máa ń rúbọ sí wọn. Nígbà tí ìjì bá sì ń jà, wọ́n sábà máa ń gbàdúrà pé kí wọ́n dáàbò bo àwọn. Àwọn atukọ̀ àtàwọn tó sábà máa ń rìnrìn àjò lórí òkun gbà pé àwọn òòṣà àkúnlẹ̀bọ tí wọ́n jẹ́ ìbejì wọ̀nyí ló máa ń fagbára wọn hàn nígbà tí iná Ẹlímósì Mímọ́ bá yọ, ìyẹn ni iná tó máa ń tàn lórí ìgbòkun ọkọ̀ òkun lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nígbà tí ìjì bá ń jà.

Àwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù ìgbàanì sábà máa ń jọ́sìn Kásítọ̀ àti Pólúsì, ìwé àtijọ́ kan sì sọ pé òrìṣà yìí ò ṣàjèjì láwọn àgbègbè tó wà nítòsí Kírénè ní Àríwá Ilẹ̀ Áfíríkà. Ìlú Alẹkisáńdíríà, lórílẹ̀-èdè Íjíbítì ni ọkọ̀ òkun tí ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ti wá.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Òkúta táwọn ará Bábílónì gbẹ́ láti fi ṣèrántí Nasimárútáṣì Ọba àtàwọn àgbájọ ìràwọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Owó ẹyọ Dínárì tí wọ́n ya “àwọn Ọmọ Súúsì” sí, 114-113 Ṣ.S.K.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]

Òkúta: Látọwọ́ Réunion des Musées Nationaux/Art Resource, NY; owó ẹyọ: Látọwọ́ Classical Numismatic Group, Inc./cngcoins.com