Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lásárù Jíǹde!

Lásárù Jíǹde!

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Lásárù Jíǹde!

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bóhun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JÒHÁNÙ 11:1-45.

Nígbà tó o ka ẹsẹ 21 àti 32, báwo lo ṣe rò pé ọ̀rọ̀ ikú àbúrò wọn ṣe dun Màtá àti Màríà tó?

․․․․․

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní ẹsẹ 33 àti 35, báwo lo ṣe máa fojúunú yàwòrán bínú Jésù ṣe bà jẹ́ tó?

․․․․․

Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Lásárù tàbí ọ̀kan lára àwọn tọ́rọ̀ náà ṣojú ẹ̀, báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ ní ẹsẹ 43 àti 44 ṣe máa rí lára ẹ.

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Ìrìn àjò ọjọ́ méjì ni ìlú Bẹ́tánì sí ibi tí Jésù wà. Kí ló wá dé tí Jésù fi pẹ́ kó tó débẹ̀? (Tún ka ẹsẹ 6.)

․․․․․

Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Màríà àti Màtá nífẹ̀ẹ́ sí ohunkóhun tó bá ti jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run? (Lúùkù 10:38, 39; Jòhánù 11:24)

․․․․․

Kí nìdí tí Jésù fi jí àwọn èèyàn dìde, nígbà tó jẹ́ pé wọ́n ṣì tún máa kú? (Máàkù 1:41, 42; Jòhánù 5:28, 29; 11:45)

․․․․․

MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. KỌ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Bí Jésù ṣe lágbára tó àti bó ṣe fẹ́ láti jí òkú dìde.

․․․․․

Bí àánú àwọn tí èèyàn wọn ṣaláìsí ṣe máa ń ṣe Jésù.

․․․․․

TA NI WÀÁ FẸ́ RÍ TÀBÍ TÍ WÀÁ TÚN FẸ́ KẸ́ Ẹ JỌ WÀ PA PỌ̀ NÍGBÀ ÀJÍǸDE?

․․․․․

KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN INÚ BÍBÉLÌ YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․