Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tẹjú Mọ́ Èrè Náà

Tẹjú Mọ́ Èrè Náà

Tẹjú Mọ́ Èrè Náà

“Mo ń lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje.”—FÍLÍ. 3:14.

1. Èrè wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń retí lọ́jọ́ iwájú?

 ILÉ ọlá ni wọ́n bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó tún ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù ará Tásù sí. Ó kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn àwọn babańlá rẹ̀, gbajúgbajà olùkọ́ Òfin Mósè tó ń jẹ́ Gàmálíẹ́lì ló sì kọ́ ọ. (Ìṣe 22:3) Ẹni ńlá ni Pọ́ọ̀lù ì bá dà láyé ká ló dúró lójú ọ̀nà tí wọ́n fẹsẹ̀ rẹ̀ lé ni, àmọ́ ó pa ẹ̀sìn ìdílé rẹ̀ tì, ó sì di Kristẹni. Ó wá ń retí èrè ìyè àìnípẹ̀kun tó máa rí gbà lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn ni pé ó máa di ọba àti àlùfáà tí kò lè kú nínú Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run. Ìjọba yẹn ni yóò ṣàkóso Párádísè ilẹ̀ ayé.—Mát. 6:10; Ìṣí. 7:4; 20:6.

2, 3. Báwo ni èrè ìyè ní ọ̀run ti ṣeyebíye tó lójú Pọ́ọ̀lù?

2 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ bí èrè yẹn ti ṣeyebíye tó lójú òun, ó ní: “Àwọn ohun tí ó jẹ́ èrè fún mi, ìwọ̀nyí ni mo ti kà sí àdánù ní tìtorí Kristi. Họ́wù, ní ti èyíinì, ní tòótọ́ mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi. Ní tìtorí rẹ̀, èmi ti gba àdánù ohun gbogbo, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí.” (Fílí. 3:7, 8) Àwọn nǹkan tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn kà sí pàtàkì, irú bí ipò, ọlá, dídi ẹni ńlá àti olókìkí, ni Pọ́ọ̀lù kà sí pàǹtírí lẹ́yìn tó ti kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó sì ti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún aráyé.

3 Látìgbà yẹn lọ, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ lójú Pọ́ọ̀lù ni ìmọ̀ ṣíṣeyebíye nípa Jèhófà àti Kristi, èyí tí Kristi sọ nínú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọ́run pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòh. 17:3) Bó ṣe wu Pọ́ọ̀lù tó láti rí ìyè àìnípẹ̀kun hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ tó sọ ní Fílípì 3:14 pé: “Mo ń lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù.” Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù tẹjú mọ́ èrè ìyè àìnípẹ̀kun tó máa rí gbà lọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn tó máa ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run.

Bí Ìyè Àìnípẹ̀kun Ṣe Máa Rí Lórí Ilẹ̀ Ayé

4, 5. Èrè wo ló ń bẹ níwájú fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lónìí?

4 Ní ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó pinnu láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n mọ̀ pé èrè tó yẹ káwọn sa gbogbo ipá àwọn láti rí gbà ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun Ọlọ́run. (Sm. 37:11, 29) Jésù fi hàn pé èrè tí wọ́n ń retí yìí dájú. Ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mát. 5:5) Sáàmù 2:8 fi hàn pé Jésù fúnra rẹ̀ ni olórí ajogún ayé, àmọ́ àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yóò bá Jésù jọba lọ́run. (Dán. 7:13, 14, 22, 27) Orí ilẹ̀ ayé ni àwọn ẹni bí àgùntàn tó máa wà láyé yóò ti “jogún” Ìjọba Ọlọ́run ‘tí a ti pèsè sílẹ̀ fún wọn láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.’ (Mát. 25:34, 46) Ohun tó mú kí èyí dá wa lójú ni pé Ọlọ́run tó ṣèlérí rẹ̀ “kò lè purọ́.” (Títù 1:2) A ní irú ìdánilójú tí Jóṣúà ní, pé Ọlọ́run á mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ìdánilójú yìí ló mú kó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.”—Jóṣ. 23:14.

5 Ìgbé ayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run kò ní máa bani nínú jẹ́ bíi ti ayé ìsinsìnyí. Nǹkan máa yàtọ̀ níbẹ̀ gan-an ni. Kò ní sí ogun, ìwà ọ̀daràn, ipò òṣì, àìsí ìdájọ́ òdodo, àìsàn àti ikú mọ́. Àwọn èèyàn yóò ní ìlera pípé nígbà yẹn, wọn yóò sì máa gbé lórí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ti sọ di Párádísè. Nígbà yẹn, ìgbésí ayé á gbádùn mọ́ wa ju bá a ṣe lè rò lọ. Dájúdájú, ojoojúmọ́ la ó máa ní inú dídùn kíkọyọyọ. Ẹ ò rí i pé èrè àgbàyanu nìyẹn jẹ́!

6, 7. (a) Kí ni Jésù ṣe tó jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nínú ayé tuntun Ọlọ́run? (b) Kí ló máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn tó ti kú láti tún bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé lákọ̀tun?

6 Nígbà tí Jésù wà lorí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run fún un ní ẹ̀mí mímọ́, èyí tó jẹ́ kó lágbára láti fi díẹ̀ hàn wá lára àwọn ohun àgbàyanu tó máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé nínú ayé tuntun. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ fún ọkùnrin kan tó ti yarọ fún ọdún méjìdínlógójì pé kó dìde kó máa rìn. Bíbélì ròyìn pé ọkùnrin náà sì rìn. (Ka Jòhánù 5:5-9.) Ìgbà kan tún wà tí Jésù bá “ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí” pàdé, ó sì wò ó sàn. Nígbà tó ṣe, àwọn èèyàn béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tó fojú tẹ́lẹ̀ rí náà nípa Ẹni tó wò ó sàn, ohun tó fi dáhùn ni pé: “Láti ìgbà láéláé, a kò gbọ́ ọ rí pé ẹnikẹ́ni la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú. Bí kì í bá ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí ti wá, kò ní lè ṣe nǹkan kan rárá.” (Jòh. 9:1, 6, 7, 32, 33) Ohun tó mú kí Jésù lè ṣe gbogbo èyí ni pé Ọlọ́run fún un lágbára. Ibi gbogbo tí Jésù lọ ló ti ń “mú àwọn tí wọ́n nílò ìwòsàn lára dá.”—Lúùkù 9:11.

7 Yàtọ̀ sí pé Jésù lè mú àwọn aláìsàn àtàwọn aláàbọ̀ ara lára dá, ó tún lè jí àwọn òkú dìde. Bí àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjìlá kan kú, èyí sì fa ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ fáwọn òbí rẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé: “Omidan, mo wí fún ọ, Dìde!” Ó sì dìde! Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ayọ̀ àwọn òbí ọmọ náà àtàwọn yòókù tó wà níbẹ̀ ṣe pọ̀ tó? (Ka Máàkù 5:38-42.) Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, ‘ayọ̀ tó pọ̀ jọjọ’ yóò wà nígbà tí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn bá jíǹde, nítorí “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15; Jòh. 5:28, 29) Àwọn èèyàn náà yóò tún bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé lákọ̀tun, wọn yóò sì láǹfààní láti lè máa wà nìṣó, àní títí láé.

8, 9. (a) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù? (b) Kí la fi máa ṣèdájọ́ àwọn òkú tó bá jíǹde?

8 Kì í ṣe torí káwọn tó jíǹde yìí bàa lè wá gba ìdájọ́ ìparun ni Ọlọ́run ṣe jí wọn dìde. Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó kú kọ́ ni wọ́n máa wá jẹ nígbà tí wọ́n bá jíǹde. (Róòmù 6:7) Bí aráyé bá ṣe ń jàǹfààní ẹbọ ìràpadà náà láàárín Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà tó jẹ́ onígbọràn yóò dẹni pípé, wọ́n á sì bọ́ pátápátá lọ́wọ́ gbogbo ìjìyà tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà. (Róòmù 8:21) Jèhófà “yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” (Aísá. 25:8) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún sọ pé a óò “ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀,” tó fi hàn pé àwọn tó máa wà láàyè nígbà yẹn yóò gba ìsọfúnni tuntun. (Ìṣí. 20:12) Nígbà tí ilẹ̀ ayé yìí bá di Párádísè, “òdodo ni àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso yóò kọ́ dájúdájú.”—Aísá. 26:9.

9 Ohun táwọn tó jíǹde bá ṣe lẹ́yìn àjíǹde la fi máa ṣèdájọ́ wọn, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. Ìṣípayá 20:12 sọ pé: “A sì ṣèdájọ́ àwọn òkú láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn,” ìyẹn ohun tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí wọ́n jíǹde. Ẹ ò rí i pé àgbàyanu ni àpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo, àánú àti ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn yìí! Láfikún síyẹn, Bíbélì sọ pé àwọn ohun ìbànújẹ́ tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ìgbésí ayé wọn tẹ́lẹ̀ “kì yóò . . . wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà” wọn mọ́. (Isa. 65:17) Bí wọ́n á ṣe máa kọ́ àwọn ohun tuntun, tí ìgbésí ayé sì kún fún ohun rere, àwọn ohun búburú tó ti ṣẹlẹ̀ nígbà àtijọ́ kò ní máa bà wọ́n nínú jẹ́ mọ́. Wọ́n á gbàgbé àwọn ohun búburú tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn tẹ́lẹ̀ rí. (Ìṣí. 21:4) Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tó máa la Amágẹ́dọ́nì já.—Ìṣí. 7:9, 10, 14.

10. (a) Báwo ni ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú ayé tuntun Ọlọ́run? (b) Kí ló máa jẹ́ kó o lè tẹjú mọ́ èrè náà?

10 Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, àwọn èèyàn yóò máa gbé láìní ṣàìsàn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní kú mọ́. “Kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísá. 33:24) Níkẹyìn, àwọn olùgbé ayé tuntun yóò máa jí lójoojúmọ́ pẹ̀lú ìlera pípé, tí wọ́n á sì máa rí i pé ojúmọ́ ire ló ń mọ́ fáwọn. Gbogbo ìdáwọ́lé wọn lá máa já sí ayọ̀, wọ́n á sì rí i pé gbogbo ẹni tó yí àwọn ká ló fẹ́ àwọn fẹ́ ire. Ẹ̀bùn àgbàyanu mà ni irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ o! O ò ṣe ṣí Bíbélì rẹ sí Aísáyà 33:24 àti 35:5-7 kó o wo àwọn asọtẹ́lẹ̀ tó wà níbẹ̀. Fojú inú wò ó pé o wà níbi táwọn nǹkan tó ò ń kà yẹn ti ń ṣẹlẹ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ wàá lè tẹjú mọ́ èrè náà.

Àwọn Tí Kò Tẹjú Mọ́ Èrè Náà

11. Ṣàlàyé bí Sólómọ́nì ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ lọ́nà tó dára.

11 Tá a bá ti mọ èrè náà, a ní láti sa gbogbo ipá wa láti tẹjú mọ́ ọn, kí ọkàn wa máa bàa kúrò lórí rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Sólómọ́nì di ọba Ísírẹ́lì àtijọ́, ó fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún òun ní òye àti ìfòyemọ̀ tóun á fi máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. (Ka 1 Ọba 3:6-12.) Bíbélì sì fi hàn pé Ọlọ́run dáhùn àdúrà náà, ó ní: “Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye ní ìwọ̀n púpọ̀ gidigidi.” Ní tòótọ́, “ọgbọ́n Sólómọ́nì sì pọ̀ jaburata ju ọgbọ́n gbogbo àwọn Ará Ìlà-Oòrùn àti ju gbogbo ọgbọ́n Íjíbítì.”—1 Ọba 4:29-32.

12. Kí ni Jèhófà sọ pé àwọn tó bá di ọba nílẹ̀ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ ṣe?

12 Àmọ́, Jèhófà ti kìlọ̀ ṣáájú pé ẹni tó bá di ọba nílẹ̀ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ “mú ẹṣin pọ̀ sí i fún ara rẹ̀,” àti pé kò “gbọ́dọ̀ sọ aya di púpọ̀ fún ara rẹ̀, kí ọkàn-àyà rẹ̀ má bàa yà kúrò.” (Diu. 17:14-17) Tí ọba kan bá ń kó ẹṣin jọ, ńṣe ló máa fi hàn pé ohun ìjà lòun gbẹ́kẹ̀ lé láti dáàbò bo orílẹ̀-èdè òun dípò kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó jẹ́ Ọba Aláàbò. Tó bá sì ń kó aya jọ, ó léwu gan-an nítorí ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn ìyàwó rẹ̀ jẹ́ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè kèfèrí abọ̀rìṣà tó wà láyìíká àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn aya yẹn sì lè mú kí ọba náà fi ìjọsìn Jèhófà sílẹ̀.

13. Kí ló fi hàn pé Sólómọ́nì kò mọrírì gbogbo ohun tí Ọlọ́run ṣe fún un?

13 Sólómọ́nì kò fetí sí ìkìlọ̀ wọ̀nyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Jèhófà ní káwọn ọba má ṣe gan-an ló ṣe. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹṣin àtàwọn ẹlẹ́ṣin ló kó jọ. (1 Ọba 4:26) Ó tún wá ní ọgọ́rùn-ún méje aya àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta wáhàrì, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì jẹ́ ọmọ àwọn orílẹ̀-èdè kèfèrí tó wà láyìíká wọn. Àwọn obìnrin wọ̀nyí “tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn; ọkàn-àyà rẹ̀ kò sì pé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà.” Àwọn àjèjì obìnrin ilẹ̀ kèfèrí tí Sólómọ́nì fẹ́ sílé yìí wá ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìjọsìn èké tó ń kóni nírìíra. Nítorí èyí, Jèhófà sọ pé òun á “fa ìjọba náà ya kúrò lọ́wọ́” Sólómọ́nì.—1 Ọba 11:1-6, 11.

14. Kí ni àìgbọràn Sólómọ́nì àti ti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì yọrí sí?

14 Sólómọ́nì Ọba kò fi àǹfààní ńlá tó ní sọ́kàn mọ́, ìyẹn àǹfààní ṣíṣojú fún Ọlọ́run tòótọ́. Ó kira bọ ìjọsìn èké pátápátá. Ohun tó sì ṣe yẹn sọ orílẹ̀-èdè náà di apẹ̀yìndà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, èyí sì mú kí orílẹ̀-èdè náà pa run ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù tún bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn tòótọ́ nígbà tó yá, síbẹ̀ lẹ́yìn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́fà sígbà náà, ìpẹ̀yìndà wọn bá wọn débi tí Jésù fi sọ fún wọn pé: “A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ sí wọn gan-an nìyẹn. Jésù sọ pé: “Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Mát. 21:43; 23:37, 38) Nítorí ìwà àìṣòótọ́ táwọn ará orílẹ̀-èdè náà hù, wọ́n sọ àǹfààní ńlá tí wọ́n ní láti máa ṣojú Ọlọ́run tòótọ́ nù. Lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù tó ṣẹ́ kù sì di ẹrú.

15. Mẹ́nu kan àwọn èèyàn kan tí wọ́n jẹ́ kí ọkàn wọn kúrò lórí ohun tó ṣe pàtàkì.

15 Júdásì Ísíkáríótù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù méjìlá. Júdásì ti fetí ara rẹ̀ gbọ́ àwọn àgbàyanu ẹ̀kọ́ Jésù, ó sì ti fojú ara rẹ̀ rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mú kí Jésù ṣe. Síbẹ̀, Júdásì kò ṣọ́ ọkàn rẹ̀. Ìkáwọ́ rẹ̀ ni àpótí owó tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá ń lò wà. Bíbélì sọ pé: “Olè ni, àti pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àpótí owó wà, a sì máa kó àwọn owó tí a fi sínú rẹ̀ lọ.” (Jòh. 12:6) Júdásì bá ìwọra rẹ̀ dójú ẹ̀ nígbà tó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí àlùfáà alágàbàgebè láti da Jésù nítorí ọgbọ̀n owó fàdákà. (Mát. 26:14-16) Ẹlòmíì tí kò tẹjú mọ́ èrè náà ni Démà tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ Pọ́ọ̀lù. Démà kò ṣọ́ ọkàn rẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Démà ti ṣá mi tì nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”—2 Tím. 4:10; ka Òwe 4:23.

Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Lèyí Jẹ́ fún Gbogbo Wa

16, 17. (a) Báwo ni àtakò tó dojú kọ wá ṣe lágbára tó? (b) Kí la gbẹ́kẹ̀ lé láti lè dènà ohunkóhun tí Sátánì bá gbé kò wá?

16 Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní láti máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì, nítorí Bíbélì sọ fún wa pé: “Wàyí o, nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.” (1 Kọ́r. 10:11) Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan búburú yìí la wà báyìí.—2 Tím. 3:1, 13.

17 Sátánì Èṣù, “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” mọ̀ pé “sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (2 Kọ́r. 4:4; Ìṣí. 12:12) Gbogbo agbára rẹ̀ ló máa fẹ́ sà láti tan àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ká lè tàpá sí ìlànà Kristẹni. Òun ló ń darí ayé yìí àti gbogbo ohun tí ayé ń lò láti fi gbé ìsọfúnni jáde. Àmọ́, àwa èèyàn Jèhófà ní ohun kan tó lágbára ju gbogbo ìyẹn lọ. A ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7) Agbára tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run yìí la gbẹ́kẹ̀ lé láti lè dènà ohunkóhun tí Sátánì bá gbé kò wá. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo, ká sì ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”—Lúùkù 11:13.

18. Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ayé ìsinsìnyí?

18 Ohun míì tó ń fún wa níṣìírí ni mímọ̀ tá a mọ̀ pé Ọlọ́run yóò pa gbogbo ètò Sátánì run láìpẹ́, tí àwa Kristẹni tòótọ́ yóò sì yè bọ́. Bíbélì sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòh. 2:17) Lójú ohun tí Bíbélì sọ yìí, ẹ ò ri pé ìwà òmùgọ̀ pátápátá ló jẹ́ fún ọ̀kan lára àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó bá rò pé ohun kan tún wà nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí yìí tó ṣeyebíye ju àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà lọ! Ayé tí Sátánì ń ṣàkóso yìí dà bí ọkọ̀ tó ń rì lójú agbami, àmọ́ Jèhófà ti pèsè ìjọ Kristẹni fún wa gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ tó máa gbé wa dé èbúté ayọ̀. Bá a ṣe wà lójú ọ̀nà ayé tuntun yìí, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí yìí pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Sm. 37:9) Nítorí náà, tẹ ojú rẹ mọ́ èrè àgbàyanu yìí!

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi ń wo èrè tó ń retí lọ́jọ́ iwájú?

• Kí la fi máa ṣèdájọ́ àwọn tí yóò wà láàyè títí láé?

• Kí ló bọ́gbọ́n mu pé kó o ṣe báyìí?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Nígbà tó o bá ń ka àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì, ǹjẹ́ ò ń fojú inú rí ara rẹ bí ẹni tó gba èrè náà?