Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé “Ábà, Baba” nígbà tó ń gbàdúrà sí Jèhófà?

Tá a bá tú ʼab·baʼʹ tó jẹ́ ọ̀rọ̀ èdè Árámáíkì sí èdè Yorùbá, ó lè túmọ̀ sí “bàbá ò.” Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ̀rọ̀ yìí fara hàn nínú Ìwé Mímọ́, inú àdúrà sí Jèhófà tó jẹ́ Bàbá wa ọ̀run ni wọ́n sì ti lò ó. Kí nìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé: “Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn ọmọ sábà máa ń sọ pé ʼabbāʼ nígbà tí wọ́n bá ń bá bàbá wọn sọ̀rọ̀, ìyẹn fi hàn pé àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín àwọn àti bàbá wọn, ó sì tún fi hàn pé àwọn ọmọ wọ̀nyẹn bọ̀wọ̀ fún bàbá wọn.” Ọ̀rọ̀ yìí ń fi hàn pé ọmọ àti bàbá nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, ó sì wà lára àwọn ọ̀rọ̀ táwọn ọmọdé kọ́kọ́ máa ń kọ́. Ìgbà tí Jésù ń gbàdúrà àtọkànwá sí Bàbá rẹ̀ ló lo ọ̀rọ̀ yìí. Jésù lo “Ábà, Baba” nínú àdúrà tó gbà sí Jèhófà nínú ọgbà Gẹtisémánì, nígbà tó ku nǹkan bíi wákàtí mélòó kan kí wọ́n pa á.—Máàkù 14:36.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ yẹn tún sọ pé: “Bóyá la máa rí ọ̀rọ̀ náà ʼabbāʼ nínú àwọn ìwé táwọn Júù kọ nígbà tí ọ̀làjú orílẹ̀-èdè Gíríìsì àti Róòmù gbayé kan, ìdí sì ni pé ṣe ló máa dà bí àfojúdi láti lo ọ̀rọ̀ yìí nígbà téèyàn bá ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.” Àmọ́, “bí Jésù ṣe lo ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń gbàdúrà tún jẹ́rìí sí i pé àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín òun àti Ọlọ́run ṣàrà ọ̀tọ̀.” Inú àwọn ìwé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ la ti rí ibi méjì yòókù tí “Ábà” ti wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́, èyí sì fi hàn pé àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìsìn Kristẹni pàápàá máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà.—Róòmù 8:15; Gálátíà 4:6.

Kí nìdí tí wọ́n fi kọ apá kan Bíbélì lédè Gíríìkì?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ìkáwọ́ àwọn Júù ni “àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run” wà. (Róòmù 3:1, 2) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé èdè Hébérù, ìyẹn èdè àwọn Júù, ni wọ́n fi kọ èyí tó pọ̀ jù lọ nínú apá àkọ́kọ́ lára Bíbélì. Àmọ́ èdè Gíríìkì ni wọ́n fi kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni. a Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni, onírúurú èdè ìbílẹ̀ Gíríìkì tó bóde mu lásìkò yẹn làwọn sójà tó ń bá Alẹkisáńdà Ńlá ṣiṣẹ́ ń sọ, àwọn èdè wọ̀nyẹn ló sì wá para pọ̀ di Koine, ìyẹn èdè Gíríìkì tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀. Ogun àjàṣẹ́gun tí Alẹkisáńdà jà wá mú kó rọrùn gan-an láti sọ èdè Koine di èdè táwọn èèyàn ń sọ nílé lóko àti lẹ́yìn odi nígbà yẹn. Nígbà tá à ń wí yìí, àwọn Júù ò sí lójú kan náà mọ́, wọ́n ti fọ́n ká sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú. Ìdí sì ni pé èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ò pa dà sílé ní Palẹ́sìnì lẹ́yìn tí wọ́n bọ́ lóko ẹrú ní Bábílónì, lọ́gọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. Ìyẹn ni ò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn Júù mọ ojúlówó èdè Hébérù sọ mọ́ tí wọ́n sì wá dẹni tó ń sọ èdè Gíríìkì. (Ìṣe 6:1) Torí tiwọn làwọn tó mọ èdè méjèèjì yìí fi ṣe Bíbélì Septuagint, ìyẹn Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tí wọ́n tú sí Koine tó jẹ́ èdè Gíríìkì tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀.

Ìwé Dictionnaire de la Bible sọ pé èdè Gíríìkì ló ní “ọ̀rọ̀ tó pọ̀ jù lọ tó ṣeé lò lónírúurú ọ̀nà tó máa rọrùn láti yé àwọn èèyàn níbi gbogbo lágbàáyé.” Torí pé èdè Gíríìkì ní onírúurú ọ̀rọ̀ tó ṣeé lò láti fi ṣàpèjúwe onírúurú nǹkan, ìlànà gírámà tó péye àtàwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tó rọrùn láti fìyàtọ̀ sáwọn nǹkan, òun lèdè “tó rọrùn jù lọ láti fi báwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa gbà yé wọn, irú èdè yẹn la sì nílò láti fi tan ẹ̀sìn Kristẹni kálẹ̀.” Ẹ ò rí i pé ó dáa gan-an bó ṣe jẹ́ pé èdè Gíríìkì ni wọ́n fi kọ ìsọfúnni táwọn Kristẹni nílò.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Èdè Árámáíkì ni wọ́n fi kọ díẹ̀ lára Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó ṣe kedere pé èdè Hébérù ni Mátíù kọ́kọ́ fi kọ ìwé Ìhìn Rere tó ń jẹ́ orúkọ ẹ̀, ó sì lè jẹ́ pé òun fúnra ẹ̀ náà ló túmọ̀ ẹ̀ sédè Gíríìkì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àjákù ìwé àfọwọ́kọ Septuagint tí wọ́n kọ lédè Gíríìkì

[Credit Line]

Látọwọ́ Israel Antiquities Authority