Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Ti Kádàrá Wa?

Ṣé Ọlọ́run Ti Kádàrá Wa?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Ṣé Ọlọ́run Ti Kádàrá Wa?

Àwọn kan máa ń sọ pé èèyàn ti yan ọjọ́ tó máa kú látòde ọ̀run. Àwọn míì sọ pé Ọlọ́run ló máa ń kádàrá ọjọ́ ikú mọ́ọ̀yàn. Àwọn èèyàn wọ̀nyí sì tún nígbàgbọ́ pé àyànmọ́ ò gbóògùn. Ṣóhun tíwọ náà rò nìyẹn?

Wá bi ara ẹ láwọn ìbéèrè wọ̀nyí: ‘Ká sọ pé lóòótọ́ lèèyàn ò lè yí kádàrá pa dà, téèyàn bá ti yan ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i látọ̀run tàbí tí Ọlọ́run ti kádàrá ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa, kí wá nìdí tá a fi ń gbàdúrà? Tó bá sì jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run ti kádàrá ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa, kí wá nìdí tá a fi ń dáàbò bo ara wa? Kí nìdí tá a fi máa ń fi bẹ́líìtì de ara wa mọ́ àga ọkọ̀? Kí sì nìdí tá a kì í fẹ́ wakọ̀ tá a bá ti mutí?’

Kò síbi tí Bíbélì ti fọwọ́ sí i pé kéèyàn máa fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu. Bíbélì ò fìgbà kankan kọ́ wa pé kádàrá ló ń darí àwa èèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ọ̀ràn tó bá la ẹ̀mí lọ. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run pàṣẹ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ìgbátí yí òrùlé wọn tó bá tẹ́ pẹrẹsẹ ká. Ìdí ni pé, tí wọn ò bá ṣe ìgbátí yí òrùlé náà ká, ẹnì kan lè ṣèèṣì ré bọ́ látibẹ̀. Ó dájú pé, ká sọ pé Ọlọ́run ti kádàrá pé àwọn kan máa ré bọ́ látorí òrùlé tí wọ́n á sì gbabẹ̀ kú ni, kò ní fún wọn nírú àṣẹ yìí.—Diutarónómì 22:8.

Ó dáa, kí la máa sọ nípa àwọn tó kú sínú àwọn ìjábá tàbí nípa àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tágbára wọn ò ká mú ẹ̀mí wọn lọ? Ṣé ọjọ́ ikú wọn ló pé ni? Rárá kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Sólómọ́nì Ọba, tóun náà wà lára àwọn tó kọ Bíbélì jẹ́ kó ye wa pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo [wa].” (Oníwàásù 9:11) Kò sí bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe lè ṣe wá ní kàyéfì tó, òótọ́ ibẹ̀ ni pé Ọlọ́run kì í kádàrá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi mọ́ wa.

Àmọ́, àwọn kan ronú pé ọ̀rọ̀ tí Sólómọ́nì sọ yìí ta ko ohun tó sọ tẹ́lẹ̀, nígbà tó sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, àní ìgbà fún gbogbo àlámọ̀rí lábẹ́ ọ̀run: ìgbà bíbímọ àti ìgbà kíkú.” (Oníwàásù 3:1, 2) Ṣóhun tí Sólómọ́nì ń sọ ni pé òótọ́ ni Ọlọ́run máa ń kádàrá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi mọ́ wa? Ẹ jẹ́ ká fòye gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ.

Ohun tí Sólómọ́nì ń sọ kọ́ ni pé Ọlọ́run ti kádàrá ọjọ́ tí wọ́n máa bí ẹnì kan àti ọjọ́ tónítọ̀hún máa kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé, bíi gbogbo nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé ẹ̀dá, ó di dandan kí wọ́n bí èèyàn kó tó lè wà láàyè, bónítọ̀hún sì dàgbà títí, dandan ni kó kú lọ́jọ́ kan. Òótọ́ pọ́ńbélé ni pé dídùn àti kíkan lọ̀rọ̀ ilé ayé, ìyẹn sì bá ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì mu pé “ìgbà sísunkún àti ìgbà rírẹ́rìn-ín” wà. Torí náà, ohun tí Sólómọ́nì fi ń yé wa ni pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wà téèyàn ò lè yẹ̀ sílẹ̀, àwọn kan sì wà téèyàn ò rò tẹ́lẹ̀, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì ni Sólómọ́nì pè ní “gbogbo àlámọ̀rí [tó wà] lábẹ́ ọ̀run.” (Oníwàásù 3:1-8; 9:11, 12) Ibi tó wá parí ọ̀rọ̀ ẹ̀ sí ni pé, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa lójoojúmọ́ gbà wá lọ́kàn débi tá ò fi ní máa ronú nípa Ẹlẹ́dàá wa.—Oníwàásù 12:1, 13.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tó ṣókùnkùn sí Ẹlẹ́dàá wa nínú ọ̀rọ̀ ìwàláàyè àti ikú, kì í kádàrá ohunkóhun mọ́ wa. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo wa pátá ni Ọlọ́run fún láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Àmọ́ Ọlọ́run ò fi dandan mú wa láti ṣohun tó máa jẹ́ ká lè wà láàyè títí láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ ẹ̀ sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìṣípayá 22:17.

Ká sòótọ́, gbogbo wa pátá ló yẹ kó máa wù láti “gba omi ìyè” náà. Torí náà, kádàrá kọ́ ló ń pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa. Ìpinnu tá a ṣe àti ìwà àwa fúnra wa ló ń pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa.