Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Máa Ń yíhùn Pa Dà?

Ṣé Ọlọ́run Máa Ń yíhùn Pa Dà?

Ṣé Ọlọ́run Máa Ń yíhùn Pa Dà?

BÍBÉLÌ sọ nípa Ọlọ́run pé: “Kò . . . sí àyídà ìyípo òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.” Ọlọ́run pàápàá fi wá lọ́kàn balẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Jákọ́bù 1:17; Málákì 3:6) Ẹ ò rí i pé Jèhófà Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá sáwọn kan tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn, téèyàn ò sì lè gbọ́kàn lé torí bí wọ́n ṣe máa ń yíhùn pa dà!

Àmọ́, àwọn kan tó máa ń ka Bíbélì máa ń rò ó bóyá Ọlọ́run ti yí àwọn ọ̀rọ̀ kan tó sọ pa dà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan Jèhófà Ọlọ́run fáwọn Kristẹni lágbára láti máa ṣiṣẹ́ ìyanu, àmọ́ ní báyìí, kò fún wọn nírú agbára yẹn mọ́. Láyé ìgbà kan, Ọlọ́run gbà pé kí ọkùnrin kan fẹ́ ju ìyàwó kan lọ, àmọ́ kò gbà bẹ́ẹ̀ mọ́. Nínú Òfin Mósè, Jèhófà pàṣẹ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa pa Sábáàtì mọ́, àmọ́ àṣẹ náà ò sí mọ́ báyìí. Ṣáwọn àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé Ọlọ́run ti yí pa dà ni?

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó dá wa lójú pé Ọlọ́run ò fìgbà kankan yí àwọn ìlànà rẹ̀ nípa ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo pa dà. Bákàn náà, “ète ayérayé” tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa bù kún gbogbo èèyàn nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ kò tíì yí pa dà. (Éfésù 3:11) Bó o ṣe lè yí ìlérí tó o ṣe fẹ́nì kan pa dà torí bónítọ̀hún ṣe ń já ẹ kulẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa ń yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà bí ipò nǹkan bá ṣe ń yí pa dà.

Ọlọ́run tún máa ń yí ìtọ́ni tó bá fáwọn èèyàn rẹ̀ pa dà kó lè bá ipò wọn àti ohun tí wọ́n nílò mu. Kò yẹ kéyìí yà wá lẹ́nu. Kí lo rò pé ẹni tó dáńgájíá lẹ́nu iṣẹ́ fífi àwọn èèyàn mọ̀nà máa ṣe tó bá rí i pé ewu wà níwájú? Ohun to máa ṣe ni pé á sọ fáwọn èèyàn tó ń fi mọ̀nà pé kí wọ́n jẹ́ káwọn gba ọ̀nà ibòmíì tí kò ti ní séwu. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé kò ní mú àwọn èèyàn náà débi tí wọ́n ń lọ ni? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta, tó máa ń rú ọ̀pọ̀ èèyàn lójú, tá a mẹ́nu bà lókè yìí.

Kí Nìdí Tí Kò Fi Sí Iṣẹ́ Ìyanu Mọ́?

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kan lágbára láti máa ṣiṣẹ́ ìyanu? Ó ṣeé ṣe kó o rántí pé nígbà tí Ọlọ́run yan orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, iṣẹ́ ìyanu ló sábà máa ń fi jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun wà pẹ̀lú wọn. Ọlọ́run lo agbára ńlá rẹ̀ nígbà tó lo Mósè láti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì àti nígbà tó tọ́ wọn sọ́nà nínú aginjù títí wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Nígbà tí Ọlọ́run pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tì lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, tó sì dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, ó fáwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì lágbára láti máa ṣe iṣẹ́ ìyanu. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù mú ọkùnrin kan tó yarọ látìgbà tí wọ́n ti bí i lára dá, Pọ́ọ̀lù náà sì jí ọkùnrin kan tó ti kú dìde. (Ìṣe 3:2-8; 20:9-11) Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí wọ́n ṣe yẹn jẹ́ káwọn èèyàn kan tó wà láwọn orílẹ̀-èdè míì di Kristẹni. Kí wá nìdí tí iṣẹ́ ìyanu ò fi sí mọ́?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpèjúwe kan ṣàlàyé, ó ní: “Nígbà tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó, ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó; ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí mo ti wá di ọkùnrin, mo ti fi òpin sí àwọn ìwà ìkókó.” (1 Kọ́ríńtì 13:11) Ọ̀nà táwọn òbí gbà ń tọ́jú ọmọ kékeré máa ń yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe máa tọ́jú ọmọ tó ti dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá ìjọ Kristẹni lò ṣe yàtọ̀ nígbà tí ìjọ náà ti dàgbà tó sì ti kúrò ní “ìkókó.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu irú bíi sísọ èdè àjèjì tàbí sísọ àsọtẹ́lẹ̀ máa “wá sí òpin.”—1 Kọ́ríńtì 13:8.

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìkóbìnrinjọ?

Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní ìlànà tó fi lélẹ̀ fún ètò ìgbéyàwó nígbà tí Ọlọ́run sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ pé: “Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.” (Mátíù 19:5) Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí tọkọtaya wà pa pọ̀ títí láé. Àmọ́, ìgbà tí Ọlọ́run fi máa yan orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó sì fún wọn ní Òfin, ìkóbìnrinjọ ti wọ́pọ̀ gan-an láàárín wọn. Torí náà, Ọlọ́run kọ́ ló dá ìkóbìnrinjọ sílẹ̀, kò sì fún wọn níṣìírí láti máa ṣe é, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fún wọn lófin tí kò ní jẹ́ kí wọ́n ki àṣejù bọ̀ ọ́. Nígbà tí Ọlọ́run wá dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ka ìkóbìnrinjọ léèwọ̀ pátápátá.—1 Tímótì 3:2.

Jèhófà Ọlọ́run máa ń fàyè gba àwọn nǹkan kan títí tó fi máa ṣàtúnṣe sí wọn. (Róòmù 9:22-24) Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fàyè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀” láti máa ṣàwọn nǹkan kan tí kò tọ́ nínú ìgbéyàwó wọn fúngbà díẹ̀ torí “líle-ọkàn” wọn.—Mátíù 19:8; Òwe 4:18.

Kí Nìdí Tí Òfin Sábáàtì Fi Jẹ́ Fúngbà Díẹ̀?

Ọlọ́run ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa pa Sábáàtì mọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lẹ́yìn tó dá wọn sílẹ̀ ní Íjíbítì. Ó wá fi í sínú Òfin tó fún orílẹ̀-èdè náà nígbà tó yá. (Ẹ́kísódù 16:22-30; 20:8-10) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Jésù yọ̀ǹda láti fi ara rẹ̀ rúbọ, ó sì tipa báyìí fi “òpin sí . . . Òfin àwọn àṣẹ tí a fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ ṣe,” ó sì “pa ìwé àfọwọ́kọ . . . rẹ́.” (Éfésù 2:15; Kólósè 2:14) Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí Jésù fi “òpin sí” àtèyí tó ‘pa rẹ́’ ni òfin Sábáàtì, torí pé Bíbélì sọ síwájú sí i pé: “Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan ṣèdájọ́ yín nínú jíjẹ àti mímu tàbí ní ti àjọyọ̀ kan tàbí ní ti ààtò àkíyèsí òṣùpá tuntun tàbí ní ti sábáàtì.” (Kólósè 2:16) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi kọ́kọ́ fún wọn ní Òfin títí kan òfin Sábáàtì?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.” Ó wá fi kún un pé: “Nísinsìnyí tí ìgbàgbọ́ ti dé, a kò sí lábẹ́ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ . . . mọ́.” (Gálátíà 3:24, 25) Dípò tí Ọlọ́run fi máa yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà, ó lo Sábáàtì fúngbà díẹ̀ láti fi kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa ronú nípa àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn òun déédéé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà díẹ̀ ni òfin Sábáàtì fi wà, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà ń bọ̀ tí ìṣòro tó ń bá aráyé fínra ò ní sí mọ́, wọ́n á sì máa jọ́sìn Ọlọ́run.—Hébérù 4:10; Ìṣípayá 21:1-4.

Ọlọ́run Onífẹ̀ẹ́ Tó Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé

Àwọn àpẹẹrẹ tá a rí látinú Bíbélì yìí ti jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run máa ń fúnni ní onírúurú ìtọ́ni àti ìtọ́sọ́nà láwọn ìgbà tó yàtọ̀ síra. Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé ó yíhùn pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló gbégbèésẹ̀ fún àǹfààní àwọn èèyàn rẹ̀ kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí onírúuru ọ̀ràn tó yàtọ̀ síra. Bó sì ṣe rí lónìí náà nìyẹn.

Torí pé Jèhófà kì í yí àwọn ìlànà rẹ̀ pa dà, kò sígbà tá ò mohun tá a lè ṣe láti múnú rẹ̀ dùn. Yàtọ̀ síyẹn, ọkàn wa balẹ̀ pé gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pátá ló máa nímùúṣẹ. Jèhófà sọ pé: “Gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe . . . Mo ti gbé e kalẹ̀, èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.”—Aísáyà 46:10, 11.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

Ọlọ́run kò fìgbà kankan yí àwọn ìlànà rẹ̀ nípa ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo pa dà

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu máa “wá sí òpin” nígbà tó bá yá

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]

Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí tọkọtaya wà pa pọ̀ títí láé