Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ “Onítara Fún Iṣẹ́ Àtàtà”!

Jẹ́ “Onítara Fún Iṣẹ́ Àtàtà”!

Jẹ́ “Onítara Fún Iṣẹ́ Àtàtà”!

“[Jésù] fi ara rẹ̀ fúnni nítorí wa kí ó bàa lè dá wa nídè kúrò nínú gbogbo onírúurú ìwà àìlófin, kí ó sì wẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ lákànṣe mọ́ fún ara rẹ̀, àwọn onítara fún iṣẹ́ àtàtà.”—TÍTÙ 2:14.

1. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní Nísàn 10, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni nígbà tí Jésù dé tẹ́ńpìlì?

 NÍ NÍSÀN 10, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ọjọ́ mélòó kan ṣáájú ọjọ́ àjọyọ̀ Ìrékọjá. Inú àwọn èrò tó wà ní tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ń dùn, bí wọ́n ṣe ń retí ìgbà tí àjọyọ̀ máa bẹ̀rẹ̀. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí Jésù bá débẹ̀? Àwọn mẹ́ta lára àwọn tó kọ̀wé Ìhìn Rere, ìyẹn Mátíù, Máàkù àti Lúùkù ròyìn pé, Jésù lé àwọn tó ń tajà àtàwọn tó ń rajà kúrò níbẹ̀ nígbà kejì. Ó sojú tábìlì àwọn tó ń pààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tó ń ta àdàbà. (Mát. 21:12; Máàkù 11:15; Lúùkù 19:45) Ìtara tí Jésù ní ò dín kù, torí pé irú nǹkan tó ṣe lọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn náà nìyẹn.—Jòh. 2:13-17.

2, 3. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìtara Jésù ò mọ sórí fífọ tẹ́ńpìlì mọ́?

2 Àkọsílẹ̀ Mátíù fi hàn pé ìtara Jésù kò mọ sórí fífọ tẹ́ńpìlì mọ́ lọ́jọ́ yẹn. Ó tún wo àwọn afọ́jú àtàwọn arọ tó wá sọ́dọ̀ ẹ̀ sàn. (Mát. 21:14) Àkọsílẹ̀ Lúùkù tọ́ka sí àwọn iṣẹ́ míì tí Jésù ṣe. Ó sọ pé, “[Jésù] ń kọ́ni lójoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì.” (Lúùkù 19:47; 20:1) Ó hàn kedere pé Jésù lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.

3 Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Títù pé, Jésù “fi ara rẹ̀ fúnni nítorí wa kí ó bàa lè dá wa nídè kúrò nínú gbogbo onírúurú ìwà àìlófin, kí ó sì wẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ lákànṣe mọ́ fún ara rẹ̀, àwọn onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” (Títù 2:14) Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà” lónìí? Báwo làpẹẹrẹ àwọn ọba rere Júdà náà sì ṣe lè fún wa níṣìírí?

Ìtara Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù àti Kíkọ́ni

4, 5. Àwọn ọ̀nà wo làwọn ọba Júdà mẹ́rin kan gbà jẹ́ onítara fún iṣẹ́ àtàtà?

4 Ásà, Jèhóṣáfátì, Hesekáyà àti Jòsáyà ṣètò láti mú ìbọ̀rìṣà kúrò nílẹ̀ Júdà. Ásà “mú àwọn pẹpẹ ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn ibi gíga kúrò, ó sì fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ túútúú, ó sì ké àwọn òpó ọlọ́wọ̀ lulẹ̀.” (2 Kíró. 14:3) Ìtara tí Jèhóṣáfátì ní fún ìjọsìn Jèhófà jẹ́ kó ní ìgboyà láti “mú àwọn ibi gíga àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀ kúrò ní Júdà.”—2 Kíró. 17:6; 19:3. a

5 Lẹ́yìn ọjọ́ keje tí wọ́n fi ṣàjọyọ̀ Ìrékọjá tí Hesekáyà ṣètò ní Jerúsálẹ́mù, “gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a rí níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú ńlá Júdà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ túútúú, wọ́n sì ké àwọn òpó ọlọ́wọ̀ lulẹ̀, wọ́n sì bi àwọn ibi gíga àti àwọn pẹpẹ wó nínú gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti ní Éfúráímù àti Mánásè títí wọ́n fi parí.” (2 Kíró. 31:1) Ọmọ ọdún mẹ́jọ péré ni Jòsáyà nígbà tó di ọba. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ní ọdún kẹjọ ìgbà ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọmọdékùnrin, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀; ní ọdún kejìlá sì ni ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ àwọn ibi gíga àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀ àti àwọn ère fífín àti àwọn ère dídà kúrò ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù.” (2 Kíró. 34:3) Èyí fi hàn pé àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló jẹ́ onítara fún iṣẹ́ àtàtà.

6. Kí nìdí tá a fi lè fi iṣẹ́ ìwàásù wa wé ìpolongo táwọn olóòótọ́ ọba Júdà ṣe?

6 Bákan náà lóde òní, àwa náà máa ń ṣe ìpolongo láti ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké àti ìbọ̀rìṣà. Iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tá à ń ṣe ti jẹ́ ká pàdé onírúurú èèyàn. (1 Tím. 2:4) Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ilẹ̀ Éṣíà kan sọ pé, òun rántí bí màmá òun ṣe máa ń rúbọ sí oríṣiríṣi èrè tó wà nílé àwọn. Ọ̀dọ́bìnrin náà ronú pé kò séyìí tó lè jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ lára àwọn ère yẹn, torí náà ó máa ń gbàdúrà pé kóun mọ Ọlọ́run tòótọ́. Lọ́jọ́ kan, àwọn kan kanlẹ̀kùn ilé wọn, nígbà tó ṣílẹ̀kùn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló rí, wọ́n sì ṣe tán láti ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ orúkọ Ọlọ́run, tó dá yàtọ̀ náà, Jèhófà. Inú ẹ̀ dùn gan-an nígbà tó mọ òtítọ́ nípa àwọn ère! Ní báyìí, ó ti ń fìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, ó sì ń ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà.—Sm. 83:18; 115:4-8; 1 Jòh. 5:21.

7. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn olùkọ́ tó lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Júdà nígbà ìṣàkóso Jèhóṣáfátì?

7 Báwo la ṣe máa ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa kúnnákúnná tó? Ó gba àfiyèsí pé, lọ́dún kẹta ìṣàkóso Jèhóṣáfátì, ó ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ aládé márùn-ún, ọmọ Léfì mẹ́sàn-án àti àlùfáà méjì. Ó ní kí wọ́n lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà, kí wọ́n máa kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn òfin Jèhófà. Ìpolongo wọn yìí gbéṣẹ́ gan-an ni, torí pé àwọn èèyàn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù Jèhófà. (Ka 2 Kíróníkà 17:9, 10.) Táwa náà bá ń lọ wàásù lákòókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, láwọn ọjọ́ tó yàtọ̀ síra, ìyẹn lè jẹ́ ká rí onírúurú èèyàn bá sọ̀rọ̀ nínú ilé kan.

8. Báwo la ṣe lè mú iṣẹ́ ìwàásù wa gbòòrò sí i?

8 Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lákòókò yìí ló múra tán láti fi ilé wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì lọ sí àgbègbè tá a ti nílò àwọn tó ń fìtara wàásù púpọ̀ sí i. Ṣéwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn tí kò bá lè lọ síbòmíì lè gbìyànjú láti máa wàásù fáwọn tó ń sọ èdè míì ládùúgbò wọn. Arákùnrin Ron, tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin [81] kọ́ ìkíni lédè méjìlélọ́gbọ̀n [32], kó bàa lè máa wàásù fún onírúurú èèyàn tó wá látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tó ń bá pàdé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ̀. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó pàdé tọkọtaya kan tó wá láti ilẹ̀ Áfíríkà lójú pópó, ó sì kí wọn lédè Yorùbá tí wọ́n ń sọ. Wọ́n wá béèrè lọ́wọ́ Arákùnrin Ron bóyá ó ti lọ sí ilẹ̀ Áfíríkà rí. Ó sọ fún wọn pé òun ò débẹ̀ rí, wọ́n wá bi í pé báwo ló ṣe gbọ́ èdè àwọn. Bí ìwàásù ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn o. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n gba àwọn ìwé ìròyìn wa, wọ́n sì júwe ilé wọn fún un. Arákùnrin Ron wá fún ìjọ tó wà ládùúgbò yẹn ní àdírẹ́sì náà, káwọn tọkọtaya yìí lè máa gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

9. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ka Bíbélì nígbà tá a bá ń wàásù? Sọ àpẹẹrẹ kan.

9 Àwọn olùkọ́ tí Jèhóṣáfátì pàṣẹ fún pé kí wọ́n lọ káàkiri ilẹ̀ Júdà mú “ìwé òfin Jèhófà” dání. Kárí ayé làwa náà máa ń lo Bíbélì láti kọ́ àwọn èèyàn, torí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. A máa ń sapá gan-an láti ka Bíbélì fáwọn èèyàn ní tààràtà nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Arábìnrin Linda lọ wàásù nílé kan, ẹni tó bá pàdé ṣàlàyé fún un pé, ọkọ òun ní àrùn rọpárọsẹ̀, òun sì fẹ́ lọ tọ́jú ẹ̀. Ó wá kédàárò pé: “Mi ò mọ ohun tí mo fi ṣe Ọlọ́run o, tó fi jẹ́ kírú èyí ṣẹlẹ̀ sí mi.” Arábìnrin Linda wá fèsì pé: “Ǹjẹ́ o lè jẹ́ kí n fi nǹkan kan dá ẹ lójú?” Ó wá ka ìwé Jákọ́bù 1:13, ó sì ṣàlàyé fún un pé: “Ọlọ́run kọ́ ló ń fi ìpọ́njú jẹ àwa àtàwọn èèyàn wa níyà o.” Nígbà tí onílé náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú ẹ̀ dùn, ló bá dì mọ́ Arábìnrin Linda. Arábìnrin Linda wá sọ pé: “Bíbélì ni mo fi tu obìnrin náà nínú. Nígbà míì, àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a máa kà lè jẹ́ èyí tí onílé ò gbọ́ rí.” Lẹ́yìn ìjíròrò ọjọ́ náà, obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń Fi Ìtara Sin Jèhófà

10. Báwo ni Jòsáyà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni lóde òní?

10 Nínú àpẹẹrẹ Jòsáyà, a rí i pé ìgbà tó ti wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti ń ṣe ìjọsìn tòótọ́, nǹkan bí ọmọ ogún ọdún sì ni nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun ti ìbọ̀rìṣà. (Ka 2 Kíróníkà 34:1-3.) Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń fi irú ìtara bẹ́ẹ̀ hàn lóde òní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run.

11-13. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára àwọn ọ̀dọ́ tó ń fìtara sin Jèhófà lóde òní?

11 Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàlá kan tó ń jẹ́ Hannah, tó ń gbé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ èdè Faransé, gbọ́ pé wọ́n ti dá àwùjọ tó ń sọ èdè Faransé sílẹ̀ ní ìlú kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà síbi tó ń gbé. Bàbá ẹ̀ gbà láti tẹ̀ lé e lọ kí wọ́n lè lọ ṣèpàdé níbẹ̀. Ní báyìí Hannah ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, ó sì ń fìtara wàásù lédè Faransé, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè kọ́ èdè míì, kó o lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà?

12 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Rachel máa ń gbádùn fídíò tó dá lórí bá a ṣe lè máa lépa ohun tó máa gbórúkọ Ọlọ́run ga, ìyẹn Pursue Goals That Honor God. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa èrò tó ní nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà lọ́dún 1995, ó sọ pé: “Mo rò pé mò ń ṣe dáadáa gan-an nínú òtítọ́, àmọ́ lẹ́yìn tí mo wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, mo wá rí i pé mi ò tí ì ṣe tó bó ṣe yẹ. Mo ní láti sapá gidigidi kí òtítọ́ lè jinlẹ̀ nínú mi, kí n máa kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, kí n sì máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó jíire.” Nísinsìnyí, Arábìnrin Rachel ti wá rí i pé ìtara tí òun fi ń sin Jèhófà ti ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kí ló ti wá jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ó ní: “Àjọṣe èmi àti Jèhófà ti jinlẹ̀ sí i. Àdúrà mi ti túbọ̀ nítumọ̀, mò ń kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀, ó sì ń yé mi, ó sì ti túbọ̀ dá mi lójú pé òótọ́ làwọn ìtàn inú Bíbélì. Torí náà, mo máa ń gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi gan-an, bí mo sì ṣe ń rí i tí ọ̀rọ̀ Jèhófà ń tu àwọn èèyàn nínú ń múnú mi dùn.”

13 Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Luke wà lára àwọn tí fídíò míì tún ràn lọ́wọ́, èyí tó dá lórí báwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lo ìgbésí ayé wọn, ìyẹn, Young People Ask—What Will I Do With My Life? Lẹ́yìn tí Luke ti wo fídíò yìí tán, ó ní: “Ó jẹ́ kí n ṣàyẹ̀wò ohun tí mò ń fi ìgbésí ayé mi ṣe.” Ó ṣàlàyé pé: “Nígbà kan, àwọn kan kó sí mi lórí pé kí n lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, kí n bàa lè dí ọlọ́rọ̀, lẹ́yìn náà kí n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa ronú nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Irú èrò bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kéèyàn tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ńṣe ló máa ń fani sẹ́yìn nípa tẹ̀mí.” Ẹ̀yin ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ṣé ẹ lè ronú lórí bẹ́ ẹ ṣe lè lo ohun tẹ́ ẹ kọ́ níléèwé láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín túbọ̀ sunwọ̀n sí i bí Hannah ti ṣe? Tàbí kẹ́ ẹ kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ Rachel, nípa lílépa àwọn ohun tó máa bọlá fún Ọlọ́run. Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Luke, máa sá fún àwọn ewu tó ti jẹ́ ìdẹkùn fún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́.

Máa Fìtara Gba Ìkìlọ̀

14. Irú ìjọsìn wo ni Jèhófà máa ń tẹ́wọ́ gbà, kí sì nìdí tó fi máa ń ṣòro láti ṣe é?

14 Àwọn èèyàn Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ tí wọ́n bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. Aísáyà kìlọ̀ pé: “Ẹ yí padà, ẹ yí padà, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan; ẹ jáde kúrò ní àárín rẹ̀ [Bábílónì], ẹ wẹ ara yín mọ́, ẹ̀yin tí ń gbé àwọn nǹkan èlò Jèhófà.” (Aísá. 52:11) Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí Aísáyà tó kọ ọ̀rọ̀ yìí, Ásà Ọba rere fi taratara ṣe ìpolongo láti lè rí i pé òun mú ìwà pálapàla kúrò nílẹ̀ Júdà. (Ka 1 Ọba 15:11-13.) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù pé, Jésù fi ara rẹ̀ fúnni kó lè wẹ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ́, kó lè sọ wọ́n di “àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ lákànṣe, . . . àwọn onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” (Títù 2:14) Kò rọrùn láti jẹ́ oníwà mímọ́, ní pàtàkì jù lọ àwọn ọ̀dọ́, nínú ayé tí ìwà ìbàjẹ́ ti wọ́pọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, tàgbàtèwe, ló gbọ́dọ̀ jìjàkadì láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìbálòpọ̀ kó èérí bá wọn, ì báà jẹ́ èyí tó wà lára pátákó tí wọ́n fi ń polówó ọjà, nínú tẹlifíṣọ̀n, fíìmù àti ní pàtàkì jù lọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

15. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti kórìíra ohun tó burú?

15 Tá a bá ń gba ìkìlọ̀ Ọlọ́run láìjáfara, èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti kórìíra ohun tó burú. (Sm. 97:10; Róòmù 12:9) A ní láti kórìíra wíwo àwọn ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìbálòpọ̀, Kristẹni kan sọ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀, “ló máa jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ tí kò tọ́, tó máa ń fani mọ́ra.” Kéèyàn tó lè ya mágínẹ́ẹ̀tì méjì tó lẹ̀ pọ̀, èèyàn nílò agbára tó ju èyí tó so mágínẹ́ẹ̀tì méjì náà pa pọ̀. Bákan náà, ó gba ìsapá gan-an kéèyàn tó lè sá fún wíwo ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìbálòpọ̀. Àmọ́ tá a bá mọ ìpalára tí wíwò ó máa ń ṣe, ìyẹn á jẹ́ ká kórìíra ẹ̀. Arákùnrin kan sapá gidigidi kó bàa lè jáwọ́ nínú àṣà wíwó ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìbálòpọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó wá gbé kọ̀ǹpútà ẹ̀ síbi táwọn tí wọ́n jọ wà nínú ilé á ti máa rí i. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún pinnu láti jáwọ́ nínú àṣà náà, ó sì di onítara fún iṣẹ́ àtàtà. Ó tiẹ̀ tún ṣe nǹkan míì. Torí pé ó máa ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì fún iṣẹ́ tó ń ṣe, ó pinnu pé ìgbà tí ìyàwó òun bá wà lọ́dọ̀ òun nìkan lóun á máa ṣí i.

Àǹfààní Tó Wà Nínú Ìwà Rere

16, 17. Ipa wo ni ìwà rere wa lè ní lórí àwọn èèyàn? Sọ àpẹẹrẹ kan.

16 Ìwà rere táwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń hù bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà máa ń wú àwọn èèyàn lórí gan-an ni! (Ka 1 Pétérù 2:12.) Ọkùnrin kan yí èrò rẹ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa dà lẹ́yìn tó lo ọjọ́ kan ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú London láti ṣàtúnṣe ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kan tó wà níbẹ̀. Ìyàwó ẹ̀ tí Ẹlẹ́rìí kan ti ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀ kíyè sí pé ọkọ òun ti yí ìwà ẹ̀ pa dà. Kì í fẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí wọlé wọn tẹ́lẹ̀. Àmọ́ nígbà tó pa dà dé láti Bẹ́tẹ́lì, ńṣe ló ń dúpẹ́ fún ọ̀nà tí wọ́n gbà bójú tó òun. Ó sọ pé kò sẹ́ni tó sọ̀rọ̀ rírùn níbẹ̀. Gbogbo wọn ló ní sùúrù, ibẹ̀ sì tuni lára. Ohun tó wú u lórí jù lọ ni báwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láìjẹ́ pé wọ́n ń gbowó oṣù, ńṣe ni wọ́n yọ̀ǹda àkókò àti okun wọn láti máa fi ti ìhìn rere lẹ́yìn.

17 Bákan náà, àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ láti gbọ́ bùkátà ìdílé wọn kì í fi iṣẹ́ ṣeré. (Kól. 3:23, 24) Ohun tó sábà máa ń jẹ́ àbájáde èyí ni pé, iṣẹ́ kì í tètè bọ́ lọ́wọ́ wọn, torí pé àwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́ mọyì bí wọ́n ṣe ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́, wọn ò sì ní fẹ́ pàdánù wọn.

18. Báwo la ṣe lè jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà”?

18 Ara ọ̀nà tá a gbà ń fi hàn pé a ní ìtara fún ilé Jèhófà ni, gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà, ṣíṣègbọràn sáwọn ìtọ́ni rẹ̀ àti fífọwọ́ pàtàkì mú àwọn ibi ìpàdé wa. Láfikún sí i, a fẹ́ máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Yálà ọmọdé ni wá tàbí àgbà, tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wà ní mímọ́ nínú gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa, a ó ká èrè púpọ̀. A ó sì máa bá a lọ ní jíjẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà.”—Títù 2:14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ibi gíga tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbọ̀rìṣà ni Ásà mú kúrò, kì í ṣàwọn ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn Jèhófà. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n tún àwọn ibi gíga míì kọ́ lọ́wọ́ ìparí ìṣàkóso Ásà, kó wá jẹ́ pé Jèhóṣáfátì ọmọ ẹ̀ ló wá mú àwọn yẹn kúrò.—1 Ọba 15:14; 2 Kíró. 15:17.

Látinú àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì àti tòde òní, kí lo rí kọ́ nípa

• bó o ṣe lè fi hàn pé o ní ìtara nípa wíwàásù àti kíkọ́ni?

• báwọn Kristẹni ọ̀dọ́ ṣe lè fi hàn pé àwọn jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà”?

• bá a ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn àṣà tó ń sọni dìbàjẹ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ṣé o máa ń lo Bíbélì déédéé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Kíkọ́ èdè míì nígbà tó o wà nílé ìwé lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i