Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Bá Aládùúgbò Rẹ Sọ Òtítọ́

Máa Bá Aládùúgbò Rẹ Sọ Òtítọ́

Máa Bá Aládùúgbò Rẹ Sọ Òtítọ́

“Nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.”—ÉFÉ. 4:25.

1, 2. Kí lèrò ọ̀pọ̀ èèyàn nípa òtítọ́?

 ỌJỌ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń jiyàn lórí bóyá ó ṣeé ṣe féèyàn láti jẹ́ olóòótọ́ tàbí kéèyàn mọ ohun tí òtítọ́ jẹ́. Ní ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni, akéwì ará ilẹ̀ Gíríìkì náà Alcaeus sọ pé: “Òtítọ́ wà nínú ọtí wáìnì.” Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé téèyàn bá ti mutí yó, tó sì ń fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nìkan lèèyàn lè sọ òtítọ́. Ọ̀nà ṣákálá tí Gómìnà Pọ́ńtíù Pílátù tó ń ṣàkóso ní ọ̀rúndún kìíní gbà bi Jésù pé: “Kí ni òtítọ́?” fi hàn pé kò ní èrò tó tọ́ nípa ohun tí òtítọ́ jẹ́.—Jòh. 18:38.

2 Àkókò yìí gan-an lèrò àwọn èèyàn nípa òtítọ́ túbọ̀ wá yàtọ̀. Ọ̀pọ̀ ló sọ pé oríṣiríṣi nǹkan lọ̀rọ̀ náà “òtítọ́” túmọ̀ sí tàbí ohun tí ẹnì kan kà sí òtítọ́ yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì. Ìgbà tó bá rọrùn tàbí tó máa ṣe wọ́n làǹfààní nìkan làwọn kan máa ń sọ òtítọ́. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa irọ́ pípa, ìyẹn The Importance of Lying sọ pé: “Òótọ́ ni pé ìwà àìlábòsí dáa, àmọ́ àǹfààní tó wà ńbẹ̀ ò tó nǹkan torí pé àfi kéèyàn dọ́gbọ́n sọ́rọ̀ ara ẹ̀ kó tó lè rọ́wọ́ mú láyé yìí.”

3. Kí ló mú kí Jésù jẹ́ àpẹẹrẹ tó ta yọ tó bá dọ̀rọ̀ ká sọ òtítọ́?

3 Èrò Kristi àti tàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sóhun táwọn èèyàn ń sọ pé òtítọ́ jẹ́. Gbogbo ìgbà ló máa ń sọ òtítọ́. Àwọn ọ̀tá ẹ̀ pàápàá jẹ́rìí sí i, wọ́n ní: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ jẹ́ olùsọ òtítọ́, o sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́.” (Mát. 22:16) Bákan náà lóde òní, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Wọn kì í lọ́ra láti sọ òtítọ́. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi gba ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: “Nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.” (Éfé. 4:25) Ẹ jẹ́ ká gbé ohun mẹ́ta yẹ̀ wò nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí. Àkọ́kọ́, tá ni aládùúgbò wa? Ìkejì, kí ló túmọ̀ sí láti sọ òtítọ́? Ìkẹta, báwo la ṣe lè fàwọn nǹkan yìí sílò nínú ìgbésí ayé wa?

Ta Ni Aládùúgbò Wa?

4. Láìdà bí àwọn aṣáájú Júù ọ̀rúndún kìíní, báwo ni Jésù ṣe fi èrò Jèhófà nípa àwọn tó jẹ́ aládùúgbò wa hàn?

4 Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, èrò àwọn kan lára àwọn aṣáájú àwọn Júù ni pé àwọn Júù bíi tàwọn tàbí àwọn ọ̀rẹ́ àwọn tímọ́tímọ́ nìkan láwọn lè pè ní “aládùúgbò.” Àmọ́, Jésù ní tiẹ̀ fara wé Baba rẹ̀ láìkù síbì kan, ó sì ń wo nǹkan bí Ọlọ́run ṣe ń wò ó. (Jòh. 14:9) Gbangba-gbàǹgbà ló fi han àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé Ọlọ́run ò fẹ́ràn ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè kan jùkan lọ. (Jòh. 4:5-26) Síwájú sí i, ẹ̀mí mímọ́ tún fi han àpọ́sítélì Pétérù pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:28, 34, 35) Torí náà, gbogbo èèyàn ló yẹ ká kà sí aládùúgbò wa, ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn tó ń bá wa ṣọ̀tá pàápàá.—Mát. 5:43-45.

5. Kí ló túmọ̀ sí láti bá aládùúgbò wa sọ òtítọ́?

5 Síbẹ̀, kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ó yẹ ká máa bá àwọn aládùúgbò wa sọ òtítọ́? Sísọ òtítọ́ ní nínú kéèyàn sọ bọ́rọ̀ kan ṣe rí gan-an láìfi ohunkóhun pa mọ́. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í yí ọ̀rọ̀ pò tàbí parọ́ láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Wọ́n “kórìíra ohun burúkú,” wọ́n sì “rọ̀ mọ́ ohun rere.” (Róòmù 12:9) Ó yẹ ká fara wé “Ọlọ́run òtítọ́,” ká máa sapá láti jẹ́ aláìlábòsí àti olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. (Sm. 15:1, 2; 31:5) Tá a bá ń fara bálẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ tá a fẹ́ sọ, a lè fọgbọ́n yanjú ọ̀rọ̀ tá a bá wà nínú ipò tí kò fara rọ tàbí tó ń dójú tini, tá ò sì ní parọ́.—Ka Kólósè 3:9, 10.

6, 7. (a) Ṣé jíjẹ́ ẹni tó ń sọ òtítọ́ túmọ̀ sí pé ká máa sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti béèrè ọ̀rọ̀? Ṣàlàyé. (b) Àwọn wo la fọkàn tán tí wọ́n sì yẹ lẹ́ni tá à ń sòótọ́ fún?

6 Ṣé jíjẹ́ ẹni tó ń sọ òtítọ́ túmọ̀ sí pé ká máa sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti béèrè ọ̀rọ̀? Kò pọn dandan. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́ ká rí i pé àwọn kan ò yẹ lẹ́ni téèyàn ń dá lóhùn ní tààràtà tàbí pé kò yẹ kí wọ́n mọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan. Nígbà táwọn alágàbàgebè aṣáájú ìsìn bi Jésù nípa agbára tàbí ọlá àṣẹ tó ń lò láti fi ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àtàwọn iṣẹ́ ìyanu tó ń ṣe, ó ní: “Èmi yóò béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ yín. Kí ẹ dá mi lóhùn, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò sì sọ ọlá àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.” Nígbà táwọn akọ̀wé àtàwọn àgbà ọkùnrin náà kọ̀ láti dá a lóhùn, Jésù sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò sọ ọlá àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.” (Máàkù 11:27-33) Torí ìwàkíwà tó kún ọwọ́ wọn àti àìnígbàgbọ́ wọn, ó rí i pé wọn ò yẹ lẹ́ni tóun ń dáhùn ìbéèrè wọn. (Mát. 12:10-13; 23:27, 28) Bákan náà, ó yẹ káwọn èèyàn Jèhófà lóde òní náà ṣọ́ra fún àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn èèyàn burúkú míì tí wọ́n máa ń lo ẹ̀tàn fún ìfẹ́ tara wọn.—Mát. 10:16; Éfé. 4:14.

7 Pọ́ọ̀lù náà jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kan lè má yẹ lẹ́ni tó ń gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bọ́rọ̀ kan ṣe rí. Ó ní, àwọn “olófòófó . . . àti alátojúbọ àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn,” máa “ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.” (1 Tím. 5:13) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tó máa ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ tàbí tí wọn ò ṣeé fọ̀rọ̀ àṣírí sí lọ́wọ́ lè rí i pé kò ní yá àwọn èèyàn lára láti sọ̀rọ̀ àṣírí fáwọn. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé ká máa fi ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ sílò pé: “Kí ẹ sì fi í ṣe ìfojúsùn yín láti máa gbé ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, kí ẹ má sì máa yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn.” (1 Tẹs. 4:11) Àmọ́ ṣá o, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn alàgbà lè ní láti béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ wa kí wọ́n bàa lè bójú tó iṣẹ́ wọn. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, wọ́n á mọrírì ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa tá a bá sọ òtítọ́, ìyẹn á sì ṣèrànwọ́ gan-an.—1 Pét. 5:2.

Máa Sọ Òtítọ́ Nínú Ìdílé

8. Báwo ni sísọ òótọ́ ṣe lè mú kí àwọn tó wà nínú ìdílé wà níṣọ̀kan?

8 Bó ṣe sábà máa ń rí, àwọn ìdílé wa la máa ń sún mọ́ jù. Kí àjọṣe yìí lè túbọ̀ lókun, ó ṣe pàtàkì pé ká máa bá ara wa sòótọ́. Ọ̀pọ̀ ìṣòro àti èdèkòyédè ló máa dín kù tàbí kó má tiẹ̀ wáyé táwọn tó wà nínú ilé bá jẹ́ ẹni tó ń sòótọ́, tí wọn kì í fi nǹkan pa mọ́, tí ọ̀rọ̀ wọn sì ń fi hàn pé wọ́n mọyì àwọn tó kù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a bá ṣàṣìṣe, ṣé ọkọ, aya, ọmọ wa tàbí àwọn míì tó sún mọ́ ìdílé wa la máa ń sọ pé ó fà á? Tá a bá ń tọrọ àforíjì látọkàn wá, èyí máa ń jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìdílé.—Ka 1 Pétérù 3:8-10.

9. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀yájú bá a tiẹ̀ ń sọ òtítọ́?

9 Béèyàn bá jẹ́ ọ̀yájú, àní bó bá sòótọ́ pàápàá àwọn èèyàn ò ní ka ohun tó sọ sí. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú. Ṣùgbọ́n kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.” (Éfé. 4:31, 32) Tá a bá ń sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, tó sì ń buyì kúnni, èyí á jẹ́ kọ́rọ̀ wa tà létí àwọn èèyàn, á sì fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fáwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀.—Mát. 23:12.

Máa Sọ Òtítọ́ Nínú Àwọn Ọ̀ràn Tó Jẹ Mọ́ Ìjọ

10. Kí làwọn alàgbà lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ tó ta yọ tí Jésù fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ sísọ òtítọ́?

10 Jésù báwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó rọrùn, tó sì ṣe ṣàkó. Àwọn ìmọ̀ràn Jésù máa ń tuni lára, síbẹ̀ kì í fomi la òtítọ́ torí káwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ bàa lè fetí sóhun tó ń sọ. (Jòh. 15:9-12) Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn àpọ́sítélì Jésù ń jiyàn léraléra nípa ẹni tó tóbi jù láàárín wọn, kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, àmọ́ ó fi sùúrù ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ìdí tó fi yẹ kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (Máàkù 9:33-37; Lúùkù 9:46-48; 22:24-27; Jòh. 13:14) Bákan náà lóde òní, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà máa ń dúró lórí òtítọ́, síbẹ̀ wọn kì í jẹ ọ̀gá lórí agbo Ọlọ́run. (Máàkù 10:42-44) Wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi nípa jíjẹ́ onínúure sáwọn ará, wọ́n sì ń fi “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn” nínú ohun tí wọ́n ń ṣe sí wọn.

11. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lóòótọ́, báwo ló ṣe yẹ ká máa lo ahọ́n wa?

11 Tá a bá ń sojú abẹ níkòó nígbà tá a bá ń báwọn ará wa sọ̀rọ̀, àmọ́ tá ò ki àṣejù bọ̀ ọ́, èyí á jẹ́ ká lè máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wa, a ò sì ní máa múnú bí wọn. Kò sí àní-àní pé a ò ní fẹ́ kí ahọ́n wa dà bí ‘abẹ fẹ́lẹ́ tí wọ́n pọ́n,’ táá máa dápàá sáwọn èèyàn lára pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń rẹni wálẹ̀. (Sm. 52:2; Òwe 12:18) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, a ó “máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ahọ́n [wa] kúrò nínú ohun búburú, àti ètè [wa] kúrò nínú ṣíṣe ẹ̀tàn.” (Sm. 34:13) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó máa bọlá fún Ọlọ́run, a ó sì túbọ̀ mú kí ìjọ wà níṣọ̀kan.

12. Ìgbà wo ni irọ́ pípa lè dohun tí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ máa bójú tó? Ṣàlàyé.

12 Àwọn alàgbà máa ń ṣiṣẹ́ kára láti dáàbò bo ìjọ lọ́wọ́ àwọn tó máa ń parọ́ láti fi ba àwọn ẹlòmíì jẹ́. (Ka Jákọ́bù 3:14-16.) Ohun tó wà lọ́kàn ẹni tó ń parọ́ láti bani jẹ́ ni pé kẹ́ni tó ń parọ́ mọ́ jìyà tàbí káwọn ìṣòro kan bá a. Àmọ́, èyí kọjá pé kéèyàn kàn sọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan, kọ́rọ̀ èèyàn má lójútùú tàbí kéèyàn ṣe àbùmọ́. Lóòótọ́, gbogbo irọ́ pípa ló burú, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà téèyàn ò bá sọ òkodoro òtítọ́ ló máa béèrè pé kí wọ́n gbé ìgbìmọ̀ onídàájọ́ dìde. Torí náà, àwọn alàgbà ní láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí wọ́n lo òye, kí wọ́n sì ro àròjinlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń pinnu bóyá ẹnì kan tó sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa ẹnì kan mọ̀ọ́mọ̀ ni, tí ìyẹn sì ti wá di irọ́ tó yẹ kí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ bójú tó. Tàbí kí wọ́n fi Ìwé Mímọ́ tún èrò ẹ̀ ṣe tìfẹ́tìfẹ́ láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀.

Máa Sọ Òtítọ́ Nínú Ọ̀ràn Iṣẹ́ Ajé

13, 14. (a) Báwo làwọn kan ṣe máa ń hùwà àìṣòótọ́ sáwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́? (b) Kí ló lè jẹ́ àbájáde ẹ̀ tá a bá jẹ́ aláìlábòsí àti olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ wa?

13 À ń gbé lákòókò kan tí ìwà àìṣòótọ́ gbalẹ̀ gbòde, torí náà ó lè má rọrùn láti máa ṣòótọ́ sí agbanisíṣẹ́. Ọ̀pọ̀ ló máa ń parọ́ nígbà tí wọ́n bá ń wáṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ṣe àbùmọ́ òye tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ tàbí bí wọ́n ṣe kàwé tó, kí wọ́n bàa lè rí iṣẹ́ tó dáa tàbí èyí tówó ẹ̀ pọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ló máa ń sọ pé àwọn ń ṣiṣẹ́ nígbà tó jẹ́ pé tara wọn ni wọ́n ń gbọ́, tí èyí sì ta ko òfin ilé iṣẹ́. Wọ́n lè máa ṣe àwọn ohun tí kò jẹ mọ́ iṣẹ́ wọn, bíi kíkàwé, bíbá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, yíyẹ ìsọfúnni wò àti fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

14 Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í wo ìwà àìlábòsí àti jíjẹ́ olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun téèyàn lè ṣe bó bá fẹ́. (Ka Òwe 6:16-19.) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Héb. 13:18) Ìdí nìyẹn táwọn Kristẹni fi máa ń gbájú mọ́ iṣẹ́ tí wọ́n ń sanwó ẹ̀ fún wọn. (Éfé. 6:5-8) Béèyàn bá jẹ́ òṣìṣẹ́ tó fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́, ìyẹn tún lè mú ìyìn bá Baba wa ọ̀run. (1 Pét. 2:12) Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Sípéènì, ẹni tó gba Arákùnrin Roberto síṣẹ́ yìn ín fún bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ tó sì mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́. Torí ìwà ọmọlúwàbí tí Arákùnrin Roberto ń hù, ilé iṣẹ́ yìí gba ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà síṣẹ́. Àwọn tí wọ́n sì gbà náà ò fiṣẹ́ ṣeré. Nítorí èyí, Arákùnrin Roberto ti bá àwọn arákùnrin mẹ́tàlélógún [23] tó ti ṣèrìbọmi àtàwọn mẹ́jọ tó ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wáṣẹ́!

15. Báwo ni Kristẹni kan tó jẹ́ oníṣòwò ṣe lè fi hàn pé òun ń sọ òtítọ́?

15 Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ ara wa là ń ṣe, ṣé a máa ń ṣòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ wa, àbí a máa ń parọ́ fáwọn oníbàárà wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? Kristẹni tó ń ṣòwò ò gbọ́dọ̀ parọ́ lórí iṣẹ́ kan tó fẹ́ ṣe tàbí lórí ọjà kan torí kó lè tètè tà á, kò sì gbọ́dọ̀ san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí gbà á. A fẹ́ máa ṣe sáwọn èèyàn bá a ṣe fẹ́ kí wọ́n ṣe sí wa.—Òwe 11:1; Lúùkù 6:31.

Máa Sọ Òtítọ́ Fáwọn Aláṣẹ

16. Kí làwọn Kristẹni ń fún (a) àwọn aláṣẹ? (b) Jèhófà?

16 Jésù sọ pé: “Nítorí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mát. 22:21) Àwọn “ohun” wo la jẹ Késárì, ìyẹn àwọn aláṣẹ? Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí, ọ̀rọ̀ nípa owó orí ni wọ́n ń jíròrò. Torí náà, láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ níwájú Ọlọ́run àtèèyàn, àwọn Kristẹni máa ń ṣègbọràn sí òfin orílẹ̀-èdè tó fi mọ́ sísan owó orí. (Róòmù 13:5, 6) Àmọ́, Jèhófà la mọ̀ sí Ọba Aláṣẹ Gíga Jù Lọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo, tá a nífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, ọkàn, èrò inú àti okun wa. (Máàkù 12:30; Ìṣí. 4:11) Ìyẹn ló jẹ́ ká máa wà nítẹríba fún Jèhófà Ọlọ́run láìkù síbì kan.—Ka Sáàmù 86:11, 12.

17. Ojú wo làwọn èèyàn Jèhófà fi ń wo gbígba ìrànwọ́ tó wà fáwọn ará ìlú?

17 Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló máa ń ṣàwọn ètò kan láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Kò sóhun tó burú tí Kristẹni kan bá jẹ àǹfààní yìí, ìyẹn tó bá lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Sísọ òtítọ́ fáwọn aládùúgbò wa gba pé ká má máa parọ́ fáwọn aláṣẹ torí àtijẹ irú àǹfààní bẹ́ẹ̀.

Ìbùkún Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Olóòótọ́

18-20. Àwọn ìbùkún wo ló wà nínú sísọ òtítọ́ fáwọn aládùúgbò wa?

18 Ọ̀pọ̀ ìbùkún ló wà nínú jíjẹ́ olóòótọ́. Ó máa ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, èyí tó ń jẹ́ ká ní àlàáfíà ọkàn àti ọkàn tó pa rọ́rọ́. (Òwe 14:30; Fílí. 4:6, 7) Ohun iyebíye ló jẹ́ téèyàn bá ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lójú Ọlọ́run. Síwájú sí i, tá a bá ń ṣòótọ́ nínú ohun gbogbo, ẹ̀rù ò ní máa bà wá pé àṣírí máa tú lọ́jọ́ kan.—1 Tím. 5:24.

19 Ẹ jẹ́ ká tún gbé ìbùkún míì yẹ̀ wò. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.” (2 Kọ́r. 6:4, 7) Bọ́rọ̀ Ẹlẹ́rìí kan tó ń gbé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe rí nìyẹn. Nígbà tó fẹ́ ta ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ẹ̀, ó ṣàlàyé gbogbo ibi tọ́kọ̀ náà dáa sí àti ibi tó kù sí, tó fi mọ́ èyí téèyàn ò lè rí lára ọkọ̀ náà fún ẹni tó fẹ́ rà á. Lẹ́yìn tí ẹni tó fẹ́ ra ọkọ̀ náà ti wà á káàkiri fún àyẹ̀wò, ó bi arákùnrin náà bóyá Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Kí ló mú kó béèrè bẹ́ẹ̀? Ọ̀gbẹ́ni yẹn ti kíyè sí ìwà àìlábòsí arákùnrin náà, ó sì tún rí i pé ìrísí ẹ̀ dáa. Èyí fún arákùnrin náà láǹfààní láti wàásù fún ọ̀gbẹ́ni náà.

20 Ṣé àwa náà ń fìyìn fún Ẹlẹ́dàá wa nípa jíjẹ́ aláìlábòsí àti olóòótọ́? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa ti kọ àwọn ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ tí ń tini lójú sílẹ̀ ní àkọ̀tán, a kò rin ìrìn àlùmọ̀kọ́rọ́yí.” (2 Kọ́r. 4:2) Torí náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti máa sọ òtítọ́ fáwọn aládùúgbò wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa fìyìn fún Baba wa ọrun àtàwọn èèyàn rẹ̀.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Ta ni aládùúgbò wa?

• Kí ló túmọ̀ sí láti máa bá àwọn aládùúgbò wa sọ òtítọ́?

• Báwo ni sísọ òtítọ́ ṣe lè fìyìn fún Ọlọ́run?

• Àwọn ìbùkún wo ló wà nínú jíjẹ́ olóòótọ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ṣó o máa ń tètè gba àwọn àṣìṣe kéékèèké tó o bá ṣe?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ṣó o máa ń sòótọ́ nígbà tó o bá ń wáṣẹ́?