Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Mo Lè San Pa Dà Fún Jèhófà?

Kí Ni Mo Lè San Pa Dà Fún Jèhófà?

Kí Ni Mo Lè San Pa Dà Fún Jèhófà?

Gẹ́gẹ́ bí Ruth Danner ṣe sọ ọ́

Màmá mi máa ń sọ ọ́ lọ́nà àwàdà pé ọdún 1933 jẹ́ ọdún táwọn àjálù kan wáyé, ọdún yẹn ni Hitler gbàjọba, Póòpù pe ọdún yẹn ní Ọdún Mímọ́ àti pé ọdún náà ni wọ́n bí mi.

ÀWỌN òbí mi ń gbé nílùú Yutz, ní àgbègbè Lorraine, tó jẹ́ ibi táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé ti wáyé nítòsí ibi tí orílẹ̀-èdè Faransé àti Jámánì ti pààlà. Lọ́dún 1921, màmá mi tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì paraku fẹ́ bàbá mi tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ọdún 1922 ni wọ́n bí ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Helen, wọ́n sì ṣèrìbọmi fún un nígbà tó wà lọ́mọ ọwọ́ ní Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì.

Lọ́jọ́ kan lọ́dún 1925, bàbá mi gba ẹ̀dà kan ìwé Dùrù Ọlọ́run lédè Jámánì. Nígbà tó kà á, ó dá a lójú pé òun ti rí òtítọ́. Ó kọ̀wé sáwọn tó ṣèwé náà, wọ́n sì sọ fún un bó ṣe máa ráwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni bàbá mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ohun tó kọ́. Inú màmá mi kò dùn sí ohun tí bàbá mi ń ṣe yìí. Ńṣe ni màmá mi máa ń fi èdè Jámánì jágbe mọ́ bàbá mi pé: “O lè ṣe ohunkóhun tó o bá fẹ́ o, àmọ́ má ṣe bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rìn!” Ṣùgbọ́n bàbá mi ti pinnu ohun tó máa ṣe, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1927.

Inú màma màmá mi ò dùn sóhun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, o sì bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ màmá mi pé kó jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fún bàbá mi. Lọ́jọ́ kan nígbà ìsìn Máàsì, àlùfáà Kátólíìkì kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ìjọ pé, “kí wọ́n yẹra fún Ọ̀gbẹ́ni Danner nítorí wòlíì èké ni.” Nígbà tí màmá màmá mi dé láti ìsìn Máàsì yẹn, ó ju ìkòkò tí wọ́n gbin òdòdó sí lu bàbá mi látòkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ilé wa. Ìkòkò ńlá náà já lu Bàbá mi léjìká, díẹ̀ ló kù kó bà wọ́n lórí. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí mú kí màmá mi ronú pé: ‘Ẹ̀sìn tó ń sọni di apààyàn kì í ṣe ẹ̀sìn tó dáa.’ Ni màmá mi bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò pẹ́ tó fi dá màmá mi lójú pé òun ti rí òtítọ́, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1929.

Àwọn òbí mi sapá gidigidi láti jẹ́ kí èmi àtẹ̀gbọ́n mi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Wọ́n máa ń ka àwọn ìtàn Bíbélì fún wa, wọ́n á sì ṣàlàyé ìdí tẹ́nì kan tí Bíbélì dárúkọ fi ṣe ohun tó ṣe. Nígbà yẹn, bàbá mi ò ṣiṣẹ́ alẹ́ tàbí iṣẹ́ ìrọ̀lẹ́, ìyẹn sì jẹ́ kí owó tó ń wọlé fún ìdílé wa dín kù gan-an. Ó fẹ́ máa lo àkókò yìí láti máa lọ́ sí ìpàdé, òde ẹ̀rí, kó sì máa kọ́ àwa ọmọ ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́.

Àwọn Àkókò Lílé Ń Bọ̀ Lọ́nà

Àwọn òbí mi máa ń gbàlejò àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ilẹ̀ Switzerland àti Faransé. Wọ́n sọ fún wa nípa ìṣòro táwọn ará wa tó wà ní Jámánì ń dojú kọ, ìyẹn àwọn tí wọ́n ń gbé ní nǹkan bíi kìlómítà mélòó kan sí ilé wa. Ìjọba Násì ń kó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, wọ́n sì ń gba àwọn ọmọ kúrò lọ́wọ́ òbí wọn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí.

Èmi àti Helen ti múra sílẹ̀ láti dojú kọ wàhálà tó ń bẹ́ níwájú. Àwọn òbí wa ti ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó máa tọ́ wa sọ́nà sórí. Wọ́n lè sọ pé: “Bó ò bá mọ ohun tó o máa ṣe, rántí ohun tí Òwe 3:5, 6 wí. Tó o bá ń bẹ̀rù àdánwò nílé ìwé, ka 1 Kọ́ríńtì 10:13. Tí wọ́n bá mú yín kúrò lọ́dọ̀ wa, ẹ ka Òwe 18:10.” Mo mọ Sáàmù 23 àti 91 sórí, mo sì wá nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà á máa dáàbò bò mí.

Lọ́dún 1940, Ìjọba Násì gba àgbègbè Alsace-Lorraine kúrò lára ilẹ̀ Faransé, ìjọba tuntun náà sì ní kí gbogbo àwọn àgbàlagbà wá wọnú ẹgbẹ́ òṣèlú Násì. Bàbá mi kọ̀ jálẹ̀, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ sì halẹ̀ mọ́ ọn pé àwọn á mú un. Nígbà ti màmá mi kọ̀ láti máa bá wọn ránṣọ àwọn ológun, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tún halẹ̀ mọ́ òun náà pé àwọn á mú un.

Ńṣe làyà mi máa ń já tí mo bá wà níléèwé. Lójoojúmọ́, kíláàsì wa máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà fún Hitler, wọ́n á kọ orin ìyìn sí Hitler, lẹ́yìn náà, wọ́n á na apá ọ̀tún wọn síwájú, wọ́n á sì kọ orin orílẹ̀-èdè. Dípò káwọn òbí mi sọ fún mi pé kí n má kọrin ìyìn sí Hitler, ńṣe ni wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀rí ọkàn mi. Torí náà, èmi fúnra mi ni mo pinnu pé mi ò ní kọrin ìyìn sí Hitler. Àwọn olùkọ́ nà mí, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ mi pé àwọn máa lé mi kúrò níléèwé. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje, lọ́jọ́ kan, wọ́n pè mí síwájú àwọn olùkọ́ méjìlá tó wà níléèwé wa. Wọ́n gbìyànjú láti fipá mú mi kọrin ìyìn sí Hitler. Àmọ́, Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti dúró gbọin.

Nígbà kan, olùkọ́ kan tiẹ̀ fẹ́ kó sí mi lórí. Ó sọ pé ọmọ dáadáa ni mí, òun fẹ́ràn mi gan-an ni, ó sì máa dun òun gan-an tí wọ́n bá lé mi kúrò níléèwé. Ó wá sọ pé: “Kì í ṣe dandan kó o nawọ́ ẹ síwájú pátápátá, ṣáà nà án díẹ̀. Kò sì pọn dandan kó o sọ pé ‘Ẹ Kókìkí Hitler!’ Ìwọ ṣáà kàn máa jẹnu wúyẹ́wúyẹ́.”

Nígbà tí mo sọ ọ̀rọ̀ yìí fún màmá mi, ó rán mi létí ìtàn àwọn ọ̀dọ́kùnrin Hébérù mẹ́ta tó wà nínú Bíbélì, tí wọ́n wà níwájú ère tí ọba Bábílónì ṣe. Ó wá bi mí pé: “Kí ni wọ́n fẹ́ kí wọ́n ṣe?” Mo wá dáhùn pé: “Wọ́n fẹ́ kí wọ́n tẹrí ba.” Màmá mi wá sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé àsìkò tí wọ́n ń retí pé kí wọ́n tẹrí ba fún ère náà làwọn Hébérù mẹ́ta yẹn wá bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ láti so okùn bàtà wọn, ǹjẹ́ ó dáa bẹ́ẹ̀? Torí náà, ìwọ lo máa pinnu ohun tó o rò pé ó tọ́.” Bíi ti Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, mo pinnu pé Jèhófà nìkan ni màá máa sìn.—Dán. 3:1, 13-18.

Àwọn olùkọ́ lé mi kúrò níléèwé láwọn ìgbà mélòó kan, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ mi pé àwọn á mú mi kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí mi. Ẹ̀rù bà mí gan-an, àmọ́ àwọn òbí mi ò yéé fún mi níṣìírí. Bí mo bá ti ń lọ síléèwé, màmá mi máa ń gbàdúrà fún mi, pé kí Jèhófà dáàbò bò mí. Mo mọ̀ pé ó máa fún mi lókun tí màá fi lè ṣe ohun tó tọ́ láìmikàn. (2 Kọ́r. 4:7) Bàbá mi sọ fún mi pé bí wàhálà náà bá ti pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, kí n má ṣe bẹ̀rù láti máa bọ̀ nílé. Ó sọ fún mi pé: “A fẹ́ràn ẹ. Ọmọ wa lo ṣì jẹ́ lọ́jọ́kọ́jọ́. Ọ̀rọ̀ àárín ìwọ àti Jèhófà lọ̀rọ̀ yìí.” Ọ̀rọ̀ yìí fún mi lókun gan-an láti di ìwà títọ́ mi mú.—Jóòbù 27:5.

Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ máa ń wá sílé wa láti wá wò ó bóyá wọ́n á ráwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì tún máa ń bi àwọn òbí mi láwọn ìbéèrè. Nígbà míì, wọ́n á mú màmá mi lọ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, wọ́n á sì lọ mú bàbá mi àti ẹ̀gbọ́n mi níbi iṣẹ́ wọn. Mi ò kì í mọ̀ bóyá màá bá màmá mi nílé tí mo bá dé láti iléèwé. Nígbà míì, aládùúgbò wa kan á sọ fún mi pé: “Wọ́n ti wá mú màmá ẹ lọ o.” Màá wá lọ bọ́ sí kọ̀rọ̀ kan nínú ilé, màá máa bi ara mi pé: ‘Ṣé kì í ṣe pé wọ́n ń fìyà jẹ màmá mi? Ṣé màá tún pa dà rí wọn báyìí?’

Wọ́n Lé Wa Kúrò Nílùú

Ní January 28, 1943, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ jí wa lójú oorun láago mẹ́ta ààbọ̀ òru. Wọ́n sọ pé táwọn òbí mi àtẹ̀gbọ́n mi bá lè dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Násì, wọn ò ní lé wa kúrò nílùú. Wọ́n fún wa ní wákàtí mẹ́ta pé ká fi palẹ̀ ẹrù wa mọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ò bá màmá mi lójijì rárá, torí náà kíá ló kó àwọn aṣọ bíi mélòó kan àti Bíbélì sínú báàgì kan, a lo ìwọ̀nba àkókò yẹn láti gbàdúrà, a sì fún ara wa níṣìírí. Bàbá mi wá rán wa létí pé kò sí ‘ohunkóhun tí yóò yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.’—Róòmù 8:35-39.

Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ yẹn pa dà wá lóòótọ́. Mi ò jẹ́ gbàgbé bí arábìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Anglade ṣe ń juwọ́ sí wa pẹ̀lú omijé. Àwọn ọlọ́pàá náà gbé wa lọ sí ibùdókọ̀ ojú irin tó wà nílùú Metz. Lẹ́yìn tá a ti lo ọjọ́ mẹ́ta nínú ọkọ̀ ojú irin, á dé Kochlowice, ìyẹn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tí Auschwitz tó wà nílùú Poland. Oṣù méjì lẹ́yìn náà, wọ́n gbé wa lọ sílùú Gliwice, nílé àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tí wọ́n sọ di àgọ́ tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́. Ìjọba Násì sọ fún wa pé tá a bá fọwọ́ síwèé pé a ò ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, àwọn á dá wa sílẹ̀, àwọn á sì dá àwọn nǹkan wa pa dà fún wa. Bàbá mi àti màmá mi kọ̀ jálẹ̀, àwọn sójà yẹn wá sọ pé: “Ẹ ò ní pa dà sílé mọ́ láé.”

Ní oṣù June, wọ́n gbé wa lọ sí àdúgbò kan tó ń jẹ́ Swietochlowice, ibẹ̀ ni ẹ̀fọ́rí kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í yọ mi lẹ́nu, ẹ̀fọ́rí ọ̀hún ṣì ń bá mi fínra títí dòní. Nígbà tó yá, kòkòrò kan wọ àwọn ìka ọwọ́ mi, dókítà kan sì yọ mélòó kan lára àwọn èékánná ìka mi, láìfún mi ní oògùn apàrora. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń rán mi lọ sí ibi tí wọ́n ti máa ń ṣe búrẹ́dì, obìnrin kan sì wà níbẹ̀ tó máa ń fún mi lóúnjẹ.

Ṣáájú àkókò yìí, ibi táwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù wà kọ́ ni wọ́n fi ìdílé wa sí. Ní oṣù October ọdún 1943, wọ́n gbé wa lọ sí àgọ́ kan nílùú Ząbkowice. A sùn sórí àwọn bẹ́ẹ̀dì alágbèékà lókè àjà kan níbi tí tọkùnrin tobìnrin ọmọdé àtàgbà tí wọ́n tó nǹkan bí ọgọ́ta [60] wà. Àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà níbẹ̀ rí sí i pé oúnjẹ tí kò dáa, tó fẹ́ẹ̀ lè má ṣeé jẹ ni wọ́n ń fún wa.

Pẹ̀lú bí nǹkan ṣe le tó yẹn, a ò sọ̀rètí nù. A ti kà nínú Ilé Ìṣọ́ nípa ìṣẹ́ ìwàásù tó máa kárí ayé tá a máa ṣe lẹ́yìn tí ogun bá ti parí. Torí náà, a mọ ìdí tá a fi ń jìyà, a sì mọ̀ pé a máa bọ́ ńbẹ̀ lọ́jọ́ kan.

Nígbà tá a gbọ́ pé àwọn sójà tó ń gbógun ti orílẹ̀-èdè Jámánì ń pọ̀ sí i, èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ìjọba Násì ò lè borí. Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1945, àwọn ẹ̀ṣọ́ pinnu láti fi àgọ́ wa sílẹ̀. Ní February 19, wọ́n fipá mú wa láti yan bí ológun lọ síbi tó fẹ́ẹ̀ jìnnà tó òjìlénígba [240] kìlómítà. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́rin, a dé ìlú Steinfels, lórílẹ̀-èdè Jámánì. Wọ́n wá da gbogbo wa sínú kòtò ńlá kan. Ọ̀pọ̀ nínú wa ló tiẹ̀ ti gba kámú pé ọjọ́ yẹn la máa kú. Àmọ́, ọjọ́ yẹn làwọn sójà tó ń gbógun ti orílẹ̀-èdè Jámánì dé, àwọn ẹ̀ṣọ́ yẹn bá sá lọ, bá a ṣe bọ́ nínú wàhálà nìyẹn o.

Ọwọ́ Mi Tẹ Àwọn Ohun Tí Mò Ń Lé

Ní May 5, 1945, lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méjì ààbọ̀, a pa dà délé wa ní Yutz. Ńṣe ni gbogbo inú ilé dọ̀tí, kòkòrò sì wà níbẹ̀. A ò tíì pàrọ̀ àwọn aṣọ tá a ti ń wọ̀ láti oṣù February, torí náà a bọ́ àwọn aṣọ yẹn a sì dáná sun wọ́n. Mo rántí pé màmá mi sọ fún wa pé: “Ẹ jẹ́ kí ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ tó dáa jù lọ láyé yín. Lóòótọ́, a ò ní nǹkan kan o. Kódà, àwọn aṣọ tá a wọ̀ yìí kì í ṣe ti wa. Àmọ́, gbogbo wa ṣì ń bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Kò sẹ́ni tó bọ́hùn.”

Lẹ́yìn tí mo ti lo nǹkan bí oṣù mẹ́ta lórílẹ̀-èdè Switzerland, tára mi sì ti bọ̀ sípò, mo pa dà síléèwé, mi ò sì bẹ̀rù pé wọ́n lè lé mi mọ́. Ó ti wá ṣeé ṣe fún wa báyìí láti máa ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ará wa láìbẹ̀rù. Ní August 28, 1947, tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, mo fẹ̀rí ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn hàn lójú ọ̀pọ̀ èèyàn. Bàbá mi ṣèrìbọmi fún mi nínú Odò Moselle. O wù mí kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àmọ́ bàbá mi sọ pé àfi kí n kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ ná. Èyí ló mú kí n kọ́ṣẹ́ aṣọ rírán. Lọ́dún 1951, tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, mo sì ń sìn ní àdúgbò kan tó ń jẹ́ Thionville.

Lọ́dún yẹn, mo lọ sí àpéjọ kan nílùú Paris, mo si sọ pé mo fẹ́ máa sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì. Mi ò tíì dàgbà tó nígbà yẹn, àmọ́ Arákùnrin Nathan Knorr sọ pé òun á ṣiṣẹ́ lórí fọ́ọ̀mù mi “tó bá yá.” Ní June 1952, wọ́n pè mí sí kíláàsì kọkànlélógún ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì nílùú South Lansing, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Àǹfààní Tí Mo Jẹ Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Àtohun tó Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Náà

Àwọn nǹkan tí mo kọ́ níbẹ̀ ṣàǹfààní gan-an ni! Ẹ̀rù sábà máa ń bà mí láti fi èdè mi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Ní báyìí, ó wá di dandan kí n máa sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́ àwọn olùkọ́ wa fìfẹ́ ràn mí lọ́wọ́. Arákùnrin kan tiẹ̀ máa ń pè mí ní Ẹlẹ́rìn-ín Ẹ̀yẹ torí bí mo ṣe máa ń rẹ́rìn-ín tójú bá ń tì mí.

Ní July 19, 1953, a ṣayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege wa ní Pápá Ìṣeré Yankee ní ìpínlẹ̀ New York, wọ́n sì ní kémi àti Arábìnrin Ida Candusso, (tó wá di Arábìnrin Seignobos nígbà tó ṣègbéyàwó,) lọ máa sìn nílùú Paris. Kò rọrùn rárá láti máa wàásù fáwọn ará Paris tí wọ́n rí towó ṣe, àmọ́ ó ṣeé ṣe fún mi láti kọ́ ọ̀pọ̀ lára wọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó di 1956, Arábìnrin Ida ṣègbéyàwó, ó sì lọ sílẹ̀ Áfíríkà, àmọ́ èmi ṣì dúró sílùú Paris.

Lọ́dún 1960, èmi àti arákùnrin kan tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ṣègbéyàwó, a sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe láwọn àdúgbò kan tí wọ́n ń pè ní Chaumont àti Vichy. Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ikọ́ ẹ̀gbẹ bẹ̀rẹ̀ sí í yọ mí lẹ́nu, èyí sì mú kí n dá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà dúró. Ọkàn mi bà jẹ́ gidigidi, torí pé àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ni iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ti ń wù mí, kò sí wù mí kí n fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Lákòókò kan lẹ́yìn náà, ọkọ mi fi mí sílẹ̀, ó sì lọ fẹ́yàwó míì. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbà tí nǹkan le koko yẹn, Jèhófà sì ń bá a nìṣó láti máa bá mi gbé ẹrù mi.—Sm. 68:19.

Àdúgbò kan tí wọ́n ń pè ní Louviers, Normandy ni mò ń gbé báyìí, nítòsí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ilẹ̀ Faransé. Bó tiẹ̀ jẹ pé àìlera ń bá mi fínra, inú mi dùn pé mo rí ọwọ́ Jèhófà láyé mi. Báwọn òbí mi ṣe tọ́ mi dàgbà ṣì ń ràn mi lọ́wọ́ títí dòní láti ní èrò tó tọ́ nípa àwọn nǹkan. Àwọn òbí mi kọ́ mi pé Ẹni gidi ni Jèhófà, pé mo lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, mo lè bá a sọ̀rọ̀, ó sì máa dáhùn àdúrà mi. Ká sòótọ́, “kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀?”—Sm. 116:12.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Inú mi dùn pé mo rí ọwọ́ Jèhófà láyé mi”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìgbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́fà, mo wọ ìbòjú onígáàsì kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Èmi àtàwọn míṣọ́nnárì àtàwọn aṣáájú ọ̀nà ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù àkànṣe lórílẹ̀-èdè Luxembourg, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni mí nígbà yẹn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Èmi àtàwọn òbí mi ní àpéjọ àgbègbè kan lọ́dún 1953