Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fífaṣẹ́lénilọ́wọ́—Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Báwo Ló sì Ṣe Yẹ Ká Ṣe É?

Fífaṣẹ́lénilọ́wọ́—Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Báwo Ló sì Ṣe Yẹ Ká Ṣe É?

Fífaṣẹ́lénilọ́wọ́—Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Báwo Ló sì Ṣe Yẹ Ká Ṣe É?

KÁLÁYÉ tó dáyé ni wọ́n ti máa ń fa iṣẹ́ léni lọ́wọ́. Jèhófà dá Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, ó sì lò ó gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́” láti dá ayé àtọ̀run. (Òwe 8:22, 23, 30; Jòh. 1:3) Nígbà tí Ọlọ́run dá tọkọtaya àkọ́kọ́, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n “kún ilẹ̀ ayé” kí wọ́n sì “ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́n. 1:28) Ẹlẹ́dàá fi síkàáwọ́ èèyàn láti mú kí ọgbà Édẹ́nì tó jẹ́ Párádísè gbòòrò kárí ayé. Láìsí àní-àní, látìbẹ̀rẹ̀ ni Jèhófà àtàwọn tó ń sìn ín tí máa ń fa iṣẹ́ léni lọ́wọ́.

Kí ni fífaṣẹ́lénilọ́wọ́ túmọ̀ sí? Kí nìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà ìjọ mọ bá a ṣe ń fa àwọn iṣẹ́ ìjọ kan léni lọ́wọ́, báwo sì ni wọ́n ṣe lè ṣe é?

Kí Ni Fífaṣẹ́lénilọ́wọ́ Túmọ̀ Sí?

Ìwé atúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì kan sọ pé: “Fífaṣẹ́lénilọ́wọ́” túmọ̀ sí “fífi nǹkan síkàáwọ́ ẹnì kan, yíyan ẹnì kan láti ṣojú ẹni, gbígbé iṣẹ́ fúnni tàbí gbígbé àṣẹ léni lọ́wọ́.” Nítorí náà, fífaṣẹ́lénilọ́wọ́ ń mú kéèyàn fáwọn ẹlòmíì láǹfààní láti gbé àwọn nǹkan ṣe. Ìyẹn sì máa ń mú kéèyàn gbé àṣẹ lé àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.

A retí pé káwọn tá a faṣẹ́ lé lọ́wọ́ nínú ìjọ Kristẹni ṣe iṣẹ́ wọn yanjú, kí wọ́n sọ ìròyìn bí iṣẹ́ wọn ṣe ń tẹ̀ síwájú sí, kí wọ́n sì máa béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ẹni tó yan iṣẹ́ fún wọn. Àmọ́, bí iṣẹ́ náà ṣe máa yọrí sí rere wà lọ́wọ́ ẹni tó fa iṣẹ́ léni lọ́wọ́. Ó yẹ kó máa wo bí iṣẹ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú sí, kó sì máa fún ẹni tó gbéṣẹ́ fún nímọ̀ràn tó yẹ. Síbẹ̀, àwọn kan lè béèrè pé, ‘Kí ló dé tó o fi ní láti faṣẹ́ lé ẹlòmíì lọ́wọ́ nígbà tó o lè ṣe iṣẹ́ ọ̀hún fúnra ẹ̀?’

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Faṣẹ́ Léni Lọ́wọ́?

Má gbàgbé pé nígbà tí Jèhófà dá Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, ó fa iṣẹ́ lé e lọ́wọ́ pé kó lọ́wọ́ nínú dídá àwọn nǹkan tó kù. Bíbélì sọ pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí.” (Kól. 1:16) Kì í ṣe pé Ẹlẹ́dàá ò lè dá ohun gbogbo fúnra rẹ̀ o, àmọ́, ó fẹ́ kí Ọmọ òun náà ní ayọ̀ tó máa ń wà nínú ṣíṣe iṣẹ́ rere. (Òwe 8:31) Èyí mú kí Ọmọ Ọlọ́run túbọ̀ mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run. Nípa báyìí, Baba lo àǹfààní yẹn láti kọ́ Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo lẹ́kọ̀ọ́.

Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fara wé Baba rẹ̀ nípa fífa iṣẹ́ lé àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Ó rán àwọn àpọ́sítélì méjìlá àti lẹ́yìn náà àwọn àádọ́rin, kí wọ́n lè mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Lúùkù 9:1-6; 10:1-7) Nígbà tí Jésù fi máa dé ibi táwọn ọmọ ẹ̀yìn ti wàásù yẹn, wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún ìwàásù Jésù. Nígbà tí Jésù fẹ́ kúrò láyé, ó fa àwọn iṣẹ́ tó túbọ̀ ṣe pàtàkì, títí kan iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé lé àwọn ọmọ ẹyìn rẹ̀ tó ti dá lẹ́kọ̀ọ́ yẹn lọ́wọ́.—Mát. 24:45-47; Ìṣe 1:8.

Fífaṣẹ́lénilọ́wọ́ àti dídáni lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ohun tí ìjọ Kristẹni máa ń ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Nǹkan wọ̀nyí ni kí o fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́, tí àwọn, ẹ̀wẹ̀, yóò tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.” (2 Tím. 2:2) Bó ṣe rí nìyẹn, àwọn tó ti mọṣẹ́ á dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, àwọn yẹn náà á sì wá dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́.

Bí alàgbà kan bá ń fa díẹ̀ lára iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un lé àwọn míì lọ́wọ́, ńṣe ló ń jẹ́ kí wọ́n nípìn-ín nínú ayọ̀ tó wà nínú kíkọ́ni àti ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn. Mímọ̀ táwọn alàgbà mọ̀ pé ó níbi tí agbára àwa èèyàn mọ jẹ́ ìdí pàtàkì tí wọ́n fi ní láti máa fa iṣẹ́ lé àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ nínú ìjọ. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà gba pé kéèyàn mọ ibi tágbára òun mọ. Bó o bá ń gbìyànjú láti ṣe gbogbo nǹkan fúnra ẹ, èyí á máa tán ẹ lókun, á sì tún gba àkókò tó yẹ kó o máa lò pẹ̀lú ìdílé ẹ. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kó o máa pín lára iṣẹ́ rẹ fáwọn ẹlòmíì. Wo àpẹẹrẹ arákùnrin tó jẹ́ olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Ó lè sọ fáwọn alàgbà míì pé kí wọ́n bá òun ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ. Bí àwọn alàgbà yẹn ṣe ń ṣàyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ náà, á jẹ́ kí wọ́n mọ bí ọ̀ràn ìnáwó ìjọ wọn ṣe rí.

Yàtọ̀ sí pé fífaṣẹ́lénilọ́wọ́ máa ń mú káwọn tó gba iṣẹ́ náà túbọ̀ ní òye àti ìrírí sí i, ó tún máa ń jẹ́ kí ẹni tó fa iṣẹ́ léni lọ́wọ́ mọ ibi tágbára àwọn tóun fa iṣẹ́ lé lọ́wọ́ mọ. Nítorí náà, táwọn alàgbà bá ń gbé àwọn iṣẹ́ kan lé àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ nínú ìjọ, wọ́n á lè dán àwọn tó máa di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́jọ́ iwájú wò láti mọ “bí wọn ti yẹ sí.”—1 Tím. 3:10.

Lékè gbogbo rẹ̀, báwọn alàgbà bá ń fa iṣẹ́ léni lọ́wọ́, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn fọkàn tán wọn. Pọ́ọ̀lù dá Tímótì lẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Èyí mú káwọn méjèèjì mọwọ́ ara wọn gan-an. Pọ́ọ̀lù pe Tímótì ní “ojúlówó ọmọ nínú ìgbàgbọ́.” (1 Tím. 1:2) Bákàn náà ni àjọṣe tímọ́tímọ́ ṣe wà láàárín Jèhófà àti Jésù bí wọ́n ṣe jọ ń dá àwọn nǹkan yòókù. Báwọn alàgbà bá ń fa iṣẹ́ léni lọ́wọ́, èyí á mú kí àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín wọn àtàwọn tí wọ́n fa iṣẹ́ lé lọ́wọ́.

Ìdí Táwọn Kan Fi Ń Lọ́ra Láti Fa Iṣẹ́ Léni Lọ́wọ́

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà mọ àǹfààní tó wà nínú fífaṣẹ́lénilọ́wọ́, ó ṣòro fáwọn kan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n máa ń lọ́ tìkọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, bóyá nítorí wọ́n rò pé àwọn ò ní láṣẹ lórí wọn mọ́. Wọ́n lè máa rò pé àwọn nìkan làwọn mọ̀ ọ́n ṣe. Àmọ́, rántí pé kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn láṣẹ láti gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta kan ṣe, ó mọ̀ pé wọ́n máa ṣe iṣẹ́ tó pọ̀ ju tòun lọ!—Mát. 28:19, 20; Jòh. 14:12.

Àwọn alàgbà kan lè ti gbé iṣẹ́ lé àwọn kan lọ́wọ́ nígbà kan rí, àmọ́ tí nǹkan ò rí bí wọ́n ṣe fẹ́. Wọ́n lè rò pé tó bá jẹ́ pé àwọn fúnra àwọn làwọn ṣiṣẹ́ náà, á dára, á sì tún yá jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Ó mọ ìjẹ́pàtàkì gbígbé iṣẹ́ léni lọ́wọ́, àmọ́ ó tún mọ̀ pé ẹni tóun ń dá lẹ́kọ̀ọ́ lè má ṣiṣẹ́ náà bóun ṣe fẹ́. Nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ lọ, ó dá Máàkù ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ rìnrìn àjò lẹ́kọ̀ọ́. Ó dun Pọ́ọ̀lù gan-an pé Máàkù pa iṣẹ́ tóun gbé fún un tì, tó sì pa dà lọ sílé. (Ìṣe 13:13; 15:37, 38) Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ò ní máa dá àwọn ẹ̀lòmíì lẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Bá a ti mẹ́nu kàn án tẹ́lẹ̀, ó pe Tímótì ọ̀dọ́ pé kó wá máa bóun rìnrìn àjò. Nígbà tí Tímótì ti múra tán láti bójú tó iṣẹ́ tó túbọ̀ wúwo, Pọ́ọ̀lù fi í sílẹ̀ ní Éfésù, ó gbé àṣẹ lé Tímótì lọ́wọ́ láti máa yan àwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ.—1 Tím. 1:3; 3:1-10, 12, 13; 5:22.

Bákan náà lóde òní, àwọn alàgbà ò gbọ́dọ̀ torí pé ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n ń dá lẹ́kọ̀ọ́ kò ṣe dáadáa, kí wọ́n wá jáwọ́ nínú dídá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Ó bọ́gbọ́n mu, ó sì ṣe pàtàkì pé ká máa fọkàn tán àwọn ẹlòmíì ká sì máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, àwọn nǹkan wo ló yẹ káwọn alàgbà fi sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń fa iṣẹ́ léni lọ́wọ́?

Bá A Ṣe Lè Faṣẹ́ Léni Lọ́wọ́

Tá a bá fẹ́ fa iṣẹ́ léni lọ́wọ́, ó yẹ ká ronú nípa báwọn ẹni náà ti kúnjú ìwọ̀n tó. Ní Jerúsálẹ́mù, nígbà tí wọ́n nílò àwọn táá máa bójú tó pínpín oúnjẹ lójoojúmọ́, àwọn àpọ́sítélì yan ‘ọkùnrin méje tí wọ́n jẹ́rìí gbè láàárín wọn, tí wọ́n kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n.’ (Ìṣe 6:3) Tó o bá yanṣẹ́ fún ẹni tí kò ṣeé gbára lé, ó lè já ọ kulẹ̀, iṣẹ́ ọ̀hún ò sì ní di ṣíṣe. Nítorí náà, ńṣe ni kó o bẹ̀rẹ̀ látorí iṣẹ́ kékeré. Tónítọ̀hún bá ṣe dáadáa, ó fi hàn pé ó lè ṣe iṣẹ́ tó túbọ̀ pọ̀ sí i nìyẹn.

Àmọ́, ó tún ku àwọn nǹkan míì. Ohun náà ni pé, ànímọ́ àti agbára àwọn èèyàn yàtọ̀ síra. Ìrírí náà ò sì dọ́gba. Arákùnrin kan tó lọ́yàyà tára ẹ̀ sì yọ̀ mọ́ni lè ṣe dáadáa tí wọ́n bá ní kó máa bójú tó èrò. Àmọ́ arákùnrin kan tó mètò, tó sì lè ṣe nǹkan fínnífínní lè ṣe dáadáa tí wọ́n bá ní kó máa ran akọ̀wé ìjọ lọ́wọ́. A lè gbé iṣẹ́ fún arábìnrin tó mọ bá a ṣe ń ṣe nǹkan lọ́ṣọ̀ọ́ láti ṣètò àwọn òdòdó nígbà Ìrántí Ikú Kristi.

Nígbà tá a bá ń yan iṣẹ́ fáwọn èèyàn, ó yẹ ká sọ ohun tá a fẹ́ kí wọ́n ṣe. Kí Jòhánù Oníbatisí tó rán àwọn ońṣẹ́ sí Jésù, ó ṣàlàyé ohun tóun fẹ́ mọ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa fi ṣèwádìí. (Lúùkù 7:18-20) Àmọ́ nígbà tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n lọ kó àṣẹ́kùsílẹ̀ oúnjẹ tó pèsè lọ́nà ìyanu, kò sọ bí wọ́n ṣe máa ṣe é. (Jòh. 6:12, 13) Ọ̀ràn náà sinmi lórí irú iṣẹ́ náà àti báwọn tá a gbéṣẹ́ lé lọ́wọ́ ṣe kúnjú ìwọ̀n tó. Ẹni tó gbéṣẹ́ léni lọ́wọ́ àtẹni tó gba iṣẹ́ náà ní láti mọ bí iṣẹ́ náà ṣe máa rí nígbà tó bá parí àti bí ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ náà á ṣe máa sọ bó ṣe ń lọ sí fún ẹni tó gbéṣẹ́ fún un. Àwọn méjèèjì ló gbọ́dọ̀ mọ̀gbà tó yẹ kẹ́ni tó máa ṣiṣẹ́ náà lo ìdánúṣe lórí iṣẹ́ ọ̀hún. Bó bá lọ́jọ́ tó yẹ kí iṣẹ́ náà parí, àwọn méjèèjì ló yẹ kí wọ́n jọ jíròrò ẹ̀, kí wọ́n sì ṣe àdéhùn ọjọ́ náà gan-an tí wọ́n fẹ́ kó parí, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ kàn-ń-pá fún ẹnì kan.

Ẹni tó gbéṣẹ́ léni lọ́wọ́ ní láti pèsè owó, ohun èlò àti àtìlẹ́yìn tẹ́ni náà nílò lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ó máa dáa kẹ́ ẹ jẹ́ káwọn ẹlòmíì mọ ètò tẹ́ ẹ ṣe nípa iṣẹ́ náà. Nígbà tí Jésù fún Pétérù ní “kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run,” àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù wà níbẹ̀. (Mát. 16:13-19) Bákan náà, nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó máa dáa láti jẹ́ kí ìjọ mọ ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ kan.

Ó gba ìṣọ́ra tá a bá ń fa iṣẹ́ léni lọ́wọ́. Tó o bá wonkoko mọ́ dídarí iṣẹ́ tó o ti gbé léni lọ́wọ́, ohun tó ò ń sọ fún ẹni náà ni pé: “Mi ò fọkàn tán ẹ.” Lóòótọ́ o, nígbà míì, iṣẹ́ náà lè má rí bó o ṣe fẹ́ kó rí gan-an. Síbẹ̀ tó o bá fún arákùnrin tó o gbéṣẹ́ lé lọ́wọ́ lómìnira láti ṣe nǹkan tóun fúnra ẹ̀ rí i pé ó dára, ọkàn ẹ̀ á balẹ̀, á sì mọ iṣẹ́ náà dunjú. Àmọ́ ṣá o, èyí ò túmọ̀ sí pé kó o kàn fi ẹni náà sílẹ̀ kó máa ṣiṣẹ́ náà bó ṣe wù ú o. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà gbé iṣẹ́ ìṣẹ̀dá lé Ọmọ ẹ̀ lọ́wọ́, síbẹ̀ Jèhófà fúnra ẹ̀ ṣe nínú iṣẹ́ náà. Ó sọ fún Àgbà Òṣìṣẹ́ náà pé: “Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa.” (Jẹ́n. 1:26) Torí náà, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe ẹ fi hàn pé ò ń ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn, kó o sì gbóríyìn fẹ́ni tó o gbéṣẹ́ lé lọ́wọ́. Àyẹ̀wò ráńpẹ́ tó o bá ṣe lẹ́yìn tíṣẹ́ náà bá parí lè ran ẹni náà lọ́wọ́. Bíṣẹ́ náà ò bá rí bó o ṣe fẹ́, má ṣe lọ́ra láti fún un ní àfikún ìmọ̀ràn tàbí ìrànlọ́wọ́. Má ṣe gbàgbé pé ìwọ tó o yanṣẹ́ fúnni ló máa dáhùn fún ohun tó bá jẹ́ àbájáde iṣẹ́ náà.—Lúùkù 12:48.

Ọ̀pọ̀ ló ti jàǹfààní nínú iṣẹ́ táwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ wọn gbé lé wọn lọ́wọ́. Ká sòótọ́, ó yẹ káwọn alàgbà mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa fa iṣẹ́ léni lọ́wọ́ àti bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é, kí wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ fìwà jọ Jèhófà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]

FÍFAṢẸ́LÉNILỌ́WỌ́ JẸ́

• ọ̀nà kan láti jẹ́ káwọn ẹlòmíì ní ayọ̀ tó wà nínú ṣíṣe nǹkan láṣeyanjú

• ọ̀nà kan láti gbà ṣe ohun tó pọ̀

• ọ̀nà kan láti fi hàn pé èèyàn gbọ́n, ó sì mẹ̀tọ́mọ̀wà

• ọ̀nà kan láti dáni lẹ́kọ̀ọ́

• ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a fọkàn tánni

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

BÁ A ṢE LÈ FA IṢẸ́ LÉNI LỌ́WỌ́

• Yan ẹni tó tọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà

• Ṣàlàyé ní kedere, kẹ́ ẹ sì jọ sọ̀rọ̀

• Jẹ́ kóhun tó o fẹ́ kẹ́ni náà ṣe yé e dáadáa

• Pèsè àwọn nǹkan pàtàkì tó máa fi ṣiṣẹ́ náà

• Fi hàn pé iṣẹ́ náà ṣe pàtàkì sí ẹ, kó o sì jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé o fọkàn tán an

• Múra tán láti dáhùn fún ohun tó bá jẹ́ àbájáde iṣẹ́ náà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ara fífaṣẹ́lénilọ́wọ́ ni yíyan iṣẹ́ àti wíwo bí iṣẹ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú sí