Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó O Lè Lóye Bíbélì?

Ṣó O Lè Lóye Bíbélì?

Ṣó O Lè Lóye Bíbélì?

“Gbogbo ọjọ́ Sunday la máa ń ka Bíbélì nílé wa. Àmọ́ mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ gbádùn ẹ̀. Mo gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan tí mò ń kà nínú ẹ̀ ló máa ń ṣòro fún mi gan-an láti lóye.”—Steven, láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

“Mo gbìyànjú láti ka Bíbélì nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17]. Àmọ́ àwọn nǹkan tí mò ń kà ò yé mi, bí mo ṣe pa á tì nìyẹn.”—Valvanera, láti orílẹ̀-èdè Sípéènì.

“Mo ti ka Bíbélì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo rí torí mo mọ̀ pé, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́sìn Kátólíìkì mi ò gbọ́dọ̀ má ka Bíbélì. Ó gbà mí ní odindi ọdún mẹ́ta gbáko kí n tó lè ka Bíbélì láti páálí dé páálí! Ohun tí mo lóye nínú nǹkan tí mo kà ò tó nǹkan rárá.”—Jo-Anne, láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà.

BÍBÉLÌ ni ìwé tó tíì gbajúmọ̀ jù lọ ní gbogbo àgbáyé. Òun ṣì ni ìwé tó ń tà jù lọ lọ́jà, torí pé àwọn èèyàn tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ló ń ní Bíbélì láwọn èdè tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, àwọn èèyàn sì ti wá ń ṣe Bíbélì sórí àwọn ohun èlò bíi kásẹ́ẹ̀tì, àwo CD àti àwo DVD ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Síbẹ̀, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ní Bíbélì láti lóye rẹ̀. Ṣé bó ṣe máa ń rí tíwọ náà bá ń ka Bíbélì nìyẹn?

Ṣé Ọlọ́run Fẹ́ Ká Lóye Ọ̀rọ̀ Rẹ̀?

Bíbélì sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Ó dájú pé, Jèhófà Ọlọ́run ni òǹṣèwé Bíbélì. Ṣó fẹ́ kí gbogbo èèyàn lóye Ọ̀rọ̀ òun? Àbí ìwọ̀nba àwọn èèyàn, irú bí àwọn olórí ìsìn àtàwọn ọ̀mọ̀wé nìkan ni Ọlọ́run dìídì fẹ́ kí wọ́n lóye Bíbélì?

Kíyè sóhun táwọn ẹsẹ tó wà nínú Bíbélì funra rẹ̀ sọ:

“Àwọn àṣẹ yìí tí mo ń pa fún ọ lónìí kò ṣòro rárá fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ibi jíjìnnàréré.”Diutarónómì 30:11.

“Ìsọdimímọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ń fúnni ní ìmọ́lẹ̀, ó ń mú kí àwọn aláìní ìrírí lóye.”—Sáàmù 119:130.

“Ní wákàtí yẹn gan-an, [Jésù] wá ní ayọ̀ púpọ̀ nínú ẹ̀mí mímọ́, ó sì wí pé: ‘Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti rọra fi ohun wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.’”Lúùkù 10:21.

Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ kó o lóye Ọ̀rọ̀ òun. Àmọ́, òótọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé ó máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó dìídì fẹ́ mọ òótọ́ láti lóye Bíbélì. Kí ló wá lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí máa sọ àwọn nǹkan mẹ́ta téèyàn lè ṣe tó bá fẹ́ lóye àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.