Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

1. Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́

1. Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́

Bó O Ṣe Lè Lóye Bíbélì

1. Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́

Ninfa tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé: “Nígbà kan, mo máa ń ka Bíbélì kí n tó lọ sùn lálẹ́. Ìdí tí mo fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, mo mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, bí mi ò tiẹ̀ kì í gbádùn kíkàwé, mo fẹ́ mohun tí Ọlọ́run kọ sínú Bíbélì fún wa. Ó wù mí kí n kà á láti páálí dé páálí. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀, mo kọ́kọ́ ń gbádùn ẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tó yá mo dé àwọn apá ibi tó ṣòro fún mi láti lóye, bí mo ṣe pa á tì nìyẹn.”

ṢÉRÚ ohun tó ṣe Ninfa yìí ti ṣe ìwọ náà rí? Ọ̀pọ̀ èèyàn nirú ẹ̀ ti ṣe rí. Àmọ́, àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí ti jẹ́ ká mọ̀ pé, Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó fún wa ní Bíbélì, fẹ́ kó o lóye Ọ̀rọ̀ òun. Báwo wá lo ṣe lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Nǹkan àkọ́kọ́ tó o ní láti ṣe ni pé kó o gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Àwọn èèyàn ka àwọn àpọ́sítélì Jésù sí “àwọn [ẹni] tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù” torí pé wọn ò lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ níléèwé àwọn rábì. (Ìṣe 4:13) Jésù jẹ́ kó dá wọn lójú pé wọ́n máa lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Báwo ni wọ́n ṣe máa lóye rẹ̀? Jésù ṣàlàyé pé: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, èyí tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo.” (Jòhánù 14:26) Ẹ̀mí mímọ́, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ yìí ni Ọlọ́run lò láti ṣẹ̀dá ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) Òun náà ló tún lò láti mí sí nǹkan bí ogójì [40] èèyàn kí wọ́n lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó fẹ́ sínú Bíbélì. (2 Pétérù 1:20, 21) Ẹ̀mí mímọ́ kan náà yìí ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ran àwọn tó bá fẹ́ lóye Bíbélì lọ́wọ́.

Báwo lo ṣe lè rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà? O ní láti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kó o sì nígbàgbọ́ pé ó máa dáhùn àdúrà ẹ. Kódà, ó lè gba pé kó o béèrè léraléra. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín, bí ẹ̀yin . . . bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:9, 13) Jèhófà máa fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó bá ń fi tọkàntọkàn béèrè fún un. Ipá ìṣiṣẹ́ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè lóye àwọn ọ̀rọ̀ tó ti wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Ẹ̀mí Ọlọ́run tún lè fún ẹ ní ọgbọ́n tó o nílò kó o lè máa fàwọn ìsọfúnni tó wúlò látinú Bíbélì sílò nígbèésí ayé rẹ.—Hébérù 4:12; Jákọ́bù 1:5, 6.

Torí náà, ní gbogbo ìgbà tó o bá ti fẹ́ ka Bíbélì, ṣe ni kó o máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́, kó o lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.