Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àbẹ̀wò sí Ilé Ìtẹ̀wé kan Tó Pabanbarì

Àbẹ̀wò sí Ilé Ìtẹ̀wé kan Tó Pabanbarì

Àbẹ̀wò sí Ilé Ìtẹ̀wé kan Tó Pabanbarì

Ó ṢEÉ ṢE kó jẹ́ pé ìwé tó ò ń kà yìí kọ́ lo máa kọ́kọ́ rí nínú àwọn ìwé ìròyìn wa. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tiẹ̀ lè ti wá sílé yín rí, kí wọ́n sì ti fún ẹ ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! kó o bàa lè túbọ̀ lóye Bíbélì dáadáa. Ó sì lè jẹ́ pé o ti rí àwa Ẹlẹ́rìí níbi tá a ti ń fàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí Bíbélì lọ àwọn èèyàn ní òpópónà tàbí láàárín ọjà kan ládùúgbò yín. Kódà iye ìwé ìròyìn yìí tá à ń pín kiri lóṣooṣù ti ju mílíọ̀nù márùnlélọ́gbọ̀n [35] lọ báyìí, ó sì wá tipa bẹ́ẹ̀ di ìwé ìròyìn tó dá lórí ìsìn tá a tíì pín kiri jù lọ lágbàáyé.

Ṣó o tiẹ̀ ti rò ó rí pé, ibo gan-an la ti ń tẹ àwọn ìwé yìí, báwo la sì ṣe ń tẹ̀ ẹ́? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ilé ìtẹ̀wé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń tẹ àwọn ìwé wa, ìyẹn èyí tó wà nílùú Wallkill, ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó lè má rọrùn fún ọ̀pọ̀ lára àwọn òǹkàwé wa yíká ayé láti rìnrìn-àjò wá sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kí wọ́n lè wá wo ilé ìtẹ̀wé wa tó wà ní New York, àmọ́ àlàyé tá a máa ṣe nínú àpilẹ̀kọ yìí àtàwọn àwòrán tó o máa rí máa jẹ́ kó o mọ̀ nípa àwọn ohun tó ń lọ níbẹ̀.

Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti mọ̀ pé látorí ìwé kíkọ ni iṣẹ́ ìwé títẹ̀ ti máa ń bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìwé Kíkọ, ní Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York máa ń lo kọ̀ǹpútà láti fàwọn ìwé tí wọ́n bá kọ ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwòrán Yíyà. Ẹ̀ka yìí máa wá fìyẹn ṣe àwo ìtẹ̀wé. Nǹkan bí egbèje [1,400] róòlù bébà ló máa ń dé sí ilé ìtẹ̀wé wa nílùú Wallkill lóṣooṣù, a sì máa ń lo ìwọ̀n bébà tó wúwo tó ẹgbẹ̀jọ [1,600] sí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] àpò sìmẹ́ǹtì láti fi tẹ̀wé lójúmọ́. Àwọn róòlù bébà, táwọn kan lára wọn tẹ̀wọ̀n tó nǹkan bí àpò sìmẹ́ǹtì méjìdínlọ́gbọ̀n [28], la máa ń gbé sínú àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńláńlá márùn-ún tá a ti fi àwọn àwo ìtẹ̀wé sí. Àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyẹn á wá tẹ ọ̀rọ̀ àtàwòrán sórí àwọn bébà wọ̀nyẹn, wọ́n á gé e sí abala-abala, wọ́n á sì ká abala kọ̀ọ̀kan sí ojú ewé méjìlélọ́gbọ̀n [32]. Abala kan látinú róòlù bébà yẹn ni ìwé ìròyìn tó ò ń kà yìí. Báwo la ṣe ń ṣe àwọn ìwé ńlá? Níbi tá a ti ń di ìwé pọ̀, a máa ń di abala kọ̀ọ̀kan, tí àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé yẹn bá ti ká, pa pọ̀ láti fi ṣe odindi ìwé. A lè ṣe ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000] ìwé ẹlẹ́yìn páálí tàbí ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínlọ́gọ́rin [75,000] ìwé ẹlẹ́yìn rírọ̀ jáde lọ́jọ́ kan ṣoṣo látinú ọ̀kan lára àwọn ibi méjì tá a ti máa ń di ìwé pọ̀. A sì lè ṣe ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] ìwé ẹlẹ́yìn rírọ̀ jáde lójúmọ́ láti ibì kejì.

Lọ́dún 2008, àwọn ìwé tá a ṣe jáde látinú ilé ìtẹ̀wé wa yìí lé ní mílíọ̀nù méjìdínlọ́gbọ̀n [28,000,000], nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta lára àwọn ìwé yìí ló sì jẹ́ Bíbélì. Iye ìwé ìròyìn tá a tẹ̀ jáde jẹ́ òjìlérúgba-lé-mẹ́ta mílíọ̀nù, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún-lé-mẹ́tàdínlógún, àti òjìdínlẹ́gbẹ̀ta-lé-mẹ́rin [243,317,564]. À ń ṣe àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì yìí jáde ní nǹkan bí okòó-dín-nírinwó [380] èdè. Lẹ́yìn tá a bá wá ṣe àwọn ìwé yìí tán, kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e?

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìlá, ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́rìnléláàádọ́ta [12,754] ni iye ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nígbà tá a ní ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mọ́kàndínláàádọ́rin [1,369] ìjọ láwọn erékùṣù Caribbean àti Hawaii. Àwọn ìjọ yìí sì máa ń kọ̀wé béèrè fáwọn ìwé tá à ń tẹ̀. Ẹ̀ka Ìkówèéránṣẹ́ wa ló máa ń di àwọn ìwé tí wọ́n bá béèrè tí wọ́n á sì ṣètò bí wọ́n á ṣe gbé e lọ fáwọn ìjọ tó bá béèrè fún un. Lọ́dọọdún, a máa ń kó àwọn ìwé tó wúwo tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27,000] àpò sìmẹ́ǹtì ránṣẹ́ sáwọn ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ló ṣe pàtàkì jù nínú ilé ìtẹ̀wé yìí, bí kò ṣe àwọn èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ló ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà nínú ilé ìtẹ̀wé náà, lára àwọn ẹ̀ka ọ̀hún ni Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwòrán Yíyà, Ẹ̀ka Tó Ń Ṣètò Iṣẹ́, Ibi Ìtẹ̀wé, Ibi Tá A Ti Ń Di Ìwé Pọ̀, àti Ẹ̀ka Ìkówèéránṣẹ́. Àwọn ọ̀ṣìṣẹ́ yìí kì í gbowó oṣù, ṣe ni wọ́n yọ̀nda ara wọn, ọjọ́ orí wọn sì bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sí méjìléláàádọ́rùn-ún [92].

Ire àwọn èèyàn ló jẹ wọ́n lógún, ìyẹn àwọn èèyàn tó máa gba ìwé yìí, tí wọ́n á kà á tọkàntọkàn, tí wọ́n á kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n á rí ìṣírí gbà nípasẹ̀ rẹ̀, tí wọ́n á sì jẹ́ káwọn ìlànà Bíbélì tá a jíròrò nínú rẹ̀ darí àwọn. A nírètí pé o wà lára irú àwọn ẹni yẹn àti pé àwọn ìwé tá à ń tẹ̀ nínú ilé ìtẹ̀wé wa á máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa gba ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi, kó o lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 17:3.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]