Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere

Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere

Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere

Kí nìdí tí obìnrin kan tí kò nígbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn kankan mọ́ fi tún wá ń lo ọ̀pọ̀ àkókò rẹ̀ láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run? Kí ló mú kí ọkùnrin kan tó fẹ́ràn eré ìnàjú oníwà ipá di èèyàn àlàáfíà? Báwo ni ọkùnrin kan tó jẹ́ ajoògùnyó, ọ̀mùtí àti oníjàgboro tẹ́lẹ̀ ṣe yí ìgbésí ayé ẹ̀ pa dà? Gbọ́ ohun táwọn èèyàn náà sọ.

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ

ORÚKỌ: PENELOPE TOPLICESCU

ỌJỌ́ ORÍ: OGÓJÌ ỌDÚN

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: ỌSIRÉLÍÀ

OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ MI: ÌSÌN JÁ MI KULẸ̀

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Sydney ni wọ́n ti bí mi, nílẹ̀ Ọsirélíà, àmọ́ nígbà tí mo wà lọ́mọdún méjì péré, àwọn òbí mi kó lọ sí erékùṣù New Guinea. A lo ọdún méjì ní ìlú Rabaul, lẹ́yìn náà a kó lọ sí erékùṣù Bougainville, a sì lo ọdún mẹ́jọ níbẹ̀. Nígbà yẹn, kò sí Tẹlifíṣọ̀n ní gbogbo erékùṣù New Guinea, torí náà èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin máa ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wa láti máa fi lúwẹ̀ẹ́ kiri nínú òkun àti láti máa gbé nínú àgọ́.

Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́wàá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ ẹ̀sìn. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni màmá mi, wọ́n sì dábàá pé kí n lọ máa kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ọ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Èmi náà di ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, mo sì ṣèrìbọmi nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá.

Àmọ́, lẹ́yìn tá a pa dà sílẹ̀ Ọsirélíà, tí mo sì ti lé lọ́mọdún méjìlá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì nípa àwọn ohun tí mo ti kọ́ nípa ẹ̀sìn. Ẹ̀kọ́ nípa ìtàn ayé àtijọ́ ni mo kọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga, èmi àti bàbá mi sì ti jọ sọ̀rọ̀ gan-an nípa bí ẹ̀sìn ṣe bẹ̀rẹ̀ àtàwọn ohun tá a kà nínú Bíbélì, tá a sì gbà pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àsọdùn lásán. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo pa ẹ̀sìn Kátólíìkì tì.

Màmá mi kó kúrò lọ́dọ̀ bàbá mi nígbà tí mo wà lọ́mọdún mẹ́rìndínlógún [16]. Nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ lọ déédéé fún màmá mi lẹ́yìn ìgbà náà, ìyẹn ló sì jẹ́ kí n kó pa dà sọ́dọ̀ bàbá mi àti ìyàwó wọn tuntun. Ẹ̀gbọ́n mi wà lọ́dọ̀ màmá wa, wọ́n sì jọ kó lọ sí apá ibòmíì nílẹ̀ Ọsirélíà. Mo máa ń nímọ̀lára pé mo dá nìkan wà gan-an ní gbogbo àkókò yìí. Ó gbà mí tó ọdún méjì gbáko kí n tó lè mú àárín èmi àti màmá mi gún pa dà. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í mutí, mò ń lo oògùn olóró, mo sì ń ti agbo àríyá kan dé agbo àríyá míì. Mo fi iléèwé sílẹ̀, mo wá iṣẹ́ kan ṣe, mo sì fi ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé mi, ìyẹn ìgbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún [20] ọdún, ṣòfò nípa gbígbé ìgbésí ayé tí kò nítumọ̀.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa Bíbélì lẹ́ẹ̀kan sí i. Mo ríṣẹ́ sílé iṣẹ́ míì, ibẹ̀ ni mo sì ti mọ ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Liene, ara ẹ̀ yá mọ́ èèyàn, kì í sì í yájú sí ọ̀gá ẹ̀, láìka pé ọ̀gá yẹn máa ń fàbùkù kàn án. Nígbà tí mo bi í pé kí nìdí tóun náà kì í fi í dá tiẹ̀ pa dà tí ọ̀gá ẹ̀ bá ń kàn án lábùkù, ó ṣàlàyé fún mi pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, òun sì ń sapá láti máa fàwọn ìlànà Bíbélì tí wọ́n ń kọ́ òun sílò nígbèésí ayé òun. Liene sọ pé òun máa kọ́ èmi náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tó sọ ò kọ́kọ́ yé mi, ṣe ni mo rò pé ó ní kò ní ju wákàtí kan lọ tóun á fi kọ́ mi ní gbogbo ohun tóun mọ̀ nípa Bíbélì. Odindi wákàtí mẹ́ta ni Liene fi dáhùn àwọn ìbéèrè tí mò ń bi í látinú Bíbélì lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé gbogbo ìbéèrè tí mo bi í ló dáhùn, tó sì tún ń ka Bíbélì láti fi ti àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́yìn.

Mo rántí pé nígbà tí mò ń wakọ̀ lọ sílé lálẹ́ ọjọ́ yẹn, lẹ́yìn tí èmi àti Liene sọ̀rọ̀ tán, mò ń bínú sí Ọlọ́run pé kí ló dé tí kò jẹ́ kí n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látọjọ́ yìí. Mo mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀, àmọ́ mo ronú pé ó tí pẹ́ jù fún mi láti yíwà mi pa dà. Mo tún rò pé mi ò ní lè máa wàásù láti ilé dé ilé báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa ń ṣe. Mò ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ mi nìṣó pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ torí kí n lè rí nǹkan kan tó lòdì sọ nípa ẹ̀kọ́ wọn ni mo ṣì ṣe ń kọ́ ọ, ìyẹn á sì jẹ́ kí n lè dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró láìsí pé ọkàn mi ń dá mi lẹ́bi. Lọ́jọ́ kan ni mo wá mọ̀ pé mi ò ní lè rí ohunkóhun tó lòdì sí ẹ̀kọ́ wọn.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì sí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rí ọkàn mi túbọ̀ ń dà mí láàmú. Kí ẹ̀rí ọkàn mi bàa lè jẹ́ kí n gbádùn díẹ̀, mo jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró. Àmọ́, nígbà tí mo kó lọ sí orílẹ̀-èdè míì, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ ságbo àríyá, mo sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í mutí nímukúmu. Ó dà bíi pé gbogbo ìgbà tí mo bá ń gbìyànjú láti ṣohun tó bá ìlànà Bíbélì mu ni mo máa ń pa dà sínú ìwà mi àtijọ́. Ojú máa ń tì mí gan-an nígbà tí mo bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, síbẹ̀ ọkàn mi ṣì máa ń bà jẹ́.

Ohun tí mo kọ́ nípa nǹkan tí Dáfídì Ọba ṣe pẹ̀lú Bátí-ṣébà àti bí Jèhófà ṣe fàánú hàn sí wọn ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Dáfídì nígboyà débi pé ó gba àṣìṣe rẹ̀, nígbà tí Ọlọ́run rán wòlíì kan pé kó bá a wí fún ohun to ṣe, kò gbìyànjú láti dára ẹ̀ láre. Ó sì gba ìbáwí tí Ọlọ́run fún un tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 12:1-13) Ní gbogbo ìgbà tí mo bá ti ṣàṣìṣe, mo máa ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó rọrùn fún mi láti tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ Jèhófà. Lẹ́yìn náà mo pinnu láti máa gbàdúrà kí n tó ṣàṣìṣe dípò kí n gbàdúrà lẹ́yìn tí mo bá ṣàṣìṣe tán, ìyẹn sì ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Mo máa ń tètè bínú tẹ́lẹ̀. Àmọ́, ohun tó wà nínú ìwé Éfésù 4:29-31 ti jẹ́ kí n rí ìdí láti máa ṣọ́ra fún “ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú.” Bí mo ṣe ń sapá láti má ṣe máa bínú bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni mò ń sapá láti máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Yàtọ̀ síyẹn, ìmọ̀ràn Jésù tó sọ pé “kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni” túbọ̀ ràn mí lọ́wọ́ láti máa dúró lórí ọ̀rọ̀ mi.—Mátíù 5:37.

Màmá mi tí wọ́n kọ́kọ́ ta ko báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ fún mi nígbà tó yá pé àmúyangàn ọmọ ni mí. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé, “Mo mọ̀ pé kì í ṣe bá a ṣe tọ́ ẹ dàgbà ló jẹ́ kó o wá dèèyàn gidi báyìí àmọ́ ohun tó o ti kọ́ nípa Jèhófà ni.” Inú mi dùn gan-an láti gbọ́rọ̀ yìí lẹ́nu màmá mi.

Mo mọ̀ pé ìgbésí ayé mi ti nítumọ̀ báyìí. Láti ọdún mẹ́sàn-án sẹ́yìn ni èmi àti ọkọ mi ti ń lo àkókò tó pọ̀ láti máa fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo máa ń lọ wàásù láti ẹnu ọ̀nà kan sí òmíràn, mo sì wá mọ̀ pé iṣẹ́ yìí ni iṣẹ́ tó lérè jù lọ tí mo tíì ṣe rí.

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ

ORÚKỌ: DENIS BUSIGIN

ỌJỌ́ ORÍ: ỌGBỌ̀N ỌDÚN

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: RỌ́ṢÍÀ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO FẸ́RÀN JÍJA KỌNFÚ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Wọ́n bí mi nílùú Perm’, àmọ́ ìlú Furmanov ni mo dàgbà sí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì [40,000] èèyàn ló ń gbé nílùú yìí, ó wà lágbègbè Ivanovo, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ìlú Furmanov lẹ́wà gan-an, ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi tó fani mọ́ra, àwọ̀ àwọn igi yìí sì máa ń yí pa dà di ràkọ̀ràkọ̀ àti àwọ̀ pupa nígbà ẹ̀rùn. Láwọn ọdún 1980 sí ọdún 1990, ìwà ọ̀daràn túbọ̀ pọ̀ gan-an nílùú yìí. Owó tó ń wọlé fún ìdílé wa kéré gan-an ni. Inú yàrá kan lèmi, àbúrò mi ọkùnrin àtàwọn òbí wa ń gbé, èyí jẹ́ kí yàrá náà há gan-an.

Nígbà tí mo wà lọ́mọdún méje, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ bí wọ́n ṣe ń ja kọnfú. Mo fẹ́ràn ìjà yìí gan-an, mi ò sì kì í ronú nípa nǹkan míì ju ìjà yìí lọ. Gbogbo àkókò tí mo bá ní ni mo máa ń lò níbi tá a ti ń kọ́ ìjà yìí, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn tá a jọ ń kọ́ ìjà yìí làwọn ọ̀rẹ́ tí mo ní. Mi ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lọ ti mo ti gba bẹ́líìtì pupa, tó fi hàn pé mo ti ń gòkè àgbà nídìí ìjà kọnfú, nígbà tó si di ọdún kan lẹ́yìn náà, mo gba oríṣi bẹ́líìtì kejì, ìyẹn bẹ́líìtì aláwọ̀ ilẹ̀, láti fi hàn pé mo túbọ̀ ń gòkè àgbà. Mo wà lára àwọn oníjà kọnfú tó lọ jà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, mo sì tún wà lára àwọn tó lọ díje fún ife ẹ̀yẹ ìjà kọnfú tó wáyé láàárín àwọn oníjà kọnfú láti ilẹ̀ Yúróòpù àti ilẹ̀ Éṣíà. Ó dà bíi pé nǹkan á túbọ̀ ṣẹnuure fún mi lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], ìgbésí ayé mi yí pa dà.

Èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi dáràn kan, ọwọ́ sì tẹ̀ wá. Wọ́n jù mí sẹ́wọ̀n ọdún méjì gbáko. Ojú mi rí màbo lẹ́wọ̀n. Ìgbà tí mo wà lẹ́wọ̀n nìgbà àkọ́kọ́ tí màá rí Bíbélì láyé mi. Mo ka ìwé Jẹ́nẹ́sísì, Sáàmù àti Májẹ̀mú Tuntun. Mo tiẹ̀ há Àdúrà Olúwa sórí, mo sì máa ń kà á lálaalẹ́ kí n tó lọ sùn, torí mo rò pé ó ṣeé ṣe kó ràn mí lọ́wọ́.

Ọdún 2000 ni wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, àmọ́ mi ò mohun tí mo fẹ́ fìgbésí ayé mi ṣe, ó sì ṣe mí bíi pé ayé mi ò nítumọ̀. Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í loògùn olóró. Àkókò yìí ni màmá mi kú. Mo nífẹ̀ẹ́ màmá mi gan-an, ó sì nira díẹ̀ fún mi láti fara da ikú wọn yìí. Mo tiraka láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró, mo sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ síbi tá a ti máa ń kọ́ ìjà kọnfú. Mo tún kó lọ sílùú Ivanovo. Ibẹ̀ ni mo ti ríṣẹ́ síbì kan tí wọ́n ti máa ń ta oúnjẹ tútù àtàwọn nǹkan èlò inú ilé. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni obìnrin tó jẹ́ ọ̀gá níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Ó ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ kan fún mi látinú Bíbélì, ó sì ṣètò bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ ọkùnrin á ṣe máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé Ọlọ́run máa sọ ayé yìí di Párádísè, ẹ̀kọ́ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sì wù mí láti ṣohun tó máa jẹ́ kí n lè wà níbẹ̀. Ìgbà tó yá, mo wá mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run láwọn ìlànà tó fẹ́ káwa èèyàn máa tẹ̀ lé. Tara mi nìkan ni mò ń fi gbogbo ọjọ́ ayé mi rò. Àmọ́, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà fẹ́ kí n máa ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tèmi, kí n sì ní àwọn ànímọ́ tí mi ò tíì ní tẹ́lẹ̀, ìyẹn àwọn ànímọ́ bíi inú rere àti jíjẹ́ èèyàn àlàáfíà.

Bí mo ṣe ń ronú jinlẹ̀ lórí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún mi àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ mi tó, irú bó ṣe gbà kí Ọmọ rẹ̀ kú torí ẹ̀ṣẹ̀ mi, ìyẹn mú kí n ṣe àwọn ìyípadà kan nígbèésí ayé mi. Bí àpẹẹrẹ, mo kẹ́kọ̀ọ́ nínú Sáàmù 11:5 pé Jèhófà kórìíra ìwà ipá. Torí náà, mi ò wo àwọn ohun tó bá ti jẹ mọ́ ìwà ipá tàbí ìwà ìkà lórí tẹlifíṣọ̀n mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó nira fún mi gan-an, síbẹ̀ mo fi eré tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà ipá sílẹ̀. Ìlànà tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:33 jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn tí mo bá ń bá ṣọ̀rẹ́ máa nípa gan-an lórí mi. Ti pé mo ti bára mi nínú ẹ̀wọ̀n nígbà kan rí jẹ́ ẹ̀rí pé òótọ́ ni ìlànà yẹn. Torí náà, mi ò bá àwọn ọ̀rẹ́ tó fẹ́ràn eré oníwà ipá ṣọ̀rẹ́ mọ́.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Dídarapọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, mo kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Hébérù 13:5 nípa ìdí tó fi yẹ kéèyàn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, kéèyàn sì ṣọ́ra fún ìfẹ́ owó. Fífi àwọn ìmọ̀ràn yìí sílò ti ràn mí lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú irọ́ pípa àti olè jíjà.

Ó máa ń wù mí pé kí n láwọn ọ̀rẹ́. Láwọn ìgbà kan, mo ti fojú ara mi rí àwọn ọ̀rẹ́ tó jà tú ká torí pé wọ́n lójú kòkòrò tàbí torí wọn ń bẹ̀rù ara wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ẹni pípé, àmọ́ mo mọ̀ pé wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn ìlànà Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń sapá gan-an láti fi àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń hùwà sáwọn èèyàn. Mo ti wá láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ lára wọn báyìí.

Mo kàn ń ro bí ìgbésí ayé mi ì bá ṣe rí ká sọ pé mi ò kọ́ láti máa fàwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé mi. Ó ṣeé ṣe kí n tún ti pa dà sẹ́wọ̀n tàbí kí n máa kó ìbànújẹ́ àti ìrora bá àwọn èèyàn. Àmọ́ ní báyìí, mo ní ìyàwó àtàtà kan àtàwọn ọmọkùnrin méjì, gbogbo wa la sì ń rí ayọ̀ tòótọ́ nínú ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run.

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ

ORÚKỌ: JOSÉ CARLOS PEREIRA DA SILVA

ỌJỌ́ ORÍ: ỌDÚN MỌ́KÀNLÉLỌ́GBỌ̀N

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: BRAZIL

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ONÍJÀGBORO

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Americana, ní ìpínlẹ̀ São Paulo tí mo dàgbà sí dọ̀tí gan-an. Kò sí omi tó ṣeé mu, inú ìdọ̀tí la sì ń gbé. Àwọn èèyàn mọ àgbègbè náà mọ́ ibi tí ìwà ipá àti ìwà ọ̀daràn pọ̀ sí.

Bí mo ṣe ń dàgbà, èmi náà di oníwà ipá, mo sì tètè máa ń bínú gan-an. Mo sábà máa ń jàjàgboro, ìyẹn sì jẹ́ káwọn ará àdúgbò máa bẹ̀rù mi. Aṣọ, ìmúra àti ìwà mi máa ń fi hàn pé ọmọọ̀ta gidi ni mí. Mo sábà máa ń mutí gan-an, lọ́pọ̀ ìgbà ni mo sì máa ń mutí para. Àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin máa ń lo oògùn olóró, èmi náà sì máa ń lò ó. Kódà, àmujù oògùn olóró ló pa ọkàn lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, wọ́n fi hàn mí nínú Bíbélì pé Ọlọ́run máa sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè. (Lúùkù 23:42, 43; Ìṣípayá 21:3, 4) Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan, torí náà Ọlọ́run ò fìyà jẹ àwọn èèyàn búburú nínú iná ọ̀rún àpáàdì. (Oníwàásù 9:5, 6) Èyí jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ gan-an. Ohun tí mo kọ́ nípa Ọlọ́run jẹ́ kí n pinnu láti yí ìgbésí ayé mi pa dà. Àmọ́, kò rọrùn fún mi láti fi oògùn olóró, ọtí mímú, ìjà àtàwọn ọ̀rọ̀ rírùn tó ti mọ́ mi lára sílẹ̀.

Àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà nínú ìwé 1 Kọ́ríńtì 6:9-11 fún mi níṣìírí gan-an. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní nírú àwọn ànímọ́ burúkú tí mo ní yìí. Síbẹ̀, ẹsẹ yẹn náà sọ pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.” Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ pé èmi náà lè ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nígbèésí ayé mi kí n bàa lè múnú Ọlọ́run dùn.

Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó dá mi lójú dáadáa pé ìsìn tòótọ́ ni ìsìn wọn. Láìka mímọ̀ tí wọ́n mọ̀ pé oníwà ipá ni mí tẹ́lẹ̀ sí, pé mo máa ń bínú gan-an, síbẹ̀ wọ́n ṣì fìfẹ́ gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀ sáàárín wọn.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Ká ní mi ò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí n sì yí ìgbésí ayé mi pa dà ni, ó ṣeé ṣe kí n ti kú báyìí. Dípò ìyẹn, mo láǹfààní láti ran ọkàn lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi lọ́wọ́ kó lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn sì jẹ́ kó jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró tó ti mọ́ ọn lára. Bákan náà, mo tún ti rọ àwọn mọ̀lẹ́bí mi tó kù náà pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo dúpẹ́ pé ó ṣeé ṣe fún mi láti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́, tí mo sì wá ń sin Ọlọ́run tó bìkítà fún wa gan-an!

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]

“Mo pinnu láti máa gbàdúrà kí n tó ṣàṣìṣe dípò kí n gbàdúrà lẹ́yìn tí mo bá ṣàṣìṣe tán, ìyẹn sì ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an”