Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ò Ń tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ ‘Ọ̀nà Ìfẹ́ Títayọ Ré Kọjá’?

Ǹjẹ́ Ò Ń tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ ‘Ọ̀nà Ìfẹ́ Títayọ Ré Kọjá’?

Ǹjẹ́ Ò Ń tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ ‘Ọ̀nà Ìfẹ́ Títayọ Ré Kọjá’?

“ỌLỌ́RUN jẹ́ ìfẹ́.” Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ yìí fi ànímọ́ tó ga jù lọ tí Ọlọ́run ní hàn. (1 Jòh. 4:8) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sáráyé ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ ọn, òun ló sì jẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Ọ̀nà wo tún ni ìfẹ́ Ọlọ́run gbà ní ipa tó dáa lórí wa? A máa ń sọ pé: “Ohun tó ń dunni ló ń pọ̀ lọ́là ẹni.” Òótọ́ sì ni. Òtítọ́ míì tún ni pé, ẹni tá a nífẹ̀ẹ́ àti ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa máa ń nípa lórí irú ẹni tá a máa jẹ́. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé àwòrán Ọlọ́run ni wá, a lè fara wé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé wa. (Jẹ́n. 1:27) Ìyẹn ló mú kí àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run “nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.”—1 Jòh. 4:19.

Ọ̀rọ̀ Mẹ́rin Tá A Lè fi Ṣàlàyé Ìfẹ́

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe ìfẹ́ ní “ọ̀nà títayọ ré kọjá.” (1 Kọ́r. 12:31) Kí ló mú kó ṣàpèjúwe ìfẹ́ lọ́nà yìí? Oríṣi ìfẹ́ wo ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí? Láti rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́.”

Àwọn Gíríìkì láyé ìgbàanì ní ọ̀rọ̀ mẹ́rin kan tí wọ́n fi ń ṣàlàyé ìfẹ́ lónírúurú ọ̀nà, àwọn ọ̀rọ̀ náà ni: stor·geʹ, eʹros, phi·liʹa, àti a·gaʹpe. Lára wọn, a·gaʹpe ni oríṣi ìfẹ́ tá à ń lò fún Ọlọ́run tó “jẹ́ ìfẹ́.” a Nígbà tí ọ̀jọ̀gbọ́n William Barclay ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ yìí nínú ìwé ẹ̀ tó pè ní New Testament Words, ó ní: “Agapē ní í ṣe pẹ̀lú èrò inú: kì í wulẹ̀ ṣe èrò ìmọ̀lára tó kàn máa ń ru sókè láìròtẹ́lẹ̀ nínú ọkàn wa; ó jẹ́ ìlànà kan tá a dìídì ń jẹ́ kó máa darí ìgbésí ayé wa. Agapē ní í ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ inú ẹni lọ́nà tó ga.” Nínú ọ̀rọ̀ yìí, ìlànà ló ń darí ìfẹ́ a·gaʹpe, àmọ́ kò túmọ̀ sí pé kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹni o. Bó sì ti wá jẹ́ pé àwọn ìlànà dáadáa àtèyí tí ò dáa ló wà, ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé káwọn Kristẹni jẹ́ káwọn ìlànà tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run gbé kalẹ̀ nínú Bíbélì máa darí wọn. Tá a bá fi àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa a·gaʹpe wéra pẹ̀lú ọ̀nà míì tó gbà ṣàlàyé ìfẹ́, ìyẹn á jẹ́ ká lóye irú ìfẹ́ tó yẹ ká máa fi hàn.

Ìfẹ́ Tó Wà Láàárín Ìdílé

Ohun ìdùnnú ló jẹ́ láti jẹ́ ara ìdílé tí ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ti ń jọba! Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà Stor·geʹ ni wọ́n máa ń lò láti tọ́ka sí ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín àwọn tó wà nínú ìdílé kan náà. Àwọn Kristẹni máa ń sapá láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wà nínú ìdílé wọn. Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ pé, lákòókò òpin, àwọn èèyàn á jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” b2 Tím. 3:1, 3.

Ó ba ni nínú jẹ́ pé kò sí ìfẹ́ tó yẹ kó wà láàárín ìdílé mọ́ nínú ayé lóde òní. Kí ló fà á táwọn ìyá tó lóyún fi ń ṣẹ́yún? Kí ló fà á táwọn ìdílé kì í fi í tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà? Kí ló fà á táwọn tó ń kọra wọn sílẹ̀ fi ń pọ̀ sí i? Ìdáhùn ẹ̀ ni pé, Kò sí ìfẹ́ni àdánidá mọ́.

Síwájú sí i, Bíbélì kọ́ wa pé, “ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ.” (Jer. 17:9) Ìfẹ́ tó wà nínú ìdílé kan ọkàn àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Nígbà náà, ó gbàfiyèsí pé Pọ́ọ̀lù lo a·gaʹpe láti ṣàlàyé ìfẹ́ tó yẹ kí ọkọ kan ní sí aya ẹ̀. Pọ́ọ̀lù fi ìfẹ́ yẹn wé ìfẹ́ tí Jésù ní sí ìjọ. (Éfé. 5:28, 29) Ìfẹ́ yìí dá lórí ìlànà látọ̀dọ̀ Jèhófà tó jẹ́ Olùdásílẹ̀ ìdílé.

Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ìdílé wa lóòótọ́, èyí á jẹ́ ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wa àgbàlagbà, á sì jẹ́ ká máa ṣe ojúṣe wa fáwọn ọmọ wa. Èyí á tún jẹ́ káwọn òbí máa fìfẹ́ bá àwọn ọmọ wí nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, á sì jẹ́ kí wọ́n ṣọ́ra fún fífọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú wọn, èyí tó sábà máa ń yọrí sí fífàyè gba àwọn ọmọ ju bó ṣe yẹ lọ.—Éfé. 6:1-4.

Ìfẹ́ Tó Wà Láàárín Takọtabo Àtàwọn Ìlànà Bíbélì

Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín takọtabo. (Òwe 5:15-17) Àmọ́, àwọn tó kọ Bíbélì kò lo eʹros, tó ń tọ́ka sí ìfẹ́ tó wà láàárín takọtabo. Kí nìdí? Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ pé: ‘Lóde òní, ó jọ pé gbogbo aráyé ló ń ṣe irú àṣìṣe kan náà táwọn Gíríìkì ìgbàanì ṣe. Wọ́n ń jọ́sìn Eros bí ọlọ́run, wọ́n ń forí balẹ̀ níbi pẹpẹ rẹ̀, wọ́n sì ń rúbọ sí i. . . . Àmọ́, ìtàn fi hàn pé àbájáde irú ìjọsìn ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ takọtabo bẹ́ẹ̀ ni ìwà ìbàjẹ́, ìwà wọ̀bìà àti rúdurùdu. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyẹn ló fà á táwọn tó kọ Bíbélì ò ṣe lo ọ̀rọ̀ yìí.’ Ká bàa lè ṣọ́ra fún níní àjọṣe tó dá lórí ìrísí nìkan, a gbọ́dọ̀ máa fi ìlànà tó wà nínú Bíbélì darí ìfẹ́ tó wà láàárín takọtabo. Torí náà, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ìfẹ́ tòótọ́ ni mo ní sí ọkọ tàbí aya mi?’

Nígbà “ìtànná òdòdó èwe,” lákòókò tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára lọ́kàn ẹni, àwọn ọ̀dọ́ tó bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ò ní ṣubú sínú ìṣekúṣe. (1 Kọ́r. 7:36; Kól. 3:5) Ẹ̀bùn mímọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà la ka ìgbéyàwó sí. Jésù sọ nípa àwọn tọkọtaya pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mát. 19:6) Ní tiwa o, a máa ń fọwọ́ pàtàkì mú àdéhùn ìgbéyàwó dípò tó fi máa jẹ́ pé ìgbà tí òòfà ẹwà bá ṣì wà nìkan ni tọkọtaya á jọ máa gbé pọ̀. Nígbà tí ìṣòro bá yọjú nínú ìgbéyàwó, a kì í wá ọ̀nà láti kọ ara wa sílẹ̀, àmọ́ a máa ń sapá láti ṣàgbéyọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run kí ìdílé wa lè máa láyọ̀. Irú ìsapá bẹ́ẹ̀ sì máa ń jẹ́ ká ní ayọ̀ tó máa kalẹ́.—Éfé. 5:33; Héb. 13:4.

Ìfẹ́ Tó Wà Láàárín Àwọn Ọ̀rẹ́

Ayé máa ń tojú súni téèyàn ò bá lọ́rẹ̀ẹ́! Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” (Òwe 18:24) Jèhófà fẹ́ ká láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́. Ṣàṣà lẹni tí ò mọ bí ìfẹ́ tó wà láàárín Dáfídì àti Jónátánì ṣe lágbára tó. (1 Sám. 18:1) Bíbélì tún sọ pé Jésù “ní ìfẹ́ni” fún àpọ́sítélì Jòhánù. (Jòh. 20:2) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí wọ́n lò fún “ìfẹ́ni” tàbí “ọ̀rẹ́” ni phi·liʹa. Kò burú tá a bá láwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nínú ìjọ. Àmọ́ 2 Pétérù 1:7 gbà wá níyànjú pé ká fìfẹ́ (a·gaʹpe) kún “ìfẹ́ni ará” wa (phi·la·del·phiʹa, jẹ́ ọ̀rọ̀ alákànpọ̀ tó ní nínú phiʹlos, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n ń lò fún “ọ̀rẹ́,” àti a·del·phosʹ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n ń lò fún “arákùnrin”). Tá a bá fẹ́ láwọn ọ̀rẹ́ tó wà pẹ́ títí, a ní láti fìmọ̀ràn yìí sílò. Á dáa ká bi ara wa pé, ‘Ṣáwọn ìlànà Bíbélì ló ń darí ìfẹ́ tí mo ní fún ọ̀rẹ́?’

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣọ́ra fún ṣíṣe ojúsàájú nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa. Kò yẹ ká ní ìlànà méjì, ìyẹn ni pé ká máa gbọ̀jẹ̀gẹ́ fáwọn ọ̀rẹ́ wa, ká wá máa fọwọ́ tó le mú àwọn tí kì í ṣe ọ̀rẹ́ wa. Síwájú sí i, a kì í fi ọ̀rọ̀ dídùn tan àwọn èèyàn kí wọ́n bàa lè di ọ̀rẹ́ wa. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, èyí á jẹ́ ká lè máa lo òye tá a bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́, á sì ràn wá lọ́wọ́ láti ṣọ́ra fún ‘ẹgbẹ́ búburú tó máa ń ba ìwà rere jẹ́.’—1 Kọ́r. 15:33.

Ìdè Ìfẹ́ Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀!

Ìdè tó so àwọn Kristẹni pọ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an ni! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí àgàbàgebè. . . . Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 12:9, 10) Kò sí àní-àní pé àwọn Kristẹni ń gbádùn ‘ìfẹ́ (a·gaʹpe) láìsí àgàbàgebè.’ Ìfẹ́ yìí kì í kàn-án ṣe ìmọ̀lára tó kàn ru sókè látọkàn ẹni wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ èyí táwọn ìlànà Bíbélì ń darí. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù tún sọ̀rọ̀ nípa “ìfẹ́ ará” (phi·la·del·phiʹa) àti “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” (phi·loʹstor·gos jẹ́ ọ̀rọ̀ alákànpọ̀ tó ní nínú phiʹlos àti stor·geʹ). Níbàámu pẹ̀lú ohun tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ, “ìfẹ́ ará” jẹ́ “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, tó nínúure, tó ń báni kẹ́dùn, tó sì máa ń ṣèrànwọ́.” Tá a bá wá fìfẹ́ a·gaʹpe, kún un, èyí á túbọ̀ jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín àwa olùjọsìn Jèhófà ṣe tímọ́tímọ́. (1 Tẹs. 4:9, 10) Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ̀rọ̀ míì tí wọ́n túmọ̀ sí “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” ti fara hàn nínú Bíbélì, ó sì ń tọ́ka sí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó máa ń wà láàárín ìdílé. c

Ìdè tó so àwa Kristẹni tòótọ́ pọ̀ ni ìfẹ́ tó wà nínú ìdílé àti ìfẹ́ téèyàn ní fún ọ̀rẹ́ tòótọ́. Ìfẹ́ tá a gbé karí àwọn ìlànà Bíbélì ló sì gbọ́dọ̀ máa darí àjọṣe yòówù ká ní. Ìjọ Kristẹni kì í ṣe ibi téèyàn ti ń lọ ṣe fàájì tàbí ìpàdé ẹgbẹ́ kan, àmọ́ ó jẹ́ ìdílé tó wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run. Arákùnrin àti arábìnrin la máa ń pe àwọn ará wa, ojú tá a sì fi ń wò wọ́n nìyẹn. Ara ìdílé wa nípa tẹ̀mí ni wọ́n, ọ̀rẹ́ wa ni gbogbo wọn, a sì ń báwọn lò níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti jẹ́ kí ìdè ìfẹ́ tó so wá pọ̀, tó sì ń fi ìjọ Kristẹni tòótọ́ hàn túbọ̀ máa lágbára sí i.—Jòh. 13:35.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà míì, a máa ń fi a·gaʹpe ṣàlàyé nǹkan tí ò dáa.—Jòh. 3:19; 12:43; 2 Tím. 4:10; 1 Jòh. 2:15-17.

b Ọ̀rọ̀ náà “aláìní ìfẹ́ni àdánidá” jẹ́ ọ̀nà kan tá a gbà túmọ̀ oríṣi ìfẹ́ stor·geʹ tó túmọ̀ sí pé “kò sí rára,” ìyẹn ni pé kò sí ìfẹ́ni àdánidá mọ́.—Tún wo Róòmù 1:31.

c Nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun, àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan wà tá a tún túmọ̀ sí “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.” Torí náà, kì í ṣe inú Róòmù 12:10 nìkan ni “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” ti fara hàn nínú Bíbélì yìí, ó tún wà nínú Fílípì 1:8 àti 1 Tẹsalóníkà 2:8.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

Ipa wo lò ń kó nínú mímú kí ìdè ìfẹ́ tó so wá pọ̀ lágbára sí i?