Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àádọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn Ni Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí í ‘Rántí Ẹlẹ́dàá Mi Atóbilọ́lá’

Àádọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn Ni Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí í ‘Rántí Ẹlẹ́dàá Mi Atóbilọ́lá’

Àádọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn Ni Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí í ‘Rántí Ẹlẹ́dàá Mi Atóbilọ́lá’

Gẹ́gẹ́ bí Edwin Ridgwell ti sọ ọ́

NÍ NOVEMBER 11, ọdún 1918, tí wọ́n ṣe àdéhùn láti fòpin sí ogun tá a wá mọ̀ sí Ogun Àgbáyé Kìíní, láìròtẹ́lẹ̀, wọ́n pe gbogbo àwa ọmọ ilé ẹ̀kọ́ jọ láti ṣayẹyẹ pé ogun ti parí. Ọmọ ọdún márùn-ún péré ni mí nígbà yẹn, nǹkan tí wọ́n ń ṣe ò sì yé mi dáadáa. Síbẹ̀, àwọn nǹkan táwọn òbí mi ti kọ́ mi nípa Ọlọ́run jẹ́ kí n mọ̀ pé kò yẹ kí n lọ́wọ́ sírú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀. Mó gbàdúrà sí Ọlọ́run, àmọ́ nígbà tára mi ò gbà á mọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Àmọ́ o, mi ò bá wọn lọ́wọ́ sí i. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ‘rántí Ẹlẹ́dàá mi Atóbilọ́lá’ nìyẹn o.—Oníw. 12:1.

Lóṣù mélòó kan kí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó wáyé níléèwé wa, ni ìdílé wa ti kó lọ sítòsí ìlú Glasgow lórílẹ̀-èdè Scotland. Àárín ìgbà yẹn ni bàbá mi gbọ́ àsọyé kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé.” Àsọyé yìí ló yí ìgbésí ayé ẹ̀ pa dà. Bàbá mi àti màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn méjèèjì sì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ìbùkún tó máa mú wá. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé láti ìgbà yẹn làwọn òbí mi ti ń kọ́ mi láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kí n sì gbẹ́kẹ̀ lé e.—Òwe 22:6.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo tóótun láti wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga, àmọ́ ó wù mi kí n ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Bàbá mi wò ó pé mo ṣì kéré, torí náà mo lọ ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì kan fúngbà díẹ̀. Síbẹ̀ náà, ó ṣì wù mí gan-an láti máa fi gbogbo àkókò mi sin Jèhófà, ni mo bá kọ lẹ́tà sí Arákùnrin J. F. Rutherford, tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé nígbà yẹn. Mo béèrè ohun tó rò nípa ìpinnu mi. Èsì tí Arákùnrin Rutherford fún mi ni pé: “Tó o bá ti dàgbà tó láti ṣiṣẹ́, ó ti dàgbà tó láti ṣiṣẹ́ Olúwa náà nìyẹn. . . . Ó dá mi lójú pé Olúwa á bù kún ẹ tó o bá sapá láti sìn ín tọkàntọkàn.” Lẹ́tà tó kọ ní March 10, 1928, yẹn nípa rere lórí ìdílé wa gan-an. Kò pẹ́ tí bàbá mi, màmá mi, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin àtèmi fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

Ní àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ṣe nílùú London lọ́dún 1931, Arákùnrin Rutherford sọ pé a nílò àwọn tó máa yọ̀ǹda ara wọn láti lọ wàásù ìhìn rere nílẹ̀ òkèèrè. Mo yọ̀ǹda láti lọ, wọ́n sì yan èmi àti Arákùnrin Andrew Jack, láti lọ sìn ní ìlú Kaunas, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Lithuania nígbà yẹn. Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni mí lásìkò yẹn.

Mo Wàásù Ìhìn Rere Nílẹ̀ Òkèèrè

Lákòókò yẹn, iṣẹ́ àgbẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa lórílẹ̀-èdè Lithuania, kò sì rọrùn láti wàásù láwọn ìgbèríko. Ó ṣòro láti rí ilé gbígbé, a ò sì lè gbàgbé àwọn ilé kan tá a gbé. Bí àpẹẹrẹ, lóru ọjọ́ kan èmi àti Andrew jí lójú oorun torí pé ara wa ò lélẹ̀. Ìgbà tá a tan àtùpà elépo, ńṣe la rí i tí ìdun ń gbá yìn-ìn lórí bẹ́ẹ̀dì tá a sùn sí. Wọ́n ti jẹ wá pátipàti! Lójoojúmọ́, fún odindi ọ̀sẹ̀ kan, tá a bá ti jí láàárọ̀, ńṣe ni mo máa ń lọ dúró sínú odò kan tómi á sì mù mí dé ọrùn kí ara lè tù mí díẹ̀. Síbẹ̀ a pinnu pé, a ó máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nìṣó. Nígbà tá a pàdé tọkọtaya kan tí wọn kò tíì dàgbà púpọ̀, tí wọ́n sì ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí ìṣòro ilé gbígbé tá a ní fi yanjú. Wọ́n gbà wá sílé wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé náà kéré gan-an, síbẹ̀ ó wà ní mímọ́. Tayọ̀tayọ̀ la fi ń sùn sórí ilẹ̀, àmọ́ ìtura ńlá gbáà ló jẹ́!

Àwọn àlùfáà Kátólíìkì àti ti Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà ló jẹ́ abẹnugan nínú ìṣàkóso orílẹ̀-èdè Lithuania nígbà yẹn. Àwọn olówó nìkan ló lè ra Bíbélì. Àfojúsùn wa ni pé ká wàásù ní ọ̀pọ̀ ibi ní àgbègbè náà bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ká sì fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀ fáwọn tó fìfẹ́ hàn. Nílùú tá a bá dé, ilé tá a máa gbé la máa ń kọ́kọ́ wá. Ọgbọ́n la fi máa ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù, àwọn ìpínlẹ̀ tó jìnnà sí ìgboro la máa ń kọ́kọ́ ṣe, lẹ́yìn náà la máa ń wàásù nígboro. Ìyẹn máa ń jẹ́ ká bá iṣẹ́ wa débi tó lápẹẹrẹ káwọn àlùfáà tó dá wàhálà sílẹ̀ fún wa.

Rúkèrúdò Tó Ṣẹlẹ̀ Mú Ká Lè Wàásù Fàlàlà

Lọ́dún 1934, wọ́n ní kí Andrew lọ máa sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Kaunas, wọ́n sì yan John Sempey láti jẹ́ ẹnì kejì mi. A láwọn ìrírí tá ò lè gbàgbé. Lọ́jọ́ kan, mo lọ sí ọ́fíìsì agbẹjọ́rò kan nílùú kékeré kan. Inú bí ọkùnrin náà, ló bá fa ìbọn yọ, ó sì sọ pé kí n máa lọ. Mo gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́, lẹ́yìn náà mo wá rántí ìmọ̀ràn Bíbélì kan pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.” (Òwe 15:1) Mo wá sọ fún un pé, “Mi ò bá tìjà wá rárá, ìhìn rere ni mo mú wá fún ẹ, àmọ́ mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ pé o ò yin ìbọn tó wà lọ́wọ́ ẹ.” Ọkùnrin yẹn wá dẹwọ́ lára ìbọn náà, ni mo bá yá a bẹ́sẹ̀ mi sọ̀rọ̀.

Nígbà tí mo rí John, ó sọ fún mi pé òun náà ní ìṣòro lọ́jọ́ yẹn. Wọ́n mú un lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá torí ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án pé ó jí owó tabua lọ́wọ́ obìnrin kan. Wọ́n tú gbogbo ara ẹ̀, kódà wọ́n bọ́ aṣọ ẹ̀. Àmọ́ wọn ò rí owó náà lára ẹ̀. Ẹ̀yìn náà ni wọ́n rí ẹni tó jí owó náà.

Ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yìí dá rúkèrúdò sílẹ̀ nílùú tó pa rọ́rọ́ yẹn, èyí sì jẹ́ ká lè wàásù ní fàlàlà.

À Ń Ṣe Iṣẹ́ Wa Ní Bòókẹ́lẹ́

Iṣẹ́ tó léwu gan-an ni láti kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ sí Latvia, ìyẹn orílẹ̀-èdè tá a jọ pààlà, níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Lẹ́ẹ̀kan lóṣù, a máa ń wọ ọkọ̀ ojú irin lọ sí orílẹ̀-èdè Latvia lálẹ́. Nígbà míì, tá a bá ti já ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a kó lọ, a máa ń lọ sí orílẹ̀-èdè Estonia láti lọ kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sí i, èyí tá a máa ń já sí orílẹ̀-èdè Latvia nígbà tá a bá ń pa dà bọ̀.

Nígbà kan, àwọn kan lọ ta òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè kan lólobó nípa iṣẹ́ wa, ó wá ní ká jáde nínú ọkọ̀ ojú irin, ká sì kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá òun. Èmi àti John wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wa pé, òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè náà ò sọ ohun tá a kó fún ọ̀gá ẹ̀, ńṣe ló kàn sọ fún un pé: “Àwọn ọkùnrin yìí ní nǹkan kan láti sọ.” Mo wá sọ nípa ìwé kan tí mo ṣàlàyé pé ó máa ran àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lọ́wọ́ láti lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé wa tí wàhálà kúnnú ẹ̀ yìí. Ńṣe ni ọ̀gá òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè náà ní ká máa lọ, a sì fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà jíṣẹ́ láìsì ìṣòro kankan.

Bí rògbòdìyàn ìṣèlú ti ń burú sí i láwọn Ìpínlẹ̀ Baltic, àwọn èèyàn túbọ̀ wá ń ta ko àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè Lithuania pẹ̀lú. Wọ́n lé Andrew àti John kúrò lórílẹ̀-èdè Lithuania, bí Ogun Àgbáyé Kejì sì ṣe ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀, wọ́n ní kí gbogbo àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì máa lọ. Inú mi bà jẹ́, àmọ́ mo ní láti kúrò níbẹ̀.

Àǹfààní Àtàwọn Ìbùkún Tí Mo Rí Ní Northern Ireland

Nígbà yẹn àwọn òbí mi ti kó lọ sí Northern Ireland, èmi náà sì lọ bá wọn níbẹ̀ lọ́dún 1937. Wọ́n tún ti fòfin de àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ní Northern Ireland náà torí bọ́rọ̀ ogun náà ṣe rí lára àwọn èèyàn, àmọ́ àwa ò yéé wàásù títí tógun náà fi parí. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, òfin gbà wá láyè láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó. Arákùnrin Harold King, tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́, tó wá lọ sìn lórílẹ̀-èdè Ṣáínà gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì nígbà tó yá ló ṣagbátẹrù àsọyé fún gbogbo èèyàn. Lọ́jọ́ kan Arákùnrin Harold King sọ fún mi pé, òun lòun kọ́kọ́ máa sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn ní Sátidé tó ń bọ̀ yìí. Lẹ́yìn náà, ó yíjú sí mi, ó sì sọ pé, “Ìwọ́ lo máa sọ àsọyé ní Sátidé tó máa tẹ̀ lé e.” Àyà mi là gàrà.

Mo ṣì máa ń rántí àsọyé tí mo kọ́kọ́ sọ dáadáa. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló wá. Orí àpótí kan ni mo dúró lé nígbà tí mò ń sọ̀rọ̀, mi ò sì lo ẹ̀rọ gbohùngbohùn kankan. Lẹ́yìn àsọyé náà, ọkùnrin kan wá sọ́dọ̀ mi, ó bọ̀ mí lọ́wọ́, ó sì sọ pé Bill Smith lorúkọ òun. Ó sọ pé òun kàn rí èrò tó pọ̀ lòun fi yà láti wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Àṣé bàbá mi ti wàásù fún Bill nígbà kan rí, àmọ́ wọn ò ríra mọ́ nígbà tí bàbá mi àti ìyàwó wọn kó lọ sí ìlú Dublin láti lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá mẹ́sàn-án lára àwọn mọ̀lẹ́bí Bill di ìránṣẹ́ Jèhófà.

Lẹ́yìn náà, mo lọ wàásù láwọn ilé ńláńlá tó wà nítòsí ìlú Belfast, ibẹ̀ ni mo ti pàdé obìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kan tó ti fìgbà kan gbé lórílẹ̀-èdè Lithuania. Nígbà tí mo fàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ hàn án, ó nàka sí ọ̀kan, ó sì sọ pé “Mo ní ìyẹn. Ẹ̀gbọ́n bàbá mi tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní yunifásítì tó wà ní Kaunas ló fún mi.” Ó wá fi ìwé Creation, lédè Polish hàn mí. Wọ́n ti kọ̀rọ̀ sí eteetí ìwé náà. Ó yà á lẹ́nu nígbà tó gbọ́ pé èmi ni mo fún ẹ̀gbọ́n bàbá ẹ̀ ní ìwé náà nígbà tá a pàdé ní ìlú Kaunas!—Oníw. 11:1.

Nígbà tí John Sempey gbọ́ pé mò ń lọ sí Northern Ireland, ó sọ pé kí n bá òun wá àbúrò òun obìnrin tó ń jẹ́ Nellie kàn, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Èmi àti Connie ẹ̀gbọ́n mi obìnrin kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nellie tètè tẹ̀ síwájú, ó sì ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wa sọ́nà, a sì ṣègbéyàwó.

Ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56] lèmi àti Nellie fi jọ sin Jèhófà, a sì láǹfààní láti ran àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ òtítọ́. Ó wù wá láti máa gbé pa pọ̀, ká sì jọ la Amágẹ́dọ́nì já sínú ayé tuntun Jèhófà, àmọ́ ikú tó jẹ́ ọ̀tá burúkú gbà á mọ́ mi lọ́wọ́ lọ́dún 1998. Ìbànújẹ́ ńlá ló jẹ́ fún mi, àsìkò yẹn ló sì burú jù lọ nígbèésí ayé mi.

Mo Pa Dà Sáwọn Ìpínlẹ̀ Baltic

Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí ìyàwó mi kú, mo rí ìbùkún àgbàyanu kan gbà. Wọ́n ní kí n wá ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní ìlú Tallinn lórílẹ̀-èdè Estonia. Lẹ́tà táwọn ará tó wà ní Estonia kọ ṣàlàyé pé: “Nínú gbogbo àwọn arákùnrin mẹ́wàá tí wọ́n yàn sí àwọn Ìpínlẹ̀ Baltic lọ́wọ́ ìparí ọdún 1920 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1930, ìwọ nìkan lo kù láyé.” Wọ́n sọ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì ń ṣàkójọ ìtàn nípa iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè Estonia, Latvia àti Lithuania, wọ́n wá béèrè pé “Ṣé wàá lè wá?”

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún mi láti sọ ìrírí tí èmi àtàwọn tá a jọ ṣiṣẹ́ ní ìgbà yẹn lọ́hùn-ún ní! Lórílẹ̀-èdè Latvia, ó ṣeé ṣe fún mi láti fi ilé tí wọ́n lò fún ẹ̀ka ọ́fíìsì han àwọn arákùnrin náà àti àjà ilé tá a máa ń tọ́jú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ pa mọ́ sí, èyí táwọn ọlọ́pàá ò rí rí. Lórílẹ̀-èdè Lithuania, wọ́n mú mi lọ sí ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Šiauliai, níbi tí mo ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tá a kóra jọ, arákùnrin kan sọ fún mi pé, ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, òun àti màmá òun ra ilé kan sáàárín ìlú. Nígbà táwọn ń kó àwọn ẹrù játijàti kúrò lókè àjà ilé náà, òun rí ìwé kan tó ń jẹ́ The Divine Plan of the Ages àti Duru Ọlọrun. Ó wá sọ pé nígbà tóun ka àwọn ìwé náà, òun gbà pé òun ti rí òtítọ́. Ó wá sọ fún mi pé ó ní láti jẹ́ pé ìwọ lo gbàgbé àwọn ìwé yẹn síbẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn!

Mo tún lọ sí àpéjọ àyíká ní ìlú kan tí mo ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Lọ́dún márùnlélọ́gọ́ta sẹ́yìn, mo ṣe àpéjọ níbẹ̀. Nígbà yẹn, àwa márùndínlógójì la pé jọ. Àmọ́ inú mi dùn gan-an láti rí àwọn èèyàn tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] tó wà níkàlẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí! Ẹ ò rí i pé Jèhófà ti bù kún iṣẹ́ náà ní ti gidi!

‘Jèhófà Ò Fi Mí Sílẹ̀’

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo tún rí ìbùkún míì tí mi ò ronú kàn gbà nígbà tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Bee gbà láti fẹ́ mi. A ṣègbéyàwó ní November ọdún 2006.

Mo lè fi dá àwọn ọ̀dọ́ tó bá ń ṣiyèméjì lórí ohun tí wọ́n fẹ́ fìgbésí ayé wọn ṣe lójú pé, ó mọ́gbọ́n dání tí wọ́n bá tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ onímìísí náà pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.” Ní báyìí, mo láyọ̀ bí i ti onísáàmù náà, tó sọ pé: “Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá, títí di ìsinsìnyí, mo sì ń bá a nìṣó ní sísọ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ. Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀, títí èmi yóò fi lè sọ nípa apá rẹ fún ìran náà, fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀, nípa agbára ńlá rẹ.”—Sm. 71:17, 18.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 25]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Iṣẹ́ tó léwu gan-an ni láti kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ sí orílẹ̀-èdè Latvia

ESTONIA

TALLINN

Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Riga

LATVIA

RIGA

LITHUANIA

VILNIUS

Kaunas

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí apínwèé-ìsìn-kiri (aṣáájú-ọ̀nà) lórílẹ̀-èdè Scotland nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti Nellie rèé lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa, lọ́dún 1942