Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìsìn Tòótọ́ Ń Kọ́ni Láti Máa Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìlànà Ọlọ́run

Ìsìn Tòótọ́ Ń Kọ́ni Láti Máa Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìlànà Ọlọ́run

Ìsìn Tòótọ́ Ń Kọ́ni Láti Máa Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìlànà Ọlọ́run

ÌSÌN tòótọ́ ń jẹ́ ká lè ronú lórí àwọn nǹkan tó dáa, ó sì máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè mú kí ìwà wa túbọ̀ dáa. Ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ nínú ìsapá wa láti ṣohun tó tọ́, ó sì ń jẹ́ ká lè máa ṣe gbogbo ohun rere tó bá wà lágbára wa. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìsìn tòótọ́ máa ń ṣe gbogbo ohun tá a sọ yìí?

Kíyè sóhun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tó ń gbé nílùú Kọ́ríńtì, lórílẹ̀-èdè Gíríìsì. Láyé àtijọ́, ibi gbogbo làwọn èèyàn ti mọ ìlú Kọ́ríńtì torí ìwàkíwà tó gbilẹ̀ níbẹ̀. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wọn pé: ‘Kì í ṣe àwọn àgbèrè tàbí àwọn abọ̀rìṣà tàbí àwọn panṣágà tàbí àwọn aláìlera tàbí àwọn tí ń fi ọkùnrin ba ara wọn jẹ́ tàbí àwọn olè tàbí àwọn olójúkòkòrò tàbí àwọn ọ̀mùtí tàbí àwọn ẹlẹ́gàn tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.’ Pọ́ọ̀lù wá fi kún un pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì ti jẹ́ rí; ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín nù, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ní orúkọ Jésù Kristi Olúwa àti nípa ẹ̀mí Ọlọ́run wa.’ (1 Kọ́ríńtì 6:9-11, Bibeli Ajuwe) Àbó ò rí nǹkan, ẹ̀sìn tòótọ́ ṣèrànwọ́ fáwọn kan tí kì í pa òfin Ọlọ́run mọ́ tẹ́lẹ̀, wọ́n sì di èèyàn mímọ́, olódodo ìránṣẹ́ Ọlọ́run!

Àmọ́ ní ìyàtọ̀ sí èyí, Bíbélì kìlọ̀ pé: ‘Àkókò ń bọ̀ tí àwọn èèyàn kò ní fẹ́ fetí sí ẹ̀kọ́ tí ó yè. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara wọn ni wọn yóò tẹ̀ lé, tí wọn yóò kó àwọn olùkọ́ni tira, tí wọn yóò máa sọ ohun tí wọ́n máa fẹ́ gbọ́ fún wọn.’—2 Tímótì 4:3, Ìròhìn Ayọ̀.

Báwo làwọn ìsìn tó o mọ̀ ṣe ń ṣe sí lórí ohun tá a sọ yìí? Ṣé wọ́n ń fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Bíbélì nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́? Àbí ọwọ́ yẹpẹrẹ ni wọ́n fi mú ìlànà tó ṣe kedere tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n kàn ń ‘sọ ohun tí àwọn èèyàn máa fẹ́ gbọ́ fún wọn’?

Kó o lè mọ̀ bóyá ìsìn kan pàtó ń so èso rere, a rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:

ÀKÒRÍ Ọ̀RỌ̀: Ìgbéyàwó.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: ‘Ohun tó lọ́lá ni ìgbéyàwó. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì yẹ kí gbogbo yín kà á sí. Ibùsùn tọkọtaya gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìléèérí. Nítorí Ọlọ́run yóò dájọ́ fún àwọn oníṣekúṣe àti àwọn àgbèrè.’—Hébérù 13:4, Ìròhìn Ayọ̀.

ÌBÉÈRÈ: Ṣé ìsìn tó o mọ̀ yìí ń béèrè pé káwọn ọmọ ìjọ wọn tí wọ́n bá jẹ́ tọkọtaya forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin?

ÀKÒRÍ Ọ̀RỌ̀: Ìkọ̀sílẹ̀.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: Nígbà táwọn èèyàn bi Jésù bóyá ìdí kankan wà tó fi yẹ kẹ́nì kan kọ ọkọ tàbí aya rẹ̀ sílẹ̀, ó sọ pé: ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí kò bá jẹ́ nítorí àgbèrè, tí ó bá fẹ́ ẹlòmíràn, ó ṣe àgbèrè.’—Mátíù 19:9, Ìròhìn Ayọ̀.

ÌBÉÈRÈ: Ṣé ìsìn tó o mọ̀ yìí ń bọ̀wọ̀ fún ohun tí Jésù sọ, tó sì jẹ́ pé ìgbà tí ọkọ tàbí aya ẹnì kan bá ṣèṣekúṣe nìkan ni wọ́n tó lè kọ ara wọn sílẹ̀?

ÀKÒRÍ Ọ̀RỌ̀: Ìṣekúṣe.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: ‘Ẹ máa sá fún àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí èèyàn ń dá ló wà lóde ara; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun tìkalára rẹ̀.’—1 Kọ́ríńtì 6:18, Bibeli Ajuwe.

Bíbélì sọ pé: ‘Nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ yí ìlò ẹ̀dá pa dà sí èyí tó lòdì sí ẹ̀dá. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọ́n á máa fi ìlò obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọ́n á máa ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gbígbóná sí ara wọn; ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ń jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.’—Róòmù 1:26, 27, Bibeli Mimọ.

ÌBÉÈRÈ: Ṣé ìsìn tó o mọ̀ yìí ń kọ́ni pé ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin tí wọn kì í ṣe tọkọtaya, obìnrin àti obìnrin tàbí ọkùnrin àti ọkùnrin, jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?

ÀKÒRÍ Ọ̀RỌ̀: Kíkọ́ àwọn ọmọ ìjọ láwọn ìlànà Bíbélì láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: ‘Ẹ má ṣe dara pọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tí á bá ń pè ní onígbàgbọ́ tí ó ń hùwà àgbèrè tàbí tí ó ní ojúkòkòrò tàbí tí ó jẹ́ abọ̀rìṣà tàbí abanijẹ́ tàbí ọ̀mùtí tàbí oníjìbìtì. Ẹ má tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.’ (1 Kọ́ríńtì 5:11, Ìròhìn Ayọ̀) Kí ló yẹ kí ìsìn kan ṣe fáwọn tó ń pera wọn ní Kristẹni, àmọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: ‘Ẹ yọ ẹni burúkú náà kúrò láàárín yín.’—1 Kọ́ríńtì 5:13, Ìròhìn Ayọ̀.

ÌBÉÈRÈ: Ṣé ìsìn tó o mọ̀ yìí máa ń yọ ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ lẹ́gbẹ́ torí pé ẹni náà ń rú àwọn ìlànà Bíbélì tó sì kọ̀ láti ronú pìwà dà?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Ìsìn wo làwọn èèyàn mọ̀ pé ó máa ń fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Ọlọ́run?