Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èló Ni Kí N Fi Ṣètọrẹ Fún Iṣẹ́ Ọlọ́run?

Èló Ni Kí N Fi Ṣètọrẹ Fún Iṣẹ́ Ọlọ́run?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Èló Ni Kí N Fi Ṣètọrẹ Fún Iṣẹ́ Ọlọ́run?

Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe tuntun létí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn yíká ayé. Àmọ́, àwọn kan tó máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lè fẹ́ fi owó tó kọjá agbára wọn ṣètọrẹ. Kódà, àwọn ẹ̀sìn kan máa ń sọ iye tó yẹ kí àwọn ọmọ ìjọ wọn máa fi ṣètọrẹ. Wọ́n máa ń pè é ní ìdámẹ́wàá, ìyẹn ni pé káwọn ọmọ ìjọ wọn fi ìdá kan nínú mẹ́wàá owó tó bá ń wọlé fún wọn ṣètọrẹ sí ṣọ́ọ̀ṣì.

Ṣé lóòótọ́ ni Bíbélì sọ pé iye báyìí la gbọ́dọ̀ máa fi ṣètọrẹ? O lè béèrè lọ́wọ́ ara ẹ pé, èló ni kí n fi ṣètọrẹ?

Ohun Tó Yẹ Kí Wọ́n Fi Ṣètọrẹ Àtàwọn Ọrẹ Àtinúwá Nígbà Àtijọ́

Bíbélì jẹ́ ká mọ ìtọ́ni tó ṣe kedere tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ohun tó yẹ kí wọ́n máa fi ṣètọrẹ. (Léfítíkù 27:30-32; Númérì 18:21, 24; Diutarónómì 12:4-7, 11, 17, 18; 14:22-27) Àwọn ohun tí Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe yìí ò kọjá agbára wọn. Jèhófà ṣèlérí fún wọn pé tí wọ́n bá ń ṣègbọràn sáwọn òfin òun, òun á mú kí ‘aásìkí wọn kún àkúnwọ́sílẹ̀.’—Diutarónómì 28:1, 2, 11, 12.

Àwọn ìgbà míì wà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ṣe ọrẹ àtinúwá, wọ́n lè fi nǹkan púpọ̀ tàbí díẹ̀ ṣètọrẹ bí agbára wọn bá ṣe gbé e. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Dáfídì Ọba ṣètò láti kọ́ tẹ́ńpìlì kan fún Jèhófà, àwọn èèyàn rẹ̀ fi “wúrà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún tálẹ́ńtì” ṣètọrẹ. a (1 Kíróníkà 29:7) Jẹ́ ká fi èyí wéra pẹ̀lú àkíyèsí tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé. Ó rí “opó aláìní kan tí ó sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọn kéré gan-an” sínú àpótí ìṣúra tó wà nínú tẹ́ńpìlì. Báwo ni owó tó fi ṣètọrẹ yẹn ṣe pọ̀ tó ná? Kò ju ìdá kan lọ tá a bá pín owó ojúmọ́ táwọn òṣìṣẹ́ ń gbà sọ́nà mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64]. Síbẹ̀ Jésù sọ pé ìwọ̀nba owó yẹn ṣètẹ́wọ́gbà.—Lúùkù 21:1-4.

Ṣé Ọlọ́run Ń Béèrè Iye Pàtó Kan Lọ́wọ́ Àwọn Kristẹni?

Àwọn Kristẹni ò sí lábẹ́ májẹ̀mú Òfin tí Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, Ọlọ́run ò fi dandan béèrè iye pàtó kan pé kí wọ́n fi ṣètọrẹ. Àmọ́, nínú ìjọ àwọn Kristẹni tòótọ́, fífúni máa ń mú ayọ̀ púpọ̀ wá. Jésù alára sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírí gbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Ọrẹ àtinúwá làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé. Àwọn ọrẹ yìí la máa fi ń tẹ àwọn ìwé jáde lóríṣiríṣi, lára ẹ̀ sì ni ìwé ìròyìn tó ò ń kà yìí, a tún máa ń lò lára àwọn ọrẹ yìí láti fi tún àwọn ibi ìjọsìn wa, tá à ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe. A kì í fi èyíkéyìí lára owó yìí san owó oṣù fún ẹnikẹ́ni. Àmọ́, a máa ń fi iye díẹ̀ ran àwọn tí wọ́n ti yọ̀nda ara wọn láti máa lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa rówó san owó ọkọ̀ àtàwọn ìnáwó míì tí wọ́n bá fẹ́ bójú tó. Kò sẹ́nì kankan tó ń fi dandan béèrè fún irú owó bẹ́ẹ̀. Kódà, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni kì í gba owó kankan láti fi bójú to ìnáwó ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wa ló ń ṣiṣẹ́ ká lè máa rówó gbọ́ bùkátà ara wa, bíi ti Pọ́ọ̀lù tó ṣe iṣẹ́ àgọ́ títa.—2 Kọ́ríńtì 11:9; 1 Tẹsalóníkà 2:9.

Tẹ́nì kan bá fẹ́ wá ṣètọrẹ láti fi ti iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lẹ́yìn, èló ni onítọ̀hún lè fi ṣètọrẹ? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Kọ́ríńtì 8:12; 9:7.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lọ́dún 2008, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún dín mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [871] owó dọ́là ni ìpíndọ́gba iye tí wọ́n ń ta wúrà tó bá tẹ̀wọ̀n tó ọgbọ̀n [30] gíráàmù. Iye owó tí wọ́n fi ṣètọrẹ yẹn nígbà náà á tó nǹkan bíi bílíọ̀nù márùn-ún owó dọ́là.