Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Àwọn wo ni àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n ta ko Jésù?

Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, kì í ṣe Jerúsálẹ́mù nìkan ló ti bá àwọn akọ̀wé òfin pàdé, ó tún bá wọn pàdé láwọn ìlú àtàwọn abúlé kéékèèké pẹ̀lú. Lẹ́yìn òde ìlú Jerúsálẹ́mù àti láwọn àdúgbò táwọn Júù ń gbé lẹ́yìn òde ìlú Palẹ́sìnì, òṣìṣẹ́ ìjọba làwọn akọ̀wé òfin wọ̀nyẹn, wọ́n mọ Òfin, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí adàwékọ tàbí adájọ́ àdúgbò.—Máàkù 2:6; 9:14; Lúùkù 5:17-21.

Nílùú Jerúsálẹ́mù, àwọn akọ̀wé òfin sábà máa ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn alákòóso àwọn Júù. (Mátíù 16:21) Ìwé The Anchor Bible Dictionary sọ pé, “ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́” làwọn akọ̀wé òfin “máa ń ṣe fáwọn àlùfáà, nígbà tí wọ́n bá ń ṣègbẹ́jọ́ àti nínú ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ àwọn Sànhẹ́dírìn, wọ́n sì tún ń rí sí i pé àwọn èèyàn ń tẹ̀ lé àṣà àti òfin àwọn Júù.” Torí wọ́n kà wọ́n sí àgbà ọ̀jẹ̀ nínú kíkọ́ àwọn ẹlòmíì ní Òfin, àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin wà nínú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn tàbí ilé ẹjọ́ gíga jù lọ àwọn Júù. Wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àlùfáà àgbà àtàwọn Farisí.

Àwọn akọ̀wé òfin ló sábà máa ń ta ko Jésù lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Àmọ́ àwọn kan lára wọn ò ta kò ó. Bí àpẹẹrẹ, akọ̀wé òfin kan sọ fún Jésù pé: “Èmi yóò tẹ̀ lé ọ lọ sí ibi yòówù tí ìwọ bá fẹ́ lọ.” Nígbà kan, Jésù náà sọ fún akọ̀wé òfin kan pé: “Ìwọ kò jìnnà sí ìjọba Ọlọ́run.”—Mátíù 8:19; Máàkù 12:28-34.

Kí ló túmọ̀ sí láti fàmì òróró yan ẹnì kan?

Ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, dída òróró sí ẹnì kan ní orí túmọ̀ sí pé wọ́n ka ẹni yẹn sí èèyàn pàtàkì, ó sì tún jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣaájò àlejò. Òróró ólífì tí wọ́n ti fi lọ́fíńdà sí ni wọ́n sábà máa ń lò. Àwọn Hébérù tún máa ń da òróró sí ẹnì kan ní orí, ìyẹn ni pé kí wọ́n fòróró yàn án nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fi onítọ̀hún sí ipò àṣẹ pàtàkì kan. Bí àpẹẹrẹ, Mósè da òróró sí Áárónì lórí nígbà tó ń yàn án sípò àlùfáà àgbà. (Léfítíkù 8:12) Ní ti Dáfídì Ọba, “Sámúẹ́lì mú ìwo òróró, ó sì fòróró yàn án . . . ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára Dáfídì láti ọjọ́ yẹn lọ.”—1 Sámúẹ́lì 16:13.

Ọ̀rọ̀ náà, ma·shachʹ lédè Hébérù ló túmọ̀ sí fífi òróró yàn, inú ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ni wọ́n sì ti fa ma·shiʹach tó túmọ̀ sí Mèsáyà yọ. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó bá a mu ni khriʹo, inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí sì ni khri·stosʹ tàbí Kristi ti wá. Torí náà, a lè pe Áárónì àti Dáfídì ní Mèsáyà tàbí ẹni àmì òróró. A tún pe Mósè pàápàá ní kristi tàbí ẹni àmì òróró nítorí pé Ọlọ́run yàn án pé kó ṣe aṣojú òun.—Hébérù 11:24-26.

Ọlọ́run ló fúnra rẹ̀ yan Jésù ará Násárétì sí ipò àṣẹ gíga. Ẹ̀mí mímọ́ ni Ọlọ́run sì fi yàn án kì í ṣe òróró. (Mátíù 3:16) Ó bá a mu nígbà náà láti máa pe Jésù ní Mèsáyà tàbí Kristi torí pé Ẹni Àmì Òróró tí Jèhófà yàn ni.—Lúùkù 4:18.