Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé O Ti Sìn Nígbà Kan Rí? Ǹjẹ́ O Tún Lè Sìn Lẹ́ẹ̀kan Sí I?

Ṣé O Ti Sìn Nígbà Kan Rí? Ǹjẹ́ O Tún Lè Sìn Lẹ́ẹ̀kan Sí I?

Ṣé O Ti Sìn Nígbà Kan Rí? Ǹjẹ́ O Tún Lè Sìn Lẹ́ẹ̀kan Sí I?

ǸJẸ́ o ti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kankan rí nínú ìjọ Kristẹni? Bóyá o ti fìgbà kan rí jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Ó sì ṣeé ṣe kó o ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún rí. Èyí wù kó jẹ́, ó dájú pé iṣẹ́ náà fún ẹ láyọ̀ o sì gbádùn rẹ̀ gan-an. Àmọ́ fún ìdí kan, o ní láti fi iṣẹ́ yẹn sílẹ̀.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí kó o lè bójú tó ìdílé rẹ lo ṣe fi àǹfààní tó o ní náà sílẹ̀. Ó sì lè jẹ́ ara tó ń dara àgbà tàbí àìlera ló fà á. Tó o bá ṣerú ìpinnu bẹ́ẹ̀, kò fi hàn pé o kò ṣàṣeyọrí. (1 Tím. 5:8) Ní ọ̀rúndún kìíní, Fílípì ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì, àmọ́ nígbà tó yá ó fi iṣẹ́ yẹn sílẹ̀, ó sì lọ fìdí kalẹ̀ sí Kesaréà kó lè máa bójú tó ìdílé rẹ̀. (Ìṣe 21:8, 9) Nígbà tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì darúgbó, ó ṣètò pé kí Sólómọ́nì ọmọ òun jọba ní ipò òun. (1 Ọba 1:1, 32-35) Síbẹ̀, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Fílípì àti Dáfídì, ó sì mọyì wọn, àwọn èèyàn sì ń rántí wọn sí rere títí dòní.

Àmọ́ ó lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó o ní lọ́wọ́ rẹ. Ṣé ìwà àìtọ́ kan tó o hù ló fà á? Àbí ìṣòro ìdílé ni? (1 Tím. 3:2, 4, 10, 12) Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé o ò gbà pé ó yẹ kí wọ́n gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó o ní, ó sì lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà kò tíì tán nínú rẹ títí dòní.

O Lè Sápá Láti Tún Pa Dà Sìn

Ṣé tí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan bá ti bọ́ lọ́wọ́ èèyàn, kò tún lè pa dà ní in mọ́? Lọ́pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé èèyàn ṣì lè pa dà ní in. Àmọ́ kéèyàn tó tún lè pa dà ní àǹfààní náà, ó ní láti sapá kọ́wọ́ rẹ̀ lè tẹ̀ ẹ́. (1 Tím. 3:1) Àmọ́ kì nìdí tó fi yẹ kó o fẹ́ láti tún pa dà máa sìn? Ohun kan náà tó mú kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni, ìyẹn ni ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà àtàwọn tó ń sìn ín. Tó bá tọkàn rẹ wá láti fi ìfẹ́ yìí hàn nípa sísìn lẹ́ẹ̀kan sí i, èyí á jẹ́ kí Jèhófà lo ìrírí tó o ti ní ṣáájú kó o tó pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ àtèyí tó o ní lẹ́yìn tó o pàdánù rẹ̀.

Rántí ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n ti pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà. Ẹ̀yin sì jẹ́ ọmọ Jékọ́bù; ẹ kò wá sí òpin yín.” (Mál. 3:6) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì tún fẹ́ pa dà lò wọ́n. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ní pé kó tún pa dà lo ìwọ náà. Kí lo lè ṣe nínú ipò tó o wà nísinsìnyí? Kì í ṣe ẹ̀bùn àbínibí èèyàn ló máa mú kéèyàn lè sìn nínú ètò Ọlọ́run, bí kò ṣe okun téèyàn ní nípa tẹ̀mí. Torí náà, nísinsìnyí tí o kò ní àfikún iṣẹ́ nínú ìjọ, o ò ṣe kúkú tẹra mọ́ bí wàá ṣe túbọ̀ di alágbára nípa tẹ̀mí.

Tó o bá fẹ́ “di alágbára” nínú ìgbàgbọ́, o gbọ́dọ̀ “máa wá Jèhófà àti okun rẹ̀.” (1 Kọ́r. 16:13; Sm. 105:4) Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe èyí ni pé kó o máa gbàdúrà látọkàn wá. Nígbà tó o bá ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ipò tó o wà, sọ èrò ọkàn rẹ fún un, kó o sì tọrọ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, èyí á sì jẹ́ kó o fẹsẹ̀ múlẹ̀. (Sm. 62:8; Fílí. 4:6, 13) Ohun míì tó o tún lè ṣe láti túbọ̀ lágbára nípa tẹ̀mí ni pé kó o tẹra mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí o kò ṣe ní iṣẹ́ tó pọ̀ tó o ń bójú tó lásìkò yìí, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti lo àkókò tó pọ̀ sí i fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ. Ó tiẹ̀ lè ṣeé ṣe fún ọ láti pa dà sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tó ti ń ṣòro fún ọ láti ṣe tẹ́lẹ̀.

Má gbàgbé ṣá o, pé o ṣì jẹ́ ọkàn lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísá. 43:10-12) Àǹfààní tó ṣe pàtàkì jù tí ẹnikẹ́ni nínú wa lè ní ni pé ká jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 3:9) Tó o bá fi kún ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù rẹ, ìyẹn á jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tó o lè gbà máa lágbára sí i nípa tẹ̀mí, àwọn tẹ́ ẹ bá sì jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí náà á máa lágbára sí i nípa tẹ̀mí.

Béèyàn Ṣe Lè Gbé Ọ̀ràn Náà Kúrò Lọ́kàn

Téèyàn bá pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ní, ó lè fa ìtìjú tàbí àbámọ̀. Ó sì lè máa ṣe èèyàn bíi pé kò jẹ̀bi ọ̀ràn náà. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé lẹ́yìn táwọn arákùnrin tó wà nípò àbójútó ti gbọ́ èrò rẹ̀, wọ́n ṣì gbà síbẹ̀ pé kò tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn náà ńkọ́? Ọ̀ràn náà lè ṣàì tán lọ́kàn onítọ̀hún bọ̀rọ̀, ó lè mú kó ṣòro fún un láti sapá kó o lè pa dà ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, ó sì lè mú kó ṣòro fún un láti rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù, Mánásè àti Jósẹ́fù ṣe lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti mọ́kàn kúrò níbi ọ̀ràn náà.

Jóòbù ti ṣojú fún àwọn míì níwájú Jèhófà rí, ó sì ti jókòó ní ìjókòó àwọn àgbààgbà àti onídàájọ́ rí. (Jóòbù 1:5; 29:7-17, 21-25) Àmọ́ àkókò kan wà tí nǹkan nira fún Jóòbù nígbèésí ayé rẹ̀, ó pàdánù ọrọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ kú, àìsàn sì dá òun náà gúnlẹ̀. Torí gbogbo èyí, àwọn èèyàn ò kà á sí mọ́. Jóòbù sọ pé: “Wọ́n ń fi mí rẹ́rìn-ín, àwọn tí kò tó mi ní ọjọ́ orí.”—Jóòbù 30:1.

Jóòbù sọ pé ìyà tó ń jẹ òun kò tọ́ sóun, ó sì fẹ́ wí àwíjàre níwájú Ọlọ́run. (Jóòbù 13:15) Síbẹ̀, Jóòbù gbà láti dúró dìgbà tí Jèhófà máa dá sọ̀rọ̀ náà, èyí sì ṣe é láǹfààní. Ó rí i pé ó yẹ kóun ṣe àtúnṣe, ní pàtàkì lórí ọ̀nà tó gbà hùwà nígbà tí àdánwò dé bá a. (Jóòbù 40:6-8; 42:3, 6) Ohun tó tẹ̀yìn ìrẹ̀lẹ̀ Jóòbù yọ ni pé Ọlọ́run bù kún un lọ́pọ̀ yanturu.—Jóòbù 42:10-13.

Tó bá jẹ́ pé ìwà àìtọ́ tó o hù ló mú kó o pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà àtàwọn arákùnrin rẹ kò ní dárí jì ọ́, wọn ò sì ní gbàgbé ohun tó o ṣe. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ Mánásè ọba Júdà. “Ní ìwọ̀n púpọ̀ gan-an ni ó ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, láti mú un bínú.” (2 Ọba 21:6) Síbẹ̀ nígbẹ̀yìn ayé rẹ̀, ó kú bí olóòótọ́ ọba. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Mánásè ronú pìwà dà nígbà tí Jèhófà bá a wí. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kò gba àwọn ìkìlọ̀ tí Jèhófà ti fún un, ni Jèhófà bá dẹ àwọn ará Ásíríà sí i, wọ́n sì mú un lọ sí ìyànníyàn Bábílónì ní dídè gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn. Ibẹ̀ ni Mánásè ti “tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú, ó sì ń bá a nìṣó ní rírẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi nítorí Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀. Ó sì ń gbàdúrà sí I ṣáá.” Mánásè ronú pìwà dà látọkàn wá, èyí mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe rere, Jèhófà sì dárí jì í.—2 Kíró. 33:12, 13.

Téèyàn bá pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, kì í sábàá rí gbogbo rẹ̀ gbà pa dà lẹ́ẹ̀kan náà. Àmọ́ bí àkókò ti ń lọ, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í fún un láwọn àǹfààní kan. Tó bá tẹ́wọ́ gbà á, tó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, ìyẹn sábàá máa ń jẹ́ kí wọ́n fún un láwọn míì sí i. Àmọ́ ìyẹn ò fi hàn pé bẹ́ẹ̀ náà ló rọrùn tó. Àwọn ìdènà díẹ̀ lè wà. Àmọ́, téèyàn bá múra tán láti tẹ̀ síwájú tí kò sì dẹwọ́, ìyẹn á so èso rere.

Jẹ́ ká fi ti Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù ṣàpẹẹrẹ. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún, àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ṣèkà fún un, wọ́n tà á sóko ẹ̀rú. (Jẹ́n. 37:2, 26-28) Ó dájú pé kì í ṣe irú ìwà yìí ló máa retí pé káwọn ọbàkan òun hù sóun. Àmọ́, ó ṣe tán láti máa bá ìgbésí ayé ẹ̀ lọ nínú ipò tó bá ara rẹ̀ yìí, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó di “ẹni tí ń bójútó ilé ọ̀gá rẹ̀.” (Jẹ́n. 39:2) Nígbà tó yá, wọ́n tún ju Jósẹ́fù sẹ́wọ̀n. Àmọ́, ó ṣe olóòótọ́, Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀ débi pé wọ́n ní kó máa bójú tó ohun tó ń lọ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tó wà.—Jẹ́n. 39:21-23.

Jósẹ́fù ò mọ̀ pé àǹfààní kan ṣì máa tìdí gbogbo èyí yọ. Ńṣe ló kàn ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tó lè ṣe. Èyí ló mú kí Jèhófà lè lò ó láti dáàbò bo ìlà ìdílé tó máa mú Irú-ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí jáde. (Jẹ́n. 3:15; 45:5-8) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹnikẹ́ni nínú wa kò lè máa retí pé kóun kó ipa tó ṣàrà ọ̀tọ̀ bíi ti Jósẹ́fù, síbẹ̀ ìtàn Bíbélì yẹn kọ́ wa pé ọwọ́ Jèhófà máa ń wà nínú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ní. Máa ṣe dáadáa bíi ti Jósẹ́fù kọ́wọ́ rẹ bàa tún lè tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn.

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ohun Tójú Rẹ Rí

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń bani lọ́kàn jẹ́ ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù, Mánásè àti Jósẹ́fù. Àmọ́ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló fara mọ́ nǹkan tí Jèhófà fàyè gbà pé kó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú rẹ̀. Kí nìwọ náà lè rí kọ́?

Gbìyànjú láti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kọ́ ẹ. Nígbà tí ìbànújẹ́ gba Jóòbù lọ́kàn, ó dẹni tó ń ro tara ẹ̀ nìkan, kò rí ọ̀ràn pàtàkì tó wà nílẹ̀. Àmọ́, nígbà tí Jèhófà tọ́ ọ sọ́nà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lọ́nà tó tọ́, ó sọ pé: “Mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kò lóye.” (Jóòbù 42:3) Tó bá ń dùn ọ́ pé o pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan, ‘má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n ronú kí o bàa lè ní èrò inú yíyèkooro.’ (Róòmù 12:3) Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà fẹ́ tún ẹ ṣe láwọn ọ̀nà tíwọ fúnra rẹ kò lóye dáadáa.

Gba ìbáwí. Mánásè lè kọ́kọ́ rò pé ìbáwí líle tí Ọlọ́run fún òun ti pọ̀ jù. Àmọ́, ó gbà á, ó ronú pìwà dà, ó sì jáwọ́ nínú ìwà búburú tó ń hù. Láìwo bí ìbáwí tí wọ́n fún ẹ ṣe rí lára rẹ, ńṣe ni kó o ‘rẹ ara rẹ sílẹ̀ ní ojú Jèhófà, yóò sì gbé ọ ga.’—1 Pét. 5:6; Ják. 4:10.

Ní sùúrù kó o sì múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù ì bá ti mú kó ní àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sínú kó sì máa wá bó ṣe máa gbẹ̀san. Àmọ́, ó fiyè dénú, ó lo àánú. (Jẹ́n. 50:15-21) Tí nǹkan tí o kò retí bá ṣẹlẹ̀, sùúrù ni kó o ṣe. Múra tán láti gba ẹ̀kọ́ tí Jèhófà fẹ́ kọ́ ẹ.

Ǹjẹ́ o ti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kankan rí nínú ìjọ Kristẹni? Fún Jèhófà láyè láti tún fún ẹ láǹfààní iṣẹ́ ìsìn lọ́jọ́ iwájú. Jẹ́ kí ipò tẹ̀mí rẹ túbọ̀ máa lágbára sí i. Ní sùúrù àti ìrẹ̀lẹ̀ kí ìbínú rẹ má bàa ru bò ọ́ lójú. Fi tọkàntọkàn gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá gbé fún ẹ. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé “Jèhófà tìkára rẹ̀ kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlálèébù.”—Sm. 84:11.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]

Máa gbàdúrà látọkàn wá kí ìgbàgbọ́ rẹ lè lágbára

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Tó o bá fi kún ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù rẹ, ìyẹn á jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tó o lè gbà máa lágbára sí i nípa tẹ̀mí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Fún Jèhófà láyè láti tún fún ẹ láǹfààní iṣẹ́ ìsìn lọ́jọ́ iwájú