Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Rí Àwọn Ìṣúra Tó Wà ní Ìpamọ́

Ó Rí Àwọn Ìṣúra Tó Wà ní Ìpamọ́

Ó Rí Àwọn Ìṣúra Tó Wà ní Ìpamọ́

ǸJẸ́ o ti rí ìṣúra kan tó wà nípamọ́ níbi tí o kò rò pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè wà? Arákùnrin Ivo Laud tó wà lórílẹ̀-èdè Estonia rí irú àwọn ìṣúra bẹ́ẹ̀ ní March 27, ọdún 2005, nígbà tó ń ran arábìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Alma Vardja lọ́wọ́ láti wó ògbólógbòó ilé kékeré kan tó ń tọ́jú nǹkan sí. Bí wọ́n ṣe wó ògiri tó wà lọ́wọ́ ìta, wọ́n rí pákó tí wọ́n fi bo ẹ̀gbẹ́ kan lára òpó kan tó wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n yọ pákó náà, wọ́n rí àlàfo kan tó kù díẹ̀ kó fẹ̀ tó ìdajì ẹsẹ̀ bàtà níbùú, tó fi ohun tó kú díẹ̀ kó tó ìdajì ẹsẹ̀ bàtà jìn wọnú, tó sì ga tó bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rin. Wọ́n fi pákó tó ṣe rẹ́gí rẹ̀ bò ó. (1) Àwọn ìṣúra tó wà nípamọ́ ló kún inú àlàfo náà! Kí làwọn ìṣúra náà? Ta ló kó wọn pa mọ́ síbẹ̀?

Wọ́n rí àwọn ìwé kan tí wọ́n dì pa pọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì fi àwọn bébà tó nípọn wé nínú àlàfo yẹn. (2) Ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà nínú àwọn àdìpọ̀ náà, èyí tó sì pọ̀ jù níbẹ̀ ló jẹ́ àwọn àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ìṣọ́, títí kan èyí tó jẹ́ tọdún 1947. (3) Ńṣe ni wọ́n fara balẹ̀ fọwọ́ kọ wọ́n lédè Estonia. Àwọn kan lára àwọn àdìpọ̀ náà ní ìsọfúnni nípa ẹni tó kó wọn pa mọ́ síbẹ̀. Ohun tí wọ́n rí lorí wọn ni àkọsílẹ̀ bí wọ́n ṣe fẹ́ gba ọ̀rọ̀ lẹ́nu Arákùnrin Villem Vardja tó jẹ́ ọkọ Arábìnrin Alma Vardja. Wọ́n tún rí àwọn ìsọfúnni nípa iye ọdún tó lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Kí nìdí tí wọ́n fi ju arákùnrin náà sẹ́wọ̀n?

Arákùnrin Vardja jẹ́ ìránṣẹ́ kan láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Ìjọ Tartu, lẹ́yìn náà ó tún sìn ní Ìjọ Otepää. Orílẹ̀-èdè Estonia, tó ti fìgbà kan jẹ́ ara orílẹ̀-èdè Soviet Socialist Republics ni ìjọ méjèèjì náà wà. Ẹ̀rí wà pé ṣáájú Ogun Àgbáyé Kejì ló ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ní nǹkan bí ọdún mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, ní December 24, ọdún 1948, ìjọba Kọ́múníìsì mú Arákùnrin Vardja torí ìgbòkègbodò ìsìn rẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá da ìbéèrè bò ó, wọ́n sì ṣe é bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú, níbi tí wọ́n ti fẹ́ fipá mú un pé kó fún wọn lórúkọ àwọn ará tó kù. Láìfún un láǹfààní láti sọ tẹnu ẹ̀ ní kóòtù, wọ́n ní kó lọ lo ọdún mẹ́wàá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.

Arákùnrin Villem Vardja sin Jèhófà tọkàntọkàn títí tó fi kú ní March 6, ọdún 1990. Ìyàwó rẹ̀ ò mọ̀ pé irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ wà níbì kan. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí tí arákùnrin náà ò fi jẹ́ kí ìyàwó rẹ̀ mọ̀ nípa àwọn ìwé náà ni pé ó lè kó obìnrin náà sí wáhálà tí wọ́n bá bi í léèrè. Kí nìdí tó fi ní láti kó àwọn ìwé náà pa mọ́? Ìdí ni pé, ìgbàkigbà làwọn ìgbìmọ̀ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB lè lọ tú ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò, torí bóyá wọ́n á ráwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Arákùnrin Vardja kó àwọn ìwé náà pa mọ́, kó lè rí i dájú pé oúnjẹ tẹ̀mí á wà fáwọn ará tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọlọ́pàá KGB kó gbogbo èyí tó kù lọ. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1990, àwọn kan ti kọ́kọ́ rí irú àwọn ìwé báyìí tí wọ́n kó pa mọ́. Wọ́n rí àwọn kan ní ìlú Tartu tó wà lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Estonia. Arákùnrin Villem Vardja náà ló kó wọn pa mọ́ síbẹ̀.

Kí nìdí tá a fi pe àwọn ìwé yìí ní ìṣúra? Ìdí ni pé àwọn ìwé tí wọ́n fara balẹ̀ dà kọ, tí wọ́n sì rọra fi pa mọ́ yìí jẹ́ ká mọ báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe mọrírì oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n ń rí ní àkókò yẹn. (Mát. 24:45) Ṣé ìwọ náà mọrírì àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tẹ́ ẹ̀ ń rí gbà lágbègbè yín? Lára rẹ̀ ni ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ tó ń jáde lédè Estonia àti ní ohun tó ju àádọ́sàn-án [170] èdè míì lọ.