Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

• Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ọmọ inú oyún tó kú sínú ìyá rẹ̀ ní àjíǹde?

Ìgbà tí wọ́n bá ti lóyún ọmọ kan ló ti di ẹ̀dá alààyè. Jèhófà lè jí ẹnikẹ́ni dìde láìfi ti bó ṣe dàgbà tó pè, “nítorí ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Máàkù 10:27) Àmọ́ Bíbélì kò sọ ọ́ tààràtà bóyá yóò jí àwọn ọmọ inú oyún tó kú sínú ìyá wọn dìde.—4/15, ojú ìwé 12 àti 13.

• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú kíkíyèsí èèrà, gara orí àpáta, eéṣú àti ọmọńlé?

Àwọn ẹ̀dá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ń fi ọgbọ́n àdámọ́ni hàn. Wọ́n sì ń tipa báyìí jẹ́ ká túbọ̀ rí i bí ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó. (Òwe 30:24-28)—4/15, ojú ìwé 16 sí 19.

• Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wo ló ṣẹlẹ̀ ní ìwòyí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Lọ́dún 1909, a gbé oríléeṣẹ́ àjọ Watch Tower Bible and Tract Society, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lábẹ́ òfin, kúrò ní ìlú Pittsburgh ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania lọ sí ìlú Brooklyn ní ìpínlẹ̀ New York. Ibẹ̀ ló sì wà látìgbà yẹn títí dòní olónìí.—5/1, ojú ìwé 22 sí 24.

• Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé ó dára kéèyàn máa dákẹ́ láwọn ìgbà míì?

Bíbélì fi hàn pé téèyàn bá ń dákẹ́ nígbà míì, ó jẹ́ àmì ọ̀wọ̀, ó ń fúnni láǹfààní láti ṣàṣàrò, ó sì jẹ́ ẹ̀rí pé èèyàn ní ọgbọ́n àti òye. (Sm. 37:7; 63:6; Òwe 11:12)—5/15, ojú ìwé 3 sí 5.

• Kí làwọn ẹni yìí, ìyẹn John Wycliffe, William Tyndale, Robert Morrison àti Adroniram Judson fi jọra?

Gbogbo àwọn wọ̀nyí ló fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀ sáwọn èdè tí mùtúmùwà ń sọ. Wycliffe àti Tyndale túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì nígbà tí Morrison túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Ṣáínà. Judson sì túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Burmese (tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Myanmar).—6/1, ojú ìwé 8 sí 11.

• Mélòó ni àwọn ọba Júdà tó ní ìtara tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fún ilé Ọlọ́run?

Mọ́kàndínlógún ni iye àwọn ọba tó jẹ lórí ẹ̀yà Júdà tó wà ní ìhà gúúsù, mẹ́rin nínú wọn ló sì ní ìtara tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fún ilé Ọlọ́run. Orúkọ wọn ni Ásà, Jèhóṣáfátì, Hesekáyà àti Jòsáyà.—6/15, ojú ìwé 7 sí 11.

• Ṣé gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà láyé ló ń kópa nínú pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí?

Rárá o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹni àmì òróró ló jẹ́ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye, àmọ́ àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí nìkan ló ń bójú tó pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí.—6/15, ojú ìwé 22 sí 24.

• Kí nìdí tí ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ Jésù fi wu àwọn ọmọ ogun Róòmù?

Àwọn ọmọ ogun tó wà níbi tí wọ́n ti pa Jésù yẹn kò pín ẹ̀wù rẹ̀ sí kélekèle. Bí wọ́n ṣe sábà máa ń ṣe irú ẹ̀wù tó gùn délẹ̀ yẹn ni pé wọ́n máa rán aṣọ méjì pọ̀ látòkèdélẹ̀. Àmọ́ ẹ̀wù Jésù kò lójú rírán, èyí sì túbọ̀ mú kó níye lórí gan-an.—7/1, ojú ìwé 22.

• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ lohun pàtàkì tó fìyàtọ̀ sáàárín ìṣe Jésù àti tàwọn aṣáájú ìsìn?

Kàkà káwọn aṣáájú ìsìn yẹn nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ṣe ni wọ́n kà wọ́n sẹ́ni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́ Jésù nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀, àánú àwọn èèyàn sì máa ń ṣe é. (Mát. 9:36) Ó kó wọn mọ́ra, ó ń gba tiwọn rò, ó sì máa ń ṣe wọ́n jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́.—7/15, ojú ìwé 15.

• Kí nìdí tí ọ̀ràn ìnáwó fi máa ń jẹ́ ìṣòro fáwọn tọkọtaya, kí ló sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yìí?

Ohun tó sábà máa ń fa èdè àìyedè lórí ọ̀ràn owó ni àìfọkàntán ara ẹni àti ìbẹ̀rù. Ìyàtọ̀ tó wà nínú bí wọ́n ṣe tọ́ tọkọtaya kan dàgbà sì tún lè fà á. Nǹkan mẹ́rin tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nìwọ̀nyí: Kí wọ́n mọ bí wọ́n á ṣe máa fi sùúrù sọ̀rọ̀ tọ́rọ̀ owó bá délẹ̀, kí wọ́n jọ fohùn ṣọ̀kan lórí bí wọ́n á ṣe máa ṣe owó tó bá ń wọlé, kí wọ́n kọ ètò ìṣúnná owó wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì sọ ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.—8/1, ojú ìwé 10 sí 12.