Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣẹ́ni Gidi ni Ádámù àti Éfà?

Ṣẹ́ni Gidi ni Ádámù àti Éfà?

Ṣẹ́ni Gidi ni Ádámù àti Éfà?

LÓJÚ ọ̀pọ̀ èèyàn, ìtàn àròsọ lásán ni wọ́n ka ìtàn Ádámù àti Éfà tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì sí. Lẹ́tà kan sí olóòtú àgbà ìwé ìròyìn Time, sọ pé, “Ọjọ́ pẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ti ka àwọn ìtàn bí ìtàn Ádámù àti Éfà tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì sí ìtándòwe lásán.” Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú ìsìn Kátólíìkì, Pùròtẹ́sítáǹtì àti Júù ló sì gbà bẹ́ẹ̀. Ohun tí wọ́n sọ ni pé ọ̀pọ̀ lára ìtàn tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ni kò bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu.

Kí lèrò ẹ? Ṣó o gbà pé ẹni gidi ni Ádámù àti Éfà? Ṣé ẹ̀rí kankan wà tó fi hàn pé lóòótọ́ ni wọ́n gbáyé rí? Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ewu wo ló wà nínú gbígbà pé ìtàn àròsọ lásán ni ìtàn tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì?

Ṣé Ìtàn Inú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì Bá Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mu?

Jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ṣe pàtàkì nínú bí Ọlọ́run ṣe dá ọkùnrin àkọ́kọ́. Bíbélì sọ nípa Ádámù pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Ṣé ọ̀rọ̀ yìí bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu?

Ìwé Nanomedicine sọ pé, èròjà mọ́kànlélógójì [41] ló para pọ̀ di ara ẹ̀dá èèyàn. Àwọn èròjà tó ṣe pàtàkì bíi, carbon, iron, afẹ́fẹ́ ọ́síjìn àtàwọn míì ló wà nínú “ekuru” orí ilẹ̀ ayé. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé “ekuru ilẹ̀” ni Ọlọ́run fi dá èèyàn.

Báwo làwọn èròjà aláìlẹ́mìí yẹn ṣe wá para pọ̀ di ẹ̀dá èèyàn? Ká lè lóye iṣẹ́ ńlá tó wà níbẹ̀, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọkọ̀ tí àjọ NASA ṣe, èyí tí wọ́n máa ń gbé lọ sí ojúde òfúrufú, ọkọ̀ yìí jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀rọ tó díjú jù lọ tí wọ́n tíì ṣe. Ẹ̀yà ara ọkọ̀ yìí pọ̀ tó mílíọ́nù méjì àtààbọ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún ló gba àwùjọ onímọ̀ ẹ̀rọ láti ṣe é àti láti tò ó pa pọ̀. Jẹ́ ká wá fi èyí wéra pẹ̀lú ara ẹ̀dá èèyàn. Bí ẹní ṣeré ọmọdé lásán ni ẹ̀yà ara ọkọ̀ yìí jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ oríṣiríṣi átọ́ọ̀mù àti sẹ́ẹ̀lì tó wà nínú ara ọmọ èèyàn tó jẹ́ pé iye mílíọ́nù wọn pọ̀ débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà lóǹkà. Oríṣiríṣi ẹ̀yà ara pàtàkì-pàtàkì sì tún wà tá a lè pín sọ́nà mẹ́sàn-án. Báwo wá ni ara ẹ̀dá èèyàn tó kàmàmà tó díjú tó sì yani lẹ́nu yìí ṣe wà? Ṣó dédé wà ni àbí Ẹlẹ́dàá onílàákàyè ló ṣe é?

Ó dáa, kí ló para pọ̀ di ẹ̀dá èèyàn? Ta ni orísun ìwàláàyè? Ó rú àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lójú débi pé, wọ́n láwọn ò mọ̀ ọ́n. Kódà, ó ṣòro fún wọn láti fẹnu kò lórí ohun tí ìwàláàyè túmọ̀ sí. Àmọ́ èrò àwọn tó gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà yàtọ̀. Torí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ni Orísun ìwàláàyè. a

Ṣó yẹ kéèyàn gbà pé òótọ́ ni àlàyé tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣe pé egungun ìhà Ádámù ni Ọlọ́run fi dá Éfà? (Jẹ́nẹ́sísì 2:21-23) Ká tó lè sọ pé ìtàn àròsọ lásán ni, jẹ́ ká gbé àwọn òtítọ́ yìí yẹ̀ wò: Ní January ọdún 2008, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó wà ní ìpínlẹ̀ Kalifóníà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe ọlẹ̀ àtọwọ́dá látara sẹ́ẹ̀lì tó wà nínú awọ ara ẹni tó ti dàgbà, èyí sì làkọ́kọ́ irú ẹ̀. Láti ìgbà yẹn sì rèé, ó kéré tán àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti lo irú ọ̀nà bí èyí láti ṣe ogún [20] àwọn ẹranko àtọwọ́dá. Èyí táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ni àgùntàn kan tí wọ́n pè ní Dolly, ọdún 1996 ni wọ́n ṣe ọlẹ̀ tó di Dolly yìí látara sẹ́ẹ̀lì tó wà lára ọmú abo àgùntàn kan. b

A ò tíì mọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde nǹkan tí wọ́n ṣe yìí. Àmọ́ ohun tó dájú ni pé: Báwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá lè lo nǹkan kan látara ẹranko kan láti fi ṣe oríṣi ẹranko náà, ṣé á wá ṣòro fún Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ Olódùmarè láti dá èèyàn látinú ẹ̀yà ara èèyàn míì? Ohun míì tó tún gbàfiyèsí ni pé àwọn oníṣẹ́ abẹ máa ń lo egungun ìhà láti fi ṣe àtúnṣe ibi tó ti bà jẹ́ nínú ara torí bó ṣe lágbára láti sọ ara rẹ̀ dọ̀tun kó sì pààrọ̀ ara rẹ̀.

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ádámù àti Éfà

Ó máa ń ya àwọn kan lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Ádámù àti Éfà. Báwo làwọn apá Bíbélì tó kù tó sọ̀rọ̀ nípa Ádámù àti Éfà ṣe jẹ́rìí sí ìtàn tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì?

Bí àpẹẹrẹ, wo orúkọ àwọn baba ńlá àwọn Júù tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Kíróníkà Kìíní, orí kìíní sí ìkẹsàn-án àti ìwé Ìhìn Rere Lúùkù orí kẹta. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn ìlà ìdílé tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Kíróníkà Kìíní jẹ́ ká mọ̀ nípa ìran méjìdínláàádọ́ta [48], èyí tó sì wà nínú ìwé Lúùkù náà jẹ́ ká mọ̀ nípa ìran márùndínlọ́gọ́rin [75]. Lúùkù sọ ìlà ìdílé Jésù Kristi, ìwé Kíróníkà sì ṣàkọsílẹ̀ ìlà ìdílé àwọn ọmọ aládé àtàwọn àlùfáà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Àwọn àkọsílẹ̀ méjèèjì ló lórúkọ àwọn èèyàn pàtàkì nínú ìtàn, àwọn bíi Sólómọ́nì, Dáfídì, Jékọ́bù, Ísákì, Ábúráhámù, Nóà àti Ádámù. Àwọn orúkọ tó wà nínú àkọsílẹ̀ méjèèjì ló jẹ́ orúkọ àwọn èèyàn gidi, ẹni gidi tó dájú pé ó wà nígbà kan rí ni Ádámù náà sì jẹ́ nínú àkọ́sílẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

Síwájú sí i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni Bíbélì máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ádámù àti Éfà gẹ́gẹ́ bí ẹni gidi, kì í sì í ṣe bí àwọn èèyàn inú ìtàn àròsọ lásán. Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé:

• “Láti ara ọkùnrin kan ni [Ọlọ́run] ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.”—ÌṢE 17:26.

• “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí . . . ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba láti ọ̀dọ̀ Ádámù títí dé ọ̀dọ̀ Mósè.”—RÓÒMÙ 5:12, 14.

• “Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ di alààyè ọkàn.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 15:45.

• “Ádámù ni a kọ́kọ́ ṣẹ̀dá, lẹ́yìn náà Éfà.”—1 TÍMÓTÌ 2:13.

• “Énọ́kù, ẹnì keje nínú ìlà láti ọ̀dọ̀ Ádámù, sọ tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú nípa [àwọn èèyàn burúkú].”—JÚÚDÀ 14.

Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jésù Kristi tó jẹ́ ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbára lé jù lọ nínú Bíbélì jẹ́rìí pé Ádámù àti Éfà ti gbé ayé rí. Nígbà táwọn èèyàn fẹ́ dán Jésù wò lórí ọ̀rọ̀ ìkọ̀sílẹ̀, Jésù dá wọn lóun pé: “Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá ‘[Ọlọ́run] dá wọn ní akọ àti abo. Ní tìtorí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’ . . . Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Máàkù 10:6-9) Ṣé Jésù á wá lo ìtándòwe lásán láti fìdí àṣẹ pàtàkì tí Ọlọ́run pa yìí múlẹ̀? Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Ńṣe ni Jésù fi ọ̀rọ̀ inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ti ohun tó sọ lẹ́yìn.

Nígbà tí ìwé The New Bible Dictionary ń ṣe àkópọ̀ àwọn ẹ̀rí tó wà nínú Ìwé Mímọ́, ó ní: “Májẹ̀mú Tuntun fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ làwọn ìtàn tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì.”

Ewu Tó Wà Nínú Gbígbà Pé Ádámù àti Éfà Ò Gbáyé Rí

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń fi tọkàntọkàn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì gbà pé, èrò náà pé Ádámù àti Éfà gbé ayé rí kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú jíjẹ́ Kristẹni tòótọ́. Èyí lè dà bí ohun tó bọ́gbọ́n mu téèyàn ò bá wádìí jinlẹ̀. Àmọ́, jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò, ká sì wo ibi tó máa yọrí sí.

Bí àpẹẹrẹ, wo ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa ìràpadà táwọn tó máa ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì nífẹ̀ẹ́ sí gan-an. Ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé, Jésù Kristi fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé ṣe ìràpadà láti gba àwa èèyàn lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Bá a ṣe mọ̀, ìràpadà ni iye tó ṣe rẹ́gí téèyàn fi ra ohun kan tó pàdánù tàbí tó sọ nù pa dà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí.” (1 Tímótì 2:6) A lè béèrè pé, ìràpadà tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú kí ni? Bíbélì dáhùn, ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 15:22) Ìwàláàyè pípé Jésù tó fi rúbọ láti dá ẹ̀dá èèyàn onígbọràn sílẹ̀ ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ìwàláàyè pípé tí Ádámù pàdánù nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì. (Róòmù 5:12) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, bí Ádámù ò bá gbáyé rí, asán ni ẹbọ ìràpadà Kristi.

Ewu kan tó wà nínú àìnígbàgbọ́ pé òótọ́ ni ìtàn Ádámù àti Éfà tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ni pé, ó lè sọ ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀! c Ohun tí irú èrò yìí máa yọrí sí ni ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí kò ní ìdáhùn àti ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.—Hébérù 11:1.

Ṣé Ìwàláàyè Nítumọ̀?

Tóò, ìbéèrè tó gbàfiyèsí kan rèé: Ṣé kíkọ̀ téèyàn bá kọ̀ láti gba ìtàn inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì gbọ́ ló máa jẹ́ kéèyàn mọ ìtúmọ̀ àti ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa? Ọ̀gbẹ́ni Richard Dawkins tó jẹ́ ògbóǹkangí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n tó sì jẹ́ aláìgbọlọ́rungbọ́ sọ nípa ayé àti ọ̀run, pé “kò sí ohun kan tó fi hàn pé a ṣètò rẹ̀, kò wúlò fún nǹkan kan, kò sí ibi tàbí ire nínú rẹ̀, kò sí ohunkóhun níbẹ̀, gbogbo rẹ̀ kàn wà bọrọgidi ni.” Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ tí kò lọ́gbọ́n nínú tí kò ba èrò ẹ̀dá mu lọ́nàkọnà lèyí jẹ́!

Ní òdìkejì sí èrò ọ̀gbẹ́ni yìí, Bíbélì fún wa láwọn ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì nígbèésí ayé, irú bí: Ibo la ti wá? Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa? Kí nìdí tí ìwà ibi àti ìjìyà fi pọ̀ láyé? Ṣé ìwà ibi lè dópin láé? Àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láfikún sí i, ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi jẹ́ ká ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè irú èyí tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì, níbi tí Ọlọ́run fàwọn èèyàn àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà sí. (Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3-5) Ẹ ò rí i pé àgbàyanu àǹfààní là ń retí! d

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìtàn Ádámù àti Éfà kò bá àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n mu, ó bá àwọn ẹ̀kọ́ míì nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó bá àwọn ọ̀rọ̀ tó kù nínú Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí mu, èyí sì jẹ́ ká mọ ìtúmọ̀ àti ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa lọ́nà tó tẹ́ni lọ́run.

Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé kó o gbé Bíbélì yẹ̀ wò fúnra rẹ? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo ìwé Is There a Creator Who Cares About You? àti Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

b Kì í ṣe pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ̀dá ìwàláàyè o, kàkà bẹ́ẹ̀ látara ohun tí Ọlọ́run dá ni wọ́n ti ṣe nǹkan tí wọ́n ṣe.

c Lára àwọn ẹ̀kọ́ náà ni ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀tọ́ Ọlọ́run láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àti ọ̀run, ìṣòtítọ́ èèyàn, ire àti ibi, òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá, ipò táwọn òkú wà, ìgbéyàwó, Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, Párádísè orí ilẹ̀ ayé, Ìjọba Ọlọ́run àti ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ míì.

d Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 3 tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ilẹ̀ Ayé?” àti orí 5 tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, bí Ádámù ò bá gbáyé rí, asán ni ẹbọ ìràpadà Kristi

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Bó ṣe gba ọgbọ́n láti ṣe ọkọ̀ tí wọ́n máa ń gbé lọ sí ojúde òfúrufú, ó gba ọgbọ́n láti ṣe ara ẹ̀dá èèyàn pẹ̀lú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jésù jẹ́rìí sí i pé Ádámù àti Éfà gbáyé rí