Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Onígbọràn Àti Onígboyà Bíi Kristi

Jẹ́ Onígbọràn Àti Onígboyà Bíi Kristi

Jẹ́ Onígbọràn Àti Onígboyà Bíi Kristi

“Ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”—JÒH. 16:33.

1. Báwo ni ìgbọràn Jésù sí Ọlọ́run ṣe jinlẹ̀ tó?

 ÌFẸ́ Ọlọ́run ni Jésù Kristi máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà. Kódà kò fàyè gba èròkérò tó lè mú kó ṣàìgbọràn sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run. (Jòh. 4:34; Héb. 7:26) Àmọ́ àwọn ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tó wà láyé jẹ́ kó ṣòro fún un láti jẹ́ onígbọràn. Láti ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ làwọn ọ̀tá rẹ̀, tó fi mọ́ Sátánì fúnra rẹ̀, ti ń gbógun tì í kó lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ tì. Wọ́n bá a débi pé wọ́n tàn án, wọ́n lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí kó bàa lè gbà pẹ̀lú wọn. (Mát. 4:1-11; Lúùkù 20:20-25) Àwọn ọ̀tá yìí kó ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀ bá Jésù, wọ́n sì tún fìyà jẹ ẹ́ gan-an. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n ṣekú pa á lórí òpó igi oró. (Mát. 26:37, 38; Lúùkù 22:44; Jòh. 19:1, 17, 18) Pẹ̀lú gbogbo ohun tójú rẹ̀ rí yìí àti gbogbo ìyà tó jẹ ẹ́, Jésù dúró gẹ́gẹ́ bí “onígbọràn títí dé ikú.”—Ka Fílípì 2:8.

2, 3. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú bí Jésù ṣe jẹ́ onígbọràn lójú gbogbo ìyà tó jẹ ẹ́?

2 Àwọn ohun tójú Jésù rí nígbà tó wà láyé fún un láǹfààní láti kọ́ ìgbọràn lọ́nà mìíràn. (Héb. 5:8) Ó lè dà bíi pé kò sí nǹkan tí Jésù kò tíì mọ̀ nípa bó ṣe yẹ ká sin Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àìmọye ọdún ló ṣáà ti fi ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, tó sì jẹ́ pé òun ni “àgbà òṣìṣẹ́” fún Ọlọ́run nígbà ìṣẹ̀dá. (Òwe 8:30) Síbẹ̀, bó ṣe fi ìgbàgbọ́ fara da gbogbo ìyà tó jẹ gẹ́gẹ́ bí èèyàn mú kí ìwà títọ́ rẹ̀ di pípé pérépéré. Adúrú Jésù Ọmọ Ọlọ́run ṣe ohun tó mú kó túbọ̀ máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Bàbá rẹ̀. Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ kankan wà táwa náà lè rí kọ́ látinú ìyẹn?

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, kò gbẹ́kẹ̀ lé agbára ara rẹ̀ láti lè ṣe ìgbọràn lọ́nà tó pé pérépéré. Ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ kóun lè jẹ́ onígbọràn (Ka Hébérù 5:7.) Káwa náà tó lè máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bí onígbọràn, ó yẹ ká ní ìrẹ̀lẹ̀ ká sì máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́. Ìdí rèé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi fún àwa Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú,” ó “rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú.” (Fílí. 2:5-8) Irú ìgbésí ayé tí Jésù gbé lórí ilẹ̀ ayé fẹ̀rí hàn pé ó ṣeé ṣe fún èèyàn láti jẹ́ onígbọràn, kódà nínú ayé búburú yìí. Lóòótọ́, ẹni pípé ni Jésù, àmọ́ àwa èèyàn aláìpé ńkọ́?

A Lè Jẹ́ Onígbọràn Bá A Tiẹ̀ Jẹ́ Aláìpé

4. Kí ni dídá tí Ọlọ́run dá wa ní ẹ̀dá tó lómìnira láti pinnu ohun tó wù wá túmọ̀ sí?

4 Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, ó dá wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá onílàákàyè tó lómìnira láti pinnu ohun tó bá wù wọ́n. Àwa àtọmọdọ́mọ wọn náà jẹ́ ẹ̀dá tó lómìnira láti pinnu ohun tó bá wù wá. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé a lè fúnra wa pinnu láti ṣe rere tàbí búburú. Ìyẹn ni pé Ọlọ́run ti fún wa lómìnira láti yàn bóyá a ó ṣègbọràn tàbí a ò ní ṣègbọràn. Òmìnira ńlá tí Ọlọ́run fún wa yìí, gbé ojúṣe pàtàkì kan lé wa lọ́wọ́, èyí ló sì máa mú ká jíhìn fún Ọlọ́run. Àní sẹ́, àwọn ìpinnu tá a bá ṣe lè yọrí sí ikú tàbí ìyè fún wa. Wọ́n sì tún máa ń nípa lórí àwọn èèyàn tó sún mọ́ wa.

5. Ìjàkadì wo ló wà fún gbogbo wa, báwo la sì ṣe lè borí?

5 Nítorí àìpé ẹ̀dá tá a ti jogún, kì í kàn-án ṣàdédé wù wá láti ṣe ìgbọràn. Ìgbà gbogbo kọ́ ló máa ń rọrùn láti ṣègbọràn sófin Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù alára ní láti jìjàkadì lórí ọ̀ràn yìí. Ó sọ pé: “Mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” (Róòmù 7:23) Ṣẹ́ ẹ mọ̀ pé ó túbọ̀ máa ń rọrùn láti ṣègbọràn nígbà tí kò bá sí pé èèyàn máa ní láti yááfì ohun kan, tí ìgbọràn náà kò sì ní mú ìṣòro kankan lọ́wọ́. Àmọ́ kí la máa ṣe tó bá di pé a fẹ́ ṣègbọràn, àmọ́ tí “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” fẹ́ mú ká ṣe ohun tí kò tọ́? Ohun tó máa ń fa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni àìpé ẹ̀dá tá a jogún àti ipa tí “ẹ̀mí ayé” tó yí wa ká ń kó. Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì lágbára gan-an ni. (1 Jòh. 2:16; 1 Kọ́r. 2:12) Láti dènà wọn, a gbọ́dọ̀ ‘múra ọkàn wa sílẹ̀’ kó tó di ìgbà tí ìṣòro tàbí àdánwò máa dé, ká pinnu pé ti Jèhófà la ó máa gbọ́, láìwo ti ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀. (Sm. 78:8) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì nípa àwọn tó borí nítorí pé wọ́n ti múra ọkàn wọn sílẹ̀.—Ẹ́sírà 7:10; Dán. 1:8.

6, 7. Sọ àpẹẹrẹ kan lórí bí ìdákẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání.

6 Ọ̀nà kan tá a lè gbà múra ọkàn wa sílẹ̀ ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, fojú inú wo ọ̀rọ̀ yìí. Ká sọ pé alẹ́ ọjọ́ tó o máa ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ fúnra rẹ rèé. O ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàdúrà tán ni pé kí ẹ̀mí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fi ohun tó ò ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò. Àmọ́ o ní in lọ́kàn láti wo eré kan tí wọ́n máa ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n lálẹ́ ọjọ́ kejì. O ti gbọ́ ọ tí wọ́n ti polówó rẹ̀, táwọn èèyàn ń sọ bó ṣe dùn tó, àmọ́ o mọ̀ pé ìṣekúṣe àti ìwà ipá díẹ̀ wà nínú eré ọ̀hún.

7 O wá ronú jinlẹ̀ lórí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà ní Éfésù 5:3 tó sọ pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́.” O tún rántí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù míì tó wà nínú Fílípì 4:8. (Kà á.) Bó o ṣe ń ro ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ yìí síwá sẹ́yìn, o wá béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Tí mo bá mọ̀ọ́mọ̀ wo irú eré tó lè gbé èròkerò síni lọ́kàn yẹn, ṣé lóòótọ́ ni mò ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀ bí Jésù ti ṣe?’ Kí ni wàá ṣe? Ṣé wàá pàpà wo eré yẹn?

8. Kí nìdí tá a ò fi gbọ́dọ̀ fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìlànà tá a ń tẹ̀ lé lórí ọ̀ràn ìwà mímọ́ àti àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run?

8 Àṣìṣe ló máa jẹ́ tá a bá fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìlànà tá a ń tẹ̀ lé lórí ọ̀ràn ìwà mímọ́ àti àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run, tàbí tá a bá lọ ń ronú pé kò sóhun tó máa ṣe wá tá a bá ń kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, tó fi mọ́ èyí tá a lè kó nípasẹ̀ eré ìnàjú oníwà ipá àti oníwà pálapàla. Dípò tá a fi máa rò bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ dáàbò bo ara wa àtàwọn ọmọ wa kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí Sátánì tó ń sọni dìbàjẹ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àgbẹ̀ máa ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láti dáàbò bo igi eléso wọn lọ́wọ́ àwọn kòkòrò tó máa ń bá igi jà tó sì lè mú kí igi náà má so bó ṣe yẹ kó so tàbí kó tiẹ̀ pa igi náà pàápàá. Ṣé kò wá yẹ káwa náà wà lójúfò láti dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ ètekéte Sátánì?—Éfé. 6:11.

9. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ojoojúmọ́ la gbọ́dọ̀ máa pinnu láti ṣègbọràn sí Jèhófà?

9 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ la máa ń ní láti yàn bóyá ọ̀nà Jèhófà la ó máa gbà ṣe nǹkan àbí ọ̀nà tara wa. Ká bàa lè rí ìgbàlà, a ní láti máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi tó ṣe ìgbọràn “títí dé ikú,” ńṣe là ń fi hàn pé ìgbàgbọ́ wa dájú. Jèhófà yóò sì pín wa lérè fún ìṣòtítọ́ wa. Jésù ṣèlérí pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mát. 24:13) Èyí á gba pé ká ní ìgboyà tòótọ́, irú èyí tí Jésù ní.—Sm. 31:24.

Jésù Ni Àpẹẹrẹ Tó Dára Jù Lọ Tó Bá Dọ̀ràn Ìgboyà

10. Àwọn nǹkan wo ló lè fẹ́ kó èèràn ràn wá nínú ayé, kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe lórí rẹ̀?

10 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀mí ayé àti ìwàkiwà rẹ̀ ti gbòde kan báyìí, a nílò ìgboyà káyé má bàa kó èèràn ràn wá. Àwa Kristẹni ń sapá láti borí àwọn nǹkan tó lè mú ká yà kúrò lọ́nà òdodo Jèhófà. Lára irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni àwọn ohun tó lè fẹ́ múni ṣèṣekúṣe, ohun tó lè fẹ́ mú ká lẹ́mìí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe, ìṣòro ìṣúnná owó tàbí ọ̀ràn ìjọsìn èké. Àtakò látinú ìdílé ni tàwọn míì lára wa. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ilé ẹ̀kọ́ ayé túbọ̀ ń gbé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n lárugẹ ju tàtẹ̀yìnwá lọ, bẹ́ẹ̀ làwọn tó fara mọ́ èrò pé kò sí Ọlọ́run túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Lójú gbogbo ọ̀ràn tá a kà sílẹ̀ yìí, a ò kàn lè káwọ́ gbera ká máa wòran. A gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti dènà ẹ̀míkẹ́mìí yìí tá a bá fẹ́ dáàbò bo ara wa. Àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká rí bá a ṣe lè ṣe é láṣeyọrí.

11. Bá a bá ń ronú nípa àpẹẹrẹ Jésù, báwo ló ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ ní ìgboyà?

11 Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nínú ayé, ẹ óò máa ní ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòh. 16:33) Kò gbà káyé sọ ohun dà bó ṣe dà. Kò sì gbà káyé ṣí òun lọ́wọ́ iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run gbé lé òun lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò gbà kí ayé sọ òun dẹni tó ń fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìlànà tó ń tẹ̀ lé lórí ìwà tó bójú mu àti ọ̀ràn ìjọsìn mímọ́. Àwa náà kò gbọ́dọ̀ gbà fún ayé. Nígbà tó ń gbàdúrà, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòh. 17:16) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àpẹẹrẹ bí Kristi ṣe jẹ́ onígboyà tá a sì ń ronú jinlẹ̀ lé e lórí, ó máa jẹ́ ká ní ìgboyà tá a nílò láti lè ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé.

Kọ́ Ìgboyà Látara Jésù

12-14. Sọ àwọn àpẹẹrẹ ìgbà tí Jésù lo ìgboyà.

12 Jésù lo ìgboyà tó ga lọ́lá látìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ títí dópin. Ó lo ọlá àṣẹ tó ní gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run, ó fìgboyà “wọ inú tẹ́ńpìlì, ó sì lé gbogbo àwọn tí ń tà, tí wọ́n sì ń rà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì sojú tábìlì àwọn olùpààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tí ń ta àdàbà.” (Mát. 21:12) Nígbà táwọn sójà fẹ́ wá mú un lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó fìgboyà bọ́ síwájú kó bàa lè dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ.” (Jòh. 18:8) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jésù sọ fún Pétérù pé kó dá idà rẹ̀ pa dà síbi tó ti yọ ọ́, ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Jèhófà ni orísun ìgboyà òun kì í ṣe ohun ìjà èyíkéyìí táráyé ṣe.—Jòh. 18:11.

13 Láìbẹ̀rù, Jésù tú àṣírí àwọn olùkọ́ èké ìgbà ayé rẹ̀ tó jẹ́ aláìnífẹ̀ẹ́, ó sì túdìí ẹ̀kọ́ èké wọn. Jésù sọ fún wọn pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorí pé ẹ sé ìjọba ọ̀run pa níwájú àwọn ènìyàn.” Ó fi kún un pé: “Ẹ ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́. . . . Ẹ fọ òde ife àti àwopọ̀kọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n kún fún ìpiyẹ́ àti àìmọníwọ̀n.” (Mát. 23:13, 23, 25) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà máa nílò irú ìgboyà bẹ́ẹ̀ torí pé àwọn aṣáájú ìsìn èké yóò ṣenúnibíni sáwọn pẹ̀lú, wọ́n sì máa pa àwọn kan lára wọn.—Mát. 23:34; 24:9.

14 Jésù tún fìgboyà kojú àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá. Ìgbà kan wà tí ọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù kan wá pàdé rẹ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù tó ń dààmú ọkùnrin yìí jẹ́ kó lágbára débi pé kò sẹ́ni tó lè fi ẹ̀wọ̀n dè é mọ́lẹ̀. Èyí ò ba Jésù lẹ́rù rárá, ńṣe ló lé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ẹ̀mí èṣù tó ti ń darí ọkùnrin yẹn dà nù. (Máàkù 5:1-13) Lóde òní, Ọlọ́run kò fún àwọn Kristẹni lágbára láti ṣerú iṣẹ́ ìyanu yẹn. Síbẹ̀, lẹ́nu ìṣẹ́ ìwàásù wa, àwa náà ní ogun tẹ̀mí tá a ní láti bá Sátánì jà, ìyẹn ẹni tó ti “fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú.” (2 Kọ́r. 4:4) Bíi ti Jésù, ohun ìjà tiwa náà kì í ṣe “ti ara, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ alágbára láti ọwọ́ Ọlọ́run fún dídojú àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé.” (2 Kọ́r. 10:4) “Àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” ni àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké tó ti fìdí múlẹ̀ lọ́kàn àwọn èèyàn. Bá a ṣe ń lo àwọn ohun ìjà tẹ̀mí tí Ọlọ́run ti fún wa yìí, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù.

15. Kí ló mú kí Jésù ní ìgboyà?

15 Ìgbàgbọ́ ló mú kí Jésù lo ìgboyà, kì í ṣe pé ó kàn fẹ́ ṣàyà gbàǹgbà. Bó ṣe yẹ kó rí fáwa náà nìyẹn. (Máàkù 4:40) Báwo la ṣe lè ní ìgbàgbọ́ tó dájú? Àpẹẹrẹ Jésù la ní láti tẹ̀ lé lórí èyí pẹ̀lú. Ó ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́, ó sì fi hàn pé òun nígbàgbọ́ tó kún rẹ́rẹ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀. Idà ti ara kọ́ ni Jésù fi ṣe ohun ìjà rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ idà ti ẹ̀mí, ìyẹn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń lò. Lemọ́lemọ́ ló máa ń fìdí ẹ̀kọ́ rẹ̀ múlẹ̀ nípa bó ṣe máa ń tọ́ka sí Ìwé Mímọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà tó bá fẹ́ sọ̀rọ̀, ó máa ń fi hàn pé ohun tóun sọ wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa sísọ àwọn gbólóhùn bí “a kọ̀wé rẹ̀,” “a kọ ọ́ pé” àti irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. a

16. Báwo la ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ wa pọ̀ sí i?

16 Ká tó lè ní irú ìgbàgbọ́ tó máa jẹ́ ká lè borí àdánwò tó ní láti kojú ẹni tó bá jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, a gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ká máa lọ sípàdé déédéé, ká sì máa jẹ́ kí àwọn òtítọ́ tó jẹ́ ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ máa fìdí múlẹ̀ lọ́kàn wa. (Róòmù 10:17) A tún gbọ́dọ̀ máa ṣàṣàrò, ìyẹn ni pé ká máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tá a ń kọ́, ká jẹ́ kí wọ́n máa wọnú ọkàn wa lọ. Irú ìgbàgbọ́ tó wà láàyè báyìí ló lè mú ká máa fìgboyà ṣe ohun tá a bá ń ṣe. (Ják. 2:17) A tún gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ torí pé ìgbàgbọ́ jẹ́ apá kan èso rẹ̀.—Gál. 5:22.

17, 18. Báwo ni arábìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ṣe lo ìgboyà ní ilé ìwé?

17 Arábìnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Kitty ní ìrírí kan tó fi hàn bí ìgbàgbọ́ tòótọ́ ṣe máa ń jẹ́ kéèyàn nígboyà. Àtikékeré ló ti mọ̀ pé kò yẹ kóun máa “tijú ìhìn rere” níléèwé, ó sì máa ń wù ú láti wàásù lọ́nà tó múnú dóko fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ bíi tiẹ̀. (Róòmù 1:16) Ọdọọdún ló máa ń pinnu pé òun á sọ ìhìn rere náà fáwọn ọmọ ilé ìwé òun, àmọ́ ó ń fà sẹ́yìn torí pé kò nígboyà. Nígbà tó kù díẹ̀ kó pọ́mọ ogún ọdún, ó lọ sí ilé ìwé míì. Ó sọ pé, “Gbogbo àǹfààní láti wàásù tí mi o lò látọjọ́ yìí ni màá lò lọ́tẹ̀ yìí.” Kitty gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun nígboyà bíi Kristi, kó fóun ní òye, kó sì jẹ́ kí àǹfààní náà yọjú.

18 Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tó lò níléèwé, wọ́n ní káwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa sọ orúkọ wọn àtàwọn nǹkan míì nípa ara wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Ọ̀pọ̀ nínú wọn sọ ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe, wọ́n sì fi kún un pé àwọn kì í fi taratara ṣe ẹ̀sìn ọ̀hún. Kitty wá rí i pé àǹfààní tóun ti ń gbàdúrà fún ló yọjú wẹ́rẹ́ yẹn. Nígbà tó dorí tiẹ̀, ó fìgboyà sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, Bíbélì ni mo sì máa ń tẹ̀ lé lórí ọ̀ràn ìjọsìn àti ọ̀ràn ìwà tí mò ń hù.” Bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ńṣe làwọn kan lára àwọn ọmọ iléèwé rẹ̀ ń wò ó ní àwòmọ́jú. Àmọ́ àwọn kan fetí sóhun tó ń sọ wọ́n sì bi í láwọn ìbéèrè kan nígbà tó yá. Kódà, olùkọ́ wọn sọ pé ohun tí Kitty ṣe yẹn ló yẹ káwọn náà máa ṣe tí wọ́n bá ní kí wọ́n wá ṣàlàyé nípa ìgbàgbọ́ wọn. Inú Kitty dùn gan-an pé ó rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ìgboyà Jésù.

Ní Ìgbàgbọ́ àti Ìgboyà bíi Ti Kristi

19. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti ní ojúlówó ìgbàgbọ́? (b) Báwo la ṣe lè mú ọkàn Jèhófà yọ̀?

19 Àwọn àpọ́sítélì náà rí i pé ìgbàgbọ́ ló yẹ kó máa mú káwọn fi ìgboyà ṣe nǹkan. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi bẹ Jésù pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.” (Ka Lúùkù 17:5, 6.) Kéèyàn ní ojúlówó ìgbàgbọ́ kì í ṣe ọ̀ràn kéèyàn kàn gbà pé Ọlọ́run wà. Ó gba pé kéèyàn ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, kò yàtọ̀ sí irú àjọṣe tó máa ń wà láàárín bàbá onínúure àti onífẹ̀ẹ́ kan pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ kékeré. Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti sọ pé: “Ọmọ mi, bí ọkàn-àyà rẹ bá gbọ́n, ọkàn-àyà mi yóò yọ̀, àní tèmi. Àwọn kíndìnrín mi yóò sì yọ ayọ̀ ńláǹlà nígbà tí ètè rẹ bá sọ̀rọ̀ ìdúróṣánṣán.” (Òwe 23:15, 16) Lọ́nà kan náà, yóò múnú Jèhófà dùn tá a bá fìgboyà dúró lórí ìlànà òdodo, èyí á sì túbọ̀ mú ká ní ìgboyà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fara wé Jésù ní gbogbo ìgbà, ká máa dúró lórí ohun tó jẹ́ òdodo!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa jẹ́ onígbọràn nìṣó láìwo ti jíjẹ́ tá a jẹ́ aláìpé?

• Orí kí ni ojúlówó ìgbàgbọ́ dá lé, báwo lèyí sì ṣe lè jẹ́ ká ní ìgboyà?

• Tá a bá jẹ́ onígbọràn tá a sì ní irú ìgboyà tí Kristi ní, kí ló máa tẹ̀yìn rẹ̀ wá?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ṣé ò ń ‘múra ọkàn rẹ sílẹ̀’ láti dènà ìdẹwò?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Bíi ti Jésù, ká máa lo ìgboyà tó dá lórí ìgbàgbọ́