Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Ṣeé Ṣe Láti Nígbàgbọ́ Nínú Ẹlẹ́dàá?

Ṣó Ṣeé Ṣe Láti Nígbàgbọ́ Nínú Ẹlẹ́dàá?

Ṣó Ṣeé Ṣe Láti Nígbàgbọ́ Nínú Ẹlẹ́dàá?

“ŃṢE ni inú máa ń bí mi nígbà tí mo bá ronú pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó lágbára láti gba èèyàn lọ́wọ́ ìnilára, àmọ́ tó kọ̀ tí kò ṣe nǹkan sí i!” Ohun tí ọkùnrin kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ aláìgbọlọ́rungbọ́ tó pàdánù àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ nígbà tí wọ́n pa àwọn èèyàn nípakúpa sọ nìyí. Òun nìkan kọ́ ló nírú èrò yìí.

Nígbà tí àwọn èèyàn bá jìyà nítorí ìwà ìkà tó burú jáì tí àwọn kan ṣokùnfà rẹ̀, ó máa ń ṣòro fún wọn láti gbà pé Ọlọ́run wà, wọ́n sì máa ń tu ara wọn nínú pé Ọlọ́run kò sí. Kí ni àwọn ìdí náà gan-an tí àwọn kan kò fi gba Ọlọ́run gbọ́? Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe rò, ṣó ṣeé ṣe fún èèyàn láti ṣàṣeyọrí láìjẹ́ pé Ọlọ́run tàbí ìsìn lọ́wọ́ sí i? Ṣó ṣeé ṣe fún aláìgbọlọ́rungbọ́ láti nígbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá kan tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́?

Àkóbá Tí Ìsìn Ti Ṣe

Ó yani lẹ́nu láti mọ̀ pé ìsìn gan-an ló fà á tí àwọn èèyàn kò fi gba Ọlọ́run gbọ́. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Alister McGrath ṣàlàyé pé: “Ohun tó mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ di aláìgbọlọ́rungbọ́ ni ìkórìíra tí wọ́n ní fún àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó kún ọwọ́ àwọn onísìn.” Àwọn onísìn ló sábà máa ń wà lẹ́yìn ogun àti ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún Ọ̀gbẹ́ni Michel Onfray tó jẹ́ aláìgbọlọ́rungbọ́ àti onímọ̀ ọgbọ́n orí pé ìwé ìsìn kan ṣoṣo lè máa darí oríṣi àwùjọ èèyàn méjì, tí àwọn kan ń “sapá láti jẹ́ ẹni mímọ́,” tí àwọn kan sì ń “hùwà tó burú jáì,” irú bí ìpániláyà.

Ọ̀pọ̀ ló máa ń kábàámọ̀ tí wọ́n bá rántí ohun tí ìsìn ti fi ojú wọn rí. Lákòókò tí Ọ̀gbẹ́ni Bertil tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Sweden ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ ológun, ó gbọ́ bí àlùfáà kan tó máa ń gbàdúrà fún àwọn ọmọ ogun ṣe fi ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé, àwọn tó bá mú idà máa ṣègbé nípa idà ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn pé, kò sóhun tó burú nínú ìwà ipá. Àlùfáà yẹn sọ pé, àwọn kan gbọ́dọ̀ lo idà, torí náà, ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni àwọn sójà!—Mátíù 26:52. a

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Bernadette tí wọ́n pa bàbá rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Faransé nígbà ogun àgbáyé kejì rántí bí ọ̀rọ̀ tí àlùfáà kan sọ nígbà ìsìnkú ọmọ ọdún mẹ́ta tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ ṣe múnú bí i, àlùfáà yẹn sọ pé: “Ọlọ́run ti pe ọmọ náà sọ́dọ̀ láti wá di áńgẹ́lì.” Nígbà tó yá, Bernadette náà bí abirùn ọmọ, kò sì sí ìkankan nínú àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ tó tù ú nínú.

Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Ciarán tí wọ́n tọ́ dàgbà lákòókò tí ìwà ipá gbòdekan ní àríwá ilẹ̀ Ireland kórìíra ìsìn nítorí ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì tí wọ́n fi ń kọ́ni. Ó tiẹ̀ máa ń sọ pé, òun kórìíra Ọlọ́run èyíkéyìí tó bá lè hu irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀, ó tún máa ń pe Ọlọ́run níjà pé, tí Ọlọ́run bá wà, kó lu òun pa. Kì í ṣe Ciarán nìkan ló kórìíra àwọn ẹ̀kọ́ èké tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni. Ká sòótọ́, àwọn ẹ̀kọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì gan-an ló mú kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í nígbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni Alister McGrath ṣe sọ, “ìkórìíra” tí Darwin ní fún ẹ̀kọ́ ọ̀run àpáàdì ló jẹ́ kó máa ṣiyèméjì pé bóyá ni Ọlọ́run wà, kì í ṣe ìgbàgbọ́ tó ní nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Ọ̀gbẹ́ni McGrath tún sọ bí “ìbànújẹ́ ṣe dorí Darwin kodò nígbà tí ọmọbìnrin rẹ̀ kú.”

Lójú àwọn kan, àwọn aláìnírònú àtàwọn onítara òdì ló máa ń ṣe ìsìn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Irina táwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tí kò nítumọ̀ àtàwọn àdúrà tí wọ́n máa ń gbà lágbà-tún-gbà ti tojú sú sọ pé: “Lójú mi, ó dà bí ẹni pé àwọn ẹlẹ́sìn kò ní àròjinlẹ̀.” Ohun tí àwọn agbawèrèmẹ́sìn ń ṣe kó Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Louis nírìíra, ìyẹn sì mú kí inú rẹ̀ túbọ̀ máa ru sáwọn onísìn, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti rí ìsìn gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní láárí, àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo túbọ̀ wá rí i pé ìsìn kò bọ́gbọ́n mu. Torí náà, inú ń bí mi sí gbogbo ìsìn, mo sì ń ta kò wọ́n.”

Ṣé Àwọn Èèyàn Lè Ṣàṣeyọrí Láìsí Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run?

Kò yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ló rí ìsìn gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń ṣèdíwọ́ fún ìlọsíwájú àti àlàáfíà ẹ̀dá èèyàn. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń ronú pé ẹ̀dá èèyàn lè ṣàṣeyọrí láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run àti ìsìn. Àmọ́, ṣé èrò pé kí èèyàn pa ìsìn tì kò ní lẹ́yìn báyìí?

Ọ̀gbẹ́ni Voltaire tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n èrò orí tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kejìdínlógún fi ẹ̀hónú hàn nítorí ìwà ìbàjẹ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó wà nígbà ayé rẹ̀. Síbẹ̀, ó sọ pé Ẹni Gíga Jù Lọ kan ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ mọ ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Nígbà tó yá, Ọ̀gbẹ́ni Friedrich Nietzsche tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n èrò orí ọmọ ilẹ̀ Jámánì sọ gbàǹgbàgbangba pé Ọlọ́run ti kú, àmọ́ ẹ̀rù ń bà á pé ìyẹn lè mú kí ìwà ọmọlúwàbí pòórá, ewu tó sì lè tìdí rẹ̀ yọ kò fi í lọ́kàn balẹ̀. Ṣé ìbẹ̀rù yìí wá yanjú ohun tó wà nílẹ̀?

Ọ̀gbẹ́ni Keith Ward tó jẹ́ òǹkọ̀wé kíyè sí pé, nígbà tí ẹ̀dá èèyàn wọ àkókò ọ̀làjú, ìwà ojú dúdú kò dín kù, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni “ìwà yìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i lọ́nà tá ò rò tẹ́lẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, gbogbo nǹkan tí àwọn aláìgbọlọ́rungbọ́ ti ṣe kò ṣàtúnṣe ìwà ìbàjẹ́ àti àìrára gba nǹkan sí tó wọ́pọ̀ láàárín ọmọ èèyàn. Èyí ti mú kí àwọn tó láròjinlẹ̀ àtàwọn aláìgbọlọ́rungbọ́ pàápàá rí i pé àǹfààní wà nínú gbígbà pé Ọlọ́run wà.

Ọ̀gbẹ́ni Keith Ward sọ àǹfààní tó wà nínú gbígbà Ọlọ́run gbọ́, ó ní: “Ìgbàgbọ́ máa ń mú kí èèyàn fẹ́ láti máa hùwà ọmọlúwàbí nígbà gbogbo, èyí sì ṣe pàtàkì láti bójú tó ayé tí Ọlọ́run dá yìí.” Ọ̀pọ̀ ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé, àìmọtara-ẹni-nìkan ń pọ̀ sí i láàárín àwọn ẹlẹ́sìn. Àìmọtara-ẹni-nìkan yìí sì ń jẹ́ kí àwọn èèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn. Àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe yìí fìdí ohun tí Jésù sọ múlẹ̀ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ aláìgbọlọ́rungbọ́, nígbà tó rí agbára tí Bíbélì ní láti yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà. Ó ní: “Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti fi gbìyànjú láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jáwọ́ nínú ohun tó lè ṣèpalára fún àwọn àtàwọn ẹlòmíì, síbẹ̀ àṣeyọrí tí mo ṣe kò tó nǹkan, àmọ́ ó jọ mí lójú láti rí bí ìgbésí ayé àwọn èèyàn ṣe ń yí pa dà tìrọ̀rùntìrọ̀rùn. Mo tún rí i pé, wọn kì í pa dà sídìí ohun tí wọn ti fi sílẹ̀.”

Síbẹ̀, lójú àwọn aláìgbọlọ́rungbọ́ kan, ìpakúpa àti ìṣòro tó pọ̀ ni ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ti fà tá a bá fi wéra pẹ̀lú kí èèyàn kàn máa ṣe rere, kó sì jẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan láìgba Ọlọ́run gbọ́. Lóòótọ́, àwọ́n aláìgbọlọ́rungbọ́ yìí rí ipa rere tí òtítọ́ ní nígbèésí ayé àwọn èèyàn kan, síbẹ̀, wọn kò fi taratara gbà gbọ́. Kí nìdí?

Àwọn Nǹkan Míì Tó Fa Àìnígbàgbọ́

Ohun tí wọ́n kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé, òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Bí àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè Alibéníà ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Anila ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kò sí. Ó sọ pé: “Ohun tí wọ́n kọ́ wa ní ilé ìwé ni pé, àwọn tí kò lajú, tí wọn kò sì mọ ohun tó ń lọ ló máa ń gba Ọlọ́run gbọ́. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń kọ́ nǹkan àgbàyanu nípa ewéko àtàwọn ohun ẹlẹ́mìí, àmọ́ ẹfolúṣọ̀n ni mo máa ń gbóṣùbà fún lórí àwọn nǹkan yìí, torí èyí ló máa jẹ́ ká nímọ̀lára pé èrò wa àti ti àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ dọ́gba.” Àmọ́ ní báyìí, ohun tí obìnrin yìí sọ ni pé, “ńṣe la kàn tẹ́wọ́ gba àwọn àwárí tí wọ́n ṣe láìronú jinlẹ̀.”

Inú tó ń bí àwọn kan lè mú kí wọ́n má fàyè sílẹ̀ fún òótọ́ ọ̀rọ̀. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń bá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ pàdé nígbà tá a bá ń wàásù ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la láti ilé-dé-ilé. Nígbà tí ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan lọ sílé Ọ̀gbẹ́ni Bertil tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, Bertil rántí pé òun sọ lọ́kàn ara òun pé: ‘Máa wo onírèégbè yìí. O kò mọ ibi tó yẹ kó o wá!’ Ó sọ pé: “Mo jẹ́ kó wọlé, mo sì wá da ìbéèrè tí mo ní nípa Ọlọ́run, Bíbélì àti ìsìn bò ó.”

Àìsídàájọ́ òdodo máa ń múnú bí Ọ̀gbẹ́ni Gus, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Scotland. Nígbà kan rí, ó máa ń jiyàn gan-an tó bá ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀, kì í sì í fún wọn láyè. Ó béèrè àwọn ìbéèrè bíi ti wòlíì Hébérù kan tó ń jẹ́ Hábákúkù, ẹni tó sọ pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, tí ìwọ sì ń wo èkìdá ìdààmú?”—Hábákúkù 1:3.

Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn èèyàn tún ti ń kọminú sí bó ṣe dà bíi pé Ọlọ́run kò ka ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ sí. (Sáàmù 73:2, 3) Òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tó ń jẹ́ Simone de Beauvoir sọ nígbà kan pé: “Ó rọrùn fún mi láti ronú pé ayé yìí wà láìsí ẹlẹ́dàá ju kí n gbà pé ẹlẹ́dàá wà pẹ̀lú bí ayé ṣe dojú rú.”

Àmọ́, ṣé bí àwọn ìsìn ṣe kùnà láti ṣàlàyé ohun tó fà á tí nǹkan fi dojú rú yìí wá túmọ̀ sí pé kò àlàyé kankan? Ọ̀gbẹ́ni Gus sọ pé, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, òun rí “àlàyé tó tẹ́ni lọ́rùn sí ìdí tí Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ alágbára gbogbo fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá èèyàn látìgbà yìí wá.” Ó wá sọ pé, “ìgbésẹ̀ pàtàkì lèyí jẹ́ fún mi.” b

Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan tí wọ́n sọ pé àwọn kò gbà pé Ọlọ́run wà máa ṣiyèméjì nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, kí wọ́n máa rò ó pé ó yẹ kí Ọlọ́run lọ́wọ́ nínú ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé àwọn, wọ́n tiẹ̀ lè gbàdúrà pàápàá. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tó mú kí àwọn kan tó jẹ́ aláìgbọlọ́rungbọ́ àtàwọn onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀ ronú jinlẹ̀, tí wọ́n sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn.

Kí Ló Jẹ́ Kí Wọ́n Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Nígbàgbọ́ Nínú Ẹlẹ́dàá?

Ọ̀dọ́kùnrin Ẹlẹ́rìí tó lọ wàásù fún Bertil ràn án lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀, ó fi hàn án pé ìyàtọ̀ kékeré kọ́ ló wà láàárín ìsìn Kristẹni tòótọ́ àti ohun tí àwọn tó pera wọn ní Kristẹni ń ṣe. Yàtọ̀ sí àlàyé tí arákùnrin yìí ṣe pé Ẹlẹ́dàá kan wà, Bertil sọ ohun tó dùn mọ́ ọn nínú, ó ní: “Inú mi dùn gan-an fún bó ṣe fi sùúrù bá mi sọ̀rọ̀ láìka orí kunkun mi sí. . . . Ara rẹ̀ balẹ̀ gan-an, gbogbo ìgbà ló máa ń fún mi ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ó sì máa ń múra ohun tó bá fẹ́ kọ́ mi dáadáa.” c

Ìgbàgbọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Svetlana, tí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n àti ètò ìjọba Kọ́múníìsì ti nípa lórí rẹ̀ ni pé àwọn alágbára nìkan ló lè gbáyé. Torí náà, àwọn nǹkan burúkú yìí dà á láàmú gan-an. Àmọ́ ohun tó kọ́ nílé ẹ̀kọ́ ìṣègùn tún dá kún iyèméjì rẹ̀, ó ní: “Nígbà tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kò sí, wọ́n kọ́ wa pé àwọn alágbára nìkan ló lè gbáyé. Àmọ́ nínú ẹ̀kọ́ nípa ìṣègùn, wọ́n kọ́ wa pé a gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìlera.” Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó kọ́, ìyàlẹ́nu ló tún jẹ́ fún un pé èèyàn tó wá látara ọ̀bọ ń ní ìdààmú ọkàn, èyí tí àwọn ọ̀bọ fúnra wọn kò ní. Ibi tí kò fọkàn sí rárá ló ti rí àlàyé sí àwọn nǹkan tó ta ko ara wọn yìí, ó ní: “Màmá màmá mi ló ṣàlàyé fún mi látinú Bíbélì pé àìpé wa ló fa ìdààmú ọkàn tá a máa ń ní.” Inú Svetlana tún dùn láti rí ìdáhùn Bíbélì sí ìdí tí àwọn olóòótọ́ èèyàn fi ń jìyà.

Ọmọ ilẹ̀ Scandinavian tó ń jẹ́ Leif ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ó sì ka Bíbélì sí ìtàn àròsọ lásán. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan bi í ní ìbéèrè lórí ohun tó gbà gbọ́ pé: “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ohun tí àwọn kan tí sọ lò ń tún sọ, láìmọ ohunkóhun nípa Bíbélì?” Nígbà tí Leif ń sọ ipa tí ọ̀rọ̀ yìí ní lórí rẹ̀, ó ní: “Mo rí i pé ńṣe ni mo kàn ń tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n láìṣe ìwádìí kankan. . . . Mo ronú pé, ìmọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì àti bí wọ́n ṣe nímùúṣẹ wà lára ohun tó lè ran àwọn aláìgbọlọ́rungbọ́ lọ́wọ́ láti tún èrò wọn ṣe.”—Aísáyà 42:5, 9.

Ìjákulẹ̀ ni Ọ̀gbẹ́ni Ciarán tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí ní fún ọ̀pọ̀ ọdún tó fi lọ́wọ́ nínú ìṣèlú. Nígbà tó ń ronú lórí ìgbésí ayé, èrò yìí wá sí i lọ́kàn pé: Ọlọ́run alágbára, tó sì nífẹ̀ẹ́ nìkan ló lè yanjú ìṣòro tó dojú kọ ayé, òun ló sì lè ran òun lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà àbájáde nínú ewu tóun wà. Ó wá kédàárò pé: ‘Ó mà ṣe o, báwo ni kò bá ti dùn tó kí n mọ irú Ọlọ́run yìí.’ Ó fi ẹ̀dùn ọkàn gbàdúrà pé: “Tó o bá ń gbọ́ mi, jọ̀wọ́ fọ̀nà àbájáde hàn mí kúrò lọ́wọ́ bí ìgbésí ayé mi ṣe dojú rú yìí, kó o sì gba ọmọ aráyé lọ́wọ́ ìnira.” Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ilẹ̀kùn ilé rẹ̀. Ẹlẹ́rìí yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa orísun ìwà ibi tó wà lẹ́yìn ìṣàkóso ẹ̀dá èèyàn. (Éfésù 6:12) Àlàyé yìí fìdí ohun tó jẹ́ ojú ìwòye Ọ̀gbẹ́ni Ciarán múlẹ̀, ó sì wá jẹ́ kó fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i. Bó ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìṣó nínú Bíbélì, ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lágbára.

Àjọṣe Rẹ àti Ẹlẹ́dàá Aráyé

Àgàbàgebè àwọn onísìn, ẹ̀kọ́ àwọn aláìgbọlọ́rungbọ́ irú bí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n àti ìwà ìbàjẹ́ tó kún inú ayé, ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣiyèméjì tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa sọ pé kò sí Ẹlẹ́dàá. Àmọ́ tó o bá yọ̀ǹda, Bíbélì lè fún ẹ ní ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sáwọn ìbéèrè rẹ. Ó tún jẹ́ ká mọ èrò Ọlọ́run, “àwọn èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti ìyọnu àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.” (Jeremáyà 29:11) Ní ti Bernadette tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí pé ó bí ọmọ abirùn, tó sì tún ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Ẹlẹ́dàá kan wà, ìrètí yìí ló tù ú nínú.

Àlàyé Bíbélì nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà wọ ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn tó ti fìgbà kan rí jẹ́ aláìgbọlọ́rungbọ́. Tó o bá wáyè láti wá ìdáhùn Bíbélì sírú àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí, ìwọ náà lè wá gbà pé Ọlọ́run kan wà lóòótọ́, “kò [sì] jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:27.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ti bóyá ó yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ máa lọ́wọ́ nínú ogun jíjà, wo àpilẹ̀kọ náà, “Ṣó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Jagun?” lójú ìwé 29 sí 31.

b Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, kà nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi, lójú ìwé 106 sí 114 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

c Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa ìṣẹ̀dá, ka ojú ìwé 20 sí 23 àti ojú ìwé 28 sí 30 nínú Ji! October—December 2006. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwọn Ìbéèrè Tí Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Kò Dáhùn

• Báwo ni nǹkan ẹlẹ́mìí ṣe lè wá láti inú nǹkan aláìlẹ́mìí?—SÁÀMÙ 36:9.

• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé irú tiwọn nìkan ni ẹranko àti ewéko ń mú jáde?—JẸ́NẸ́SÍSÌ 1:11, 21, 24-28.

• Bó bá jẹ́ pé látara ọ̀bọ lásán-làsàn làwa èèyàn ti wá, kí ló dé tí kò sí ìnàkí-èèyàn kankan tó ṣẹ́ kù lára àwọn ìnàkí tí wọ́n sọ pé ó di èèyàn?—SÁÀMÙ 8:5, 6.

• Báwo ni àìmọtara-ẹni-nìkan àti ẹ̀kọ́ pé àwọn alágbára ló lè gbáyé ṣe bára mu?—RÓÒMÙ 2:14, 15.

• Ṣé ẹ̀dá èèyàn nírètí kankan tó dájú nípa ọjọ́ ọ̀la?—SÁÀMÙ 37:29.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Báwo ni Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ṣe lè dá ayé kan nínú èyí tí àwọn ọmọdé ti ń jìyà?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni àgàbàgebè àwọn onísìn ti mú kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run