Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican Fi Ṣeyebíye?

Kí Nìdí Tí Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican Fi Ṣeyebíye?

Kí Nìdí Tí Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican Fi Ṣeyebíye?

IBÙJÓKÒÓ Ìjọba Póòpù tí wọ́n ń pè ní Vatican ní àwọn ohun tó ṣeyebíye. Àwọn àwòrán tí wọ́n yà sára ògiri àti èyí tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri àti bí wọ́n ṣe kọ́ àwọn ilé tó wà níbẹ̀ lẹ́wà gan-an, ó sì buyì kún wọn. Síbẹ̀, ó tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tó fi jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló làǹfààní láti rí ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣeyebíye jù lọ tó wà níbẹ̀. Ìwé àfọwọ́kọ kan tó ṣeyebíye wà tí wọ́n fi pa mọ́ sí Ibi Ìkówèésí Ti Ìjọba Póòpù tó jẹ́ ká túbọ̀ ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa àwọn apá kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ti wà lákọọ́lẹ̀ láti nǹkan bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Wọ́n máa ń pè é ní Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican. a

Ìtàn míì tó tún fani lọ́kàn mọ́ra ni ìtàn nípa bí wọ́n ṣe ṣàwárí ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ méjì tí wọ́n ń pè ní Alexandrine àti Sinaitic àti bí wọn kò ṣe jẹ́ kí àwọn ìwé yìí pa run, wọ́n ti wà tipẹ́tipẹ́, àwọn ọ̀mọ̀wé sì mọyì wọn gan-an. Àmọ́, ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ la mọ̀ nípa orísun Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican.

Ìṣúra Iyebíye Tó Fara Sin

Níbo ni Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican ti wá? Ìwádìí fi hàn pé ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n kọ́kọ́ sọ nípa ìwé yìí nínú ìwé àkọsílẹ̀ tó wà ní Ibi Ìkówèésí Ti Ìjọba Póòpù. Àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Íjíbítì, Kesaréà tàbí Róòmù pàápàá ni wọ́n ti ṣe é. Àmọ́, lẹ́yìn tí ọ̀jọ̀gbọ́n J.  Neville Birdsall tó wà ní Yunifásitì ìlú Birmingham ní ilẹ̀ England gbé àwọn ohun tí wọ́n sọ yìí yẹ̀ wò, ó sọ pé: “Ní kúkúrú, a kò lè sọ ní pàtó pé ọjọ́ báyìí ni wọ́n kọ Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican tàbí ibi báyìí ló ti wá, kódà akitiyan àwọn ọ̀mọ̀wé gan-an kò lè jẹ́ ká mọ ìtàn èyíkéyìí nípa rẹ̀ ṣáájú ọ̀rúndún kẹrìndínlógún.” Síbẹ̀, Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican ni wọ́n pè ní ọ̀kan lára ìwé tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwọn ìwé Bíbélì aláfọwọ́kọ tó wà lójú kan. Kí nìdí?

Bọ́dún ti ń gorí ọdún, àwọn adàwékọ kan ṣàṣìṣe bí wọ́n ti ń ṣe àdàkọ Bíbélì náà. Ìṣòro àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n fẹ́ tú Bíbélì láti orísun tó péye ni bí wọ́n ṣe máa rí ìwé àfọwọ́kọ tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ bá ti Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu. Torí náà, wo bí àwọn ọ̀mọ̀wé á ṣe máa hára gàgà tó láti ṣàyẹ̀wò Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican, ìyẹn ìwé àfọwọ́kọ èdè Gíríìkì tí wọ́n kọ ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Kristẹni ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n kọ Bíbélì tán. Gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ló wà nínú ìwé àfọwọ́kọ yìí, àyàfi àwọn apá kọ̀ọ̀kan tó ti sọnù bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́.

Dípò kí àwọn aláṣẹ Ìjọba Póòpù jẹ́ kí ìwé àfọwọ́kọ yìí wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn atúmọ̀ Bíbélì, wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é ní àṣírí fún ọ̀pọ̀ ọdún. Alàgbà Frederic Kenyon tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú títúmọ̀ àkọ́sílẹ̀ ìwé àtijọ́ sọ pé: “Lẹ́yìn tí [ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan tó ń jẹ́ Konstantin von] Tischendorf ti dúró fún ọ̀pọ̀ oṣù lọ́dún 1843, wọ́n gbà á láyè láti rí ìwé àfọwọ́kọ náà fún wákàtí mẹ́fà. . . . Lọ́dún 1845, wọ́n gba ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Tregelles láyè láti rí i àmọ́ wọn kò jẹ́ kó da ẹyọ ọ̀rọ̀ kan kọ nínú rẹ̀.” Ọ̀gbẹ́ni Tischendorf gbàṣẹ láti rí ìwé àfọwọ́kọ yẹn lẹ́ẹ̀kan sí i, àmọ́ wọn kò fún un láyè mọ́ lẹ́yìn tó ti ṣàdàkọ ogún [20] abala nínú ìwé náà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Kenyon sọ, “torí pé Ọ̀gbẹ́ni Tischendorf kò jáwọ́ láti máa gbàṣẹ kó lè rí ìwé náà, wọ́n fún un láǹfààní ọjọ́ mẹ́fà mìíràn láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀, àpapọ̀ ọjọ́ tó sì lò jẹ́ ọjọ́ mẹ́rìnlá tá a bá fi wákàtí mẹ́ta ṣe ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, àmọ́ torí pé ó fọgbọ́n lo àkókò tó ní yìí, ó ṣeé ṣe fún un lọ́dún 1867 láti tẹ ẹ̀dà ìwé àfọwọ́kọ tí kò ní àṣìṣe èyíkéyìí jáde. Ẹ̀dà náà ṣì wà títí dòní.” Nígbà tó yá àwọn aláṣẹ Ìjọba Póòpù jẹ́ kí àwọn èèyàn láǹfààní láti máa rí ẹ̀dà tó péye nínú ẹ̀dà ìwé àfọwọ́kọ náà.

Wọ́n Fara Balẹ̀ Kọ Ọ́’

Irú àwọn ọ̀rọ̀ wo ló wà nínú Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican? Ìwé The Oxford Illustrated History of the Bible sọ pé, “àwọn ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ péye, àwọn tó sì ṣe àdàkọ rẹ̀ ṣe é lọ́nà tó pé pérépéré, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ẹ̀dà ìwé tó péye jáde látinú rẹ̀.” Ìwé yẹn ń bá a lọ pé: “Torí náà, a lè parí èrò sí pé ìwé yìí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé adàwékọ tó mọṣẹ́ náà dunjú.”

Àwọn ọ̀mọ̀wé pàtàkì méjì tí wọ́n dìídì jàǹfààní Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican ni B. F. Westcott àti F.J.A. Hort. Àwọn Ọ̀gbẹ́ni yìí gbé Bíbélì tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní New Testament in the Original Greek, jáde ní ọdún 1881, inú Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican àti Sinaitic ni wọ́n sì ti tú u, Bíbélì wọn ni ọ̀pọ̀ atúmọ̀ èdè ṣì ń lò láti fi tú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó wà lónìí, títí kan The Emphasised Bible, látọwọ́ J. B. Rotherham, àti Bíbélì New World Translation.

Àmọ́, àwọn aṣelámèyítọ́ kan rò pé àṣìṣe ni Ọ̀gbẹ́ni Westcott àti Ọ̀gbẹ́ni Hort ṣe bí wọ́n ṣe gbára lé Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican. Ṣé ìwé àfọwọ́kọ yẹn gbé ohun tó wà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ jáde lọ́nà tó pé pérépéré? Ìwé kan tí Ọ̀gbẹ́ni Bodmer kọ sórí òrépèté láàárín ọdún 1956 sí ọdún1961 wúlò gan-an fún àwọn ọ̀mọ̀wé torí pé ìwé Lúùkù àti ìwé Jòhánù wà nínú òrépèté yẹn, wọ́n sì ti kọ àwọn ìwé Bíbélì yìí láti ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Kristẹni. Ṣé ohun tó wà lórí òrépèté yìí máa wá bá ohun tó wà nínú Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican mu?

Ọ̀gbẹ́ni Philip B. Payne àti Paul Canart nínú ìwé tí wọ́n pè ní Novum Testamentum sọ pé: “Ìjọra tó yani lẹ́nu ló wà nínú Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican àti ọ̀rọ̀ tí Ọ̀gbẹ́ni Bodmer kọ sórí òrépèté. Torí ìjọra yìí, ó bọ́gbọ́n mu tá a bá parí èrò sí pé ẹni tó dìídì ṣàdàkọ Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican ṣàdàkọ ìwé tó sún mọ́ èyí tí Ọ̀gbẹ́ni Bodmer kọ sórí òrépèté. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwé àfọwọ́kọ tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ gan-an tàbí àdàkọ ìwé yìí ni adàwékọ náà lò.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Birdsall sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé àfọwọ́kọ méjèèjì sún mọ́ra gan-an. . . . Wọ́n fara balẹ̀ ṣàdàkọ [Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican]: àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fara balẹ̀ kọ látinú ibi tí wọ́n ti ṣàdàkọ rẹ̀.”

Ó wúlò Fáwọn Atúmọ̀ Èdè

Lóòótọ́ kì í ṣe bí ìwé àfọwọ́kọ kan bá ṣé pẹ́ tó ni wọ́n fi ń díwọ̀n bí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ á ṣe bára mu pẹ̀lú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Àmọ́ ṣá o, Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican àti àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì ti ran àwọn ọ̀mọ̀wé lọ́wọ́ gan-an láti mọ ohun tó wà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, kò sí èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìwé tó jẹ́ ìwé ìtàn irú bíi ìwé Jẹ́nẹ́sísì sí Kíróníkà Kínní nínú àwọn apá tó ṣẹ́ kù lára Ìwé Àfọwọ́kọ Sinaitic tí wọ́n gbé jáde ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ wíwà tí àwọn ìwé yìí wà nínú Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican jẹ́ kó dájú pé ibi tó yẹ ni wọ́n wà nínú Bíbélì.

Ìwé The Oxford Illustrated History of the Bible sọ pé, “apá ibi tó sọ bá a ṣe máa dá Kristi mọ̀ àti èyí tó sọ̀rọ̀ nípa Mẹ́talọ́kan” sábà máa ń dá àríyànjiyàn sílẹ̀ láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé. Báwo ni Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican ṣe jẹ́ kí àlàyé àwọn apá ibí yìí ṣe kedere?

Kíyè sí àpẹẹrẹ yìí. Bó ṣe wà nínú ìwé Jòhánù 3:13, Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó sọ kalẹ̀ láti ọ̀run, Ọmọ ènìyàn.” Àwọn atúmọ̀ Bíbélì kan ti fi gbólóhùn náà, “[ẹni] tó wà ní ọ̀rún,” kún ẹsẹ yìí. Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi kún un yìí ń fi hàn pé Jésù wà ní ọ̀run àti ayé nígbà kan náà, èyí sì ti ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan lẹ́yìn. Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi kún un yìí fara hàn nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan tí wọ́n kọ ní ọ̀rúndún kárùn-ún sí ìkẹwàá Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ yìí kò ṣe sí nínú àwọn Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican àti Sinaitic, tó ti wà tipẹ́, jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè òde òní yọ ọ́ kúrò. Èyí yanjú àríyànjiyàn tó wà nípa bá a ṣe lè dá Kristi mọ̀, ó sì bá àwọn Ìwé Mímọ́ tó kù mu. Dípò kó wà níbi méjì lẹ́ẹ̀kan náà, Jésù láti ọ̀rún, ó ti pa dà sọ́run, ó sì ti “gòkè lọ” sọ́dọ̀ Baba rẹ̀.—Jòhánù 20:17.

Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican tún jẹ́ ká lóye àwọn ẹsẹ tó sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Wo àpẹẹrẹ kan. Bó ṣe wà nínú Bibeli Mimọ, àpọ́sítélì Pétérù sọ tẹ́lẹ̀ pé, “aiye ati awọn iṣẹ ti o wà ninu rẹ̀ yio si jóna lulu.” (2 Peteru 3:10) Bí àwọn Bíbélì míì, tí wọ́n tú látinú Ìwé Àfọwọ́kọ Alexandrine ti ọ̀rúndún karùn-ún àti àwọn àdàkọ rẹ̀ tí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà, ṣe kà nìyẹn. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń fi tọkàntọkàn ka Bíbélì fi parí èrò sí pé Ọlọ́run máa pa ilẹ̀ ayé run.

Àmọ́, ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kan ṣáájú kí wọ́n tó gbé Ìwé Àfọwọ́kọ Alexandrine jáde, Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican (àti akẹgbẹ́ rẹ̀, ìyẹn Ìwé Àfọwọ́kọ Sinaitic) sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí Pétérù sọ lọ́nà yìí, “ayé àtàwọn iṣẹ́ tó wà nínú rẹ̀ ni a ó sì wá rí.” Ṣé èyí bá àwọn Bíbélì tó kù mu? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni! Ayé tá à ń gbé yìí ni a “kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Báwo wá ni wọ́n á ṣe “wá” ilẹ̀ ayé “rí”? Àwọn Ìwé Mímọ̀ tó kù jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n lè lo ọ̀rọ̀ náà “ayé” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. “Ilẹ̀ ayé” lè sọ èdè kan, ó sì lè kọ orin. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1; Sáàmù 96:1) Torí náà, “ilẹ̀ ayé” lè dúró fún ẹ̀dá èèyàn tàbí àwùjọ èèyàn. Ìtùnú ló jẹ́ láti mọ̀ pé Ọlọ́run kò ní pa ilẹ̀ ayé wa yìí run, àmọ́ ó máa tú ìwà ibi fó pátápátá, ó sì máa mú òpin dé bá ìwà ibi àti àwọn tó ń hùwà ibi.

“Yóò Wà fún Àkókò Tí Ó Lọ Kánrin”

Ó ṣeni láàánú pé wọn kò jẹ́ kọ́wọ́ àwọn èèyàn tẹ Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, èyí kò sì jẹ́ kí àwọn tó ń ka Bíbélì lóye òtítọ́ nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì kan. Àmọ́, látìgbà tí wọ́n ti tẹ Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican jáde, òun àtàwọn ìtúmọ̀ Bíbélì tó wà lóde òní tó ṣeé gbára lé ti ran àwọn tó ń fi tọkàntọkàn wá òtítọ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì kọ́ni.

Àwọn adàwékọ ìgbàanì sábà máa ń fi ọ̀rọ̀ yìí kún ìwé àfọwọ́kọ wọn pé: “Ọwọ́ tó kọ ìwé [yìí] ti jẹrà nínú sàréè, àmọ́ ohun tí wọ́n kọ wà fún ọ̀pọ̀ ọdún.” A mọrírì iṣẹ́ takun-takun tí àwọn adàwékọ yìí ṣe, bá ò tiẹ̀ mọ̀ wọ́n. Àmọ́ Òǹṣèwé Bíbélì ni ọpẹ́ tó ga jù lọ tọ́ sí fún bí Bíbélì ṣe wà títí dòní, ẹni tó mí sí wòlíì rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ pé: “Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ; ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Aísáyà 40:8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wọ́n tún máa ń pe Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican ní Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican 1209 tàbí Ìwé Àfọwọ́kọ Vaticanus, “B” sì ni ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé máa ń lò tí wọ́n bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Òun ni ìwé àfọwọ́kọ alábala tó kọ́kọ́ wà ṣáájú àwọn ìwé tó wà lóde òní. Wo “Bíbélì Di Odindi Ìwé Ó Kúrò Ní Àkájọ Ìwé, Ó Di Ìwé Alábala,” nínú ẹ̀dà ìwé ìròyìn yìí ti June 1, 2007.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]

Bí Wọ́n Ṣe Ń Mọ Ìgbà Tí Wọ́n Kọ Àwọn Ìwé Àfọwọ́kọ Ìgbàanì

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn adàwékọ kan ṣàkọsílẹ̀ ìgbà tí wọ́n parí iṣẹ́ wọn, ọ̀pọ̀ àwọn ìwé àfọwọ́kọ ti èdè Gíríìkì kò ní irú àwọn ìsọfúnni yìí. Báwo ni àwọn ọ̀mọ̀wé ṣe wá ń mọ ìgbà tí wọ́n ṣàdàkọ àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì? Bí èdè àti iṣẹ́ ọnà ṣe máa ń yàtọ̀ láti àkókò kan sí òmíràn, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà ìgbàkọ̀wé náà ṣe máa ń yàtọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn lẹ́tà gàdàgbà gàdàgbà tí wọ́n máa ń tẹ̀ kọrọdọ lórí tí àwọn ìlà ọ̀rọ̀ wọn sì máa ń dọ́gba ni wọ́n ń lò ní ọ̀rúndún kẹrin, bí wọ́n sì ṣe ń lò ó nìyẹn fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Àwọn ọ̀mọ̀wé lè túbọ̀ sọ ìgbà tí wọ́n kọ àwọn ìwé àfọwọ́kọ ìgbàanì, tí wọ́n bá fara balẹ̀ ṣàfiwéra àwọn ìwé onílẹ́tà gàdàgbà tí kò ní àkókò tí wọ́n kọ wọ́n pẹ̀lú àwọn ìwé tó lákòókò tí wọ́n kọ wọ́n.

Àmọ́, ó níbi tí wọ́n lè gbára lé èyí mọ. Ọ̀gbẹ́ni Bruce Metzger tó jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìsìn Princeton kíyè sí pé: Níwọ̀n bó ti ṣeé ṣe kí ọ̀nà tẹ́nì kan gbà ń kọ̀wé rí bákan náà títí tí onítọ̀hún fi máa kú, a jẹ́ pé kò bọ́gbọ́n mu láti fi ọdún tó kéré sí àádọ́ta [50] pinnu ọ̀nà ìgbàkọ̀wé kan. Látinú àwọn àlàyé tí wọ́n fara balẹ̀ ṣe yìí, àwọn ọ̀mọ̀wé fi ohùn ṣọ̀kan pé ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican.